Aláàánú Ará Samáríà Òde Òní
LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ MẸ́SÍKÒ
Ọ̀pọ̀ nínú wa ló ti gbọ́ ìtàn tí Bíbélì sọ nípa ọkùnrin kan tó fẹ́ràn aládùúgbò rẹ̀, táwọn èèyàn sábà máa ń pè ní Aláàánú ará Samáríà. (Lúùkù 10:29-37) Nínú àkàwé yìí, Jésù Kristi ṣàlàyé bí ọkùnrin ará Samáríà kan ṣe ṣe gudugudu méje kó bàa lè fi ìfẹ́ hàn sí aládùúgbò rẹ̀ tó nílò ìrànlọ́wọ́. Ǹjẹ́ a ṣì tún lè rí irú Aláàánú ará Samáríà bẹ́ẹ̀ lónìí? Èyí tá a rí gbọ́ láti orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò rèé, ẹ gbé e yẹ̀ wò.
Nígbà tí Betuel àti ìdílé rẹ̀ ń ti àjò bọ̀, ó ku bíi kìlómítà mélòó kan kí wọ́n délé ni wọ́n rí ìjàǹbá mọ́tò kan tó burú jáì lójú pópó. Wọ́n dúró láti ran àwọn tí ìjàǹbá náà ṣẹlẹ̀ sí lọ́wọ́. Dókítà tó wa ọ̀kan lára àwọn ọkọ̀ tí ìjàǹbá náà ṣẹlẹ̀ sí ní kí wọ́n bá òun gbé ìyàwó òun tó lóyún àtàwọn ọmọbìnrin òun kékeré méjì lọ gbàtọ́jú ní ilé ìwòsàn tó bá wà nítòsí ibẹ̀. Wọ́n gbé wọn lọ, Betuel sì padà síbi tí ìjàǹbá náà ti ṣẹlẹ̀ bóyá a tún rí ohun tó lè ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.
Betuel sọ pé: “Àwọn ọlọ́pàá tó ń ṣọ́ ojú pópó ti débẹ̀, wọ́n sì mú dókítà náà, wọ́n fẹ́ lọ fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, nítorí pé a rẹ́ni tó kú nínú ìjàǹbá náà. Nígbà tí dókítà náà béèrè ìdí tí mo fi ń ran òun lọ́wọ́, mo ṣàlàyé fún un pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, a sì ti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú Bíbélì pé a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa. Mo sọ fún un pé kó má ṣèyọnu nípa ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ̀, a máa bójú tó wọn. Ó kún fún ìmoore débi pé ńṣe lomi ń dà lójú ẹ̀, ló bá kó àwọn ohun iyebíye tó wà lọ́wọ́ ẹ̀ fún mi pé kí n bá òun tọ́jú wọn.”
Betuel àti ìdílé rẹ̀ gba ìyàwó àtọmọ dókítà náà sínú ilé wọn, wọ́n sì bójú tó wọn fún ọjọ́ mélòó kan. Bí Betuel ṣe bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn o. Nígbà tí ọkùnrin náà jáde kúrò látìmọ́lé, ó sọ pé òun mọrírì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, òun sì dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn gan-an ni. Ó ṣèlérí pé òun á máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó tóun bá padà dé ìlú òun, ó sì sọ pé bí ìyàwó òun bá bí ọkùnrin, Betuel lorúkọ tóun máa sọ ọ́. Betuel ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Wàyí o, lẹ́yìn ọdún méjì, a ṣalábàápàdé wọn. Ó sì yà mí lẹ́nu pé wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Betuel sì lorúkọ ọmọkùnrin wọn kékeré!”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Betuel