ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ed ojú ìwé 19-25
  • Ìtóye Ọ̀nà Ìwà Híhù tí Ó Yẹ Láti Bọ̀wọ̀ fún

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtóye Ọ̀nà Ìwà Híhù tí Ó Yẹ Láti Bọ̀wọ̀ fún
  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kíkí Àsíá
  • Ẹ̀tọ́ Àwọn Òbí
  • Agbo Ilé Tí Ó Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ Ní Ti Ìsìn
  • Ẹ̀tọ́ Àwọn Ọmọ Láti Lo Ẹ̀rí Ọkàn
  • “Ìgbàlà Jẹ́ Ti Jèhófà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Kí Nìdí Táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Máa Ń Fi Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ Kọ̀ Láti Ka Ẹ̀jẹ́ Tàbí Kọ Orin Orílẹ̀-Èdè?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Kíkí Àsíá, Dídìbò àti Sísin Ìlú Ẹni
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Àlàyé Jessica
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́
ed ojú ìwé 19-25
Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbìyànjú láti gbin ìtóye Kristẹni tòótọ́ sínú àwọn ọmọ wọn

Ìtóye Ọ̀nà Ìwà Híhù tí Ó Yẹ Láti Bọ̀wọ̀ fún

Jálẹ̀ ìtàn, àwọn ọkùnrin àti obìnrin onígboyà ti mú ìdúró tí ó yàtọ̀ sí èrò tí ó gbajúmọ̀ ní àkókò wọn. Wọ́n tí fara da ìwà òṣìkà agbonimọ́lẹ̀ ti ìṣèlú, ti ìsìn, àti ti ẹ̀yà ìran, tí wọ́n sì sábà máa ń fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ fún ìlànà tí wọ́n tẹ́wọ́ gbà.

ÀWỌN Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ jẹ́ onígboyà ní pàtàkì. Nígbà inúnibíni gbígbóná janjan ní ọ̀rúndún mẹ́ta àkọ́kọ́, àwọn ará Róòmù olórìṣà pa ọ̀pọ̀ wọn nítorí tí wọ́n kọ̀ láti jọ́sìn olú ọba. Ní àwọn ìgbà kan, a gbé pẹpẹ kan kalẹ̀ sí gbọ̀ngàn ìṣeré. Láti jèrè òmìnira wọn, àwọn Kristẹni yóò wulẹ̀ ní láti sun tùràrí tẹ́ẹ́rẹ́ kan láti jẹ́wọ́ ipò àtọ̀runwá olú ọba. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn díẹ̀ juwọ́ sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ yàn láti kú jù láti sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn lọ.

Lóde òní, àwọn Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú ipò kan náà lórí ọ̀ràn àìdásítọ̀túntòsì ìṣèlú. Fún àpẹẹrẹ, ìdúróṣinṣin wọn láìka àtakò ètò ìjọba Nazi sí jẹ́ ọ̀rọ̀ ìtàn tí ó lákọsílẹ̀. Ṣáájú àti nígbà ogun àgbáyé kejì, ìdámẹ́rin àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ará Germany pàdánù ìwàláàyè wọn, ní pàtàkì nínú ọgbà ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, nítorí pé wọ́n ṣàìdásí tọ̀túntòsì, wọ́n sì kọ̀ láti sọ pé “Ẹ fọn rere Hitler.” A fi agbára pín àwọn ọmọdé níyà kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn Ẹlẹ́rìí. Láìka ìkìmọ́lẹ̀ náà sí, àwọn ọmọdé dúró ṣinṣin, wọ́n sì kọ̀ láti di ẹni tí a sọ di ẹlẹ́gbin nípasẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá ìwé mímọ́ mú, tí àwọn ẹlòmíràn ń gbìyànjú láti fi agbára mú wọn tẹ́wọ́ gbà.

