ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g05 1/8 ojú ìwé 15
  • Wọ̀n Ń Ṣàníyàn Jù Nítorí Ẹwà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ̀n Ń Ṣàníyàn Jù Nítorí Ẹwà
  • Jí!—2005
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bi Mo Se Mo Ohun Ti Maa Fi Aye Mi Se
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
  • “Mo Figboya Ja Bii Kinniun”
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
  • Ewu Tó Wà Nínú Kéèyàn Fẹ́ Lẹ́wà Ní Gbogbo Ọ̀nà
    Jí!—2005
  • A Fara Da Ìpọ́njú, Jèhófà sì Bù Kún Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
Àwọn Míì
Jí!—2005
g05 1/8 ojú ìwé 15

Wọ̀n Ń Ṣàníyàn Jù Nítorí Ẹwà

NǸKAN ń lọ déédéé fún Mariaa gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́bìnrin, iléere ló sì ti wá. Síbẹ̀, inú ẹ̀ kì í dùn. Kí ló wa ń bà á nínú jẹ́? Bó ṣe rí ò tẹ́ ẹ lọ́rùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn ará ilé ẹ̀ ló ń gbà á níyànjú, Maria ṣì gbà pé òun ò lẹ́wà páàpáà, ìyẹn sì máa ń dà á láàmú.

Iléere ni wọ́n ti bí José, èèyàn ò sì lé rí i kó rò pé ó yẹ kí ohunkóhun máa bà á nínú jẹ́. Àmọ́, ó gbà pé òun ò lè rí ìyàwó fẹ́. Kí ló dé tó fi rò bẹ́ẹ̀? José rò pé ojú òun ò fani mọ́ra, ó lóun tiẹ̀ burẹ́wà. Lójú ara ẹ̀, kò sí obìnrin gidi kan tá á wù kó fẹ́ ẹ.

Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni Luis, kì í fẹ́ pa ilé ìwé jẹ, ó sì máa ń yá mọ́ọ̀yàn. Ó máa ń fẹ́ bá àwọn ọmọ ilé ìwé ẹlẹgbẹ́ ẹ̀ ṣeré ṣùgbọ́n ó máa ń sunkún ṣáá pé wọ́n ń fi òun ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí bóun ṣe rí. Wọ́n máa ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ pé ó sanra.

Àwọn mẹ́tà yìí nìkan kọ́ lọ̀rọ̀ wọn rí báyìí o. Ohun tó ń ṣe Maria, José, àti Luis kọjá pé wọn ò fojú ẹni iyì wo ara wọn. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé kò sẹ́ni tó máa ń fẹ́ káwọn èèyàn fojú tí ò dáa wo òun nítorí bóun ṣe rí.

Àmọ́ ohun tó ń ká àwọn èèyàn lára láyé tá a wà nínú ẹ̀ ni pé ìrínisí ni ìsọni lọ́jọ̀. Ó tiẹ̀ dà bíi pé ìrísí èèyàn gan-an lá sọ bóyá onítọ̀hún á rọ́wọ́ mú àbí kò ní rọ́wọ́ mú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tí ìrísí wọn fani mọ́ra jù ló dà bíi pé wọ́n tètè máa ń ríṣẹ́. Pilar Muriedas, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdarí Agbo Ìlera Àwọn Obìnrin Láwọn Ilẹ̀ Latin-America àti Erékùṣù Caribbean sọ pé, ní ti àwọn obìnrin “ọ̀kan lára àwọn nǹkan pàtàkì tó lè mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí ni pé kí wọ́n dùn ún wò.” Bákan náà, Ọ̀mọ̀wé Laura Martínez sọ pé àwọn obìnrin gan-an mọ̀ pé bí wọ́n bá wo gbogbo nǹkan lọ bí wọ́n bá wò ó bọ̀, wọ́n ṣì ń bọ̀ wá fàbọ̀ sorí “bí wọ́n ṣe rí kí wọ́n tó lè gbà wọ́n síṣẹ́.”

Ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin pẹ̀lú ló ti dẹni tó kó gbogbo àníyàn wọn lórí bí ara wọn ṣe máa wà “láìlábàwọ́n.” Àní ọ̀pọ̀ èèyàn, lọ́kùnrin àti lóbìnrin ni ò kọ nǹkan tó bá máa ná wọn láti lè di arẹwà, kódà wọ́n lè pebi mọ́nú tàbí kí wọ́n fara mọ́ títa ríro nítorí àtiṣe ojú tàbí ara wọn kí wọ́n lè lẹ́wà débi tí wọ́n bá ń lẹ́wà dé. Kí ni wọ́n fẹ́ rí gbà nínú gbogbo eléyìí o? Ǹjẹ́ ewu kankan tiẹ̀ wà nídìí ẹ̀?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ tá a lò padà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ìrísí ara lè jẹ́ kí àǹfààní tó dáa tẹ èèyàn lọ́wọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́