“Kò Yẹ Kí Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìlú Gbófin Tara Ẹ̀ Kalẹ̀”
LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ KÁNÁDÀ
ÒFIN Ẹ̀tọ́ àti Òmìnira Aráàlú Ti Orílẹ̀-èdè Kánádà ń dáàbò bo òmìnira tí gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè náà ní. Òfin fáwọn èèyàn lómìnira ọ̀rọ̀ sísọ, ìwé títẹ̀ àti ẹ̀sìn, ilé ẹjọ́ sì ní àṣẹ láti rí sí i pé a kò fi irú òmìnira bẹ́ẹ̀ du ẹnikẹ́ni.
Nítorí náà, nígbà tí àwọn aláṣẹ ìlú Blainville, àgbègbè kan tó wà ní apá àríwá ìwọ̀ oòrùn ìlú Montreal, fẹ́ ṣe àtúnṣe àwọn òfin wọn kí ẹnikẹ́ni má bàa lè ṣe ‘àbẹ̀wò’ ilé-dé-ilé sọ́dọ̀ àwọn èèyàn ‘lórúkọ ẹ̀sìn,’ láìkọ́kọ́ gbàṣẹ, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí gbára dì. Ó dájú pé nítorí iṣẹ́ ìwàásù wọn láti ilé dé ilé ni wọ́n ṣe fẹ́ tún òfin náà ṣe. (Ìṣe 20:20, 21) Ṣùgbọ́n kí ló tiẹ̀ pàdí àtúnṣe tí wọ́n fẹ́ ṣe sí òfin náà? Àwọn aláṣẹ ìlú sọ pé awuyewuye ti ń pọ̀ nípa bíbẹ̀ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bẹ àwọn èèyàn wò látẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà. Àmọ́ ṣá o, nínú àkọsílẹ̀ tó wà nílé iṣẹ́ àwọn ọlọ́pàá, látọdún márùn-ún sẹ́yìn, ẹnikẹ́ni ò tíì mú ẹjọ́ kankan lọ sọ́dọ̀ wọn nípa ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà!
Síbẹ̀, òfin tí wọ́n tún ṣe náà di òfin tààrà lọ́dún 1996. Lẹ́yìn èyí, àwọn agbẹjọ́rò tó ń ṣojú fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Blainville fi tó ìgbìmọ̀ aṣòfin ìlú náà létí pé olúkúlùkù ní ẹ̀tọ́ sí òmìnira ẹ̀sìn lábẹ́ òfin, kò sì ní bófin mu fáwọn aláṣẹ ìlú náà láti fi òfin dí iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́. Àwọn aláṣẹ ìlú ò kọbi ara sí ìsọfúnni yìí, wọ́n sì fìwé pe àwọn mẹ́tàdínlógún lẹ́jọ́. Àwọn agbẹjọ́rò fáwọn Ẹlẹ́rìí bá pẹjọ́ sí kóòtù kí ìlú Blainville má bàa bẹ́gi dínà òmìnira ẹ̀sìn àti òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, èyí tó jẹ́ ẹ̀tọ́ gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè Kánádà.
Ìgbẹ́jọ́ wáyé ní Ilé Ẹjọ́ Gíga ti Ìpínlẹ̀ Quebec, níwájú Onídàájọ́, Jean Crépeau, ní October 3 àti 4, 2000. Lẹ́yìn àgbéyẹ̀wò ẹjọ́ náà, onídàájọ́ fọwọ́ sí i pé kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa bá ìwàásù wọn lọ láìsí àtakò. Onídàájọ́ Crépeau gbà “pé ipasẹ̀ àwọn ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ làwọn olùpẹ̀jọ́ ń tẹ̀lé bí wọ́n ti ń lọ láti ilé dé ilé kí wọ́n lè kọ́ àwọn èèyàn láti máa hùwà tí kò lábùkù kí wọ́n sì máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ọlọ́run. . . . Ìbẹ̀wò táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe sílé àwọn èèyàn jẹ́ iṣẹ́ tó yẹ káwọn Kristẹni máa ṣe fún àǹfààní aráàlú. Ní ìpíndọ́gba, ẹ̀ẹ̀kan lóṣù mẹ́rin làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń bẹ àwọn ará ìlú Blainville wò kí wọ́n lè fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn lórí àwọn kókó ọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró táwọn èèyàn sì máa ń fẹ́ gbọ́.” Nígbà tó ń kéde ìdájọ́ rẹ̀, Onídàájọ́ Crépeau sọ pé: “Ìkéde [ilé ẹjọ́] yìí ni pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ béèrè pé kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba ìyọ̀ǹda kí wọ́n tó ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn.”