Kíkí Àsíá

Ní gbogbogbòò, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ìfojúsùn fún inúnibíni rírorò bẹ́ẹ̀ lónìí. Bí ó ti wù kí ó rí, èdè àìyedè máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà míràn nítorí ìpinnu àfẹ̀rí-ọkàn-ṣe ti àwọn ọmọdé Ẹlẹ́rìí láti má ṣe lọ́wọ́ nínú àwọn ayẹyẹ ìfọkànsìn orílẹ̀-èdè, irú bíi kíkí àsíá.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21

“Ẹ dá ohun tí ó jẹ́ ti Késárì padà fún Késárì​—àti fún Ọlọ́run, ohun tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run”​—Mátíù 22:21, Jerusalem Bible

A kọ́ àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti má ṣe dí àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kí àsíá; ìpinnu oníkálùkù nìyẹn. Bí ó ti wù kí ó rí, ipò tí àwọn Ẹlẹ́rìí fúnra wọ́n dì mú kò ṣeé yẹ̀: Wọn kì í kí àsíá orílẹ̀-èdè èyíkéyìí. Èyí dájúdájú kì í ṣe láti ṣàfojúdi. Wọ́n bọ̀wọ̀ fún àsíá orílẹ̀-èdè èyíkéyìí tí wọ́n bá ń gbé, wọ́n sì ń fi ọ̀wọ̀ yìí hàn nípa ṣíṣègbọràn sí àṣẹ orílẹ̀-èdè náà. Wọn kì í lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò èyíkéyìí lòdì sí ìjọba. Ní tòótọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí gbà gbọ́ pé àwọn ìjọba ẹ̀dá ènìyàn tí ó wà nísinsìnyí jẹ́ “ìṣètò Ọlọ́run” tí òun ti fàyè gbà láti wà. Nítorí náà, wọ́n gbà pé àwọn wà lábẹ́ àṣẹ àtọ̀runwá láti san owó orí, kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún “àwọn aláṣẹ onípò gíga” bẹ́ẹ̀. (Róòmù 13:1-7) Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú gbólóhùn olókìkí Kristi pé: “Ẹ dá ohun tí ó jẹ́ ti Késárì padà fún Késárì​—àti fún Ọlọ́run, ohun tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run.”​—Mátíù 22:21, Jerusalem Bible ti Kátólíìkì.

Àwọn kan lè béèrè pé, ‘Ṣùgbọ́n èé ṣe nígbà náà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í bọ̀wọ̀ fún àsíá nípa kíkí i?’ Ó jẹ́ nítorí pé, wọ́n ka kíkí àsíá sí ìjọsìn kan, ìjọsìn sì jẹ́ ti Ọlọ́run; wọn kò lè fínnúfíndọ̀ fún ẹlòmíràn tàbí ohun mìíràn ní ìjọsìn yàtọ̀ sí Ọlọ́run. (Mátíù 4:10; Ìṣe 5:29) Nítorí náà, wọ́n máa ń mọrírì rẹ̀ nígbà tí àwọn olùkọ́ bá bọ̀wọ̀ fún èrò ìgbàgbọ́ yìí tí wọ́n sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí pa ohun tí wọ́n gbà gbọ́ mọ́.

Kò yani lẹ́nu pé, kì í ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni ó gbà gbọ́ pé kíkí àsíá jẹ mọ́ ìjọsìn, bí àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí ti fi hàn:

“Àwọn àsíá àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ti ìsìn látòkèdélẹ̀. . . . Ó dà bíi pé ìgbà gbogbo ni a ń wá ìtìlẹyìn ìsìn láti fún àsíá orílẹ̀-èdè ní ìjẹ́mímọ́.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.)​—Encyclopædia Britannica.

“Àsíá, gẹ́gẹ́ bí àgbélébùú, jẹ́ mímọ́. . . . Àwọn ìlànà àti òfin tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìwà ènìyàn sí ìlànà orílẹ̀-èdè lo àwọn ọ̀rọ̀ lílágbára, tí ó nítumọ̀ pàtàkì bí, ‘Iṣẹ́ Ìsìn fún Àsíá,’ . . . ‘Ọ̀wọ̀ fún Àsíá,’ ‘Ìfọkànsìn fún Àsíá.’” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.)​—The Encyclopedia Americana.

