ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 1/1 ojú ìwé 3-5
  • Òtítọ́ Ń Yí Ìgbésí Ayé Pa Dà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Òtítọ́ Ń Yí Ìgbésí Ayé Pa Dà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ète Nínú Ìgbésí Ayé
  • Ìdílé Tuntun
  • “Mo Figboya Ja Bii Kinniun”
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
  • Mo Bọ́ Lọ́wọ́ Ìdààmú Ìgbà Ọ̀dọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Jèhófà Ṣèlérí Èrè Àgbàyanu fún Dáníẹ́lì
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
  • Bíbélì Máa Ń Sọni Dèèyàn Rere
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 1/1 ojú ìwé 3-5

Òtítọ́ Ń Yí Ìgbésí Ayé Pa Dà

Ó BANI nínú jẹ́ ṣùgbọ́n òtítọ́ ni pé ìgbésí ayé ṣòro fún ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí, ó tilẹ̀ kún fún àìnírètí pàápàá. Ó ha ṣeé ṣe fún irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ láti rí ayọ̀ bí? Ọ̀daràn ni àwọn kan, wọ́n sì ń pa àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn lára. Wọ́n ha lè di aláìlábòsí nínú àwùjọ láé bí? Bẹ́ẹ̀ ni ni ìdáhùn sí ìbéèrè méjèèjì náà jẹ́. Àwọn ènìyàn lè yí pa dà. A lè yí ìgbésí ayé ẹni pa dà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi bí a ṣe lè ṣe èyí hàn nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà, kí ẹ̀yin lè fún ara yín ní ẹ̀rí ìdánilójú ìfẹ́ inú Ọlọ́run tí ó dára tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà tí ó sì pé.”—Róòmù 12:2.

Mímẹ́nu kan ‘ìfẹ́ inú Ọlọ́run tí ó pé’ lè mú wa rántí ohun tí Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní iye tí ó lé ní 20 ọdún ṣáájú kí Pọ́ọ̀lù tó kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà lókè yí. Jésù sọ pé: “Ẹ óò . . . mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:32) Nípa “òtítọ́” Jésù ń sọ nípa ìsọfúnni tí Ọlọ́run mí sí—pàápàá ìsọfúnni tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìfẹ́ inú Ọlọ́run—tí a pa mọ́ fún wa nínú Bíbélì. (Jòhánù 17:17) Òtítọ́ Bíbélì ha ń mú kí àwọn ènìyàn lómìnira ní tòótọ́ bí? Gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ inú Ọlọ́run ha ń yí ìgbésí ayé pa dà ní tòótọ́ bí? Ó ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní tòótọ́. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

Ète Nínú Ìgbésí Ayé

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Moisés, ní Gibraltar, jẹ́ ọkùnrin kan tí inú rẹ̀ kì í dùn rárá. Ó sọ pé: “Ọ̀mùtí ni mí, ìta ni mo sì máa ń sùn. Mo nímọ̀lára pé ìgbésí ayé mi ti bà jẹ́. Ní alaalẹ́, mo máa ń sọ fún Ọlọ́run láti bojú àánú wò mí, kí ó sì máà jẹ́ kí n tún wà nínú ipò kan náà ní ọjọ́ kejì. Mo sunkún bí mo ti bi Ọlọ́run léèrè ìdí tí mo fi wà láyé, bí mo ti jẹ́ ẹni tí kò ní láárí, tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́, tí kò nídìílé, tí kò sì ní olùrànlọ́wọ́ kankan. Kí ni mo wà láyé fún?” Lẹ́yìn náà, nǹkan kan ṣẹlẹ̀.

Moisés ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Mo mọ̀ pé Ọlọ́run ti gbọ́ àdúrà mi nígbà tí mo pàdé Roberto, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Roberto fún mi ní Bíbélì àti ẹ̀dà kan àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?a Lójoojúmọ́, a máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ lórí àga gbọọrọ ti mo máa ń sùn lé ní alẹ́. Lẹ́yìn oṣù kan Roberto mú mi lọ sí ìpàdé tí a ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kò pẹ́ kò jìnnà, òtítọ́ Bíbélì ti yí ojú ìwòye mi pa dà pátápátá. N kì í sùnta mọ́; n kò sì mu ọtí tàbí sìgá mọ́. Ìgbésí ayé mi ti yí pa dà, mo sì láyọ̀. Mo nírètí àtiṣe batisí láìpẹ́, kí n sì máa sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀.”

