Ǹjẹ́ Ó Ní Nǹkan Tí ìrètí Lè Ṣe fún Wa?
ỌMỌ ọdún mẹ́wàá péré ni Daniel, àmọ́ ó tó ọdún kan tí àrùn jẹjẹrẹ ti ń bá a fínra. Àwọn oníṣègùn tó ń tọ́jú rẹ̀ àtàwọn èèyàn rẹ̀ ti gba kámú pé ọmọkùnrin yìí ò lè rù ú là. Ṣùgbọ́n Daniel ò sọ̀rètí nù. Ó ní ìgbàgbọ́ pé òun á dàgbà lọ́jọ́ kan, òun á di olùṣèwádìí, òun á sì máa tọ́jú àwọn tó bá lárùn jẹjẹrẹ. Ìrètí tó ń mú inú rẹ̀ dùn ni pé dókítà tó ń wo irú jẹjẹrẹ tó ń ṣe é yẹn máa tó wá wò ó. Àmọ́, nígbà tó dọjọ́ tó yẹ kí dókítà yẹn wá, kò lè wá mọ́ nítorí ojú ọjọ́ tí ò dára. Ọkàn Daniel gbọgbẹ́. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tó máa rọ jọwọrọ sórí bẹ́ẹ̀dì. Ọjọ́ kẹta ló kú.
Olùtọ́jú aláìsàn kan tó kọ́ nípa bí ìrètí àti àìnírètí ṣe lè nípa lórí ìlera wa ló sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Daniel. Bóyá ni ìwọ náà ò ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí. Bí àpẹẹrẹ, arúgbó kan wà tí ò lè pẹ́ kú ṣùgbọ́n ó ń retí ọjọ́ pàtàkì kan, bóyá àlejò pàtàkì tó fẹ́ wá kí i ni o tàbí ayẹyẹ kan. Nígbà tọ́jọ́ tó ń retí yẹn pé tó sì lọ, kò pẹ́ tó fi kú. Kí ló mú káwọn ọ̀ràn yẹn rí bẹ́ẹ̀? Àbí ìrètí tiẹ̀ lágbára tó báwọn kan ṣe rò?
Àwọn olùwádìí nípa ìtọ́jú ìṣègùn tí iye wọn ń pọ̀ sí i ló ń sọ pé ìfojúsọ́nà fún rere, ìrètí, àtàwọn nǹkan ìdùnnú mìíràn ń nípa tó lágbára gan-an lórí ìgbésí ayé àti ìlera ènìyàn. Àmọ́, èrò àwọn olùwádìí ò ṣọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ yẹn. Àwọn olùwádìí kan sọ pé àsé tí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ni gbogbo irú èrò bẹ́ẹ̀. Wọ́n máa ń fẹ́ sọ pé kò sí nǹkan mìíràn tó ń dá àárẹ̀ síni lára ju àìsàn lọ.
Kì í ṣòní, kì í ṣàná rèé táwọn kan ti gbà pé ìrètí ò já mọ́ nǹkan kan. Ní ẹgbẹ̀rún ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, nígbà tí wọ́n ní kí Aristotle tó jẹ́ onímọ̀ èrò orí Gíríìkì sọ ohun tó ń jẹ́ ìrètí, ó dáhùn pé: “Àlá orí ìrìn ni.” Láìpẹ́ yìí sì rèé, Benjamin Franklin tó jẹ́ àgbà òṣèlú kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ ọ́ ṣàn-án bó ṣe rí lọ́kàn rẹ̀ pé: “Inú ààwẹ̀ lẹni tó bá jókòó sórí ìrètí máa kú sí.”
Ó dáa nígbà náà, kí ló ń jẹ́ ìrètí gan-an? Ṣé ríronú pé ohun tó wù wá yóò ṣẹlẹ̀ lásán ni, ìyẹn ọ̀nà téèyàn kàn máa ń gbà láti fi àlá tí ò lè ṣẹ dára rẹ̀ nínú dùn? Àbí ìdí wà tó fi yẹ ká ka ìrètí sí ohun tó jù bẹ́ẹ̀ lọ, ohun tá a gbọ́dọ̀ ní nítorí pé ó ṣe pàtàkì fún ìlera àti ayọ̀ wa àti pé ó jẹ́ ohun tá a nílò, ó sì láǹfààní gidi tó lè ṣe fún wa?