Àwọn Èwe Tí Wọn Ò Fi Ìgbàgbọ́ Wọn Bò
Ọ̀PỌ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n fẹ́ràn Ọlọ́run wọ́n sì ń sapá láti jẹ́ kí àwọn ìlànà tó là kalẹ̀ nínú Bíbélì máa darí àwọn. Kóríyá ni ìgbàgbọ́ àwọn èwe wọ̀nyí jẹ́ fún wọn, wọn ò sì tijú láti sọ fáwọn ẹlòmíì nípa ìgbàgbọ́ wọn nílé ìwé. Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ rèé.
◼ Nígbà tí Holly wà ní kíláàsì kẹfà, wọ́n ní kí òun àtàwọn tí wọ́n jọ wà ní kíláàsì kọ àròkọ lórí ìbéèrè náà “Báwo ni wàá ṣe yanjú ìṣòro àwọn apániláyà láìfipá ṣe é?” Holly lo àǹfààní yìí láti kọ̀wé nípa ìgbàgbọ́ tó ní nínú ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ iwájú. Ó ṣàlàyé pé láti ọjọ́ táláyé ti dáyé ni “ènìyàn ti [ń] jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Lẹ́yìn náà ló wá ṣàlàyé nípa ìrètí tòótọ́ kan ṣoṣo tó wà fún aráyé, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run. Ó kọ̀wé pé: “Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jésù ni ẹni tí Ọlọ́run yàn ṣe Ọba Ìjọba yẹn, gbogbo ìṣòro pátá, tó fi mọ́ ìpániláyà, ni Ọlọ́run á mú kúrò.” Holly wá ṣàlàyé síwájú sí i nípa bí Jésù á ṣe ṣe ohun tí alákòóso ẹ̀dá èèyàn kankan ò lè ṣe. Ó kọ̀wé pé: “Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ìṣesí rẹ̀ jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú alákòóso tó máa jẹ́. Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó sì ṣe ohun tí wọ́n nílò fún wọn. Ó fi agbára tó ní hàn nípa wíwo onírúurú àìsàn àti nípa jíjí òkú dìde. Kò sí ìjọba èèyàn kankan tó lè jí àwọn òkú dìde. Ṣùgbọ́n ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe nìyẹn.” Holly wá parí àròkọ rẹ̀ báyìí pé, “Ọlọ́run ló lè yanjú ìṣòro náà, kì í ṣe ẹ̀dá èèyàn.”
Olùkọ́ rẹ̀ kọ ọ́ sábẹ́ àròkọ náà pé: “Èyí mà ga o! Holly, àròkọ ẹ yìí ti lọ wà jù. Alárògún gbáà ni.” Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí Holly tọ́ka sí tún wú olùkọ́ rẹ̀ lórí. Èyí fún Holly láǹfààní láti bá olùkọ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni, èyí tó máa ń wáyé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tayọ̀tayọ̀ ni olùkọ́ rẹ̀ fi gba ẹ̀dà kan ìwé àkànlò tí wọ́n máa ń lò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run yìí.
◼ Jessica náà ti láǹfààní láti sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀ nígbà tó ń kọ àròkọ ní ilé ẹ̀kọ́. Ó sọ pé: “Ní báyìí, ó ti di àròkọ mẹ́ta tí mo kọ nípa ìgbàgbọ́ mi. Ọ̀kan dá lórí ẹ̀tọ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní láti ṣe ẹ̀sìn wa. Olùkọ́ náà fi í síbi ìkówèésí kí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ lè lọ kà á níbẹ̀. Lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, mo kọ àròkọ kan nípa ìrìbọmi mi àti bí ọjọ́ yẹn ṣe ṣe pàtàkì fún mi tó. Àwa akẹ́kọ̀ọ́ gba àròkọ ara wa kà nígbà tá a kọ́kọ́ kọ ọ́, ìyẹn sì mú káwọn tá a jọ wà ní kíláàsì rí àròkọ mi kà. Ọmọbìnrin kan lára wọn sọ pé: ‘Iṣẹ́ lo ṣe. Ó dáa kéèyàn mọ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo kí ẹ kúu ti ìrìbọmi rẹ o!’ Ọmọbìnrin míì sọ pé: ‘Àgbà ẹ̀ ni àròkọ rẹ yìí o! Inú mi dùn pé ìgbàgbọ́ rẹ lágbára gan-an!’ Ọmọkùnrin kan ní tiẹ̀ kọ̀wé pé: ‘Ọgbọ́n yí ẹ nínú po. Mo bá ẹ yọ̀.’”
