ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 4/8 ojú ìwé 14-15
  • Bí A Ṣe Kọ́ Kristi Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí A Ṣe Kọ́ Kristi Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Kristi Ṣe Relé Ìwé
  • ‘Àwọn Ìbéèrè Inú Ọkàn-Àyà Wa’
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2004
  • Ohun Tó Mú Kí Ìgbésí Ayé Wa Nítumọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Wọn Kò Bẹ̀rù Òpin Ayé Mọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Máa Ṣìkẹ́ Àwọn Arákùnrin àti Arábìnrin Rẹ Tó Jẹ́ Adití!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 4/8 ojú ìwé 14-15

Bí A Ṣe Kọ́ Kristi Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run

ỌDÚN 1977 la bí ọmọbìnrin wa, Kristi. Kété lẹ́yìn ìgbà náà, dókítà wa sọ ìròyìn àgbọ́sọgbánù kan fún wa pé Kristi ò lè gbọ́ràn, ó sì ní àrùn cerebral palsy, ìyẹn ni pé ibì kan nínú ọpọlọ rẹ̀ tó máa ń darí ìséraró àti ọ̀rọ̀ sísọ, ti bà jẹ́. A ò mọ nǹkan tí ohun tó ṣubú lù wá yẹn máa fojú wa rí.

Lóṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, èmi àti ọkọ mi, Gary, bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àkànṣe ní ìlú Melbourne, lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà, níbẹ̀ la sì ti kọ́ báa ṣe máa tọ́ ọmọ wa. A tún fẹsẹ̀ kan yà ní Ibi Ìwádìí tí Ìjọba Dá Sílẹ̀ fún Bíbójú Tó Ìṣòro Ìgbọràn, èyí tó wà nílùú Melbourne. Níbẹ̀ ni wọ́n ti ki ẹ̀rọ bóńbó kan báyìí sí i létí, kó bàa lè máa gbọ́ràn. Kristi ò fẹ́ràn ẹ̀rọ náà rárá, nítorí pé wọ́n sì so wáyà mọ́ ọn lára, bí a bá ṣe ń ki àwọn wáyà náà bọ̀ ọ́ létí báyìí, kíá lá ti yọ wọ́n dà nù! A tún máa ń fi ohun kan tó dà bí àgbékọ́ so bátìrì tí ẹ̀rọ náà ń lò mọ́ ọn lára, bátìrì náà sì wúwo gan-an ni.

Nítorí pé apá tó ń darí ìséraró nínú ọpọlọ Kristi ti bà jẹ́, tàgétàgé báyìí ló ń ṣe nígbà tó ń kọ́ ìrìn. Nítorí náà, lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ là ń gbé e lọ sọ́dọ̀ oníṣègùn akọ́mọ-nírìn. Ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi pé ọmọ ọdún mẹ́ta, ó bẹ̀rẹ̀ sí dá rìn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kọ́kọ́ ṣubú lọ́pọ̀ ìgbà. A ò yé lọ sọ́dọ̀ akọ́mọ-nírìn náà títí tó fi pé ọmọ ọdún márùn-ún. Ẹnu ìyẹn la ṣì wà tá a fi kó lọ sí ìlú Benalla, tí ò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà, níbi tí ọkọ mi ti ń bá iṣẹ́ ajé rẹ̀ lọ.

Bí Kristi Ṣe Relé Ìwé

Olùkọ́ àwọn adití kan sọ fún wa pé Kristi máa nílò àkànṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Ìyẹn ló mú ká kó lọ sí ìlú Bendigo, níbi tí ilé ẹ̀kọ́ àwọn adití wà. Nítorí pé mo ti lóyún ọmọ wa kejì, a jẹ́ kí Kristi pé ọmọ ọdún mẹ́rin, tí ọmọkùnrin tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, Scott, sì pé ọmọ oṣù márùn-ún ká tó kó lọ. A bẹ̀rẹ̀ sí gbé e lọ sílé ìwòsàn kan ní Bendigo, níbẹ̀ ló ti ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀rọ̀ sísọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀; ó sì máa tó ọdún mẹ́wàá kí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà tó parí. Èmi àti ọkọ mi pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ èdè àwọn adití.

Kíkọ́ Kristi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló jẹ wá lógún jù lọ. Ohun tó sì fa èyí ni pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni èmi àti ọkọ mi, a sì ti pinnu láti tọ́ Kristi dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Ṣùgbọ́n ọ̀nà wo la fẹ́ gbé e gbà? Ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ tí Kristi ń lọ sọ pé: “Ohun tó máa ṣòro láti kọ́ Kristi jù lọ ni ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run. Ẹ ò lè fojú rí Ọlọ́run, nítorí náà, báwo lẹ ṣe fẹ́ ṣàlàyé nípa rẹ̀ fún un?” Ìpèníjà ńlá gbáà mà lèyí tó dojú kọ wá yìí o! Kò pẹ́ tá a fi mọ̀ pé èyí á gbà wá ní ọ̀pọ̀ àkókò, ìkẹ́kọ̀ọ́ àti sùúrù.

