ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 12/8 ojú ìwé 13-15
  • Kí Ni Kí N Ṣe Bí Mi Ò Bá Ṣe Dáadáa Tó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Kí N Ṣe Bí Mi Ò Bá Ṣe Dáadáa Tó?
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mọ̀wọ̀n Ara Ẹ
  • Táwọn Mìíràn Bá Ń Retí Pé Kó O Ṣe Ju Bó O Ṣe Ń Ṣe Lọ Ńkọ́?
  • “Kíkùnà” Láti Ṣe Ojúṣe Rẹ Nípa Tẹ̀mí
  • Àwọn Àṣìṣe Tó Lágbára
  • Bó O Ṣe Lè Gbọ́kàn Kúrò Lórí Nǹkan Tó Ò Bá Ṣe Dáadáa Tó
  • Kí Ló Dé Tí N Kò Lè Kẹ́kọ̀ọ́?
    Jí!—1996
  • Kí Ló Dé Témi Ò fi Mọ Nǹkan Kan Ṣe?
    Jí!—2011
  • Bí A Ṣe Lè Ran Awọn Ọmọ Lọ́wọ́ Láti Borí Ìjákulẹ̀
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Kí Ló Burú Nínú Bíbára Ẹni Jáde Ní Bòókẹ́lẹ́?
    Jí!—2007
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 12/8 ojú ìwé 13-15

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Ni Kí N Ṣe Bí Mi Ò Bá Ṣe Dáadáa Tó?

“Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gba káàdì mi ni, mo sì tún fìdí rẹmi nínú àwọn iṣẹ́ mẹ́rin yìí kan náà. Mo mà gbìyànjú títí o, síbẹ̀ mo tún pàpà féèlì.”—Lauren, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún.

“Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, nǹkan kì í rọrùn fẹ́ni tó bá ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó. Kì í pẹ́ tá fi bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé ó ti bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́.”— Jessica, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún.

KÒ SẸ́NI tó máa ń fẹ́ gbọ́ pé òun ò ṣe dáa tó bó ṣe yẹ. Ṣùgbọ́n gbogbo wa la máa ń ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Yálà èèyàn fìdí rẹmi nínú ìdánwò ilé ìwé ni o, tàbí ó ṣe nǹkan tó lè mú kójú tì í, ì báà sì jẹ́ pé ó ṣe nǹkan tó dun ẹnì kan tó wúwo lọ́wọ́ ẹ̀ ni, tàbí kó hùwà kan tí ò dáa, ó máa ń dun èèyàn kọjá sísọ.

A mọ̀ pé kò sẹ́ni tí kì í ṣàṣìṣe. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Síbẹ̀, ó máa ń ṣòro fáwọn kan lára wa láti gbé àṣìṣe wọn kúrò lọ́kàn. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Jason sọ pé: “Èmi ló máa ń ka ẹ̀sùn síra mi lẹ́sẹ̀ jù. Bí mo bá ṣàṣìṣe, àwọn èèyàn lè rẹ́rìn-ín o, ṣùgbọ́n wọ́n máa ń gbàgbé nípa ẹ̀. Èmi kì í gbàgbé ní tèmi, ńṣe ni màá máa ronú nípa ẹ̀ ṣáá.”

Kì í ṣe pé ó burú pátápátá téèyàn bá ń ronú lórí àwọn nǹkan téèyàn ṣe tó kù díẹ̀ káàtó, pàápàá bó bá jẹ́ pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ á mú kí nǹkan sunwọ̀n sí i. Àmọ́, téèyàn bá ń ka ẹ̀sùn síra ẹ̀ lẹ́sẹ̀ lemọ́lemọ́ jù, ó léwu ó sì lè ba ohun tó dáa jẹ́. Òwe 12:25 sọ pé: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba.”

Wo àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tí Bíbélì pè ní Ẹpafíródítù. Wọ́n rán an lọ Róòmù láti lọ ran àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ bí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́. Àmọ́, Ẹpafíródítù ṣàìsàn kò sì lè ṣiṣẹ́ tí wọ́n rán an. Ó le débi pé Pọ́ọ̀lù gan-an ló tún wá ń tọ́jú ẹ̀! Pọ́ọ̀lù ṣètò bó ṣe máa jẹ́ kí Ẹpafíródítù padà sílé, ó kọ lẹ́tà sáwọn ará ìjọ ẹ̀ pé inú ọkùnrin olóòótọ́ yìí ti bàjẹ́ pẹ̀lú. Kí nìdí? Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Ẹ gbọ́ pé ó ti dùbúlẹ̀ àìsàn.” (Fílípì 2:25, 26) Nígbà tí Ẹpafíródítù rí i pé àwọn ẹlòmíràn mọ̀ pé òun ṣàìsàn tóun ò sì lè ṣiṣẹ́ tí wọ́n rán òun, ó ṣeé ṣe kó ronú pé òun ò lè dá iṣẹ́ tí wọ́n rán òun ṣe. Abájọ tínú ẹ̀ fi bàjẹ́!

