ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 9/8 ojú ìwé 13-14
  • Àwọn Bàbá Tó Wà bí Aláìwà Ń Pọ̀ Sí I

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Bàbá Tó Wà bí Aláìwà Ń Pọ̀ Sí I
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọ́n Wà Bí Aláìwà
  • Ó Yẹ Káwọn Bàbá Yẹ Ara Wọn Wò
  • Bí Wọ́n Á Ṣe Mọ Èyí Tó Ṣe Pàtàkì Jù
  • Ojúṣe Bàbá Ò Ṣeé Fọwọ́ Rọ́ Sẹ́yìn
    Jí!—2001
  • Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Bàbá Rere
    Jí!—2013
  • Ta Ló Yẹ Kí Ó Kọ́ Àwọn Ọmọdé Nípa Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Irú Bàbá Táwọn Ọmọ Nílò
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 9/8 ojú ìwé 13-14

Àwọn Bàbá Tó Wà bí Aláìwà Ń Pọ̀ Sí I

ÀWỌN bàbá tó ń pa ìdílé wọn tì túbọ̀ ń pọ̀ sí i ni. Nígbà tó ku díẹ̀ ká wọ ọdún 2000, ìwé ìròyìn USA Today pe orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní “ọ̀gá nínú àwọn orílẹ̀-èdè táwọn ìdílé tí ò ní bàbá pọ̀ sí.” Àmọ́, ìṣòro kí bàbá wà bí aláìwà yìí kò mọ síbì kan o, ìṣòro gbogbo ayé ni.

Àbájáde ètò ìkànìyàn kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Brazil lọ́dún 2000 fi hàn pé nínú àwọn ìdílé tí iye wọ́n jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́rìnlélógójì, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [44,700,000] tí wọ́n wà lórílẹ̀-èdè náà, mílíọ̀nù mọ́kànlá, ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ìdílé [11,200,000] ni obìnrin ń darí wọn. Ìdámẹ́rin àwọn ọmọ tó wà lórílẹ̀-èdè Nicaragua, ni wọ́n ń gbé lọ́dọ̀ ìyá wọn nìkan. Ní orílẹ̀-èdè Costa Rica, iye àwọn ọmọ táwọn bàbá tiwọn fúnra wọn ò dá mọ̀ ròkè láàárín ọdún 1990 sí ọdún 1999 láti nǹkan tó lé díẹ̀ ní ìpín mọ́kànlélógún nínú ọgọ́rùn-ún sí ohun tó lé díẹ̀ ní ìpín ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún.

Àwọn ìwádìí tí wọ́n fi ìṣirò ṣe láwọn orílẹ̀-èdè yìí kàn jẹ́ àpẹẹrẹ tó ń fi hàn pé kárí ayé ni ìṣòro yìí ni. Ẹ jẹ́ ká tún ti apá ibòmíràn wo ìṣòro tí ọ̀rọ̀ àwọn bàbá tó wà bí aláìwà yìí dá sílẹ̀.

Wọ́n Wà Bí Aláìwà

Jọ̀wọ́ wo àpótí náà, “Bàbá Mi, Ìgbà Wo Lẹ Tún Máa Padà Wálé?” Nao tó ti di ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún báyìí jẹ́wọ́ pé: “Kí n tó bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, n kì í sábà rí Bàbá mi. Lọ́jọ́ kan, nígbà tó ń jáde ńṣe ni mò ń bẹ̀ ẹ́, tí mo sì ń sọ pé, ‘Ẹ máà pẹ́ dé o, ṣe bí ẹ̀ máa padà wálé?’”

Nítorí bí nǹkan ṣe ń lọ nínú ìdílé bíi ti Nao àti bàbá ẹ̀ yìí ló mú kí òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Poland náà, Piotr Szczukiewicz sọ pé: “Ó dà bíi pé àìsí bàbá nínú ilé ń dá wàhálà tó pọ̀ sínú ìdílé.” Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ àwọn bàbá ló ń gbé pẹ̀lú ọmọ àti aya tí wọ́n sì ń gbọ́ bùkátà ìdílé. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn èdè Faransé náà, Capital ṣe sọ, “àwọn bàbá tó pọ̀ jù ló gbà pé táwọn bá ti ń fowó oúnjẹ sílẹ̀ nínú ilé, àbùṣe bùṣe, báwọn ò bá tiẹ̀ dá sí ọ̀rọ̀ kíkọ́ ọmọ lẹ́kọ̀ọ́.”

