Àwọn Nǹkan Tó Ń Fa Ẹ̀tanú
OHUN tó ń fa ẹ̀tanú lè pọ̀ o. Ṣùgbọ́n, ìdí méjì pàtàkì tí ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ jẹ́rìí sí ni (1) kéèyàn máa wá ẹni tó máa di ẹ̀bi rù ṣáá àti (2) ìkórìíra nítorí ìrẹ́jẹ tó ti wáyé rí nígbà kan gbàkàn.
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, nígbà tí ìjábá bá ṣẹlẹ̀, àwọn èèyàn sábà máa ń wá ẹni tí wọ́n á di ẹ̀bi rẹ̀ rù. Táwọn sànmàrí ìlú bá ń fẹ̀sùn kan àwọn tí wọn ò kà sí láwùjọ lemọ́lemọ́, ìyẹn ti tó fáwọn èèyàn láti ka ẹ̀sùn náà sóòótọ́ kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ẹ̀tanú sí wọn. Àpẹẹrẹ kan tí kò mù ni tìgbà tí ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ ní Yúróòpù àti Àríwá Amẹ́ríkà, àwọn òṣìṣẹ́ tó jẹ́ àjèjì ni wọ́n ń di ẹ̀bi àìríṣẹ́ rù ṣáá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ọmọ onílẹ̀ tó máa ń fẹ́ láti ṣe irú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe.
Àmọ́, kì í ṣe wíwá ẹni di ẹ̀bi rù ló ń fa gbogbo ẹ̀tanú ṣá o. Ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá nígbà kan gbàkàn náà tún lè fà á. Ìròyìn kan tí wọ́n pè ní UNESCO Against Racism sọ pé: “Kì í ṣe àsọdùn bá a bá sọ pé òwò ẹrú ló gbin èèbù ìkà tó wá yọrí sí kíkórìíra táwọn ẹ̀yà mìíràn kórìíra ẹ̀yà ìran àwọn adúláwọ̀ àti ọ̀nà tí wọ́n gbà ń gbé ìgbésí ayé wọn.” Àwọn olówò ẹrú gbìyànjú láti dá ìwà àìlójútì tó mú kí wọ́n máa ra àwọn èèyàn kí wọ́n sì máa tà wọ́n lọ́jà bí ẹran orí ìso láre, nípa sísọ pé ẹni rírẹlẹ̀ làwọn Adúláwọ̀. Ẹ̀tanú tí ò nídìí yìí, tó tún wá gbòòrò dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n ń ṣàkóso lé lórí, ṣì ń bá a nìṣó.
Jákèjádò ayé, àwọn ìtàn ìninilára àti ìwà ìrẹ́nijẹ bí èyí tá a mẹ́nu kàn lókè yìí ló ń mú kí ẹ̀ṣẹ́ná ẹ̀tanú ṣì máa ta pàràpàrà. Láti ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, nígbà táwọn alákòóso ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń ṣe inúnibíni sáwọn Kátólíìkì tí wọ́n sì ń lé wọn kúrò nílùú, ni kèéta ti wà láàárín àwọn Kátólíìkì àtàwọn Pùròtẹ́sítáǹtì. Ìwà ìkà bíburú jáì táwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ hù nígbà tí wọ́n ja Ogun Ẹ̀sìn ṣì ń mú kí inú máa bí àwọn Mùsùlùmí tó wà ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn. Pípa tí wọ́n pa àwọn aráàlú lọ bẹẹrẹbẹ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì ló tún bepo síná gbúngbùngbún tó ti fẹ̀ẹ̀kàn wà láàárín àwọn ará Serbia àti Croatia tí wọ́n ń gbé ní ibi tó ń jẹ́ Balkan. Gẹ́gẹ́ bí àwọn àpẹẹrẹ yìí ṣe fi hàn, bọ́jọ́ bá ti pẹ́ táwùjọ àwọn èèyàn méjì ti ń bára wọn ṣọ̀tá, ńṣe ni ẹ̀tanú tí wọ́n ní síra wọn á túbọ̀ máa lágbára sí i.