Ǹjẹ́ ohun kan wà téèyàn lè ṣe láti dín ẹ̀dùn ọkàn téèyàn máa ń ní kù béèyàn bá ṣe ohun tí ò dáa tó?

Mọ̀wọ̀n Ara Ẹ

Ohun kan tó o lè ṣe tó fi ní máa kùnà ni pé kó o máà gbé àwọn nǹkan tó pọ̀ jura lọ síwájú ara ẹ. Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” (Òwe 11:2; 16:18) Bẹ́ẹ̀ sì ni, awọ̀lúmátẹ̀ẹ́, ìwọ̀n ara rẹ̀ ló mọ̀. Lóòótọ́, ó dára pé kó o máa wáyè fi àwọn nǹkan dánra wò kó o bàa lè máa já fáfá sí i kó o sì lè mọ nǹkan ṣe sí i. Ṣùgbọ́n má retí ohun tí ò ṣeé ṣe. O lè má lè mọ ìṣirò débi tí wọ́n ń mọ̀ ọ́n dé, bákan náà, o lè má lè mọ eré ìdárayá ṣe bí ìlúmọ̀ọ́ká eléré ìdárayá kan á ṣe ṣe é. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Michael jẹ́wọ́ pé: “Mi ò fi bẹ́ẹ̀ gbóná nínú eré ìdárayá. Nítorí náà, mo máa ń báwọn ṣe é, ṣùgbọ́n n kì í kọjá àyè mi nídìí ẹ̀.” Ó ṣàlàyé pé: “Ohun tó o mọ̀ pé ọwọ́ ẹ lè tẹ̀ ni kó o máa lé.”

Ìwọ wo ojú tí ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan tó ń jẹ́ Yvonne fi ń wo ọ̀rọ̀ yìí. Ọ̀dọ́bìnrin yìí ní àrùn tó máa ń mú kí ọ̀pá ẹ̀yìn là àti àrùn tó máa ń ba apá ibi tó ń darí ìséraró àti ìsọ̀rọ̀ jẹ́ nínú ọpọlọ. Yvonne sọ pé: “Mi ò lè rìn tàbí kí n jó tàbí kí n sáré bí àwọn tó kù. Ó máa ń tojú sú mi gan-an pé mi ò lè ṣe nǹkan táwọn ẹlòmíì lè ṣe. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í mọ ohun tó ń dùn mí. Ṣùgbọ́n mo máa ń fara da irú ìbànújẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ìmọ̀ràn wo ló wá fáwọn tọ́kàn wọn máa ń dà rú bí ohun kan bá wà tí wọn ò lè ṣe? Ó ní: “Má ṣe jẹ́ kó rẹ̀ ọ́. Ṣáà máa gbìyànjú nìṣó. Tó o bá kùnà tàbí tó o fìdí rẹmi, má juwọ́ sílẹ̀. Ṣáà máa ṣe gbogbo ohun tágbára ẹ bá gbé.”

Bákan náà, má fìyà jẹra ẹ nípa wíwo aago aláago ṣiṣẹ́. Andrew, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sọ pé: “Mo máa ń gbìyànjú láti má máa fi ara mi wé àwọn ẹlòmíràn nítorí pé ìka ò dọ́gba.” Ọ̀rọ̀ tí Andrew sọ jọ ohun tí Bíbélì sọ nínú Gálátíà 6:4 pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn.”

Táwọn Mìíràn Bá Ń Retí Pé Kó O Ṣe Ju Bó O Ṣe Ń Ṣe Lọ Ńkọ́?

Àmọ́ nígbà míì, àwọn òbí ẹ, àwọn olùkọ́ ẹ tàbí àwọn mìíràn lè máa retí pé kó o ṣe ohun tó ga gan-an. O sì lè wá rí i pé ò báà forí ṣe fọrùn ṣe, o ò lè tẹ́ wọn lọ́rùn. Ohun tó lè jẹ kí ìbànújẹ́ yẹn túbọ̀ pọ̀ sí i ni pé àwọn wọ̀nyí lè máa sọ̀rọ̀ tá á dùn ẹ̀ tàbí ọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí ẹ nítorí pé o ò lè ṣe nǹkan tí wọ́n fẹ́ kó o ṣe. (Jóòbù 19:2) Ì bá

dáa tó bá yé ẹ pé àwọn òbí ẹ ò lè mọ̀ọ́mọ̀ máa ṣe nǹkan tá á dà ẹ́ lọ́kàn rú. Jessica sọ pé “ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọn ò ní mọ̀ pé ohun táwọn ń ṣe ń dùn ẹ́. Nígbà míì ńṣe ló máa ń jẹ́ pé ọ̀rọ̀ yín ni ò yéra.”