Ẹ wo irú ìyípadà tí èyí jẹ́! Nígbà tí àwọn ènìyàn kò bá nírètí, àìní ìmọ̀ ni ó sábà máa ń fà á. Wọn kò mọ̀ nípa Ọlọ́run tàbí nípa àwọn ète rẹ̀ àgbàyanu. Nínú ọ̀ràn Moisés, nígbà tí ó gba ìmọ̀ yẹn, ó fún un ní okun àti ìgboyà láti yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà. Àdúrà onísáàmù náà sí Ọlọ́run rí ìdáhùn nínú ọ̀ràn Moisés pé: “Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ àti òtítọ́ rẹ jáde, kí wọn kí ó máa ṣe amọ̀nà mi: kí wọn kí ó mú mi gun [òkè] mímọ́ rẹ, àti sínú àgọ́ rẹ wọnnì.”—Orin Dáfídì 43:3.

Ní Belize, Daniel ní irú ìrírí tí ó fara pẹ́ ẹ. Daniel kì í ṣe asùnta—ó ní iṣẹ́ tí ó buyì kúnni. Ṣùgbọ́n fún 20 ọdún ni ó ti ń bá ìjoògùnyó àti ìsọtí-di-bárakú jagun, ó sì jẹ́ oníṣekúṣe. Bí a tilẹ̀ tọ́ ọ dàgbà gẹ́gẹ́ bíi Kátólíìkì, Daniel kò rí ète èyíkéyìí nínú ìgbésí ayé, ó sì ṣiyè méjì nípa wíwà Ọlọ́run. Ó lọ sí onírúurú ṣọ́ọ̀ṣì, ní wíwá ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n ó rí i pé púpọ̀ nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì àti díẹ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ àlùfáà pàápàá ń joògùnyó tàbí ń mutí para. Láàárín àkókò náà, aya rẹ̀ ti ń múra àtikọ̀ ọ́ sílẹ̀.

Pẹ̀lú ìgbékútà, Daniel lọ sí ibùdó ìmúnipadàsípò. Síbẹ̀, ó mọ̀ pé lẹ́yìn tí wọ́n bá tú òun sílẹ̀, òun yóò pa dà sẹ́nu ìjoògùnyó òun láìpẹ́, bí kò bá rí ìrànlọ́wọ́ gbà. Ṣùgbọ́n, irú ìrànlọ́wọ́ wo? Ní May 1996, lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí ó fi ibùdó ìmúnipadàsípò sílẹ̀, Daniel tọ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ, ó sì yà á lẹ́nu pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ náà pé, “Jọ̀wọ́, kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú mi.” Ẹlẹ́rìí náà ṣètò láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Daniel lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀, kò sì pẹ́ tí Daniel fi bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìgbésí ayé rẹ̀ bá ìfẹ́ inú Ọlọ́run mu, tí ó sì fi àwọn ọ̀rẹ́ Kristẹni, tí kì í joògùnyó tàbí mu ọtí àmupara, tí wọ́n sì kọ ìwà pálapàla sílẹ̀, rọ́pò àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtijọ́. Nípa báyìí, Daniel rí i pé ohun tí Bíbélì sọ jẹ́ òtítọ́ pé: “Ẹni tí ó ń bá ọlọgbọ́n rìn yóò gbọ́n; ṣùgbọ́n ẹgbẹ́ àwọn aṣiwèrè ni yóò ṣègbé.” (Òwe 13:20) Láìpẹ́, ó sọ pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí nínú ìgbésí ayé mi ti mo mọ ohun tí níní ẹ̀rí ọkàn mímọ́ túmọ̀ sí.” Ìgbésí ayé Daniel pẹ̀lú yí pa dà.

Ní Puerto Rico, ọkùnrin mìíràn nírìírí ìyípadà ńláǹlà. Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni ó wà, wọ́n sì kà á sí eléwu ènìyàn, níwọ̀n bí ó ti pa ọ̀pọ̀ ènìyàn. Òtítọ́ Bíbélì ha lè yí i pa dà bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Ó ṣeé ṣe fún ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti fún un ní àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, kíá ni ó sì béèrè fún púpọ̀ sí i. A bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀, bí òtítọ́ Bíbélì sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í nípa lórí ọkàn àyà rẹ̀, ìyípadà tí ó ṣe fara hàn kedere sí gbogbo ènìyàn. Ọ̀kan lára ẹ̀rí àkọ́kọ́ tí ó ṣe kedere nínú ìyípadà rẹ̀ ni pé ó gé irun rẹ̀ gígùn mọ́lẹ̀, ó sì fá irùngbọ̀n rẹ̀ tí ó ti ta kókó dànù.

Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ń dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n ronú pìwà dà ní tòótọ́, tí wọ́n sì yí ọ̀nà ìgbésí ayé wọn pa dà. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé àwọn aláìṣòdodo ènìyàn kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? . . . Síbẹ̀ ohun tí àwọn kan lára yín sì ti jẹ́ rí nìyẹn. Ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín mọ́.” (Kọ́ríńtì Kíní 6:9, 11) Kò sí iyè méjì pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tu ọkùnrin yìí nínú, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ inú Ìṣe 24:15 tí ó sọ pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà,” ṣe tù ú nínú. Ó wí pé: “N óò fẹ́ láti wà níbẹ̀ nígbà tí àjíǹde àwọn òkú bá wáyé, kí n baà lè tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn tí mo gba ẹ̀mí wọn.”

Ìdílé Tuntun

Ní ọjọ́ kan, a mú Luis, ajíhìnrere alákòókò kíkún ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ajẹntínà, mọ ọ̀dọ́kùnrin kan tí ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ ṣeni láàánú. Àwọn òbí rẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bí i, a sì tọ́ ọ dàgbà ní onírúurú ibùdó. Nígbà tí ó tó nǹkan bí ọmọ 20 ọdún, ó gbọ́ nípa ibi tí ìyá rẹ̀ wà, ó sì pinnu láti gbé nítòsí rẹ̀. Ó ṣiṣẹ́ kára, ó tu ọ̀pọ̀ owó jọ, ó sì rìnrìn àjò lọ sí ìlú tí ìyá rẹ̀ wà. Ìyá rẹ̀ jẹ́ kí ó gbé pẹ̀lú òun títí owó rẹ̀ fi tán, ó sì sọ fún un pé kí ó fi ilé òun sílẹ̀ lẹ́yìn náà. Ìkọ̀tì yí mú un fẹ́ kí ó pa ara rẹ̀.

Ṣùgbọ́n, ó ṣeé ṣe fún Luis láti ṣàjọpín òtítọ́ Bíbélì pẹ̀lú ọ̀dọ́kùnrin yìí. Òtítọ́ náà ní ìmúdánilójú náà nínú pé: “Nígbà tí bàbá àti ìyá mi kọ̀ mí sílẹ̀, nígbà náà ni Olúwa yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” (Orin Dáfídì 27:10) Ọ̀dọ́kùnrin náà wá rí i pé òun ní Bàbá kan ní ọ̀run tí kì yóò pa òun tì láé. Ó láyọ̀ nísinsìnyí láti jẹ́ ara ìdílé tuntun kan, ìdílé Jèhófà.

Ọkùnrin mìíràn ní orílẹ̀-èdè kan náà sọ fún ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé òun nífẹ̀ẹ́ sí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́. Èé ṣe? Nítorí pé ó dá ìgbéyàwó rẹ̀ sí. Ó jọ bíi pé ní ọjọ́ kan, ọkùnrin yìí, bí ó ti ń fi ibi iṣẹ́ sílẹ̀, ó rí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tí a kọ “Ìkọ̀sílẹ̀” ní lẹ́tà gàdàgbàgàdàgbà sí lórí nínú apẹ̀rẹ̀ ìdalẹ̀sí. Níwọ̀n bí ìṣòro ti bá ìgbéyàwó rẹ̀, tí òun àti aya rẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbégbèésẹ̀ láti pínyà lọ́nà tí ó bófin mu, ó yọ ìwé ìròyìn náà jáde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Ó mú un lọ sílé, ó sì kà á pẹ̀lú aya rẹ̀. Tọkọtaya náà gbìyànjú láti fi ìmọ̀ràn inú ìwé ìròyìn náà tí a gbé karí Bíbélì sílò. (Éfésù 5:21–6:4) Kò pẹ́ kò jìnnà, ipò ìbátan wọn sunwọ̀n sí i. Wọn dáwọ́ ìgbégbèésẹ̀ láti pínyà dúró, wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya tí ó wà níṣọ̀kan nísinsìnyí.

