ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 6/22 ojú ìwé 11-13
  • Kí Ló Dé Tí N Kò Lè Kẹ́kọ̀ọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Dé Tí N Kò Lè Kẹ́kọ̀ọ́?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpèníjà Kíkojú Rẹ̀
  • Kọ́ Láti Pọkàn Pọ̀
  • Dídín Àìsinmi Kù
  • Ní Ọ̀wọ̀ Ara Ẹni Rẹ Síbẹ̀
  • Ibo La Ti Lè Rí Òtítọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
  • Kí Ni Kí N Ṣe Bí Mi Ò Bá Ṣe Dáadáa Tó?
    Jí!—2004
  • Kí Ló Burú Nínú Bíbára Ẹni Jáde Ní Bòókẹ́lẹ́?
    Jí!—2007
  • Àlàyé Jessica
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 6/22 ojú ìwé 11-13

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Ló Dé Tí N Kò Lè Kẹ́kọ̀ọ́?

Jessica rántí pé: “N kò fẹ́ láti wá sí ilé, kí ń wá kojú àwọn òbí mi. Mo tún fìdí rẹmi nínú àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ bíi mélòó kan lẹ́ẹ̀kan sí i.”a Ní ọmọ ọdún 15, Jessica jẹ́ olóye ọmọ, ó sì rẹwà. Àmọ́, bíi ti àwọn èwe púpọ̀, ó máa ń fìdí rẹmi nínú àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀.

ÀÌṢE dáadáa ní ilé ẹ̀kọ́ ni ó sábà máa ń jẹ́ ìyọrísí ìṣarasíhùwà tí kò dára sí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tàbí sí olùkọ́ ẹni. Àmọ́, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀ràn ti Jessica kọ́ nìyẹn. Ó wulẹ̀ rí i bí ohun tí ó ṣòro gidigidi láti lóye àwọn àlàyé dídíjú ni. Lọ́nà ti ẹ̀dá, èyí mú kí ó ṣòro fún Jessica láti kẹ́sẹ járí nínú ẹ̀kọ́ ìṣirò. Ìṣòro àìlèkàwé sì mú kí ó ṣòro fún un láti ṣe dáradára nínú àwọn iṣẹ́ ẹ̀kọ́ mìíràn.

Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Maria kò lè kọ ẹyọ ọ̀rọ̀ pé lọ́nà yíyẹ rẹ́gí. Ó sábà máa ń fi àwọn àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní àwọn ìpàdé Kristẹni pa mọ́ nítorí pé ojú ń tì í fún àwọn àṣìṣe tí ó ń ṣe nínú kíkọ ẹyọ ọ̀rọ̀ sílẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, kò sí èyí tí kò lóye lórí nínú Jessica àti Maria. Jessica ń ní àjọṣe dídán mọ́rán pẹ̀lú àwọn ènìyàn débi tí a fi yàn án gẹ́gẹ́ bí alárinà tàbí olùyanjú ìṣòro fún ilé ẹ̀kọ́, tí wàhálà bá ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Ní ti ìmọ̀ ẹ̀kọ́, Maria wà lára àwọn ìpín 10 àkọ́kọ́ nínú ọgọ́rùn-ún akẹ́kọ̀ọ́ tí ń ṣe dáradára jù lọ ní kíláàsì rẹ̀.

Ìṣòro ibẹ̀: Jessica àti Maria ní àwọn ìṣiṣẹ́gbòdì agbára ìkẹ́kọ̀ọ́. Àwọn ògbógi gbà gbọ́ pé nǹkan bí ìpín 3 sí ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún lára gbogbo àwọn ọmọdé lè ní irú ìṣòro kan náà nípa kíkẹ́kọ̀ọ́. Tania, tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé díẹ̀ ní ọmọ 20 ọdún nísinsìnyí, ní ìṣòro Àrùn Araàbalẹ̀ Tí Ń Fa Agbára Ìfiyèsílẹ̀ Tí Ó Lábùkù (ADHD).b Ó sọ pé: “Nǹkan máa ń le koko fún mi ní àwọn ìpàdé Kristẹni, ìkẹ́kọ̀ọ́ ara ẹni, àti lákòókò àdúrà nítorí àìlèpọkànpọ̀ tàbí láti lè jókòó sójú kan pàápàá. Ó nípa lórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi nítorí pé mo máa ń yára fò láti orí kókó ọ̀rọ̀ kan sí òmíràn jù tí kò fi ń rọrùn fún ẹnì kan láti máa fọkàn bá mi lọ.”