Wò ó lọ́nà míì, àbí ó wa lè jẹ́ pé wọ́n rí ohun kan tí ìwọ ò rí ni? Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ pé ńṣe lo kàn ń fojú kéré ara ẹ tó o sì ń fojú ẹni tí ò lè dá nǹkan ṣe wo ara ẹ. Dípò tí wàá fi rọ́ àbá tí wọ́n ń dá fún ẹ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ńṣe ló yẹ kó o “fetí sí ìbáwí.” (Òwe 8:33) Michael ṣàlàyé pé: “Fún àǹfààní ara ẹ ni. Wọ́n fẹ́ kó o máa ṣe dáadáa sí i ni, kó o lè wúlò fún ara ẹ. Ńṣe ni kó o kà á sí ìpèníjà.”

Àmọ́ tó o bá wá ń rí i pé ohun táwọn òbí ẹ fẹ́ kó o máa ṣe ti pọ̀ ju agbára rẹ lọ ńkọ́, tó o tún ń wò ó pé ńṣe ni wọ́n fẹ́ kó o ṣe àṣetì? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á bọ́gbọ́n mu pé kó o bá wọn sọ ọ́ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, àmọ́ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ, jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. Ẹ lè jọ sọ ọ́ kẹ́ ẹ sì ṣàlàyé àwọn nǹkan tí wàá máa lépa tí wàá sì lè bá.

“Kíkùnà” Láti Ṣe Ojúṣe Rẹ Nípa Tẹ̀mí

Àwọn ọ̀dọ́ tó wà láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dojú kọ ìṣòro lórí bí wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù wọn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run. (2 Tímótì 4:5) Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́ Kristẹni, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o ò ṣe dáadáa tó lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bóyá ìdáhùn ẹ nínú ìpàdé kì í dáa tó. Ó sì lè jẹ́ pé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì fáwọn ẹlòmíràn. Bí àpẹẹrẹ, Jessica ń kọ́ ọmọbìnrin ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún kan lẹ́kọ̀ọ́. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn ń fìgbà kan tẹ̀ síwájú dáadáa o. Àfi bírí tí ọmọbìnrin náà yí padà, ó lóun ò fẹ́ sin Ọlọ́run. Jessica rántí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, ó sọ pé: “Ńṣe ló dà bíi pé èmi ni mi ò kọ́ ọ dáadáa.”

Báwo wá ni Jessica ṣe borí àwọn èrò yìí? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó fi sọ́kàn pé kì í ṣe òun ni akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ pa tì bí kò ṣe Ọlọ́run. Ohun tó tún ràn án lọ́wọ́ ni ríronú lórí àpẹẹrẹ Pétérù, ẹni tó bẹ̀rù Ọlọ́run ṣùgbọ́n tóun náà ní tiẹ̀ lára. Ó ṣàlàyé pé: “Bíbélì fi hàn pé Pétérù borí àwọn àìlera ẹ̀, Jèhófà sì lò ó lọ́pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà láti mú kí ọ̀ràn tó jẹ mọ́ Ìjọba rẹ̀ máa tẹ̀ síwájú.” (Lúùkù 22:31-34, 60-62) Gbọ́ ná, tó bá jẹ́ pé ó yẹ kó o mú kí ọ̀nà tó ò ń gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ sunwọ̀n sí i, o ò ṣe sapá díẹ̀ sí i kó o lè túbọ̀ jáfáfá gẹ́gẹ́ bí olùkọ́? (1 Tímótì 4:13) Wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn àgbààgbà nínú ìjọ, ìyẹn àwọn tó lè kọ́ ẹ bí wọ́n ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.

Àbí ó lè jẹ́ pé iṣẹ́ ìwàásù àtilé-délé ló máa ń ṣòro fún ẹ jù láti ṣe? Jason gbà pé: “Gbogbo ìgbà tónílé kan ò bá ti fẹ́ gbọ́rọ̀ mi ló máa ń dà bíi pé èmi ni mi ò ṣe dáadáa.” Báwo ló ṣe wá borí èrò yẹn? “Mo máa ń rántí pé mi ò tíì kùnà ní ti gidi.” Bẹ́ẹ̀ sì ni lóòótọ́, ó ti ṣe ohun tí Ọlọ́run ní kó ṣe láṣeyọrí, ìyẹn ni pé kó wàásù! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń dunni táwọn èèyàn ò bá fẹ́ gbọ́rọ̀ wa, kì í ṣe gbogbo èèyàn ni ò ní gbọ́ ọ̀rọ̀ Bíbélì. Jason sọ pé: “Tí mo bá wá rí ẹnì kan tó fetí sílẹ̀, màá wá rí i pé iṣẹ́ ni mo ṣe.”

