Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Kí Ló Dé Témi Ò fi Mọ Nǹkan Kan Ṣe?
“Mo máa ń wo ara mi bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀rẹ́ mi kan. Gbogbo nǹkan ló rọ̀ ọ́ lọ́run, àfi bíi pé kì í ṣe wàhálà rárá kọ́wọ́ ẹ̀ tó tẹ ohun tó ń fẹ́! Torí náà, ó máa ń ṣe mí bíi pé kò sóhun tí mo lè mọ̀ ọ́n ṣe. Èyí máa ń mú kí n kórìíra ara mi.”—Annette.a
ǸJẸ́ ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé o kò mọ nǹkan kan ṣe, tí kì í sì í jẹ́ kó o fẹ́ dáwọ́ le nǹkan tuntun? Ṣé ọ̀rọ̀ tí àwọn kan tó o bọ̀wọ̀ fún fi òótọ́ inú bá ẹ sọ máa ń jẹ́ kó o máa wo ara rẹ bí ẹni tí kò lè dá nǹkan kan ṣe? Ǹjẹ́ àwọn àṣìṣe tó o ti ṣe sẹ́yìn máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ, tí kì í sì í jẹ́ kó o fẹ́ gbìyànjú láti tún dáwọ́ lé nǹkan míì? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo lo ṣe lè mọ́kàn kúrò nínú àwọn àṣìṣe tó o ti ṣe kọjá, yálà ó jẹ́ àṣìṣe lóòótọ́, tàbí èyí tó o kàn kà sí àṣìṣe?
Ó ṣe pàtàkì pé kó o wá ìdáhùn sí ìbéèrè tó gbẹ̀yìn yìí, torí pé gbogbo èèyàn ló máa ń ṣe àṣìṣe ní àwọn àkókò kan nígbèésí ayé wọn. (Róòmù 3:23) Àmọ́, àwọn tó mọ béèyàn ṣe ń mú nǹkan mọ́ra nígbà tí ìjákulẹ̀ bá dé máa ń lè tètè borí ìṣòro. Ìyẹn túmọ̀ sí pé wọ́n á lè ronú jinlẹ̀ nípa ohun tó fa àṣìṣe wọn, wọ́n á mọ́kàn kúrò níbẹ̀, wọ́n á sì lè gbìyànjú nǹkan náà wò lẹ́ẹ̀kan sí i. Nígbà míì, ó ṣeé ṣe kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí! Ní báyìí, jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò bó o ṣe lè kojú àwọn ìṣòro mẹ́ta yìí: ohun tó lè ṣẹlẹ̀, ohun tó o ronú pé ó ṣẹlẹ̀ àti ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́.
OHUN TÓ LÈ ṢẸLẸ̀ O ronú pé ohun tó o fẹ́ ṣe kò ní yọrí sí rere, ìyẹn mú kó o má ṣe dáwọ́ lé nǹkan náà, èrò rẹ ni pé o kò ní ṣàṣeyọrí.
Mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro. Fi àmì yìí ✔ síwájú ohun tó wù ẹ́ pé kó o ṣe ní àṣeyọrí, àmọ́ tó dá ẹ lójú pé o kò lè ṣàṣeyọrí tó o bá gbìyànjú ẹ̀ wò.
◯ Ṣíṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ fún àwọn ọmọ kíláàsì rẹ
◯ Wíwá iṣẹ́
◯ Sísọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ
◯ Kíkópa nínú eré ìdárayá
◯ Kíkọrin tàbí lílo ohun èlò ìkọrin kan
◯ Nǹkan míì ․․․․․
Ronú jinlẹ̀. Ronú nípa èyí tó o mú lára àwọn kókó tá a tò sókè yìí, kó o sì ro ohun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àbájáde rẹ̀ nípa dídáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
‘Kí ni mo fẹ́ kó ṣẹlẹ̀?’
․․․․․
Kí ló ń bà mí lẹ́rù gan-an?
․․․․․
Ní báyìí, kọ ìdí kan tó o fi ronú pé ó yẹ kó o gbìyànjú rẹ̀ wò, láìwo ti ẹ̀rù tó ń bà ẹ́ pé o lè má ṣàṣeyọrí.
