ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/07 ojú ìwé 14-17
  • Kí Ló Burú Nínú Bíbára Ẹni Jáde Ní Bòókẹ́lẹ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Burú Nínú Bíbára Ẹni Jáde Ní Bòókẹ́lẹ́?
  • Jí!—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Ń Mú Káwọn Ọ̀dọ́ Kan Gbà
  • “Wọ́n Lá Ò Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Kí Ẹnikẹ́ni Gbọ́”
  • Ewu Tó Wà Nínú Bíbára Ẹni Jáde ní Bòókẹ́lẹ́
  • “Mo Ti Mọ Ohun Tó Yẹ Kí N Ṣe”
  • Kí Ló Burú Nínú Fífẹ́ra Sọ́nà Ní Bòókẹ́lẹ́?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Ìgbà Wo Ló Yẹ Kí N Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Bá Ẹni Tí Kì Í Ṣe Ọkùnrin Tàbí Obìnrin Bíi Tèmi Jáde?
    Jí!—2007
  • Ṣó Ti Yẹ Kí N Lẹ́ni Tí Mò Ń Fẹ́?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Bí Àwọn Òbí Mi Bá Sọ Pé Mi Ò Tíì Tẹ́ni Ń Dájọ́ Àjọròde Ńkọ́?
    Jí!—2001
Àwọn Míì
Jí!—2007
g 7/07 ojú ìwé 14-17

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Ló Burú Nínú Bíbára Ẹni Jáde Ní Bòókẹ́lẹ́?

Jessicaa ò tiẹ̀ wá mọ èyí tí ì bá ṣe mọ́ báyìí. Jẹ́jẹ́ ẹ̀ ló jókòó tọ́mọ kíláàsì ẹ̀ kan tó ń jẹ́ Jeremy bẹ̀rẹ̀ sí í ta sí i. Jessica fúnra ẹ̀ sọ pé: “Ọmọkùnrin dáa síbẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ mi sì sọ pé èèyàn bíi tiẹ̀ ṣọ̀wọ́n. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbìnrin ni wọ́n ti wá báwọn á ṣe bá a da nǹkan pọ̀, àmọ́ kò tiẹ̀ wojú wọn. Èmi nìkan yìí ló ṣáà lóun fẹ́ràn.”

Kò pẹ́ kò jìnnà ti Jeremy fi sọ fún Jessica pé kó jẹ́ káwọn jọ máa bára àwọn jáde. Jessica sọ pé: “Mo ṣàlàyé fún un pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí, mi ò sì ní lè máa bá ẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi tèmi jáde. Àmọ́ Jeremy ni òun mọ ọgbọ́n tá a lè máa dá sí i. Ó bi mí pé, ‘Bá a bá ń bára wa jáde láìjẹ́ káwọn òbí ẹ mọ̀ ńkọ́?’”

BÍ ẸNÌ kan tó o wù bá dá irú àbá yìí fún ẹ, kí lo máa ṣe? Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu láti gbọ́ pé Jessica kọ́kọ́ gbà láti máa bá Jeremy jáde. Ó sọ pé: “Ó dá mi lójú gbangba pé bí mo bá ń bá a jáde, màá sọ ọ́ dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.” Ibo lọ̀rọ̀ náà wá já sí o? Ká ṣì máa bọ́rọ̀ nìṣó ńlẹ̀ ná. Àmọ́, jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ohun tó fà á tó fi jẹ́ pé wẹ́rẹ́ bẹ́ẹ̀ yẹn ni irú Jessica tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere fi kó sínú pańpẹ́ à ń bára ẹni jáde ní bòókẹ́lẹ́.

