ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 9/8 ojú ìwé 22-23
  • Bíbélì Geneva Ìtumọ̀ Bíbélì Táráyé Ti Gbàgbé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bíbélì Geneva Ìtumọ̀ Bíbélì Táráyé Ti Gbàgbé
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bíbélì Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀
  • Gbígbìyànjú Láti Túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Lọ́nà Pípéye
  • Àwọn Àlàyé Etí Ìwé Tó Ń Fa Arukutu
  • Bí Bíbélì Geneva Ṣe Wọlẹ̀
  • A Ò Lè Gbàgbé Rẹ̀ Bọ̀rọ̀
  • Kí Ló Ti Jẹ́ Àbájáde Ẹ̀kọ́ Ìsìn Calvin Láti Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Ọdún?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Ọ̀kẹ́ Àìmọye Èèyàn Mọyì Rẹ̀ Kárí Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ìṣẹ̀lẹ̀ Mánigbàgbé Fáwọn Tó Fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Bíbélì Tó Rọrùn Láti Lóye
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 9/8 ojú ìwé 22-23

Bíbélì Geneva Ìtumọ̀ Bíbélì Táráyé Ti Gbàgbé

Látọwọ́ òǹkọ̀wé Jí! ní New Zealand

ǸJẸ́ o ní Bíbélì kóńkó kan tó ṣe é mú dání tó sì ní àwọn lẹ́tà tó rọrùn láti kà láìní da ojú ẹ láàmú? Ṣé bí wọ́n ṣe ṣe é mú kó rọrùn fún ọ láti tètè rí nǹkan tó ò ń wá nínú ẹ̀? Bí ìdáhùn rẹ sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kó o dúpẹ́ gan-an pé wọ́n tẹ ìtumọ̀ Bíbélì kan tí wọ́n ń pè ní Bíbélì Geneva jáde lọ́dún 1560.

Lóde òní ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló tíì gbọ́ nípa Bíbélì Geneva rí. Síbẹ̀, nígbà ayé ẹ̀, wìtìwìtì ni Bíbélì yìí ń tà. Ó gbayì gan-an nígbà yẹn nítorí pípé tọ́rọ̀ inú ẹ̀ pé pérépéré àti ọ̀nà tí wọ́n gbà tẹ̀ ẹ́ lábala lábala, èyí ló mú káwọn èèyàn fẹ́ràn àtimáa kà á. Shakespeare àti Marlowe, àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n jẹ́ eléré orí ìtàgé lò ó nígbà tí wọ́n ń fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú Bíbélì.

Báwo tiẹ̀ ni Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì tó gbajú gbajà ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún yìí ṣe wá di nǹkan tó wá láti ìlú Geneva tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé lórílẹ̀-èdè Switzerland? Kí làwọn ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ẹ̀? Kí ló fà á tó fi wọlẹ̀? Báwo la ṣì ṣe ń jàǹfààní ẹ̀ títí dòní?

Bíbélì Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀

Àwọn tó sá lọ sẹ́yìn odi láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà tí Mary Tudor gorí àlééfà lọ́dún 1553, tó sì lóun máa rẹ́yìn gbogbo àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn mìíràn yàtọ̀ sí ẹ̀sìn Kátólíìkì ló ṣe Bíbélì Geneva. Tọ́wọ́ tẹsẹ̀ ni wọ́n gba àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ yìí sáàárín àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì tó wà nílùú Geneva. Níwọ̀n bí iṣẹ́ ìtẹ̀wé ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in nígbà náà ní Geneva táwọn èèyàn sì nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì kíkà níbẹ̀, pẹrẹu niṣẹ́ títúmọ̀ àti títẹ Bíbélì ń lọ ní ìlú yìí.

Ọdún 1560 ni wọ́n gbé Bíbélì Geneva jáde, William Whittingham àtàwọn olùrànlọ́wọ́ ẹ̀ ló sì túmọ̀ rẹ̀. Láìpẹ́ sígbà náà làwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í kà á lákàtúnkà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ó rọrùn kà ju àwọn Bíbélì tí wọ́n tẹ̀ jáde ṣáájú ẹ̀, ohun ni Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n kọ́kọ́ pín sí ẹsẹẹsẹ tí wọ́n sì kọ nọ́ńbà sí ẹsẹ kọ̀ọ̀kan, gbogbo Bíbélì tó wà lóde títí dòní ni wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Lára àwọn nǹkan tó tún wà níbẹ̀ làwọn àkọlé ojú ìwé, ìyẹn àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì ṣókí tí wọ́n kọ sókè ojú ìwé kọ̀ọ̀kan láti ran àwọn tó bá ń kà á lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ibi tí wọ́n ń wá lójú ìwé náà. Kò tán síbẹ̀ o, dípò kí wọ́n fi lẹ́tà dúdú tó ki tí wọ́n fi máa ń ṣe bátànì sórí ìwé tẹ̀ ẹ́, lẹ́tà tó hàn ketekete tí wọ́n fi máa ń tẹ àwọn Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì lóde òní ni wọ́n fi tẹ̀ ẹ́.

Fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ fẹrẹgẹdẹ làwọn Bíbélì tí wọ́n ṣe ṣáájú ìgbà náà fún kíkà lórí àga ìwàásù inú ṣọ́ọ̀ṣì rí, àwọn ojú ìwé kọ̀ọ̀kan sì ti ṣe jàn-àn-ràn jù. Àmọ́ Bíbélì Geneva kéré débi pé ó ṣeé mú dání, kò fẹ̀ ju ìlàjì ojú ìwé kan ti àwọn Bíbélì tó wà tẹ́lẹ̀ lọ. Kì í ṣe pé Bíbélì kóńkó yìí dùn ún kà tó sì dùn ún kẹ́kọ̀ọ́ nìkan ni ṣùgbọ́n kò tún wọ́n rárá.

Gbígbìyànjú Láti Túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Lọ́nà Pípéye

Àwọn tó túmọ̀ Bíbélì Geneva rí i dájú pé àwọn ò sọ ẹwà èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi kọ Bíbélì nù. Jèhófà, tí í ṣe orúkọ Ọlọ́run fara hàn láwọn ibi mélòó kan nínú ẹ̀, tó fi mọ́ Ẹ́kísódù 6:3; 17:5; àti Sáàmù 83:18. Wínníwínní ni wọ́n kọ àwọn ọ̀rọ̀ táwọn olùtumọ̀ náà gbà pé dandan ni káwọn fi kún Bíbélì, àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi kún un kí ohun tó wà níbẹ̀ lè ṣe kedere níbàámu pẹ̀lú ìlò èdè sì wà nínú àkámọ́.

Kò pẹ́ tí wọ́n fi fọwọ́ sí Bíbélì Geneva gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n á máa lò nílẹ̀ Scotland. Wọ́n tún lò ó káàkiri ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì òun sì làwọn èèyàn gbà gbọ́ pé àwọn arìnrìn àjò tó tẹ̀dó sílùú Plymouth mú dání nígbà tí wọ́n rìnrìn àjò lọ́dún 1620 lọ síbi tó wá di Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà báyìí. Wọ́n mú Bíbélì Geneva lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tó wà lábẹ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì títí tó fi dé ilẹ̀ New Zealand tó jìnnà jù lára wọn. Níbẹ̀, lọ́dún 1845 ẹ̀dà kan Bíbélì náà di ara ohun tó wà nínú ẹrù Ọlọ́lá Gómìnà George Grey.

Àwọn Àlàyé Etí Ìwé Tó Ń Fa Arukutu

Ara nǹkan tó jẹ́ kí Bíbélì Geneva gbayì láàárín àwọn tó ti ń kà á fún àkókò gígùn ni àwọn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé tí wọ́n ṣe sí etí ìwé tí wọ́n tẹ̀ ẹ́ sí. Ìdí tí wọ́n fi fàwọn àlàyé yẹn kún un ni pé, àwọn olùtumọ̀ náà wòye pé ‘àwọn ibi tó le’ tàbí àwọn apá ibi tó ṣòro láti lóye wà nínú Bíbélì. Irú àwọn àlàyé etí ìwé bẹ́ẹ̀ kì í ṣe nǹkan tuntun. Tyndale ti fi wọ́n sínú “Májẹ̀mú Tuntun” tó ṣe lọ́dún 1534. Yàtọ̀ sí àwọn àlàyé etí ìwé, Bíbélì Geneva tún ní àwọn àwòrán, àwọn ọ̀rọ̀ ìṣáájú àtàwọn àwòrán ilẹ̀ tó lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lóye rẹ̀. Lára àwọn ohun tó wà láwọn ojú ìwé mìíràn ni àwọn ìṣètò àkọsílẹ̀ oníṣirò tí wọ́n fi ṣàlàyé nípa ìlà ìran, àwọn àkópọ̀ ohun tó wà láwọn ojú ewé náà àti apá ibì kan tó ń rọni láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́ pàápàá.