․․․․․
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì. Nígbà tí Ọlọ́run gbé iṣẹ́ fún Mósè pé kó di aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ohun tó kọ́kọ́ wá sí i lọ́kàn ni pé nǹkan lè má lọ dáadáa. Mósè bi Ọlọ́run pé: “Ká ní wọn kò gbà mí gbọ́ tí wọn kò sì fetí sí ohùn mi” ńkọ́? Lẹ́yìn náà, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro rẹ̀. Ó sọ pé: “Èmi kì í ṣe ẹni tí ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó já geere. . . . Ẹnu mi wúwo, ahọ́n mi sì wúwo.” Kódà lẹ́yìn tí Jèhófà ti ṣèlérí fún un pé òun máa ràn án lọ́wọ́, Mósè bẹ̀bẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, ránṣẹ́ nípa ọwọ́ ẹni tí ìwọ yóò rán.” Tàbí gẹ́gẹ́ bí Bíbélì Contemporary English Version ṣe túmọ̀ ibi yìí, “jọ̀wọ́, rán ẹlòmíì pé kó lọ ṣe é.” (Ẹ́kísódù 4:1, 10, 13) Níkẹyìn, Mósè gba iṣẹ́ náà, a sì mọ̀ pé ó ṣe é ní àṣeyọrí. Ọlọ́run darí Mósè, ó sì ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún ogójì ọdún.
Ohun tó o lè ṣe. Sólómọ́nì Ọba kọ̀wé pé: “Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é.” (Oníwàásù 9:10) Torí náà, dípò tí wàá fi máa bẹ̀rù pé o kò ní ṣàṣeyọrí, ńṣe ni kó o ṣe gbogbo ohun tí agbára rẹ bá gbé. O ò ṣe ronú nípa ìgbà tó o ṣe dáadáa ju bó o ṣe rò lọ? Ẹ̀kọ́ wo lo kọ́ nípa ara rẹ látinú àṣeyọrí tó o ṣe? Báwo ni ẹ̀kọ́ tó o kọ́ ṣe lè mú kó o borí ìbẹ̀rù tó ṣeé ṣe kó wà lọ́kàn rẹ pé o lè má ṣàṣeyọrí?
Àbá: Tó bá pọn dandan, gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ kan tó dàgbà tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè túbọ̀ dá ara rẹ lójú.b
OHUN TÓ O RONÚ PÉ Ó ṢẸLẸ̀ Bí ẹnì kan bá ṣàṣeyọrí nínú ohun kan, ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé ìwọ ò kúkú mọ nǹkan kan ṣe ní tìẹ.
Mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro. Ta lò ń fi ara rẹ wé, kí sì ni ẹni yẹn ṣe tó mú kó máa ṣe ẹ́ bíi pé o kò mọ nǹkan kan ṣe?
․․․․․
Ronú jinlẹ̀. Ṣé òótọ́ ni pé àṣeyọrí tí ẹni yẹn ṣe túmọ̀ sí pé ìwọ ò mọ nǹkan kan ṣe? Kọ ohun kan tó ṣẹlẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, irú bí ìdánwò nílé ìwé, tó jẹ́ pé ìwọ ṣe dáadáa, àmọ́ tí ẹlòmíì ṣe dáadáa jù ẹ́ lọ.
․․․․․
Ní báyìí, wá ṣàkọsílẹ̀ ìdí tó o fi fẹ́ ṣe dáadáa jù lọ.
․․․․․
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì. ‘Ìbínú Kéènì gbóná’ nígbà tó rí i pé Jèhófà fojú rere wo Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀. Jèhófà kìlọ̀ fún Kéènì nípa ìlara tó wà lọ́kàn rẹ̀, àmọ́ Jèhófà tún sọ ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ó gbà pé Kéènì lè ṣàṣeyọrí tó bá fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Jèhófà sọ fún un pé: “Bí ìwọ bá yíjú sí ṣíṣe rere, ara rẹ kò ha ní yá gágá bí?”c—Jẹ́nẹ́sísì 4:6, 7.
Ohun tó o lè ṣe. Nígbà táwọn ẹlòmíì bá ṣàṣeyọrí, dípò tí wàá fi máa ru “ìdíje sókè,” ì báà jẹ́ nínú ọkàn rẹ pàápàá, ńṣe ni kó o máa bá wọn yọ̀. (Gálátíà 5:26; Róòmù 12:15) Bákan náà, máa fojú pàtàkì wo àwọn ẹ̀bùn rere tí ìwọ náà ní, àmọ́ má ṣe gbéra ga. Bíbélì sọ pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan.”—Gálátíà 6:4.
OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ LÓÒÓTỌ́ Ò ń ronú nípa àwọn àṣìṣe tó o ti ṣe sẹ́yìn, ó wá ń ṣe ẹ́ bíi pé kò sí ohun tó o lè ṣe láṣeyọrí mọ́.
Mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro. Àṣìṣe wo lo ti ṣe sẹ́yìn tó kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ jù lọ?
