Irú Bàbá Táwọn Ọmọ Nílò
ÀWỌN ọmọdé nílò bàbá tó lè fara ẹ̀ jìn fún wọn, tó lè ṣe ohunkóhun tó bá yẹ kó ṣe káwọn ọmọ ẹ̀ fi lè dàgbà, kí wọ́n yàn kí wọ́n sì yanjú. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn ò fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ pé àwọn ọmọ nílò irú bàbá báyìí.
Lóòótọ́, ìyá ni ọlọ́kọ̀ tó wa ọmọ wá sáyé, kò sì sí nǹkan tí ìyà tó dáa lè ṣe fọ́mọ ẹ̀ tó pọ̀ jù. Àmọ́ nígbà tí ìwé ìròyìn The Wilson Quarterly ń ṣàlàyé pé ipa tí bàbá náà ń kó ṣe pàtàkì, ó sọ pé: “Bó ṣe ń di pé àwọn bàbá kì í fi bẹ́ẹ̀ bójú tó ìdílé wọn mọ́ ni olórí ohun tó ń fa èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìṣòro àwùjọ tó ń kọni lóminú nílẹ̀ Amẹ́ríkà,” tàbí ká kúkú sọ pé ní gbogbo àgbáyé.
Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Brazil náà Jornal da Tarde ròyìn ìwádìí kan nínú èyí tí wọ́n ti rí i pé “àìkìí gbélé àwọn bàbá ló fà á” táwọn ọ̀dọ́ fi ń hu irú ìwàkiwà tí wọ́n ń hù bí ìwà jàgídíjàgan, ìwà ewèlè, àìṣedáadáa nílé ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀dájú. Ìwé mìíràn tí wọ́n kọ lédè Ítálì, Gli imperfetti genitori (Àwọn Òbí Aláìpé), látọwọ́ Marcello Bernardi sọ ojú abẹ níkòó pé kí ọmọ tó lè ṣàṣeyọrí, àfi káwọn òbí méjèèjì pawọ́ pọ̀ tọ́ ọ.
A Lè Tún Nǹkan Ṣe Nínú Ìdílé
Ká tiẹ̀ sọ pé bí bàbá kan ò ṣe bójú tó ilé ẹ̀ ti pa kún ìṣòro tó wà nínú ìdílé náà tàbí kó jẹ́ pé òun ló ṣe okùnfà èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìṣòro ọ̀hún, kò túmọ̀ sí pé nǹkan ò lè yí padà kí wọ́n sì ṣe àtúnṣe tó bá yẹ nínú ìdílé. Báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe é? Kí ló yẹ kí bàbá ṣe?
Ó hàn gbangba pé àwọn ọmọ nílò ìdílé tí gbogbo nǹkan ti ń lọ ní mẹ̀lọmẹ̀lọ, wọ́n ń fẹ́ nímọ̀lára pé ẹnì kan tó ń fẹ́ ire fún wọn ló ń bójú tó ilé àwọn. Bọ́rọ̀ ò bá ti rí bẹ́ẹ̀, ó máa ń ba àwọn ọmọ láyé jẹ́ ni, gẹ́gẹ́ bá a ṣe ń rí i lónìí. Síbẹ̀, ẹ máà jẹ́ ká sọ̀rètí nù, yálà bàbá wà nínú ilé o tàbí kò sí níbẹ̀. Nínú Sáàmù 68:5, Bíbélì sọ pé: “Baba àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba . . . ni Ọlọ́run nínú ibùgbé rẹ̀ mímọ́.”a
Bá A Ṣe Lè Rí Ìrànlọ́wọ́ Gbà
Bí Lidia ọmọbìnrin ará Poland tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú ṣe ṣàlàyé bí ipò nǹkan ṣe rí jẹ́ ká mọ̀ pé ká tó lè ṣàṣeyọrí nínú títọ́ ọmọ, ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run ṣe pàtàkì àti pé a lè rí i gbà. Báwo ni wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn nínú ìdílé rẹ̀? Báwo ni ìdílé rẹ̀ ṣe rí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run gbà?
Franciszek tó jẹ́ bàbá Lidia gbà pé nígbà táwọn ọmọ òun wà ní kékeré, òun pa ìdílé òun tì gẹ́gẹ́ bí ọmọbìnrin rẹ̀ ti sọ. Ó sọ pé: “Kò sí nǹkan tó kàn mí nínú ohun táwọn ọmọ wa ń ṣe. N kì í bá wọn ṣeré, kò sì sí ìfẹ́ òbí sọmọ́ láàárín wa.” Nítorí náà kò mọ̀ pé nígbà tí Lidia di ọmọ ọdún mẹ́rìnlá òun àti àbúrò rẹ̀ ọkùnrin ti ń lọ síbi àríyá tí ọtí ti ń ṣàn, wọ́n ti ń mu sìgá àti ọtí, wọ́n sì ti ń jà nígboro.