“Àwọn Kristẹni kọ̀ láti . . . rúbọ sí òrìṣà olú ọba [àwọn ará Róòmù]​—tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ bára dọ́gba pẹ̀lú kíkọ̀ láti kí àsíá tàbí ṣe àtúnsọ ẹ̀jẹ́ ìfọkànsìn ní ọjọ́ wa.”​—Those About to Die (1958), láti ọwọ́ Daniel P. Mannix, ojú ìwé 135.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin Hébérù mẹ́ta kọ̀ láti tẹrí ba níwájú ère tí ọba Bábílónì, Nebukadinésárì, gbé kalẹ̀

Kí a tún sọ ọ́ lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò pète láti fojú di ìjọba èyíkéyìí tàbí àwọn alákòóso rẹ̀ nípa kíkọ̀ láti kí àsíá. Ó wulẹ̀ jẹ́ pé, nínú ìṣe ìjọsìn, wọn kì yóò tẹrí ba fún àwòrán kan tí ń ṣojú fún Orílẹ̀-Èdè, wọn kì yóò sì kí i. Wọ́n kà á sí ohun kan náà pẹ̀lú ìdúró tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin Hébérù mẹ́ta dì mú ní àkókò tí a kọ Bíbélì, tí wọ́n kọ̀ láti tẹrí ba níwájú ère tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì gbé kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà. (Dáníẹ́lì, orí 3) Nítorí náà, bí àwọn yòó kù tilẹ̀ ń kí àsíá, tí wọ́n sì ń jẹ́jẹ̀ẹ́ ìfọkànsìn, àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni a kọ́ láti tẹ̀ lé ẹ̀rí ọkàn wọn tí a ti fi Bíbélì kọ́. Nípa báyìí, wọ́n ń fi ìdákẹ́jẹ́ẹ́ àti tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fà sẹ́yìn nínú kíkópa. Fún ìdí kan náà, àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí yàn láti má ṣe kópa nígbà tí a bá ń kọ tàbí lu àwo orin ìjẹ́wọ́ orílẹ̀-èdè.

Ọ̀wọ̀, Ṣùgbọ́n Kì í Ṣe Ìjọsìn

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan, ní ilé ẹ̀kọ́ kan ní Kánádà, ọmọdébìnrin Ẹlẹ́rìí ọlọ́dún 11 kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Terra, kíyè sí i pé olùkọ́ rẹ̀ mú akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan jáde nínú kíláàsì fún ìgbà díẹ̀. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, olùkọ́ náà rọra sọ fún Terra pé kí ó tẹ̀ lé òun lọ sí ọ́fíìsì ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́.

Bí ó ṣe wọnú ọ́fíìsì, Terra rí i lójú ẹsẹ̀ pé a fi àsíá Kánádà há tábìlì ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́. Lẹ́yìn náà, olùkọ́ náà pàṣẹ fún Terra láti tutọ́ sára àsíá náà. Ó dábàá pé, níwọ̀n bí Terra kì í ti í kọ orin ìjúbà orílẹ̀-èdè, tí kì í sì í kí àsíá, kò sí ìdí tí kò fi yẹ kí ó tutọ́ sára àsíá náà nígbà tí a bá pàṣẹ fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. Terra kọ̀, ní ṣíṣàlàyé pé bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò tilẹ̀ jọ́sìn àsíá, wọ́n ń bọ̀wọ̀ fún un.

Nígbà tí wọ́n padà dé kíláàsì, olùkọ́ náà kéde pé òun ṣẹ̀ṣẹ̀ dán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjì wò tán ni, ní pípàṣẹ fún wọn láti tutọ́ sára àsíá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé akẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́ ń lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ ìfọkànsìn orílẹ̀-èdè, síbẹ̀síbẹ̀, ó tutọ́ sára àsíá náà nígbà tí a pàṣẹ fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, bí Terra kì í tilẹ̀ kọ orin ìjúbà, tí kì í sì í kí àsíá, ó kọ̀ láti tàbùkù sí i lọ́nà yìí. Olùkọ́ náà ṣàlàyé pé nínú àwọn méjèèjì, Terra ni ó fi ọ̀wọ̀ yíyẹ hàn.