Àwọn Àṣìṣe Tó Lágbára

Tó o bá wá ṣe àṣìṣe tó lágbára tàbí tó o bá tiẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ ńlá ńkọ́? Ana, ọmọbìnrin ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ṣe irú àṣìṣe yẹn.a Ó jẹ́wọ́ pé, “Mo ṣe ohun tó dun àwọn ará ìjọ àti ìdílé mi, èyí tó wá burú jù ni pé mo ṣe ohun tó dun Jèhófà Ọlọ́run.” Láti lè kọ́fẹ padà, o ní láti ronú pìwà dà kó o sì lọ sọ́dọ̀ àwọn àgbà ọkùnrin nípa tẹ̀mí tí wọ́n wà nínú ìjọ pé kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Jákọ́bù 5:14-16) Ana rántí ọ̀rọ̀ alàgbà kan tó ràn án lọ́wọ́, ó ní alàgbà náà sọ pé: “Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tí ò dáa tí Ọba Dáfídì ṣe, Jèhófà ṣì múra tán láti dárí jì í, Dáfídì sì kọ́fẹ padà. Ọ̀rọ̀ yẹn ràn mí lọ́wọ́ gan-an.” (2 Sámúẹ́lì 12:9, 13; Sáàmù 32:5) Ó tún yẹ kó o ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti fún ara ẹ lágbára nípa tẹ̀mí. Ana sọ pé: “Mo ka ìwé Sáàmù lákàtúnkà mo sì ní ìwé kan tí mo máa ń kọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ń fún mi níṣìírí sí nínú.” Bó bá yá, olúwa rẹ̀ á kọ́fẹ padà látinú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tó dá. Òwe 24:16 sọ pé: “Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje pàápàá, yóò sì dìde dájúdájú.”

Bó O Ṣe Lè Gbọ́kàn Kúrò Lórí Nǹkan Tó Ò Bá Ṣe Dáadáa Tó

Kódà, àwọn ìkùnà tá a lè kà sí kéékèèké gan-an lè dun èèyàn wọnú eegun. Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí wọn? Lákọ̀ọ́kọ́, mọ̀ pé ńṣe lo ṣàṣìṣe. Michael dábàá pé: “Dípò tí wàá fi máa ronú pé aláìdáa ni ẹ́, mọ nǹkan ọ̀hún tó o kùnà láti ṣe àti nǹkan tó fà á. Èyí lá á jẹ kó o lè ṣe dáadáa jù bẹ́ẹ̀ lọ nígbà míì.”

Máà máa ka bó ṣe ń ṣe ẹ́ sí ju bó ṣe yẹ lọ. “Ìgbà rírẹ́rìn-ín” wà èyí sì lè jẹ́ ìgbà tó yẹ kó o fira ẹ rẹ́rìn-ín! (Oníwàásù 3:4) Tó bá dà bíi pé ò ń kárí sọ, gbọ́kàn ẹ lọ sára nǹkan tó o ṣe dáadáa irú bí eré ìgbà ọwọ́ dilẹ̀ tàbí eré ìdárayá. Jíjẹ́ “ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà,” irú bíi sísọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ ẹ fáwọn ẹlòmíì, lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa fojú tó dáa wo ara ẹ.—1 Tímótì 6:18.

Lákòótán, rántí pé “Jèhófà jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́ . . . Òun kì yóò máa wá àléébù ṣáá nígbà gbogbo.” (Sáàmù 103:8, 9) Jessica sọ pé: “Mo rí i pé bí mo ṣe ń sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run tó, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ṣe ń balẹ̀ tó pé á dúró tì mí, á sì ràn mí lọ́wọ́ nínú gbogbo ohun tó bá ń ṣẹlẹ̀ sí mi.” Bẹ́ẹ̀ ni, ó tuni nínú láti mọ̀ pé láìka àwọn ìkùnà ẹ sí, Bàbá rẹ tí ń bẹ lọ́rùn kà ẹ́ sí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí orúkọ rẹ̀ padà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Tó o bá rí i pé àwọn nǹkan tí wọ́n kó lé ọ láyà ti kà ẹ́ láyà, wá ọ̀nà tí wàá fi fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ tinú ẹ jáde

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ṣíṣe àwọn nǹkan tó o mọ̀ ọ́n ṣe dáadáa á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti gbọ́kàn kúrò lórí nǹkan tó ò bá ṣe dáadáa tó

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́