ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 9/8 ojú ìwé 3-5
  • Ẹ̀tanú Lóríṣiríṣi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀tanú Lóríṣiríṣi
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀tanú Tó Ti Wà Láti Ọ̀pọ̀ Ọ̀rúndún
  • Ìwà ẹ̀tanú—ìṣòro tó kárí ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àwọn Nǹkan Tó Ń Fa Ẹ̀tanú
    Jí!—2004
  • Ṣé O Ní Ìkórìíra?
    Jí!—2020
  • Ìgbà Wo Ni Ayé Yìí Máa Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀tanú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 9/8 ojú ìwé 3-5

Ẹ̀tanú Lóríṣiríṣi

“Bó o bá lé ẹ̀tanú gba ẹnu ilẹ̀kùn jáde, á tún padà gba ojú fèrèsé wọlé.”—Frederick Ńlá, Ọba Prussia.

PALIYAD, abúlé kan tó wà ní Íńdíà ni Rajesh ń gbé. Bíi tàwọn míì tí wọ́n jẹ́ ẹni ìtanù láwùjọ, ó ní láti rin ìrìn ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kó tó lè gbé omi dé ibi táwọn ẹbí ẹ̀ ń gbé. Ó ṣàlàyé pé: “Wọn kì í jẹ́ ká pọnmi lẹ́nu ẹ̀rọ tó wà lábúlé, nítorí pé ẹnu ẹ̀rọ yẹn làwọn tó fira wọn sípò ajunilọ ti ń pọnmi.” Nígbà tí Rajesh wà nílé ẹ̀kọ́, òun àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ò tiẹ̀ lè fọwọ́ kan bọ́ọ̀lù táwọn ọmọ yòókù ń gbá. Ó sọ pé: “Òkúta la fi ń ṣeré ní tiwa.”

Christina, ọ̀dọ́langba kan tó wá láti ilẹ̀ Éṣíà, ṣùgbọ́n tó ń gbé ní Yúróòpù, sọ pé: “Mo mọ̀ pé àwọn èèyàn kórìíra mi, ṣùgbọ́n mi ò mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.” Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ohun tó ń bani lọ́kàn jẹ́ gbáà ni. Ó sì sábà máa ń mú kí n ya ara mi láṣo, síbẹ̀, ìyẹn ò ní kí ọ̀ràn náà ṣẹ́ pẹ́rẹ́.”

Stanley, tó wá láti Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà sọ pé: “Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni mí nígbà tí mo kọ́kọ́ mọ ohun tó ń jẹ́ ẹ̀tanú. Àwọn tá ò jọ mọra rí ni wọ́n sọ fún mi pé kí n káńgárá mi kúrò nílùú. Wọ́n tiẹ̀ jó ilé àwọn kan tá a jọ wá látinú ẹ̀yà kan náà kanlẹ̀. Wọ́n sì gbẹ́sẹ̀ lé owó bàbá mi tó wà ní báńkì. Nítorí èyí, mo bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra ẹ̀yà tó ń yàn wá jẹ.”

Ẹ̀tanú ni wọ́n ń ṣe sí Rajesh, Christina àti Stanley yẹn o, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń ṣe é sí àwọn míì. Olùdarí àgbà fún Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tó Ń Bójú Tó Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀ (UNESCO), Koichiro Matsuura, ṣàlàyé pé: “Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló ṣì ń fojú winá ìṣòro ẹ̀tanú ẹ̀yà ìran, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ẹ̀mí àìfẹ́ rí àjèjì sójú àti ìdẹ́yẹsíni lónìí.” “Ọmọ tí àìmọ̀kan àti ẹ̀tanú bí ni irú ìwà ìfojú-ẹ̀dá-gbogi bẹ́ẹ̀, ó ti dá rògbòdìyàn abẹ́lé sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, ó sì ti fojú àwọn èèyàn rí màbo.”

Bí wọn ò bá tíì ṣe ẹ̀tanú sí ọ rí, ó lè ṣòro fún ọ láti lóye bó ṣe máa ń dani lọ́kàn rú tó. Ìwé Face to Face Against Prejudice sọ pé: “Àwọn kan wulẹ̀ ń rún un mọ́ra ni. Bí wọ́n bá sì ṣe ẹ̀tanú sáwọn kan, ọ̀pọ̀ ẹ̀tanú ni wọ́n fi ń san án padà.” Láwọn ọ̀nà wo ni ẹ̀tanú ń gbà ṣe ìgbésí ayé ẹni báṣabàṣa?

Bó o bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn tí ò pọ̀ láwùjọ, o lè rí i pé ńṣe làwọn èèyàn á máa yẹra fún ọ, wọ́n á máa fojú pa ọ́ rẹ́, tàbí kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ àbùkù nípa ibi tó o ti wá. Àtiríṣẹ́ lè dogun, àyàfi tó o bá máa ṣiṣẹ́ rírẹlẹ̀ tí ò sẹ́ni tó fẹ́ ṣe é. Bóyá ó sì lè ṣòro fún ọ láti rílé tó dáa gbé. Wọ́n lè máa dẹ́yẹ sáwọn ọmọ rẹ nílé ẹ̀kọ́ káwọn ọmọ tí wọ́n jọ ń lọ sílé ẹ̀kọ́ má sì fẹ́ gba tiwọn.