Àwọn aláṣẹ ìlú Blainville ò fara mọ́ ìpinnu Onídàájọ́ Crépeau, wọ́n sì pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti Ìpínlẹ̀ Quebec. Wọ́n sì gbọ́ ẹjọ́ náà ní June 17, ọdún 2003. Ìkéde ìdájọ́, èyí tó wáyé ní August 27, ọdún 2003, sì fara mọ́ ìpinnu onídàájọ́ tó kọ́kọ́ dá ẹjọ́ náà. Ilé ẹjọ́ fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Òfin Ẹ̀tọ́ àti Òmìnira Aráàlú Ti Orílẹ̀-èdè Kánádà, èyí tó dáàbò bo ẹ̀tọ́ òmìnira ẹ̀sìn tí olúkúlùkù ní títí kan ẹ̀tọ́ láti ṣe ohun tó gbà gbọ́ nípa fífi í kọ́ni àti títàn án kálẹ̀. Ilé Ẹjọ́ náà ṣe àgbéjáde gbólóhùn tó kà pé: “Ńṣe ni òfin tí wọ́n fẹ́ fi pa iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu mọ́ yìí fi gírímọ́káì ká ẹ̀tọ́ òmìnira ẹ̀sìn tí wọ́n ní lọ́wọ́ kò, ó sì ṣèdíwọ́ fún òmìnira ìrònú, ìgbàgbọ́, èrò àti ìmúṣe ohun táwọn ará ìlú Blainville gbà gbọ́ . . . Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn olùgbé ìlú Blainville ò wíjọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fipá ti ohunkóhun mọ́ àwọn lọ́rùn bíi tàwọn alájàpá tó ń kiri ọjà. Kò pọn dandan, kò sì sí ìdí gúnmọ́ kankan tá a fi gbọ́dọ̀ ṣòfin tí yóò máa darí ìwàásù ilé-dé-ilé táwọn kan ń ṣe bí ọ̀nà ìgbàjọ́sìn tiwọn. Ìyẹn nìkan wá kọ́ o, ìkánjú gbáà ni wọ́n fi gbé òfin náà kalẹ̀, wọn ò wádìí wò kí wọ́n tó fọwọ́ sí i, kò bọ́gbọ́n mu, àṣejù sì ti wọ̀ ọ́ bó bá jẹ́ torí àtifi dáàbò bo ẹ̀tọ́ àwọn aráàlú láti dá wà ni wọ́n fi gbé e kalẹ̀. . . . Láwùjọ táwọn èèyàn ti lómìnira tí wọ́n sì wà lábẹ́ ìjọba tiwa-n-tiwa, kò yẹ kí ìgbìmọ̀ aṣòfin ìlú gbófin tara ẹ̀ kalẹ̀ nípa gbígbìyànjú láti pinnu ẹni táwọn èèyàn á gbà sílé wọn ní ìrọ̀lẹ́ tàbí lópin ọ̀sẹ̀. Onídàájọ́ tó kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ náà ò ṣìsọ nígbà tó sọ pé òfin tí wọ́n ṣe náà ò de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”
Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dùn pé àwọn ilé ẹjọ́ tó wà ní ìpínlẹ̀ Quebec fi ohun tí Òfin Ẹ̀tọ́ Aráàlú sọ sílò nínú ẹjọ́ yìí láti dáàbò bo òmìnira ẹ̀sìn tó wà fún gbogbo olùgbé ìpínlẹ̀ Quebec kí wọ́n máa bàa yọ wọ́n lẹ́nu mọ́.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 10]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
KÁNÁDÀ
Blainville
Montreal
AMẸ́RÍKÀ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Òfin Ẹ̀tọ́ àti Òmìnira Aráàlú Ti Orílẹ̀-èdè Kánádà ń dáàbò bo òmìnira tí gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè náà ní
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Àwọn Ẹlẹ́rìí ti ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé wọn ní fàlàlà báyìí ní ìlú Blainville. Àwòrán inú àkámọ́: Wọ́n ń ṣèpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn