ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb15 ojú ìwé 118-ojú ìwé 119 ìpínrọ̀ 4
  • “Mo Figboya Ja Bii Kinniun”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Mo Figboya Ja Bii Kinniun”
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Òtítọ́ Ń Yí Ìgbésí Ayé Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Gbogbo Wa La Nílò Ìtùnú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Irú Bàbá Táwọn Ọmọ Nílò
    Jí!—2004
  • Wọ̀n Ń Ṣàníyàn Jù Nítorí Ẹwà
    Jí!—2005
Àwọn Míì
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
yb15 ojú ìwé 118-ojú ìwé 119 ìpínrọ̀ 4

ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

“Mo Fìgboyà Jà Bíi Kìnnìún”

Luis Eduardo Montás

  • WỌ́N BÍ I NÍ 1906

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1947

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ó wà lára àwọn aláṣẹ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Rafael Trujillo tẹ́lẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì, ó sì sin Jèhófà tọkàntọkàn títí tó fi kú lọ́dún 2000.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 118

LUIS jẹ́ mọ̀lẹ́bí Trujillo, òun sì ni akápò ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń ṣèjọba nígbà náà, ìyẹn Partido Dominicano (Ẹgbẹ́ Òṣèlú Dominican). Àmọ́ Luis kò fara mọ́ ọ̀nà tí Trujillo gbà ń ṣèjọba, ó sì gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti fi ipò náà sílẹ̀, àmọ́ apàṣẹwàá yìí kò gbà fún un.

Nígbà tí Trujillo pa méjì lára àwọn ẹ̀gbọ́n Luis, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Luis náà gbìyànjú láti gbẹ̀mí Trujillo. Àmọ́ wọn ò fura sí i rárá. Luis tiẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń lo agbára òkùnkùn, ó ń wá bó ṣe máa pa Trujillo. Ó ní: “Bí ẹhànnà ló máa ń ṣe, ó sì gbà pé kò sí ẹni tó tó òun.” Nígbà tó dé ilé ọ̀kan lára àwọn tó ń lo agbára òkùnkùn náà, ó rí ìwé “Otitọ Yio Sọ Nyin Di Ominira” lórí tábìlì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Ohun tí Luis kà nínú ìwé náà wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an, torí náà, ó mú un lọ sílé, ó sì wá rí i pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ tóun ti ń wá ló wà níbẹ̀.

Nígbà tí Luis lọ sí ìlú Ciudad Trujillo, ó lọ sípàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì gba ìwé àti ìwé ìròyìn mélòó kan. Gbogbo òru ló fi ka àwọn ìwé náà, ó sì ní kí wọ́n wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí Luis ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ, ó pinnu pé òun ò ní bá Trujillo ṣèjọba mọ́. Nígbà tí apàṣẹwàá yìí gbọ́ ohun tí Luis fẹ́ ṣe, ó ní òun máa fún un ní ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́, pé òun máa sọ ọ́ di aṣojú ìjọba ilẹ̀ Dominican ní erékùṣù Puerto Rico. Àmọ́ Luis kò gba ìgbéga yẹn, bó tiẹ̀ mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí ìpinnu tóun ṣe yìí yọrí sí inúnibíni.

Luis sọ pé: “Kò sírú ìyà tíjọba yẹn ò fi jẹ mí tán, ṣe ni wọ́n ń dẹ pàkúté fún mi káàkiri. Àmọ́ mo ti pinnu pé mi ò ní lé adùn ayé yìí rárá.” Luis wá di akéde ìhìn rere tí kì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ débi pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Kátólíìkì àdúgbò rẹ̀ máa ń pè é ní “oníwàásù.” Luis ṣèrìbọmi ní October 5, ọdún 1947, oṣù mẹ́fà péré lẹ́yìn tó kọ́kọ́ wá sípàdé.

Lẹ́yìn tí Luis ṣèrìbọmi, wọ́n wá a kàn, wọ́n fi sẹ́wọ̀n, wọ́n sì tì í mọ́nú àhámọ́ lóun nìkan. Àìmọye ìgbà ni wọ́n gbìyànjú láti gbẹ̀mí rẹ̀. Síbẹ̀, ṣe ló máa ń wàásù nígbàkigbà tí wọ́n bá mú un lọ sílé ẹjọ́. Ó ní: “Mo fìgboyà jà bíi kìnnìún kí n lè gbèjà ohun tí mo gbà gbọ́, inú mi sì máa ń dùn tí n bá ti ń rántí.”

Àwọn ará àdúgbò Luis kíyè sí bó ṣe ń fi hàn pé òun jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Lọ́dún 1994, ìwé ìròyìn Orílẹ̀-èdè Dominican náà, El Siglo, sọ nípa Luis pé: “Ọmọlúwàbí èèyàn ni wọ́n mọ Ọ̀gbẹ́ni Luis Eduardo Montás sí nílùú San Cristobal. Ẹ̀bùn nínú èèyàn ni, ó máa ń gba tẹni rò, ó sì níwà jẹ́jẹ́. Gbogbo ohun tá a mọ̀ nípa ọkùnrin yìí nínú ìtàn ìlú San Cristobal kò ju pé ó máa ń ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́