Àwọn ọmọ Ìjọ Áńgílíkà ta ko ìtumọ̀ Bíbélì náà ní gbangba nítorí pé wọ́n gbà pé àwọn àlàyé etí ìwé yẹn ti dorí Bíbélì kodò, síbẹ̀ wọ́n gbédìí fún ìtumọ̀ Bíbélì náà ní kọ̀rọ̀. Matthew Parker, tó jẹ́ Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà àgbègbè Canterbury nígbà yẹn, pè wọ́n ní “àwọn àlàyé tí ò lórí tí ò nídìí tó lè fa ẹ̀tanú.” Ọba James Kìíní sọ pé àwọn àlàyé yẹn “pọ̀n sọ́nà kan, wọ́n kì í ṣe òótọ́, wọ́n sì lè rúná sí ọ̀tẹ̀.” Ìdí tí wọ́n fi sọ gbogbo ìyẹn ò yani lẹ́nu, nígbà tó jẹ́ pé àwọn kan nínú àwọn àlàyé yẹn ti sọ pé kì í ṣe “àṣẹ Ọlọ́run” làwọn ọba yẹn ń lò!

Bí Bíbélì Geneva Ṣe Wọlẹ̀

Lọ́dún 1604, Ọba James fàṣẹ sí i pé kí wọ́n ṣe ìtumọ̀ Bíbélì tuntun tó máa káńgárá Bíbélì Geneva kúrò nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Òpìtàn ìsìn náà, Alister McGrath sọ pé “olórí ìṣòro tó dojú kọ Bíbélì King James Version lákòókò táwọn èèyàn ń fẹ́ máa mọ̀ ọ́n ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún ni rírí tí Bíbélì Geneva ṣì ń rọ́wọ́ mú láàárín àwọn èèyàn.” Fún ọ̀pọ̀ ọdún làwọn aráàlú fi gba ti Bíbélì Geneva, ọ̀pọ̀ ọdún ló sì fi jẹ́ Bíbélì àjùmọ̀lò nílẹ̀ Scotland. Títí di ọdún 1644 làwọn ẹ̀dà rẹ̀ tí wọ́n ń tún ṣe ṣì fi wà nígboro.

Ẹgbẹ́ Bíbélì ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Ilẹ̀ Òkèèrè sọ pé “àyẹ̀wò Bíbélì Ọba James tí wọ́n tẹ̀ jáde lọ́dún 1611 fi hàn pé àwọn tó túmọ̀ Bíbélì náà . . . lo Bíbélì Geneva ju bí wọ́n ṣe lo ìtumọ̀ Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì èyíkéyìí mìíràn.” Ọ̀pọ̀ ọgbọ́n táwọn olùtumọ̀ Bíbélì Geneva dá àti ọ̀pọ̀ ọ̀nà tí wọ́n gbà gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ ní wọ́n tẹ̀ lé nínú Bíbélì King James Version.

A Ò Lè Gbàgbé Rẹ̀ Bọ̀rọ̀

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì Authorized Version, tí wọ́n tún ń pè ní King James Version ló rọ́pò Bíbélì Geneva, síbẹ̀ ipa tó kó nínú ìtàn táwọn èèyàn ń kà lónìí kì í ṣe kékeré. Yàtọ̀ sí ti pé ó la ọ̀nà tuntun tí wọ́n á gbà máa túmọ̀ Bíbélì àti ọ̀nà tí wọ́n á gbà máa ṣe é, òun tún ni wọ́n sábà máa ń tọ́ka sí nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe àtúnṣe sáwọn Bíbélì tó wà lédè Gẹ̀ẹ́sì. Ó gbin ìfẹ́ láti máa ka Bíbélì àti ìfẹ́ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sọ́kàn onírúurú àwọn èèyàn tí wọn ì bá máa tiẹ̀ fojú kàn án.

Nípa bó ṣe jẹ́ pé òun ló jẹ́ kí Bíbélì Ọba James wá sójú táyé, Bíbélì Geneva tún mú àwọn gbólóhùn inú Bíbélì wọnú àwọn ìwé Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Gẹ̀ẹ́sì fúnra rẹ̀. Nítorí náà, bí onírèsé Bíbélì Geneva ò bá tiẹ̀ fíngbá mọ́ èyí tó ti fín sílẹ̀ ó lè pa run láéláé.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Ẹ́kísódù 6:3, níbi tí a ti rí orúkọ Ọlọ́run

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwọn àkọlé ojú ìwé

Àwòrán

Àwọn àlàyé etí ìwé

[Credit Line]

Gbogbo fọ́tò: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure ti American Bible Society

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 22]

Gbogbo fọ́tò: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure ti American Bible Society

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́