Nígbà tí àìlèfiyèsílẹ̀ kò bá bá a rìn, àrùn náà ni a ń pè ní Àrùn Agbára Ìfiyèsílẹ̀ Tí Ó Lábùkù (ADD). A sábà máa ń ṣàpèjúwe àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àrùn yìí gẹ́gẹ́ bí alálàá-ọ̀sán-gangan. Nípa ti àwọn tí wọ́n ní àrùn ADD, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ètò ìgbékalẹ̀ iṣan ọpọlọ, Dókítà Bruce Roseman, sọ pé: “Wọn óò ṣíwèé síwájú fún ìṣẹ́jú 45, ṣùgbọ́n nǹkan kan kò ní wọ ọpọlọ wọn.” Fún ìdí yòówù kí ó jẹ́, wọ́n ní ìṣòro ìpọkànpọ̀.

Àwọn olùṣèwádìí ìṣègùn gbà gbọ́ pé àwọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í lóye ohun tí ń fa ìṣòro wọ̀nyí. Síbẹ̀, púpọ̀ ṣì wà tí wọn kò tí ì mọ̀. Àwọn ààlà tí ó sì wà láàárín onírúurú àrùn àti àbùkù ara tí ń nípa lórí ẹ̀kọ́ kíkọ́ kì í fìgbà gbogbo ṣe kedere. Láìka okùnfà rẹ̀ gan-an tàbí orúkọ tí a fún àrùn kan pàtó sí—yálà ìṣòro ìwé kíkà, rírántí nǹkan, fífiyè sílẹ̀, tàbí aláraàbalẹ̀—àrùn náà lè nípa lórí ẹ̀kọ́ ìwé ẹnì kan, ó sì lè fa ìjìyà púpọ̀. Bí o bá ní àbùkù ní ti ìkẹ́kọ̀ọ́, báwo ni o ṣe lè kojú rẹ̀?

Ìpèníjà Kíkojú Rẹ̀

Gbé ọ̀rọ̀ Jessica, tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀, yẹ̀ wò. Níwọ̀n bí ó ti pinnu láti borí àbùkù ìwé kíkà rẹ̀, ó ń gbìyànjú láti máa ka onírúurú ìwé. Ìyípadà dé nígbà tí ó rí ìwé ewì kan tí ó wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an. Ó ra irú ìwé yẹn kan náà, ó tún gbádùn kíkà rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó wá lọ́kàn ìfẹ́ nínú ọ̀wọ́ àwọn ìwé ìtàn kan, òkè ìṣòro ìwé kíkà sì wá ń di pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n ibẹ̀ ni pé àìjuwọ́sílẹ̀ ń ṣàǹfààní. Ìwọ pẹ̀lú lè borí àbùkù ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí ó kéré tán, o lè tẹ̀ síwájú gidigidi lọ́nà yẹn nípa ṣíṣàìjuwọ́sílẹ̀.—Fi wé Gálátíà 6:9.