Èyí tó tún wá burú ńbẹ̀ ni pé ẹ̀tanú lè sún àwọn èèyàn hùwà ipá tàbí kí wọ́n tiẹ̀ pààyàn. Kódà, látilẹ̀ wá la ti ń rí ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn ìwà ipá tí ń dani lọ́kàn rú èyí tí ẹ̀tanú lè fà, tó fi mọ́ ìpakúpa, ìpẹ̀yàrun àti mímọ̀ọ́mọ̀ pa ẹ̀yà ìran kan run.

Ẹ̀tanú Tó Ti Wà Láti Ọ̀pọ̀ Ọ̀rúndún

Ìgbà kan wà tí wọ́n dìídì dojú ẹ̀tanú kọ àwọn Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, kété lẹ́yìn ikú Jésù, wọ́n dojú inúnibíni líle koko kọ àwọn Kristẹni. (Ìṣe 8:3; 9:1, 2; 26:10, 11) Ní ọ̀rúndún méjì lẹ́yìn náà, ńṣe ni wọ́n ń ṣe àwọn tó bá sọ pé Kristẹni làwọn bí ọṣẹ ṣe ń ṣe ojú. Tertullian, òǹkọ̀wé kan tó gbáyé ní ọ̀rúndún kẹta, kọ̀wé pé: “Bí àjàkálẹ̀ àrùn èyíkéyìí bá bẹ́ sílẹ̀, igbe tí wọ́n á mú bọnu ni pé, ‘Ẹ Fi Àwọn Kristẹni fún Kìnnìún Jẹ.’”

Àmọ́ ṣá o, látìgbà táwọn Ogun Ìsìn ti bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀rúndún kọkànlá, àwọn Júù ti di àwùjọ kéréje tí wọn kì í fẹ́ rí sójú nílẹ̀ Yúróòpù. Nígbà tí àrùn tó ń jẹ́ kí kókó so sára gbalẹ̀ kan ní àgbáálá Ilẹ̀ yìí, tó sì pa nǹkan bí ìdámẹ́rin lára àwọn tó ń gbé níbẹ̀ ní ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ péré, àwọn Júù ni wọ́n di ẹ̀bi ọ̀ràn rù, níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ èèyàn ti kórìíra wọn tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Nínú ìwé rẹ̀, Invisible Enemies, Jeanette Farrell kọ̀wé pé: “Àjàkálẹ̀ àrùn yìí ni wọ́n sọ pé ó fà á táwọn fi kórìíra àwọn Júù. Ìkórìíra yìí sì sún àwọn tó ń bẹ̀rù àjàkálẹ̀ àrùn náà láti dúnràn mọ́ àwọn Júù pé àwọn ló fà á.”

Nígbà tó ṣe, ọkùnrin Júù kan tó wà ní gúúsù ilẹ̀ Faransé “jẹ́wọ́” nígbà tí ìyà tọ̀ ọ́ lára já pé májèlé táwọn Júù dà sínú kànga ló fa àjàkálẹ̀ àrùn náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èké ni ìjẹ́wọ́ tó ṣe, òótọ́ làwọn èèyàn gba ọ̀rọ̀ náà sí. Kò pẹ́ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí dúńbú gbogbo àwọn Júù ní Sípéènì, ilẹ̀ Faransé àti Jámánì bí ẹní dúńbú ẹran. Ó dà bí ẹni pé kò sẹ́ni tó kọbi ara sáwọn ọ̀dádá tó dá àjàkálẹ̀ àrùn náà sílẹ̀ gan-an, ìyẹn àwọn eku. Ìwọ̀nba èèyàn kéréje ló sì kíyè sí i pé bí àjàkálẹ̀ àrùn náà ṣe ń pa ará yòókù, bẹ́ẹ̀ náà ló ń pa àwọn Júù!

Léyìí tí wọ́n sì ti wá tanná ran ẹ̀tanú yìí o, kí iná náà máa jó lọ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ló kù. Ní apá ìdajì ọ̀rúndún ogún, Adolf Hitler mú káwọn èèyàn máa kórìíra àwọn Júù nípa dídẹ́bi fún wọn pé àwọn ló fà á tí wọ́n fi ṣẹ́gun àwọn ará Jámánì nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Ní ìparí Ogún Àgbáyé Kejì, Rudolf Hoess, olórí àwọn ọmọ ogun Násì tó ń bójú tó ibi àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Auschwitz, sọ pé: “Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wa gẹ́gẹ́ bí ológun àti èrò tí wọ́n gbìn sí wa lọ́kàn ti mú ká gbà pé á ṣáà gbọ́dọ̀ gba Jámánì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Júù ni.” Kí wọ́n bàa lè “dáàbò bo Jámánì,” Hoess ṣètò bí wọ́n ṣe pa mílíọ̀nù méjì èèyàn, tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn jẹ́ Júù.

