Àlàyé Jessica
JESSICA, ọmọdébìnrin ọlọ́dún 13 kan láti United States, ni a yàn pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní kíláàsì láti sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Ọlọrun, Àsíá àti Orílẹ̀-Èdè.” Bí ó ti mọ̀ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ń tọpinpin nípa ìdí tí òun gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kì í fi í kí àsíá, Jessica fi tìgboyàtìgboyà lo àǹfààní àyè tí ó ṣí sílẹ̀ yìí láti ṣàlàyé àwọn èrò ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí jẹ́ àyọkà láti inú àlàyé rẹ̀.
“Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ní ilé ìwé, wọ́n máa ń sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ka ẹ̀jẹ́ ìtúúbá, ṣùgbọ́n nítorí ìgbàgbọ́ àti ìsìn mi, èmi kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń ṣe kàyéfì nípa ìdí rẹ̀. Èmi yóò sọ fún yín nísinsìnyí.
“Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣáájú nínú kíkí àsíá náà ni: ‘Mo jẹ́jẹ̀ẹ́ ìtúúbá fún àsíá.’ Ó dára, kí ni ìtúúbá? Ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ ìtìlẹyìn, ìdúróṣinṣin àti ìfọkànsìn. Níwọ̀n bí mo ti jẹ́jẹ̀ẹ́ ìtúúbá mi fún Ọlọrun tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, n kò lè jẹ́jẹ̀ẹ́ ìtúúbá mi fún àsíá, n kì yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, pé n kò jọ́sìn tàbí jẹ́jẹ̀ẹ́ ìtúúbá mi fún àsíá kò túmọ̀ sí pé n kò bọ̀wọ̀ fún un.
“Ọlọrun ni ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé mi. Mo ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti tẹ̀ lé àwọn òfin rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti là á lẹ́sẹẹsẹ nínú Bibeli. Mo máa ń gbàdúrà sí i lójoojúmọ́, mo sì tún máa ń gbàdúrà nígbà tí mo bá nílò àfikún ìrànlọ́wọ́ tàbí ìṣírí. Mo sábà máa ń rí ìrànlọ́wọ́ àti ìṣírí yẹn gbà ní àkókò yíyẹ. Mo ti rí i pé, mo túbọ̀ ń láyọ̀ sí i nígbà tí mo bá fí Ọlọrun ṣáájú àti nígbà tí mo bá ṣe àwọn ohun tí òún ti pa láṣẹ fún wa láti ṣe.
“Nítorí náà, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, n kì í kí àsíá, mo bọ̀wọ̀ fún un, n kì yóò sì tàbùkù sí i lọ́nàkọnà. Ṣùgbọ́n, ìtúúbá mi wà fún Ọlọrun, ó sì rí bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, nítorí pé òun ni ó dá mi, mo sì jẹ ẹ́ ní gbèsè ìtúúbá yẹn.”
A béèrè pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní kíláàsì Jessica díye lé àlàyé tí wọ́n gbọ́. Ẹ wo bí Jessica ti láyọ̀ tó pé nítorí ìsapá rẹ̀, àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní kíláàsì sọ pé, àwọn ti jèrè òye kíkún sí i nípa àwọn èrò ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ní pàtàkì, àwọn èwe tí wọ́n ń fi tìgboyàtìgboyà sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlànà Bibeli ń mú ọkàn-àyà Jehofa Ọlọrun láyọ̀!—Owe 27:11.