Ohun Tó Ń Mú Káwọn Ọ̀dọ́ Kan Gbà

Àtikékeré làwọn ọ̀dọ́ kan ti máa ń yan ara wọn lọ́rẹ̀ẹ́. Susan, láti ilẹ̀ Britain sọ pé: “Mo ti ráwọn ọmọdé lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ń yan ara wọn lọ́rẹ̀ẹ́ látìgbà tí wọ́n ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá sí mọ́kànlá!” Kí ló ń lé wọn láré ná? Kò sí ohun méjì tó ń fà á ju òòfà takọtabo tí Ọlọ́run dá mọ́ gbogbo ẹ̀dá àti fífẹ́ láti ṣe bíi tàwọn ojúgbà wọn. Lois láti ilẹ̀ Ọsirélíà sọ pé: “Ara èèyàn á túbọ̀ máa yí padà, èèyàn á sì tún rí i pé gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ èèyàn ni wọ́n lẹ́ni tí wọ́n jọ ń bára wọn jáde.”

Kí ló wá fà á táwọn kan fi ń bára wọn jáde ní bòókẹ́lẹ́? Jeffrey, láti ilẹ̀ Britain sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀rù ohun táwọn òbí wọn máa sọ ló ń bà wọ́n.” Ohun ti David, láti orílẹ̀-èdè South Africa náà rò nìyẹn. Ó sọ pé: “Wọ́n mọ̀ pé àwọn òbí àwọn ò ní gbà, nítorí náà wọn kì í sọ fún wọn.” Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Jane, láti ilẹ̀ Ọsirélíà, tún sọ ohun míì tó ṣeé ṣe kó máa fà á. Ó ní: “Bíbára-ẹni-jáde ní bòókẹ́lẹ́ tún jẹ́ ọ̀nà táwọn ọ̀dọ́ kan gbà ń fi hàn pé àwọn fẹ́ dá dúró láyè ara àwọn. Béèyàn bá ti ń wo ara ẹ̀ bí àgbà, àmọ́ tí wọn ò yé fojú ọmọdé wò ó, ẹnu kéèyàn máa gbé ohun tó bá fẹ́ ṣe gbẹ̀yìn àwọn òbí ni. Kò sì sóhun tó rọrùn bíi kéèyàn máa ṣe é ní bòókẹ́lẹ́.”

Àmọ́ ṣá o, Bíbélì pàṣẹ pé kó o máa gbọ́ràn sáwọn òbí ẹ lẹ́nu. (Éfésù 6:1) Báwọn òbí ẹ bá sì sọ pé àwọn ò fẹ́ kó o máa bá ẹnikẹ́ni jáde, ó dájú pé ìdí rere kan wà tí wọ́n fi ní láti sọ bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, bó bá jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí ẹ, Ẹlẹ́rìí bíi tìẹ nìkan ni wọ́n á fẹ́ kẹ́ ẹ jọ máa bára yín jáde, ìyẹn bí ẹ̀yin méjèèjì bá ti dàgbà tó láti fẹ́ra yín.b Àmọ́, má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu bó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú báyìí pé:

◼ Mi ò rẹ́ni bá rìn nítorí pé gbogbo èèyàn ló ń rẹ́ni bá jáde àfèmi.

◼ Ẹni tí ìsìn ẹ̀ yàtọ̀ sí tèmi lọkàn mi ń fà sí.

◼ Á wù mí kí n rí Kristẹni bíi tèmi máa bá jáde bí mi ò tiẹ̀ tíì tó ẹni tó yẹ kó ṣègbéyàwó.

Ó ṣeé ṣe kó o mọ ohun táwọn òbí ẹ á sọ nípa àwọn nǹkan tó ò ń rò lọ́kàn yìí. Ìwọ náà sì ní láti mọ̀ nínú ọkàn ẹ lọ́hùn-ún pé òótọ́ ni wọ́n ń sọ. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ ẹ lè rí bíi ti Manami, tó wà lórílẹ̀-èdè Japan, ẹni tó sọ pé: “Ńṣe lọ̀rọ̀ pé kí n máa bá ẹlòmíràn jáde yìí ṣáà ń gbà mí lọ́kàn débi tí mo fi máa ń ṣiyè méjì pé bóyá ni mi ò kúkú ní wẹ́ni máa bá jáde. Agbára káká lọ̀dọ́ kan lóde ìwòyí á fi sọ pé òun ò ní lẹ́ni táwọn á jọ máa jáde.” Àwọn kan tọ́rọ̀ wọn rí bá a ṣe sọ tán yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí bára wọn jáde, wọ́n sì ti ṣe ọ̀rọ̀ náà lókùú òru fáwọn òbí wọn. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?