Bí Àìmọ̀kan Ṣe Ń Sọ Àwọn Èèyàn Di Ẹlẹ́tanú
Ẹ̀tanú kì í sí lọ́kàn ọmọ àfànítẹ̀ẹ̀tẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn olùṣèwádìí sọ pé àwọn ọmọdé kì í wojú kí wọ́n tó bá ọmọ míì tí ẹ̀yà tiẹ̀ yàtọ̀ ṣeré. Àmọ́ ṣá o, nígbà tọ́mọ kan á bá fi pé ọmọ ọdún mẹ́wàá sí mọ́kànlá, ó lè máà fẹ́ràn àwọn èèyàn tí ẹ̀yà tàbí ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ mọ́. Nígbà tọ́mọdé bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbọ́njú, ọ̀pọ̀ èrò búburú tó máa wà lọ́kàn ẹ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀ ni wọ́n a ti gbìn sí i lọ́kàn.
Báwo ni wọ́n ṣe ń gbin èrò yìí síni lọ́kàn? Látinú ohun tí òbí ọmọ kan bá ń sọ tàbí tó ń hù níwà, lá á ti kọ́kọ́ kọ́ nípa níní èrò òdì káwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn olùkọ́ rẹ̀ tó wá fi tiwọn kún un. Bó bá sì yá, àwọn aládùúgbò, ìwé ìròyìn, rédíò tàbí tẹlifíṣọ̀n tún lè gbin àfikún oró sí i nínú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìwọ̀nba ni ohun tó mọ̀ nípa àwọn èèyàn tó kórìíra náà tàbí kó má tiẹ̀ mọ nǹkan kan nípa wọn, nígbà tóun náà bá fi máa dàgbà á ti gbà nínú ọkàn ara ẹ̀ pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan, wọn ò sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Ó tiẹ̀ lè kórìíra wọn pàápàá.
Bí àwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń rìnrìn àjò tí wọ́n sì ń ṣowó káàkiri àgbáyé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè làwọn èèyàn tí ibùgbé wọn yàtọ̀ síra tí wọ́n sì wá látinú ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti ń bára pàdé wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ báyìí. Síbẹ̀, èrò òdì tí wọ́n bá ti gbìn sọ́kàn ẹni tó ní ẹ̀tanú yẹn náà kò ní kúrò lọ́kàn rẹ̀ bọ̀rọ̀. Ó lè máa fi ojú kan náà wo ẹgbẹẹgbẹ̀rún tàbí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn kó sì gbà lọ́kàn ara rẹ̀ pé irúkìírú kan náà ni gbogbo wọn. Bí ẹnì kan péré nínú wọn bá wá jàjà ṣe ohun kan tí ò tẹ́ ẹ lọ́rùn, á kúkú yáa koná mọ́ ẹ̀tanú tó ní sí wọn. Ẹ̀wẹ̀, bí àwọn kan nínú wọn bá ṣe ohun tó dára, ńṣe lá wulẹ̀ kà á sí pé ó ṣèèṣì ni.
Jíjáwọ́ Nínú Ẹ̀tanú
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnu lásán lọ̀pọ̀ èèyàn fi ń sọ pé ẹ̀tanú ò dára, ìwọ̀nba èèyàn kéréje ni kò ní ẹ̀tanú. Kódà, ọ̀pọ̀ àwọn tí ẹ̀tanú ti ta gbòǹgbò lọ́kàn wọn ṣì máa ń sọ pé àwọn kì í ṣe ẹlẹ́tanú. Àwọn kan ní kò sóhun tó burú níbẹ̀, báwọn ò bá ti ṣe é sí ẹnikẹ́ni. Síbẹ̀, ẹ̀tanú burú, ó bùrùjà pàápàá, nítorí pé ó máa ń pa àwọn èèyàn lára ó sì máa ń pín wọn níyà. Bó bá jẹ́ pé àìmọ̀kan ló ń fa ẹ̀tanú, nígbà náà, a jẹ́ pé ẹ̀tanú ló sábà máa ń fa ìkórìíra. Òǹkọ̀wé Charles Caleb Colton (tó ṣeé ṣe kó gbáyé lọ́dún 1780 sí ọdún 1832) ṣàlàyé pé: “Ohun tó máa ń múni kórìíra àwọn èèyàn kan ni pé a ò mọ̀ wọ́n; a ò sì ní mọ̀ wọ́n nítorí pé a kórìíra wọn.” Àmọ́ ṣá o, bó bá jẹ́ pé kíkọ́ lèèyàn máa ń kọ́ ẹ̀tanú, a jẹ́ pé kì í ṣe ohun téèyàn ò lè jáwọ́ nínú ẹ̀. Ṣùgbọ́n lọ́nà wo lèèyàn lè gbà jáwọ́ nínú ẹ̀?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
Ṣé Ẹ̀tanú Ló Yẹ Kí Ẹ̀sìn Fi Kọ́ni Ni àbí Ẹ̀mí Ìkónimọ́ra?