Lọ́pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ńṣe ni bàbá máa ń wà nílé bí aláìsí, kì í fẹ́ mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí nínú ìgbésí ayé àwọn ọmọ rẹ̀. Ibòmíì lọkàn rẹ̀ wà. Ìwé ìròyìn èdè Faransé náà, Famille chrétienne sọ pé: “Kà tiẹ̀ ní bàbá ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ gbélé, ọkàn rẹ̀ lè máà sí nínú ilé ọ̀hún.” Kí nìdí tí ọkàn ọ̀pọ̀ bàbá kì í fi í sí lára ìdílé wọn tí wọn kì í sì í ronú nípa wọn?

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn náà ṣe ṣàlàyé ohun tó sábà máa ń fà á ni pé “bàbá náà ò lóye ìlà iṣẹ́ bàbá àti ọkọ nínú ilé.” Ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn bàbá gbà gbọ́ ni pé bàbá tó bá ṣáà ti ń rówo tó tówó mú wálé ni bàbá dáadáa. Òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Poland náà Józef Augustyn sọ pé “ọ̀pọ̀ bàbá ló gbà pé bàbá tó tó bàbá ọmọ ṣe làwọn, táwọn bá ṣáà ti ń mówó wálé fún ìdílé àwọn.” Ṣùgbọ́n fífowó sílẹ̀ nínú ilé wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára iṣẹ́ bàbá ni, ibẹ̀ kọ́ ló parí sí.

Òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé lójú àwọn ọmọ, owó fífúnni kò tó èèyàn, bí bàbá wọn ṣe lówó lọ́wọ́ tó tàbí iye nǹkan tó ń rà fún wọn kọ́ ni wọn fi máa ń díwọ̀n bó ṣe ń ṣe dáadáa tó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun táwọn ọmọ ń fẹ́ ju ẹ̀bùn yòówù kó máa rà fún wọn lọ fíìfíì, wọ́n ń fẹ́ kí bàbá àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn, kó lo àkókò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn, kó sì máa fetí sí àwọn. Àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì lójú wọn nìyí.

Ó Yẹ Káwọn Bàbá Yẹ Ara Wọn Wò

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan tó wá látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ètò Ẹ̀kọ́ Lórílẹ̀-Èdè Japan ṣe sọ, “ó yẹ káwọn bàbá tí wọ́n fara wọn jin iṣẹ́ púpọ̀ jù ṣàgbéyẹ̀wò ìgbésí ayé wọn.” Ìbéèrè tó wá ń jà ràn-ìn báyìí ni pé, Ṣe bàbá kan á fẹ́ ṣàtúnṣe nítorí àwọn ọmọ rẹ̀? Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Jámánì náà Gießener Allgemeine ròyìn ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nínú èyí tí àwọn tó pọ̀ jù nínú àwọn bàbá tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ti sọ pé àwọn ò lè fi ọmọ ṣáájú iṣẹ́ àwọn.

Ó máa ń dun àwọn ọmọdé gan-an tó bá dà bíi pé bàbá wọn ò bìkítà nípa wọn. Lidia tó ti pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún báyìí rántí bí bàbá rẹ̀ ṣe máa ń ṣe nígbà tó ṣì wà ní kékeré tí wọ́n ń gbé ní orílẹ̀-èdè Poland. Ó ṣàlàyé pé: “Kì í bá wa sọ nǹkan kan. Kóńkó jabele, kálukú ló ń ṣe tirẹ̀ ni ìdílé wa. Kò mọ̀ pé mo máa ń lọ ságbo ijó lákòókò tọ́wọ́ mi bá dilẹ̀.” Bákan náà, Macarena, ọmọbìnrin ọmọ ọdún mọ́kànlélógún tó ń gbé ní ilẹ̀ Sípéènì sọ pé nígbà tóun wà lọ́mọdé, bàbá òun “máa ń jáde lọ lópin ọ̀sẹ̀ láti lọ gbádùn ara ẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ò sì ní wálé fún bí ọjọ́ mélòó kan.”