Ti kíkojú ìṣòro agbára ìrántí onígbà kúkúrú ńkọ́? Kọ́kọ́rọ́ pàtàkì sípa yíyanjú ìṣòro náà wà nínú òwe tí ó sọ báyìí pé: “Àpètúnpè ni ìyá àìgbàgbé.” Nicky rí i pé títún ohun tí ó ń gbọ́, tí ó sì ń kà pè sókè ràn án lọ́wọ́ láti máa rántí nǹkan. Gbìyànjú rẹ̀. Ó lè ran ìwọ pẹ̀lú lọ́wọ́. Lọ́nà tí ó gbàfiyèsí, ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, àwọn ènìyàn máa ń jẹ ọ̀rọ̀ náà lẹ́nu, kódà bí wọ́n bá ń dá kàwé. Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà pàṣẹ fún òǹkọ̀wé Bíbélì náà, Jóṣúà, pé: “Ìwọ ó máa ṣe àṣàrò nínú [Òfin Ọlọ́run] ní ọ̀sán àti ní òru.” (Jóṣúà 1:8; Sáàmù 1:2) Èé ṣe tí jíjẹ ọ̀rọ̀ náà lẹ́nu fi ṣe pàtàkì bẹ́ẹ̀? Nítorí pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń gbé agbára ìmọ̀lára méjì ṣiṣẹ́—agbára ìgbọ́rọ̀ àti ìríran—ó sì ń ṣèrànwọ́ láti fi èrò àtẹ̀mọ́nilọ́kàn jíjinlẹ̀ sí èrò inú ẹni tí ń kàwé náà.

Ní ti Jessica, kíkẹ́kọ̀ọ́ ìṣirò tún jẹ́ iṣẹ́ kàbìtì kan. Bí ó ti wù kí ó rí, ó gbìyànjú kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìlànà ìṣirò nípa pípè wọ́n lápètúnpè—nígbà míràn, ó máa ń lò tó ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lórí ìlànà kan. Ìsapá rẹ̀ wá ṣàǹfààní lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Nítorí náà, tún un pè, tún un pè, tún un pè! Ìfidánrawò tí ó bọ́gbọ́n mu ni láti mú bébà àti lẹ́ẹ̀dì sítòsí nígbà tí o bá ń tẹ́tí sílẹ̀ ní kíláàsì tàbí tí o bá ń kàwé, kí o lè máa ṣàkọsílẹ̀.

Ó ṣe pàtàkì pé kí o fi ara rẹ fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Sọ ọ́ di àṣà láti dúró lẹ́yìn àkókò ilé ẹ̀kọ́ kí o sì bá àwọn olùkọ́ rẹ sọ̀rọ̀. Mọ̀ wọ́n. Sọ fún wọn pé o ní ìṣòro ìkẹ́kọ̀ọ́, àmọ́, pé o ti pinnu láti borí rẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ olùkọ́ yóò fẹ́ láti ṣèrànwọ́. Nítorí náà, wá ìrànlọ́wọ́ wọn. Jessica ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì rí ọ̀pọ̀ ìtìlẹ́yìn tí ó nílò láti ọ̀dọ̀ olùkọ́ kan tí ó lẹ́mìí ìbánikẹ́dùn.

Kọ́ Láti Pọkàn Pọ̀

Yóò tún ṣèrànwọ́ láti gbé ọgbọ́n ìlépa góńgó àti èrè ẹ̀san kalẹ̀ fún ara rẹ. Gbígbé góńgó pàtó kan kalẹ̀—bíi píparí apá kan iṣẹ́ àṣetiléwá—kí o tó ṣí tẹlifíṣọ̀n tàbí orin tí o nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ lè sún ọ láti pọkàn pọ̀. Rí i dájú pé àwọn góńgó tí o gbé kalẹ̀ bọ́gbọ́n mu.—Fi wé Fílípì 4:5.

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ṣíṣe àwọn ìyípadà tí ń mú nǹkan sunwọ̀n ní àyíká rẹ lè ṣèrànwọ́. Nicky ṣètò láti máa jókòó ní ọwọ́ iwájú nínú kíláàsì nítòsí olùkọ́, kí ó lè máa pọkàn pọ̀ dáadáa. Jessica rí i pé ó ṣàǹfààní láti máa ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ kan tí ó láápọn fún ẹ̀kọ́ kíkọ́. O lè rí i bí ohun tí ń ṣèrànwọ́ láti wulẹ̀ mú kí iyàrá rẹ jẹ́ èyí tí ó gbádùn mọ́ni tí ó sì ń mára tuni.