◼ Nígbà tí Melissa pé ọmọ ọdún mọ́kànlá, ó ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ó sọ pé: “Nọ́ọ̀sì ilé ẹ̀kọ́ wa yọjú sí wa nígbà tá à ń kọ́ ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì kó lè bá wa sọ̀rọ̀ nípa àwọn adènà àrùn tó wà nínú ara. Bá a ṣe bá ọ̀rọ̀ dórí ìfàjẹ̀sínilára nìyẹn o. Lẹ́yìn tí iṣẹ́ ọjọ́ náà parí, mo sọ fún olùkọ́ tó ń kọ́ wa ní sáyẹ́ǹsì nípa àwọn kásẹ́ẹ̀tì fídíò wa tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀jẹ̀. Mo mú un lọ síléèwé lọ́jọ́ kejì, olùkọ́ mi mú un relé òun àti ìdílé rẹ̀ sì wò ó. Ó mú un padà wá fún mi lọ́jọ́ kejì ó sì fi han àwa akẹ́kọ̀ọ́ tá a wà ní kíláàsì méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Lẹ́yìn ìyẹn ló wá sọ àwọn ọ̀rọ̀ kóríyá nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì sọ fún àwa akẹ́kọ̀ọ́ tá a wà ní kíláàsì náà pé bí kì í bá ṣe nítorí tiwa ni kì bá tí rọrùn láti tètè rí ohun téèyàn lè lò dípò ẹ̀jẹ̀. Nígbà tó ń dá kásẹ́ẹ̀tì fídíò náà padà fún mi, ó bi mí pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè rí ẹ̀dá kan tí màá fi síbi ìkówèésí ilé ìwé?’ Mo fún un ní ẹ̀dà kan. Inú àwa méjèèjì dùn kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ!”
Holly, Jessica, àti Melissa wà lára ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń tẹ̀ lé ìṣílétí Bíbélì pé kí wọ́n rántí Ẹlẹ́dàá wọn nígbà èwe wọn. (Oníwàásù 12:1) Ìwọ náà ńkọ́? Bó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, mọ̀ dájú pé ò ń mú inú Jèhófà dùn, òun náà sì mọrírì ìsapá rẹ gidigidi.—Òwe 27:11; Hébérù 6:10.
Nígbà tẹ́yin ọ̀dọ́ bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ yín fáwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ àti fáwọn olùkọ́ yín, ẹ̀rí tó lágbára ni ìyẹn á jẹ́ fún wọn nípa Jèhófà Ọlọ́run àti àwọn ohun tó fẹ́ ṣe. Yóò mú kí ìgbàgbọ́ tiyín pẹ̀lú lágbára, yóò sì mú kínú yín dùn kára yín sì yá gágá pé ẹ ní àǹfààní láti wà lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. (Jeremáyà 9:24) Jíjẹ́rìí ní ilé ẹ̀kọ́ tún jẹ́ ààbò. Nígbà tó ń ṣàlàyé bó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀, Jessica sọ pé: “Àǹfààní kan tí mo ti rí látinú sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí mo gbà gbọ́ ni pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kì í sún mi ṣe àwọn nǹkan tí kò bá ohun tí Bíbélì sọ mu.”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Holly
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30, 31]
Jessica
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Melissa