“Wọ́n Lá Ò Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Kí Ẹnikẹ́ni Gbọ́”

Èdè tí wọ́n ń lò, ìyẹn “bíbára ẹni jáde ní bòókẹ́lẹ́” fi hàn pé ẹ̀tàn ò ṣàìwà nídìí ọ̀ràn náà. Káwọn kan lára wọn bàa lè ṣe bíbá tí wọ́n ń bára wọn jáde ní bòókẹ́lẹ́, orí fóònù tàbí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni wọ́n ti sábà máa ń bára wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n á kàn máa bára wọn ṣọ̀rẹ́ lásán lójútáyé, àmọ́ nǹkan míì pátápátá lọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń kọ síra wọn lórí kọ̀ǹpútà àti lórí fóònù alágbèéká, títí kan èyí tí wọ́n ń bára wọn sọ lórí fóònù.

Caleb, láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tún táṣìírí ọgbọ́n míì tí wọ́n máa ń dá. Ó sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n ń bára wọn jáde ní bòókẹ́lẹ́ máa ń lo ẹnà àti orúkọ ìnagijẹ tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ lágbo àwọn ojúgbà wọn kẹ́lòmíì má bàa mọ ohun tí wọ́n ń bára wọn sọ.” Ọgbọ́n míì tí wọ́n tún máa ń dá ni pé wọ́n á ṣètò fún iṣẹ́ àjùmọ̀ṣe kan, wọ́n á sì wá dọ́gbọ́n fọwọ́ kọ́ ara wọn kúrò níbẹ̀. James, láti ilẹ̀ Britain sọ pé: “Wọ́n sọ nígbà kan pé káwa mélòó kan jọ pàdé níbì kan báyìí, a wá rí i nígbà tá a débẹ̀ pé àjọmọ̀ àwọn tó pè wá ni, wọ́n ṣe é tó fi jẹ́ pé gbogbo àwa ọkùnrin tá a wà níbẹ̀ á lè mú àwọn obìnrin tó wà níbẹ̀ níkọ̀ọ̀kan. Wọ́n sì sọ fún wa pé ká ṣe é lọ́rọ̀ àṣírí.”

Bí James ṣe sọ, àwọn ọ̀dọ́ máa ń bo àṣírí ara wọn lọ́pọ̀ ìgbà kí wọ́n lè máa bá ara wọn jáde ní bòókẹ́lẹ́. Carol tó wá láti ilẹ̀ Scotland sọ pé: “Ó kéré tán, ọ̀rẹ́ wa kan mọ ọgbọ́n tá à ń dá, àmọ́ ó ṣẹnu fúrú nítorí gbogbo wa ti gbà pé bójú bá rí, ńṣe ni kẹ́nu yáa dákẹ́.”

Lọ́pọ̀ ìgbà sì rèé, ọgbọ́n ẹ̀tàn ló máa ń wà nídìí ẹ̀. Beth, láti orílẹ̀-èdè Kánádà sọ pé: “Irọ́ lọ̀pọ̀ ń pa fáwọn òbí wọn dípò kí wọ́n sọ ibi tí wọ́n gbà lọ.” Misaki, tó wà lórílẹ̀-èdè Japan, gbà pé ohun tóun ṣe gan-an nìyẹn. Ó sọ pé: “Mo ní láti ronú irọ́ tí màá gbé kalẹ̀ fáwọn òbí mi. Mo sì máa ń ṣọ́ra kí n má pa irọ́ míì yàtọ̀ sí èyí tó bá jẹ mọ́ bíbá tá à ń bára wa jáde kó má lọ di pé àwọn òbí mi á máa mú mi lónírọ́.”