Dídín Àìsinmi Kù

Bí o bá ní ìtẹ̀sí jíjẹ́ aláraàbalẹ̀, kíkẹ́kọ̀ọ́ lè jẹ́ ìrírí búburú tí ń roni lára. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ògbógi kan sọ pé a lè yí araàbalẹ̀ sí eré ìmárale. Ìwé ìròyin U.S.News & World Report sọ pé: “Ẹ̀rí ń pọ̀ sí i pé àwọn ìyípadà inú ọpọlọ lọ́nà ti ẹ̀dá, tí a fi eré amú-èémí-sunwọ̀n ṣẹ̀dá, ń mú kí agbára ẹnì kọ̀ọ̀kan láti mọ àwọn ìsọfúnni tuntun dunjú, kí ó sì rántí àwọn tí ó ti pẹ́ sunwọ̀n sí i.” Nípa bẹ́ẹ̀, ìwọ̀ntúnwọ̀nsì eré ìmárale—lílúwẹ̀ẹ́, sísáré, gbígbá bọ́ọ̀lù, gígùn kẹ̀kẹ́, yíyọ̀ lórí yìnyín, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ—lè dára fún ara àti èrò inú.—Tímótì Kìíní 4:8.

A sábà máa ń júwe egbòogi fún ìṣiṣẹ́gbòdì ìkẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n sọ pé nǹkan bí ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn èwe tí àrùn ADHD ń pọ́n lójú, tí a fún ní àwọn egbòogi arùmọ̀lárasókè, ni ara wọ́n ti yá. Yálà o gbà láti lo egbòogi tàbí o kò gbà jẹ́ ọ̀ràn tí ìwọ àti àwọn òbí rẹ yóò pinnu lẹ́yìn tí ẹ bá ti ṣàgbéyẹ̀wò bí ìṣòro náà ṣe le koko tó, àwọn ohun tí ó lè jẹ́ àbájáde búburú egbòogi, àti àwọn kókó abájọ mìíràn.

Ní Ọ̀wọ̀ Ara Ẹni Rẹ Síbẹ̀

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ka ìṣòro ìkẹ́kọ̀ọ́ sí ìṣòro èrò ìmọ̀lára, ó lè ní àwọn àbájáde elérò ìmọ̀lára. Àpapọ̀ ìṣeláìfí àti ìṣelámèyítọ́ àwọn òbí àti olùkọ́ látìgbàdégbà, èsì ẹ̀kọ́ tí kò dára tàbí tí ó relẹ̀, àti àìní àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ lè tètè ṣokùnfà iyì ara ẹni rírẹlẹ̀. Àwọn èwe kan máa ń fi ìmọ̀lára yìí pa mọ́ nípa bíbínú àti dídẹ́rù bani.

Àmọ́, ìwọ kò ní láti sọ iyì ara ẹni rẹ nù nítorí ìṣòro ìkẹ́kọ̀ọ́.c Amọṣẹ́dunjú kan tí ń ṣiṣẹ́ lórí àwọn èwe tí wọ́n ní ìṣòro ìkẹ́kọ̀ọ́ sọ pé: “Ète mi jẹ́ láti yí ojú ìwòye wọn nípa ìgbésí ayé padà—láti orí ‘Òmùgọ̀ ni mí, n kò sì lè ṣe nǹkan kan kí ó dára’ . . . sí ‘Mo ń borí ìṣòro kan, mo sì lè ṣe púpọ̀ sí i ju bí mo ṣe rò lọ.’”