A kọ́kọ́ ń lo àwọn àwòrán, a sì ń sọ èdè tó lè tètè yéni. À ń mú un lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni àti òde ẹ̀rí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tá à ń ṣe ò fi bẹ́ẹ̀ yé e. Bí Kristi ṣe túbọ̀ ń lóye èdè àwọn adití, àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ wá túbọ̀ ń yé e ju ti tẹ́lẹ̀ lọ! Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀, gbólóhùn àtàwọn ẹ̀kọ́ ló wà nínú Bíbélì tó ṣòro láti ṣàlàyé. Ọ̀kan lára ìwé tó fẹ́ràn jù lọ ni Iwe Itan Bibeli Mi,a tí wọ́n dìídì kọ nítorí àwọn ọmọdé. Ìrànlọ́wọ́ táwọn àwòrán rírẹwà tó wà nínú ìwé náà, àtàwọn míì tá a fọwọ́ ara wa yà, ṣe kúrò ní kékeré. Bí àkókò ti ń lọ, Kristi bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run látọkàn rẹ̀ wá.

Ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ Kristi fojú wa mọ àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn kan tí wọ́n ń tọ́ àwọn ọmọ tó jẹ́ adití. Ọwọ́ wa sì tẹ ohun tá à ń wá nígbà tí wọ́n ṣàlàyé fún wa bí adití ṣe lè wàásù fáwọn tó ń gbọ́ràn. Ọ̀nà kan ni pé wọ́n á fún wọn ní káàdì kan tí wọ́n kọ ìsọfúnni tó wà nínú Ìwé Mímọ́ sí. Nítorí náà, nígbà tí Kristi ṣe tán láti máa fi òtítọ́ Bíbélì kọ́ àwọn ẹlòmíràn, bí ẹni fi ẹran jẹ̀kọ ni! Ó di akéde ìhìn rere náà tí kò tíì ṣèrìbọmi nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá. Ó sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1994, nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún.

Síbẹ̀, Kristi ṣì nílò àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rere, ó sì ṣòro fún un láti bá àwọn Ẹlẹ́rìí tí kì í ṣe adití ṣọ̀rẹ́. Nítorí náà, èmi àti Gary bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn tó bá fẹ́ láti ran àwọn adití lọ́wọ́ nínú ìjọ wa ni èdè àwọn adití. Wọ́n pàpà gba díẹ̀ lára àwọn tá a kọ́ síṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí atúmọ̀ èdè fáwọn adití. Àmọ́, èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kọ́ èdè àwọn adití gbádùn bíbá Kristi sọ̀rọ̀ dọ́ba. Ó ti wá ṣeé ṣe fún Kristi láti jàǹfààní ní kíkún látinú àwọn ìpàdé àti àpéjọ Kristẹni wa. Ó sì ń kópa nínú àwọn ìpàdé náà títí dòní. Kristi mọrírì báwọn ará ṣe ṣàníyàn nípa rẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́.

Lọ́jọ́ kan Kristi sọ fún wa pé òun fẹ́ láti di aṣáájú ọ̀nà déédéé, tàbí ajíhìnrere alákòókò kíkún. Gary bá a gba ìwé àṣẹ ìrìnnà ọkọ̀, lẹ́yìn tí wọ́n sì ti parí gbogbo ètò yòókù tó yẹ ní ṣíṣe, Kristi di ọ̀kan lára àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé lọ́dún 1995. Lọ́dún 2000, wọ́n gbà á sẹ́nu iṣẹ́ aláàbọ̀ àkókò ní ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ kan. Ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ níbẹ̀ láti bá wọn bójú tó kíkọ́ àwọn ọmọ tó jẹ́ adití lẹ́kọ̀ọ́.

Ní báyìí, Kristi, Gary, Scott, ọmọ wa ọkùnrin, àtèmi la jọ ń gbádùn iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé. Ó dùn mọ́ wa pé a lè máa lo àkókò wa láti fi kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà, Ọlọ́run wa!

‘Àwọn Ìbéèrè Inú Ọkàn-Àyà Wa’

Ọ̀ràn tó bá bá ojú, á bá imú, lọ̀rọ̀ àìlègbọ́ràn Kristi jẹ́ fún gbogbo wa. Nígbà míì, bí Kristi bá jáde òde ẹ̀rí, kì í rẹ́ni ràn án lọ́wọ́ láti túmọ̀ ohun tó ń sọ fáwọn èèyàn, kì í sì í rẹ́ni sọ ohun tó ń rò àti bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ fún. Ó sọ pé: “Ó máa ń ṣe mí bí ẹni pé mò ń gbé lórílẹ̀-èdè kan tí gbogbo èèyàn ti ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tèmi.” Síbẹ̀ náà, gbogbo wa la ti kọ́ bá a ṣe lè máa ro tiẹ̀ mọ́ tiwa.

Àwọn ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 37:4, máa ń tù wá nínú. Ó kà pé: “Máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà, òun yóò sì fún ọ ní àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá.” Kristi ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí yóò lè gbọ́ orin àti ohùn àwọn ẹ̀dá alààyè, tí yóò sì lè bá tẹbí tará sọ̀rọ̀ tí òun náà á lè fetí ara ẹ̀ gbọ́. Mò ń wọ̀nà fún ọjọ́ náà tí Kristi á lè gbọ́ ohùn mi. A nígbàgbọ́ pé gbogbo ohun tá a fẹ́ yìí ni Ọlọ́run yóò ṣe fún wa, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti ṣèlérí.—Aísáyà 35:5.—A kọ ọ́ ránṣẹ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Kristi rèé tí “Ìwé Itan Bibeli Mi” wà lọ́dọ̀ ẹ̀, nígbà tó pé ọmọ oṣù mẹ́rìnlá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Kristi ń lo káàdì tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sí láti wàásù ìhìn rere

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Scott, Kristi, Gary àti Heather Forbes lónìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́