Ewu Tó Wà Nínú Bíbára Ẹni Jáde ní Bòókẹ́lẹ́

Bó bá ń ṣe ẹ́ bíi kó o máa bá ẹlòmíì jáde ní bòókẹ́lẹ́, tàbí bó o bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní báyìí, ó dára kó o gbé àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí yẹ̀ wò:

◼ Ibo lọ̀nà ẹ̀tàn tí mò ń tọ̀ á sìn mí lọ? Ṣó o ní in lọ́kàn láti fẹ́ onítọ̀hún láìpẹ́ láìjìnnà? Evan, láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Béèyàn bá ń bá ẹlòmíì jáde láìṣe pé ó fẹ́ fẹ́ ẹ, ṣe ló dà bí ìgbà téèyàn ń polówó ọjà tóun fúnra ẹ̀ kì í tà.” Òwe 13:12 sọ pé: “Ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn.” Ṣé wàá sì fẹ́ láti mú kí ọkàn ẹni tó o fẹ́ràn ṣàìsàn nítòótọ́?

◼ Ojú wo ni Jèhófà Ọlọ́run fi ń wo ohun tí mò ń ṣe gan-an? Bíbélì sọ pé “ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.” (Hébérù 4:13) Nítorí náà, bó o bá ń báwọn míì jáde ní bòókẹ́lẹ́ tàbí tó o lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ ẹ kan tó ń ṣe bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó yé ẹ pé Jèhófà mọ ohun tó ò ń ṣe o. Bó bá sì jẹ́ pé ńṣe lò ń tan àwọn òbí ẹ, a jẹ́ pó yẹ kó o túbọ̀ yẹra ẹ wò. Ọwọ́ kékeré kọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run fi mú irọ́ pípa o. Kódà, gbangba gbàǹgbà ni “ahọ́n èké” fara hàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run kórìíra.—Òwe 6:16-19.

Dájúdájú, bẹ́ ẹ bá ń bára yín jáde ní bòókẹ́lẹ́ dípò kẹ́ ẹ jẹ́ káwọn èèyàn rí i gbangba pé kò sí ẹ̀tàn tàbí èrú kankan nínú àjọṣepọ̀ yín, ńṣe lẹ̀ ń tọrùn ara yín bọ ewu o. Ìyẹn ò sì lè yani lẹ́nu, torí pé a ti rí lára àwọn tó ń bára wọn jáde ní bòókẹ́lẹ́ tó jẹ́ pé ìṣekúṣe náà ló gbẹ̀yìn ẹ̀. Jane, láti Ọsirélíà táṣìírí ọ̀rẹ́ ẹ̀ tí ọkùnrin kan ń bá jáde ní bòókẹ́lẹ́ àmọ́ tó ń ṣe bí ọmọ gidi nílé tó sì ń ṣèyí tó wù ú níta. Ó sọ pé: “Nígbà tí bàbá ẹ̀ fi máa mọ̀ pé ọkùnrin kan wà tí wọ́n jọ ń bára wọn jáde, ó ti gboyún.”

O lè wá rí i báyìí pé ohun tó dáa ni pé kó o jẹ́ káwọn òbí ẹ tàbí Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ mọ̀ nípa àjọṣepọ̀ bòókẹ́lẹ́ èyíkéyìí tó o bá ní pẹ̀lú ẹlòmíì. Bó o bá sì lọ́rẹ̀ẹ́ tó lẹ́ni tí wọ́n jọ ń bára wọn jáde ní bòókẹ́lẹ́, má ṣe bá a bo ohun tí ò ṣeé bò o. (1 Tímótì 5:22) Àbí, báwo ló ṣe máa rí lára ẹ bí irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ bá lọ já sí ibi tí ò dáa? Ṣé ìwọ náà ò ní bá a pín díẹ̀ nínú ẹ̀bi ẹ̀? Jẹ́ ká sọ pé ọ̀rẹ́ ẹ kan tó lárùn àtọ̀gbẹ ń jẹ mindin-mín-ìndìn ní bòókẹ́lẹ́. Ni àṣírí ọ̀rọ̀ náà wá tú sí ẹ lọ́wọ́, àmọ́ ọ̀rẹ́ ẹ bẹ̀ ẹ́ pé kó o máà jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀? Kí ló máa ká ẹ lára jù nínú ọ̀rọ̀ náà, ṣé bíbò tó o fẹ́ bá ọ̀rẹ́ ẹ bo ọ̀rọ̀ náà ni àbí ti gbígbà tó yẹ kó o gba ẹ̀mí ẹ̀ là?

Bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn bó o bá mọ̀ pé àwọn kan ń bára wọn jáde ní bòókẹ́lẹ́. Ìwọ gbàgbé ti pé ọ̀rẹ́ tẹ́ ẹ jọ ń bára yín ṣe lè bà jẹ́! Bó bá yá, ọ̀rẹ́ tòótọ́ á mọ̀ pé àlàáfíà òun ló jẹ ẹ́ lógún.—Òwe 27:6.

“Mo Ti Mọ Ohun Tó Yẹ Kí N Ṣe”

Jessica, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí yí ọkàn ẹ̀ padà lórí ọ̀rọ̀ à ń bára ẹni jáde ní bòókẹ́lẹ́ nígbà tó gbọ́ ohun tó ṣẹ́lẹ̀ sí Kristẹni kan tóun àti ẹlòmíì jọ ń bára wọn jáde. Jessica sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo gbọ́ bó ṣe fòpin sí bíbá onítọ̀hún jáde, kíá ni mo ti mọ ohun tó yẹ kémi náà ṣe.” Ṣó rọrùn láti fòpin sírú àjọṣe bẹ́ẹ̀? Rárá o! Jessica sọ pé: “Ká sòótọ́, mi ò tíì fẹ́ràn ọmọkùnrin tó bí mo ṣe fẹ́ràn ẹ̀ rí. Ó tó ọ̀sẹ̀ bíi méjì sí mẹ́ta tí mo fi ń sunkún lójoojúmọ́.”

Ohun mìíràn tí Jessica tún mọ̀ ni pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àti pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun fìgbà díẹ̀ ṣe ohun tí kò tọ́, òun ṣì ń fẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, ẹ̀dùn ọkàn tó ní nítorí pé kò bá ọkùnrin jáde mọ́ dópin. Jessica tún wá sọ pé: “Àjọṣe àárín èmi àti Jèhófà ti wá dáa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Mo ṣọpẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ pé ó ń fún wa ní ìtọ́sọ́nà tá a nílò ní àkókò tá a bá nílò rẹ̀ gẹ́lẹ́!”

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ́ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

b Wo àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ìgbà Wo Ló Yẹ Kí N Bẹ̀rẹ̀ sí Í Bá Ẹni Tí Kì Í Ṣe Ọkùnrin Tàbí Obìnrin Bíi Tèmi Jáde? èyí tó wà nínú ìtẹ̀jáde wa ti January–March 2007.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Tún padà lọ wo àwọn kókó mẹ́ta tá a fi lẹ́tà tó dúdú kirikiri kọ lójú ìwé 15. Ṣé èyíkéyìí wà nínú ẹ̀ tó bá bọ́ràn ṣe máa ń rí lára ẹ nígbà míì mu? Èwo ni nínú wọn?

◼ Báwo lo ṣe lè wá nǹkan ṣe sí i láìbá ẹnikẹ́ni jáde ní bòókẹ́lẹ́?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]

Ní Bòókẹ́lẹ́ àbí Láìsí Ariwo?