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba ni o lè ṣe nípa ìṣesí àwọn ẹlòmíràn, o lè ṣàkóso tìrẹ. Jessica ṣe bẹ́ẹ̀. Ó wí pé: “Nígbà tí mo ṣèdájọ́ ara mi látàrí ohun tí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ mi ń sọ àti orúkọ tí wọ́n ń pè mí, mo fẹ́ láti sá kúrò ní ilé ẹ̀kọ́. Àmọ́, ní báyìí, mo máa ń gbìyànjú láti kọtí ikún sí ohun tí wọ́n ń sọ, mo sì ń sa ipá mi. Ó ṣòro, mo sì ní láti máa rán ara mi létí, àmọ́, ó ṣiṣẹ́.”

Jessica ní láti bá ìṣẹ̀lẹ̀ míràn wọ̀dìmú. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí ó lóye, tí ipò rẹ̀ wà ní ìpele A. Jessica sọ pé: “Ìyẹn máa ń pa iyì ara ẹni mi run, àyàfi ìgbà tí mo jáwọ́ fífi ara mi wé e.” Nítorí náà, má ṣe fi ara rẹ wé àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ.—Gálátíà 6:4.

Bíbá ọ̀rẹ́ kan tí o gbẹ́kẹ̀ lé sọ̀rọ̀ yóò tún ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní ojú ìwòye títọ́ nípa àwọn nǹkan. Ọ̀rẹ́ tòótọ́ yóò dúró ṣinṣin tì ọ́ gbágbáágbá, bí o ti ń gbìyànjú láti ṣe dáradára sí i. (Òwe 17:17) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀rẹ́ èké yóò kó ọ sínú ìdàrúdàpọ̀ tàbí fún ọ ní ojú ìwòye tí a gbé ga, tí kò tọ́ nípa ara rẹ̀. Nítorí náà, yan ọ̀rẹ́ rẹ tìṣọ́ratìṣọ́ra.

Bí o bá ní ìṣòro ìkẹ́kọ̀ọ́, a lè máa bá ọ wí ju àwọn èwe mìíràn lọ. Àmọ́, má ṣe jẹ́ kí ìyẹn fún ọ ní ojú ìwòye òdì nípa ara rẹ. Fojú ìwà-bí-Ọlọ́run wo ìbáwí, gẹ́gẹ́ bí ohun kan tí ìníyelórí rẹ̀ ga. Rántí, ìbáwí tí àwọn òbí rẹ ń fún ọ jẹ́ ẹ̀rí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ, wọ́n sì fẹ́ ire fún ọ.—Òwe 1:8, 9; 3:11, 12; Hébérù 12:5-9.

Àgbẹdọ̀, kò yẹ kí ìṣòro ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ. O lè ṣe ohun kan nípa rẹ̀, kí o sì gbé ìgbésí ayé améso-rere-wá. Àmọ́, ìdí gíga jù kan tún wà fún ìrètí. Ọlọ́run ti ṣèlérí láti mú ayé tuntun òdodo kan wá nínú èyí tí ìmọ̀ yóò ti wà lọ́pọ̀ yanturu, tí a óò ti ṣàtúnṣe gbogbo àrùn èrò orí àti ara. (Aísáyà 11:9; Ìṣípayá 21:1-4) Nítorí náà, múra tán láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun púpọ̀ sí i nípa Jèhófà Ọlọ́run àti ète rẹ̀, kí o sì hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ yẹn.—Jòhánù 17:3.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí díẹ̀ padà nínú àwọn orúkọ náà.

b Jọ̀wọ́ wo àwọn ọ̀wọ́ náà “Lílóye Àwọn Oníyọnu Ọmọ” nínú ìtẹ̀jáde Jí!, November 22, 1994, àti ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Ọmọ Rẹ Ha Ní Awọn Iṣoro Ikẹkọọ Bi?” nínú ìtẹ̀jáde ti September 8, 1984.

c Wo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Awọn Ọ̀dọ́ Beere Pe . . . Bawo Ni Mo Ṣe Le Gbé Ọ̀wọ̀-Ara-Ẹni Mi Ró?” nínú Jí!, ìtẹ̀jáde ti August 8, 1985.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Fi ara fún ìkẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́