․․․․․
Ronú jinlẹ̀. Ṣé àṣìṣe tó o kọ sókè yìí fi hàn pé o kò mọ nǹkan kan ṣe lóòótọ́? Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé nǹkan kan ló kàn ṣẹlẹ̀ sí ẹ nígbà yẹn tó mú kó o ṣe àṣìṣe yẹn, ṣé ìyẹn wá fi hàn pé ọ̀rọ̀ rẹ kò ní àtúnṣe mọ́ rárá ni? Àbí ńṣe ló kàn jẹ́ àmì pé o nílò ìrànlọ́wọ́? Tó o bá ṣubú nígbà tó ò ń ṣeré ìdárayá, ó dájú pé wàá fẹ́ kí ẹnì kan ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa ṣe eré náà lọ. Kí ló dé tí o kò ṣe ohun kan náà láti borí àṣìṣe tó o ṣe? Kọ orúkọ ẹni kan tó o lè sọ ìṣòro rẹ fún.d
․․․․․
Àpẹẹrẹ inú Bíbélì. Nígbà míì, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń ní ìrẹ̀wẹ̀sì nítorí àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó rẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Èmi abòṣì ènìyàn!” (Róòmù 7:24) Àmọ́, ó ṣe kedere pé Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni òun, ìyẹn kò sọ òun di èèyàn burúkú. Ó sọ pé: “Mo ti ja ìjà àtàtà náà, mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.”—2 Tímótì 4:7.
Ohun tó o lè ṣe. Dípò tí wàá fi máa ronú ṣáá nípa àwọn àṣìṣe rẹ, ronú nípa àwọn ibi tó o dáa sí. Ohun tí Jèhófà máa ń ṣe gan-an nìyẹn. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.”—Hébérù 6:10; Sáàmù 110:3.
Rántí pé: Ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa. Gbogbo èèyàn ló máa ń ṣe àṣìṣe. Tó o bá kọ́ bó o ṣe lè borí ìṣòro, á jẹ́ pé o ti ní ohun pàtàkì kan tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní gan-an tó o bá di àgbàlagbà nìyẹn. Òwe 24:16 sọ pé: “Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje pàápàá, yóò sì dìde dájúdájú.” Ìwọ náà lè dìde tó o bá ṣubú!
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.
b Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo Jí! July–September ọdún 2010, ojú ìwé 26 sí 28.
c Kéènì yàn láti má ṣe ka ìṣílétí tí Jèhófà fún un sí. Ìṣubú Kéènì fi hàn pé tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o ṣe ìlara àwọn ẹlòmíì nígbà tí wọ́n bá ṣàṣeyọrí, àfi kó o yáa mú irú èrò bẹ́ẹ̀ kúrò lọkàn rẹ.—Fílípì 2:3.
d Bí Kristẹni kan bá ti ṣe àṣìṣe ńlá, ó máa jàǹfààní tó bá sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ọ̀kan nínú àwọn alàgbà ìjọ.—Jákọ́bù 5:14, 16.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ
“Tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan tó o mọ̀ ọ́n ṣe nìkan lo máa ń ṣe, tí o kò gbìyànjú láti ṣe àwọn nǹkan tó ò tíì ṣe rí, torí pé ẹ̀rù ń bà ẹ́ pé kó o má lọ ṣe àṣìṣe, ọ̀pọ̀ nǹkan ni wàá máa pàdánù.”
“O lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe rẹ, kó o sì ṣàtúnṣe, o sì lè máa ronú ṣáá nípa àṣìṣe rẹ, kó o wá máa ṣe àwọn nǹkan tó o ronú pé ó rọ̀ ẹ́ lọ́rùn nìkan. Ìyẹn sinmi lórí irú ẹni tó o yàn láti jẹ́.”
“Tí mo bá mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí n má ṣàṣeyọrí nínú ohùn kan, mi ò kì í da ara mi láàmù ju bó ṣe yẹ lọ lórí nǹkan ọ̀hún. Ó sàn láti fi ọ̀ràn náà rẹ́rìn-ín ju pé kéèyàn wá máa kárí sọ. Téèyàn bá ń fẹ́ ṣe kọjá ohun tí agbára rẹ̀ gbé, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè láyọ̀ láéláé.”
[Àwọn àwòrán]
Andrea
Trenton
Naomi
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]
O Ò ṢE BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ÒBÍ RẸ?
Nígbà tẹ́ ẹ wà ní ọ̀dọ́, àwọn ìjákulẹ̀ wo lẹ ní? Báwo lẹ ṣe borí rẹ̀? Ṣé ẹ ṣì máa ń dojú kọ irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ látìgbàdégbà?
․․․․․
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Tí ẹnì kan bá ṣubú, tó bá fẹ́ kí ara òun tètè bọ̀ sípò, ńṣe ló máa dìde, ó sì lè wá ìrànlọ́wọ́ tó bá pọn dandan