Ó bani nínú jẹ́ pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ti kọjá lẹ́yìn ìgbà yẹn, ìwà ìkà bíburú jáì ò tíì kásẹ̀ nílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní ọdún 1994, ìkórìíra ẹ̀yà wáyé ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà láàárín àwọn ẹ̀yà Tutsi àti Hutu, ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] èèyàn ló sì bá a lọ. Ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Kò sí ibi àsálà kankan. Ọ̀gbàrá ẹ̀jẹ̀ ṣàn gba inú ṣọ́ọ̀ṣì níbi táwọn èèyàn fara pa mọ́ sí. . . . Ìjà ojú-ko-ojú làwọn èèyàn ń jà, wọ́n ń para wọn bí wọ́n ṣe fẹ́, ìjà náà múni gbọ̀n rìrì, ńṣe ló dà bíi pé ó kàn ṣáà wu àwọn èèyàn láti máa tàjẹ̀ sílẹ̀ ni, ṣìbáṣìbo bá àwọn tó ṣèèṣì là á já, jẹbẹtẹ sì gbọ́mọ lé wọn lọ́wọ́.” Kódà, ìwà ipá tí ń múni díjì náà ò yọ àwọn ọmọdé sílẹ̀. Ọmọ ilẹ̀ Rwanda kan ṣàlàyé pé: “Orílẹ̀-èdè kékeré ni Rwanda. Ṣùgbọ́n ibẹ̀ ni ìkórìíra pin sí.”

Ìjà tó wáyé nígbà tí Yugoslavia àtijọ́ pín sí méjì dá ẹ̀mí àwọn èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba [200,000] légbodò. Àwọn aládùúgbò tí wọ́n ti ń bára wọn gbé láìjà láìta fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún pa ara wọn. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn obìnrin ni wọ́n fipá bá lò pọ̀, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn ni wọ́n sì fipá lé kúrò nínú ilé wọn lórúkọ ìlànà rírorò tó ń jẹ́ pípa ẹ̀yà ìran run.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ẹ̀tanú ni kò yọrí sí ìpànìyàn, ó sábà máa ń pín àwọn èèyàn níyà ó sì máa ń fa ìkórìíra. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé ti lu jára lóòótọ́, síbẹ̀ ẹ̀tanú ẹ̀yà ìran àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà “ló fẹ́rẹ̀ẹ́ gbilẹ̀ jù lọ níbi tó pọ̀ jù lọ lórí ilẹ̀ ayé,” gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ẹnu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí látọ̀dọ̀ àjọ UNESCO ṣe sọ.

Ǹjẹ́ ohun kan wà tá a lè ṣe láti mú ẹ̀tanú kúrò? Láti dáhùn ìbéèrè yẹn, a gbọ́dọ̀ mọ bí ẹ̀tanú ṣe ń bẹ̀rẹ̀ nínú ọkàn àti àyà àwọn èèyàn.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Bí A Ṣe Lè Dá Ẹlẹ́tanú Mọ̀

Nínú ìwé rẹ̀ The Nature of Prejudice, Gordon W. Allport to ìwà márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ẹ̀tanú máa ń fà lẹ́sẹẹsẹ. Ẹlẹ́tanú èèyàn máa ń ṣe ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ohun márùn-ún wọ̀nyí.

1. Kòbákùngbé ọ̀rọ̀. Onítọ̀hún á máa fọ̀rọ̀ tàbùkù àwọn èèyàn tí kò bá fẹ́ràn.

2. Yíyẹra fúnni. Kò ní fẹ́ fojú gán-ánní ẹni tó bá jẹ́ ara àwọn èèyàn yẹn.

3. Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Kò ní jẹ́ kí ẹni tó bá wá látinú àwùjọ yẹn ṣe irú àwọn iṣẹ́ kan, kò ní jẹ́ kí wọ́n gbé ní irú àdúgbò kan, kò sì ní jẹ́ kí wọ́n gbádùn irú àwọn àǹfààní kan tí ìjọba fi ń ran ìlú lọ́wọ́.

4. Ìfìyàjẹni. Á máa kópa nínú ìwà ipá tí wọ́n bá dá sílẹ̀ nítorí àtiṣẹ̀rùba àwọn èèyàn tó bá kórìíra.

5. Ìfikúpani. Á máa bá wọn dáwọ́ jọ lu èèyàn pa, á máa kópa nínú ìpakúpa, tàbí nínú àwọn ààtò ìfikúpani mìíràn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi ní Benaco, lórílẹ̀-èdè Tanzania, May 11, 1994

Obìnrin kan tó gbé ọwọ́ lé orí ike omi rẹ̀. Ó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àwọn ara Rwanda olùwá-ibi-ìsádi, tí èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn jẹ́ Hutu, tí wọ́n sá gba Tanzania lọ

[Credit Line]

Fọ́tò tí Paula Bronstein/Liaison yà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́