Gbogbo àwọn tó bá ń bára wọn jáde ní bòókẹ́lẹ́ kọ́ ni ọ̀rọ̀ wọn máa ń la ẹ̀tàn lọ o. Ó lè ṣẹlẹ̀ pé ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin kan tí wọ́n ti tó ṣègbéyàwó á fẹ́ láti túbọ̀ mọ ara wọn kí wọ́n sì pinnu pé títí dìgbà táwọn á fi mọra àwọn dáadáa, àwọn ò fẹ́ ariwo kankan. Ó sì lè jẹ́ pé ohun tó fà á, gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Thomas ṣe sọ, ni pé, “wọn ò fẹ́ káwọn èèyàn máa yọ wọ́n lẹ́nu nípa bíbéèrè pé, ‘Ìgbà wo lẹ wá máa ṣègbéyàwó?’”

Káwọn ẹlòmíì máa kó gìrìgìrì báni ní ìpalára tó ń ṣe lóòótọ́. (Orin Sólómọ́nì 2:7) Nítorí náà, nígbà tí ọkùnrin kan àti obìnrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jáde, wọ́n lè máà tíì fẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí wọ́n má bàa yara wọn láṣo. (Òwe 10:19) Anna, ọmọ ogún ọdún sọ pé: “Àìṣe é ní aláriwo yìí máa jẹ́ káwọn méjèèjì ní àkókò tó pọ̀ tó láti fi mọ̀ bóyá àwọn á lè jọ fẹ́ra. Bó bá ti wá dá wọn lójú wàyí, nígbà náà, wọ́n lè jẹ́ káyé gbọ́.”

Kò sì tún ní bójú mu pé kó o fi ọ̀rọ̀ ìwọ àtẹni tẹ́ ẹ jọ fẹ́ fẹ́ra pa mọ́ fáwọn tó yẹ kí wọ́n mọ̀ nípa ẹ̀, irú bí àwọn òbí ẹ àtàwọn òbí ẹni tẹ́ ẹ jọ ń bára yín jáde. Bó bá ṣòro fún ẹ láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹ̀ ń bára yín jáde, a jẹ́ pé kó o bí ara ẹ léèrè ohun tó fà á. Ṣé bíi ti Jessica tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí lọ̀rọ̀ tìẹ náà ṣe rí? Ṣéwọ náà mọ̀ lọ́kàn ara ẹ pé àwọn ìdí pàtàkì kan wà táwọn òbí ẹ ò fi ní gbà fún ẹ?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

Ọ̀RỌ̀ RÈÉ O Ẹ̀YIN ÒBÍ

Ó dájú pé o gbádùn àpilẹ̀kọ tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán yìí. ‘O sì lè máa bi ara ẹ pé, Ṣó wa lè jẹ́ pé ọmọ mi àti ẹlòmíì ń bára wọn jáde ní bòókẹ́lẹ́?’ O ò ṣe kúkú fúnra ẹ ka ohun táwọn ọ̀dọ́ mélòó kan sọ fún aṣojú ìwé ìròyìn Jí! nípa ohun tó lè mú káwọn ọ̀dọ́ kan máa bára wọn jáde ní bòókẹ́lẹ́, lẹ́yìn náà kó o wá ronú sí àwọn ìbéèrè tá a kọ sísàlẹ̀ ohun tí wọ́n sọ.

◼ “Àwọn ọmọ kan wà tí wọn kì í rí ohun tó lè mórí wọn yá nínú ilé, wọ́n á bá torí ìyẹn pinnu pé ó yẹ káwọn lọ́rẹ̀ẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin táwọn á máa jẹ̀ sí lọ́dọ̀.”—Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Wendy.

Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè rí i dájú pé ẹ̀ ń tẹ́tí gbọ́ ohun táwọn ọmọ yín bá ní í sọ? Ṣé àwọn ohun kan wà tó yẹ kẹ́ ẹ ṣiṣẹ́ lé lórí? Kí sì làwọn ohun náà?

◼ “Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ni mí nígbà tí akẹ́kọ̀ọ́ kan wá síléèwé wa láti orílẹ̀-èdè míì. Ó ní kí n jẹ́ ká máa ṣọ̀rẹ́, èmi náà sì gbà fún un. Èrò mi ni pé ó dáa kémi náà ní bọ̀bọ́ kan táá máa fọwọ́ kọ́ mi lọ́rùn.”—Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Diane.

