Kí Nìdí Táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Máa Ń Fi Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ Kọ̀ Láti Ka Ẹ̀jẹ́ Tàbí Kọ Orin Orílẹ̀-Èdè?
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń bọ̀wọ̀ fún ìjọba àtàwọn àmì ìlú. A sì gbà pé àwọn míì lè pinnu láti ka ẹ̀jẹ́ orílẹ̀-èdè, láti bẹ́rí tàbí kí àsíá tàbí kí wọ́n kọ orin orílẹ̀-èdè.
Àmọ́, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan yìí torí a gbà pé ó ta ko ìlànà Bíbélì. Inú wa máa ń dùn táwọn míì bá bọ̀wọ̀ fún ìpinnu tá a ṣe yìí torí àwa náà máa ń bọ̀wọ̀ fún ìpinnu táwọn míì bá ṣe.
Nínú àpilẹ̀kọ yìí
Àwọn ìlànà Bíbélì wo ni kì í jẹ́ ká lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan yìí?
Ṣé torí ká lè gbè sẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú kan làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan yìí?
Àwọn ìlànà Bíbélì wo ni kì í jẹ́ ká lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan yìí?
Àwọn ìlànà Bíbélì méjì yìí la gbé ìpinnu wa kà:
Ọlọ́run nìkan ló yẹ ká máa sìn. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.” (Lúùkù 4:8) Ẹ̀jẹ́ orílẹ̀-èdè àti orin orílẹ̀-èdè sábà máa ń ní àwọn ọ̀rọ̀ kan níbi tí ẹni tó ń kà á ti máa ṣèlérí pé òun á fi gbogbo agbára òun sin orílẹ̀-èdè òun, àtipé orílẹ̀-èdè òun ni òun á fi ṣáájú ohun gbogbo. Torí náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò lè ṣe irú ìlérí bẹ́ẹ̀ torí pé kò bá ẹ̀rí ọkàn wa mu.
Bákan náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé tá a bá bẹ́rí tàbí kí àsíá, ṣe là ń jọ́sìn ohun tí àsíá náà ṣàpẹẹrẹ. Ìbọ̀rìṣà nìyẹn, Bíbélì sì sọ pé a ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ìbọ̀rìṣà. (1 Kọ́ríńtì 10:14) Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé àmì ìjọsìn kan ni àsíá. Kódà, òpìtàn kan tó ń jẹ́ Carlton J. H. Hayes sọ pé: “Àsíá ni àmì tí wọ́n fi ń gbé ìjọsìn orílẹ̀-èdè lárugẹ.” a Òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Daniel P. Mannix sọ nípa àwọn Kristẹni ayé àtijọ́ pé: “Àwọn Kristẹni kọ̀ láti rúbọ sí olú ọba Róòmù, ìyẹn sì dà bí ìgbà téèyàn kọ̀ láti bẹ́rí tàbí kí àsíá.”b
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í bẹ́rí tàbí kí àsíá, a kì í fà á ya tàbí ká dáná sun ún, a kì í sì í ṣe ohunkóhun tó fi hàn pé a ò bọ̀wọ̀ fún àsíá tàbí àmì míì tí ìjọba ń lò.
Ọ̀kan náà ni gbogbo èèyàn jẹ́ lójú Ọlọ́run. (Ìṣe 10:34, 35) Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run pé “láti ara ọkùnrin kan ló ti dá àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Ìṣe 17:26) Ìdí nìyẹn táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé kò ní dáa ká máa gbé ẹ̀yà kan tàbí orílẹ̀-èdè kan lárugẹ ju òmíì lọ. Torí náà, gbogbo èèyàn la máa ń bọ̀wọ̀ fún láìka ibi tí wọ́n ti wá àti ibi tí wọ́n ń gbé sí.—1 Pétérù 2:17.
Tí ìjọba bá ṣòfin pé dandan ni ká lọ́wọ́ sí ńkọ́?
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ta ko ìjọba. A gbà pé àwọn ìjọba yìí wà lára “ètò tí Ọlọ́run ṣe,” tó sì gbà láàyè. (Róòmù 13:1-7) A tún gbà pé àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí ìjọba.—Lúùkù 20:25.
Àmọ́ tí ìjọba bá ṣe òfin tó ta ko òfin Ọlọ́run ńkọ́? Láwọn ipò kan, a lè tọ̀ ọ́ lọ́nà òfin, ká sì kọ̀wé sí ìjọba pé kí wọ́n ṣe àwọn àyípadà kan sí òfin náà.c Tí wọ́n bá kọ̀ jálẹ̀, tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa yàn láti “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí alákòóso dípò èèyàn.”—Ìṣe 5:29.
Ṣé torí ká lè gbè sẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú kan làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan yìí?
Rárá o. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Ti pé a ò ka ẹ̀jẹ́ orílẹ̀-èdè, a ò bẹ́rí fún àsíá, a ò sì kọ orin orílẹ̀-èdè, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé à ń ta ko ìjọba. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn nǹkan yìí la pinnu láti ṣe.