Nígbà tí Franciszek wá mọ bí ìjàngbọ̀n táwọn ọmọ òun ti fẹ́ kó sí ṣe lágbára tó, ẹ̀rù bà á débi tó fi pinnu láti ṣe nǹkan kan lórí ọ̀rọ̀ náà. Ó sọ pé: “Mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́.” Nígbà tí àdúrà rẹ̀ máa gbà, kò pẹ́ sígbà náà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ṣèbẹ̀wò sílé ẹ̀, òun àti ìyàwó ẹ̀ sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá àwọn méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí fi ohun tí wọ́n kọ́ ṣèwà hù. Ipa wo nìyẹn wá ní lórí àwọn ọmọ wọn o?
Franciszek ṣàlàyé pé: “Àwọn ọmọ mi bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé mo ti fi ọtí sílẹ̀, mo sì ti ń ṣe dáadáa sí wọn bíi bàbá. Wọ́n fẹ́ mọ̀ sí i nipa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn náà bá bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ́ọ̀ Bíbélì wọ́n sì kúrò nínú àwọn ẹgbẹ́ buburú tí wọ́n wà.” Rafał, ọmọkùnrin rẹ̀, sọ nípa bàbá ẹ̀ pé: “Mo wá fẹ́ràn rẹ̀ bí ọ̀rẹ́.” Ó fi kún un pé: “Mo kàn ṣáà dédé rí i pé ọkàn mi ṣí lára àwọn ọmọ ìta tí mò ń bá rìn yẹn ni. Ọwọ́ gbogbo wa nínú ìdílé wá dí fún àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí.”
Ọ̀kan nínú àwọn alàgbà ìjọ ni Franciszek báyìí ní ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń dara pọ̀ mọ́, ó ṣì ń bá a lọ láti máa bójú tó ìdílé rẹ̀ àti ìdàgbàsókè tẹ̀mí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn títí di báyìí. Aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn ajíhìnrere alákòókò kíkún, ni ìyàwó ẹ̀ àti Lidia. Rafał àti Sylwia, àbúrò rẹ̀ obìnrin ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, wọ́n máa ń lóhùn sí àwọn ìpàdé Kristẹni, wọ́n sì máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wọn fáwọn ẹlòmíràn.
Ó Fi Ohun Tó Kọ́ Wọn Sílò
Ẹ wo àpẹẹrẹ Luis bàbá Macarena náà. Ẹ má gbàgbé pé Macarena ni ọmọbìnrin ọmọ ọdún mọ́kànlélógún ará Sípéènì tá a kọ ọ̀rọ̀ tó sọ sí àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ yìí. Luis bá mímutí lámuyíràá lọ́wọ́ bàbá ẹ̀ ni. Gẹ́gẹ́ bí Macarena ṣe sọ, bàbá rẹ̀ yìí á kàn dédé pòórá nígbà míì tòun tàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ni, ó sì máa ń tó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ kó tó padà wálé. Kò tán síbẹ̀ o, bí ẹrú ló ṣe máa ń lo ìyàwó ẹ̀ dípò kó kà á sí ẹnì kejì òun. Béléńjá báyìí ló kù kí ìgbéyàwó wọn tú ká, èyí sì ń da ọkàn Macarena àtàwọn àbúrò rẹ̀ láàmú.
Àmọ́, nígbà tó yá, Luis gbà káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ṣàlàyé pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí lo àkókò mi lọ́dọ̀ ìyàwó àtàwọn ọmọ mi. À ń sọ̀rọ̀ pa pọ̀, à jọ ń jẹun a sì tún jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A tún jọ ń pín iṣẹ́ ilé ṣe bẹ́ẹ̀ la sì jọ ń ṣeré ìnàjú.” Macarena sọ pé: “Ìgbà náà ni mo tó bẹ̀rẹ̀ sí mọ̀ pé mo ní bàbá tó ń bójú tó ọmọ tó sì fi ọ̀rọ̀ ìdílé ẹ̀ sọ́kàn.”
Ohun kan tó yẹ ká kíyè sí nínú ọ̀rọ̀ yìí ni pé, kì í kàn ṣe pé Luis rọ ìdílé ẹ̀ láti máa sin Ọlọ́run nìkan ni o, àmọ́ ó fi ohun tó kọ́ wọn sílò. Ó pa “òwò kan tó ń mówó gọbọi wọlé” tì, gẹ́gẹ́ bí Macarena ṣe ṣàlàyé, “ìdí ni pé ó ń gba àkókò tó pọ̀ jù, ó sì fẹ́ bójú tó ọ̀ràn ìdílé ẹ̀ dáadáa sí i.” Ohun tó tẹ̀yìn ẹ̀ wá kọyọyọ. Macarena sọ pé: “Àpẹẹrẹ rẹ̀ ti kọ́ mi bó ṣe yẹ kí n jẹ́ kí ojú mi mú ọ̀nà kan kí n sì fi nǹkan tẹ̀mí sí ipò àkọ́kọ́.” Ó ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé báyìí, ìyá ẹ̀ àti àwọn àbúrò rẹ̀ sì ń ṣe déédéé nínú ìjọ Kristẹni.