Ní Uruguay, ọkùnrin mìíràn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Luis kò láyọ̀ rárá. Ìjoògùnyó, ìbẹ́mìílò, jíjọ́sìn ère, ìmutípara—àwọn nǹkan wọ̀nyẹn jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ohun tí ó mú kí ìgbésí ayé rẹ̀ dojú rú. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, nígbà tí gbogbo nǹkan tojú sú u, Luis di aláìgbọlọ́rungbọ́. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan fún un ní ìwé Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation?b Èyí yọrí sí níní àjọṣe ráńpẹ́ pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ìgbà díẹ̀, ṣùgbọ́n kò pẹ́ tí Luis fi pa dà sídìí ọtí àti oògùn líle rẹ̀. Nígbà tí ó bá ara rẹ̀ lórí àkìtàn, nínú làásìgbò gidi kan, ó gbàdúrà, ó gbà á sí “bàbá Jésù Kristi,” níwọ̀n bí kò ti mọ orúkọ Ọlọ́run.

Ó sọ fún Ọlọ́run pé kí ó fi han òun bí ìdí èyíkéyìí bá wà fún wíwà tí òun wà nínú ayé. Luis ròyìn pé: “Ní ọjọ́ kejì gan-an, ojúlùmọ̀ mi kan fún mi ní ìwé kan tí kò wúlò fún un mọ́. Kí ni àkọlé rẹ̀? Revelation—Its Grand Climax At Hand!”c Ìwé náà ràn án lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè rẹ̀. Luis tún gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ nínú rírí ìsìn tí yóò fi bí a ti ń sin Ọlọ́run han òun. Ẹ wo irú ìyàlẹ́nu tí ó jẹ́! Agogo ẹnu ọ̀nà dún, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì sì ni ó wà lẹ́nu ọ̀nà. Lọ́gán ni Luis bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn. Ìtẹ̀síwájú rẹ̀ yára kánkán, ó sì nímọ̀lára nísinsìnyí pé ìbùkún ńlá ni ó jẹ́ fún òun pé òun jẹ́ Ẹlẹ́rìí tí ó ti batisí. Ó ń gbé ìgbésí ayé oníwà mímọ́, ó sì ń ran àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú lọ́wọ́ láti rí ète nínú ìgbésí ayé wọn. Fún un, ọ̀rọ̀ inú Orin Dáfídì 65:2 ti nímùúṣẹ: “Ìwọ tí ń gbọ́ àdúrà, sí ọ̀dọ̀ rẹ ni gbogbo ènìyàn ń bọ̀.”

Ní Philippines, Allan ti fìgbà kan rí jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ alákitiyan ọ̀ràn ìṣèlú. Ó jẹ́ mẹ́ńbà àjọ kan tí ète wọ́n jẹ́ “láti dojú ìjọba dé, kí àwọn ìran ẹ̀yìn ọ̀la lè gbádùn wíwà lọ́gbọọgba.” Ṣùgbọ́n, ní ọjọ́ kan, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn sí i, ó sì kọ́ nípa ète Ọlọ́run fún aráyé láti inú Bíbélì. Ète náà ní ìlérí tí a mí sí náà nínú pé: “Nígbà díẹ̀, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sì . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ayé; wọn óò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.” (Orin Dáfídì 37:10, 11) Allan sọ pé: “Kò pẹ́ tí mo fi rí i pé a ti ṣèlérí ohun tí àjọ wa ń jà fún tipẹ́tipẹ́ nínú Bíbélì. Gbogbo ohun tí a ń fìgbónára fọkàn fẹ́ yóò wáyé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.” Nísinsìnyí, Allan ń ṣalátìlẹyìn Ìjọba Ọlọ́run, ó sì ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ nínú òtítọ́ Bíbélì.

Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbésí ayé ń yí pa dà nígbà tí àwọn ènìyàn bá kọbi ara sí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì. Ní tòótọ́, àkókò ń bọ̀ nígbà tí gbogbo ẹ̀dá ènìyàn tí ó bá là á já yóò ti mú ìgbésí ayé wọn bá ìfẹ́ inú Ọlọ́run mú. Ẹ wo irú ìyípadà tí ìyẹn yóò jẹ́! Nígbà náà, àsọtẹ́lẹ̀ náà yóò ti nímùúṣẹ pé: “Wọn kì yóò pani lára, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò pani run ní gbogbo òkè mímọ́ mi: nítorí ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwa gẹ́gẹ́ bí omi ti bo òkun.”—Aísáyà 11:9.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

b Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

c Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́