Bí Wọ́n Á Ṣe Mọ Èyí Tó Ṣe Pàtàkì Jù

Ọ̀pọ̀ bàbá mọ̀ pé àkókò àti àfiyèsí táwọn ń fáwọn ọmọ àwọn ti kéré jù. Bàbá kan nílẹ̀ Japan tó ní ọmọkùnrin tí kò ju ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún lọ sọ pé: “Mo rò pé ọ̀rọ̀ mi á ti yé ọmọ mi. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń ronú nípa ẹ̀, kódà nígbà tọ́wọ́ mi bá dí pàápàá.” Síbẹ̀, ṣé tó bá ṣáà ti wu bàbá kan pé kí ọmọ rẹ̀ lóye ìdí tí kì í fi í gbélé, ìṣòro náà ti tán nìyẹn?

Láìsí àní àní, kéèyàn tó lè ṣe nǹkan tí ọmọ kan nílò fún un, ó ń béèrè ìsapá, àní kéèyàn yááfì àwọn nǹkan kan. Ó ṣe kedere pé kò rọrùn láti pèsè ohun táwọn ọmọ ń fẹ́ fún wọn, ìyẹn àwọn nǹkan bí ìfẹ́, àkókò, àti àfiyèsí. Jésù Kristi sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo.” (Mátíù 4:4) Òótọ́ sì tún ni pé àwọn ọmọ ò lè dàgbà kí wọ́n sì ṣàṣeyọrí tó bá jẹ́ kìkì àwọn nǹkan tara nìkan ni òbí ń pèsè fún wọn. Bó o bá jẹ́ bàbá, ṣó o lè yááfì àwọn nǹkan tó lè ṣe pàtàkì gan-an sí ọ, bóyá bí àkókò rẹ tàbí ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ kó o bàa lè ráyè bójú tó àwọn ọmọ rẹ?

Ìwé ìròyìn Mainichi Daily News ti February 10, 1986, sọ nípa bàbá kan tó mọ báwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ṣe pàtàkì tó. Ó ròyìn pé: “Ọ̀gá àgbà kan ní Ilé Iṣẹ́ Ọkọ̀ Ojú Irin ti Orílẹ̀-Èdè Japan fínnúfíndọ̀ kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ dípò tí ì bá fi fi ìdílé rẹ̀ sílẹ̀.” Ìwé ìròyìn náà gbé ọ̀rọ̀ tí ọ̀gá àgbà yìí sọ jáde, ó ní: “Ẹnikẹ́ni ló lè gba iṣẹ́ ọ̀gá àgbà. Àmọ́ èmi nìkan ni bàbá àwọn ọmọ mi.”

Ká sòótọ́, ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tó yẹ kéèyàn gbé kó tó lè di bàbá dáadáa ni pé kó mọ irú bàbá táwọn ọmọ nílò. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ irú bàbá bẹ́ẹ̀.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]

“Bàbá Mi, Ìgbà Wo Lẹ Tún Máa Padà Wálé?”

Ìbéèrè tí Nao, ọmọbìnrin ọmọ ọdún márùn-ún kan láti ilẹ̀ Japan bi bàbá ẹ̀ nìyẹn lọ́jọ́ kan tí bàbá ẹ̀ ń lọ síbi iṣẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé kan náà lòun àti bàbá ẹ̀ ń gbé, síbẹ̀ ọmọbìnrin yìí kì í sábà fojú kan bàbá ẹ̀. Nao ti máa ń sùn kó tó ti ibi iṣẹ́ dé lálẹ́, kó sì tó jí lọ́jọ́ kejì, á ti lọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́