Ìpinnu Ọ̀gá Àgbà Kan Nílé Iṣẹ́ Ọkọ̀ Ojú Irin
Ó ṣe kedere pé irú bàbá táwọn ọmọ nílò lẹni tá á ro tàwọn ọmọ ẹ̀ kó tó ṣèpinnu. Takeshi Tamura, tó jẹ́ ọ̀gá nílé iṣẹ́ kan lórílẹ̀-èdè Japan, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ní ọmọkùnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́langba tó ti ń kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́, ó sì dà bí i pé ọmọkùnrin rẹ̀ yìí ò ní pẹ́ kó sí wàhálà ńlá. Ọdún 1986 nìyẹn ṣẹlẹ̀, ọdún yẹn gan-an ni Takeshi pinnu láti fi ipò ọ̀gá ní Ilé Iṣẹ́ Ọkọ̀ Ojú Irin ti Orílẹ̀-Èdè Japan sílẹ̀. Ó ti pé ọdún méjìndílógún báyìí tó ti ṣe ìpinnu yẹn, báwo ló ṣe rí lára ẹ̀ nísinsìyí?
Láìpẹ́ yìí ó sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìpinnu tó dáa jù lọ tí mo tíì ṣe láyé mi nìyẹn. Èrè díẹ̀ kọ́ ni mo jẹ látinú lílo àkókò pẹ̀lú ọmọkùnrin mi àti ṣíṣe àwọn nǹkan pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀ títí tó fi mọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀. A di ọ̀rẹ́ ara wa, ó já gbogbo ọ̀rẹ́ burúkú tó ń bá rìn dà nù, ó sì jáwọ́ nínú ìwá tí ò bójú mu.”
Ìyàwó Takeshi ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí ọdún mélòó ṣáájú ìgbà yẹn, àpẹẹrẹ ìwà tó ń hù ló sì mú kí ọkọ rẹ̀ fẹ́ ṣàyẹ̀wò Bíbélì kó sì máa wà nítòsí ìdílé rẹ̀. Ní àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, àtòun, àtọmọkùnrin ẹ̀, àtọmọbìnrin ẹ̀, gbogbo wọn ló di Ẹlẹ́rìí. Takeshi àti ọmọkùnrin ẹ̀ ń sìn báyìí bí alàgbà ní ìjọ tí kálukú wọn wà, ìyàwó ẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ náà sì ń sìn bí aṣáájú-ọ̀nà.
Àwọn Bàbá Nílò Ìrànlọ́wọ́
Ọ̀pọ̀ bàbá ló mọ̀ pé àwọn ń pa àwọn ọmọ àwọn tì ṣùgbọ́n tí wọ́n ò mọ ohun tí wọ́n lè ṣe fún wọn. Ìwé ìròyìn èdè Sípéènì náà, La Vanguardia gbé àkọlé ìròyìn kan jáde tó kà pé “Ìdá Méjìlélógójì Nínú Ọgọ́rùn-ún Àwọn Òbí [Nílẹ̀ Sípéènì] Sọ Pé Àwọn Ò Mọ Báwọn Á Ṣe Tọ́ Àwọn Ọmọ Wọn Tó Jẹ́ Ọ̀dọ́langba.” A lè sọ ohun kan náà nípa àwọn bàbá tí wọ́n ní àwọn ogo wẹẹrẹ àtàwọn aròbó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ò rò bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ àwọn ọmọ kéékèèké wọ̀nyí nílò bàbá tá máa bójú tó wọn.
Kí la tún lè rí kọ́ nípa béèyàn ṣe lè jẹ́ bàbá dáadáa? Àwọn wo ló fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ lélẹ̀ fún àwọn bàbá, kí la sì lè rí kọ́ lára wọn? Àpilẹ̀kọ tá ó fi kádìí ìjíròrò wa yìí yóò yànàná àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ẹ jọ̀wọ́ ẹ wo àkòrí náà “Àwọn Ìdílé Olóbìí Kan Lè Kẹ́sẹ Járí!” nínú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn bàbá tó fún àwọn ọmọ wọn ní ohun tí wọ́n nílò
Franciszek àti ìdílé ẹ̀
Luis àti ìdílé ẹ̀
Takeshi àti ìdílé ẹ̀