Bó bá jẹ́ pé ọmọ ẹ ni Diane, kí lo máa ṣe sọ́rọ̀ tó wà ńlẹ̀ yìí?

◼ “Tẹlifóònù alágbèéká máa ń túbọ̀ mú nǹkan rọrùn fáwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ń bára wọn jáde. Àwọn òbí ò sì ní mọ ohun tó ń lọ!”—Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Annette.

Báwọn ọmọ yín bá ń lo tẹlifóònù alágbèéká, àwọn ọ̀nà wo lẹ lè gbà kọ́ wọn láti máa ṣọ́ra ṣe?

◼ “Ó túbọ̀ máa ń rọrùn fáwọn ọ̀dọ́ láti máa bára wọn jáde ní bòókẹ́lẹ́ báwọn òbí ò bá fojú sí ohun táwọn ọmọ wọn ń ṣe àti irú ẹni tí wọ́n ń bá rìn.”—Ọmọkùnrin kán tó ń jẹ́ Thomas.

Ṣó o lè wá nǹkan ṣe sí i táwọn ọmọ ẹ á fi rí ẹ bí alábàárò síbẹ̀ tí wàá sì máa fún wọn lómìnira tó yẹ?

◼ “Ó ṣeé ṣe káwọn òbí míì má tíì darí sílé nígbà táwọn ọmọ wọ́n bá tilé ìwé dé. Tàbí kó jẹ́ pé kò sẹ́ni tí wọn ò lè jẹ́ kọ́mọ wọn bá najú lọ síbi tó bá fẹ́.”—Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Nicholas.

Ngbọ́, àwọn wo ló jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ jù lọ fọ́mọ ẹ? Ǹjẹ́ o mọ ohun tí wọ́n ń ṣe bí wọ́n bá jọ wà pa pọ̀?

◼ “Báwọn òbí bá ti le koko jù, àwọn ọmọ wọn lè bẹ̀rẹ̀ sí báwọn ẹlòmíì jáde ní bòókẹ́lẹ́.”—Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Paul.

Láìkóyán àwọn òfin àtàwọn ìlànà Bíbélì kéré, báwo lo ṣe lè “jẹ́ kí ìfòyebánilò [rẹ] di mímọ̀”?—Fílípì 4:5.

◼ “Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́tàlá, mi ò fi bẹ́ẹ̀ rí ara mi bí ẹni táwọn èèyàn kà sí, nítorí náà mo máa ń fẹ́ káwọn èèyàn dá sí mi. Kò pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ ímeèlì sí ọmọkùnrin kan nínú ìjọ tó wà nítòsí, bíná ìfẹ́ ṣe ràn láàárín àwa méjèèjì nìyẹn o. Èmi náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí ara mi bí ẹni iyì.”—Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Linda.

Ṣó o lè ronú nípa àwọn ọ̀nà mìíràn kan tó sàn jù táwọn òbí Linda ì bá ti gbà ràn án lọ́wọ́ nínú ilé?

O ò ṣe lo àpilẹ̀kọ tó wà lójú ewé yìí láti bá ọmọ ẹ ọkùnrin tàbí ọmọ ẹ obìnrin jíròrò? Bó ò bá fẹ́ káwọn ọmọ ẹ máa ṣe nǹkan ní bòókẹ́lẹ́, ṣe ni kó o jẹ́ kí wọ́n rí ẹ bí alábàárò tó máa ń sọ bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an. Ó máa ń náni ní àkókò, ó sì máa ń gba sùúrù kéèyàn tó lè fòye mọ ohun tí ọ̀dọ́ kan ń fẹ́, àmọ́ kékeré kọ́ ni èrè táwọn òbí tó bá lo àkókò àti sùúrù bẹ́ẹ̀ máa rí.—Òwe 20:5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́