Nínú ìwé rẹ̀, The Nature of Prejudice, Gordon W. Allport sọ pé: “ní ìpíndọ́gba, ó dà bí ẹni pé ẹ̀tanú tàwọn tí ń re Ṣọ́ọ̀ṣì pọ̀ ju tàwọn tí kì í lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì lọ.” Èyí kò yani lẹ́nu nítorí pé dípò kí ìsìn mú ẹ̀tanú kúrò ńṣe ló sábà máa ń fà á. Bí àpẹẹrẹ, fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún làwọn àlùfáà fi súnná sí ìkórìíra àwùjọ àwọn Júù. Gẹ́gẹ́ bí ìwé A History of Christianity ṣe sọ, Hitler sọ nígbà kan rí pé: “Ní ti àwọn Júù, ìlànà tó ti bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì láti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1500] ọdún sẹ́yìn ni mò ń gùn lé.”
Nígbà ìwà ìkà bíburú jáì tó wáyé níbi tó ń jẹ́ Balkan, ó dà bí ẹni pé ẹ̀kọ́ táwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì àti Kátólíìkì fi ń kọ́ àwọn èèyàn ò lágbára tó láti mú kí wọ́n ní ẹ̀mí ìkónimọ́ra àti ọ̀wọ̀ fún àwọn aládùúgbò tí ìsìn tiwọn yàtọ̀.
Bákan náà, lórílẹ̀-èdè Rwanda, ńṣe làwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì kan náà ń dúńbú ara wọn. Ìwé ìròyìn National Catholic Reporter sọ pé ìjà tó wáyé níbẹ̀ jẹ́ “ìpẹ̀yàrun pọ́ńbélé, èyí tó ṣeni láàánú pé àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì pàápàá pín nínú ẹ̀bi ẹ̀.”
Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì náà ti wá gbà pé àwọn ò rára gba nǹkan sí. Níbi ayẹyẹ Máàsì fún gbogbo èèyàn tó wáyé nílùú Róòmù, lọ́dún 2000, Póòpù John Paul Kejì bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì nítorí “àwọn ohun tó kù-díẹ̀-káàtó tí wọ́n ti ṣe kọjá.” Nígbà tí ayẹyẹ náà ń lọ lọ́wọ́, “àìfàyè gba ẹ̀sìn àwọn Júù àti ìwà ìrẹ́jẹ tí wọ́n hù sí àwọn obìnrin, àwọn ọmọ onílẹ̀, àwọn àjèjì, àwọn òtòṣì àtàwọn tí wọn ò tíì bí” ni wọ́n dìídì mẹ́nu kàn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Òkè: Àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, Bosnia àti Herzegovina, October 20, 1995
Àwọn olùwá-ibi-ìsádi ará Serbia méjì tí wọ́n wà ní Bosnia tí wọ́n ń retí ìgbà tí ogun abẹ́lé máa parí
[Credit Line]
Fọ́tò tí Scott Peterson/Liaison yà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
A kọ́ wọn láti kórìíra
Ọmọ kan lè kọ́ èrò òdì látọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, látorí tẹlifíṣọ̀n àti láti ibòmíràn