Ẹ̀tọ́ Àwọn Òbí

Lónìí, ọ̀pọ̀ jù lọ orílẹ̀-èdè máa ń bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àwọn òbí láti fún àwọn ọmọ wọn ní ìtọ́ni ìsìn ní ìbámu pẹ̀lú èrò ìgbàgbọ́ wọn. Gbogbo ìsìn ni ó ti ẹ̀tọ́ yìí lẹ́yìn, gẹ́gẹ́ bí òfin ṣọ́ọ̀ṣì, tí ó ṣì gbéṣẹ́, nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ti sọ pé: “Bí àwọn òbí bá ti bí àwọn ọmọ wọn, wọ́n wà lábẹ́ ẹrù iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe gidi láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì ní ẹ̀tọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀; ìdí nìyẹn tí ó fi pọn dandan ní pàtàkì fún àwọn òbí láti pèsè ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Kristẹni fún àwọn ọmọ wọn ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì.”​—Canon 226.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25

A fún àwọn ọmọ níṣìírí láti fìfẹ́ hàn nínú àwọn ẹlòmíràn

Ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń béèrè kò ju ìyẹn lọ. Gẹ́gẹ́ bí òbí tí ó bìkítà, wọ́n ń gbìyànjú láti gbin ìtóye Kristẹni tòótọ́ sínú àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì ń fi ìfẹ́ fún aládùúgbò àti ọ̀wọ̀ fún ohun ìní àwọn ẹlòmíràn kọ́ wọn. Wọ́n fọkàn fẹ́ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni ní Éfésù pé: “Ẹ̀yin òbí, ẹ má ṣe bá àwọn ọmọ yín lò lọ́nà kan tí ẹ óò fi mú wọn bínú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ tọ́ wọn dàgbà pẹ̀lú ìlànà àti ìtọ́ni Kristẹni.”​—Éfésù 6:4, Today’s English Version.

Àwọn Ìlànà Ìwà Híhù Kan Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Tẹ̀ Lé

Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìtóye ìwà híhù, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ àwọn ọmọ wọn láti yẹra fún àwọn ìwà, àṣà, àní ẹ̀mí ìrònú pàápàá, tí ó lè mú ìpalára wá bá wọn tàbí bá àwọn ẹlòmíràn, bí wọ́n tilẹ̀ wọ́pọ̀ nínú ayé lónìí. (Jákọ́bù 1:27) Nítorí náà, wọ́n ń kìlọ̀ fún àwọn ọmọ wọn nípa àwọn ewu oògùn líle àti àwọn àṣà míràn, bíi sìgá mímu àti ìmukúmu. (Òwe 20:1; Kọ́ríńtì Kejì 7:1) Wọ́n gbà gbọ́ nínú ìjẹ́pàtàkì àìlábòsí àti ṣíṣiṣẹ́ kára. (Éfésù 4:28) Wọ́n ń kọ́ àwọn ọmọ wọn láti yẹra fún àwọn èdè rírùn. (Éfésù 5:3, 4) Wọ́n tún ń kọ́ wọn láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì lórí ìwà rere ìbálòpọ̀ takọtabo, kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ àti fún ara àti ohun ìní àwọn ẹlòmíràn. (Kọ́ríńtì Kìíní 6:9, 10; Títù 3:1, 2; Hébérù 13:4) Wọ́n gbà gbọ́ tinútinú pé gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà wọ̀nyẹn jẹ́ fún ire dídára jù lọ àwọn ọmọ wọn.

Agbo Ilé Tí Ó Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ Ní Ti Ìsìn

Nínú àwọn ìdílé kan, òbí kan ṣoṣo ni ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, a fún òbí tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí náà níṣìírí láti mọ ẹ̀tọ́ tí òbí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí náà pẹ̀lú ní, láti fún àwọn ọmọ rẹ̀ nítọ̀ọ́ni ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ ìsìn rẹ̀. Ìrírí tí kò dára tí àwọn ọmọ tí a ṣí sílẹ̀ sí ojú ìwòye ìsìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ máa ń ní kò tó nǹkan, bí ó bá tilẹ̀ wà rárá.a Ní ti gidi, gbogbo ọmọ ní láti pinnu ìsìn tí wọn yóò tẹ̀ lé. Ní ti ẹ̀dá, kì í ṣe gbogbo èwe ní ń yàn láti tẹ̀ lé ìlànà ìsìn àwọn òbí wọn, yálà wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

Ẹ̀tọ́ Àwọn Ọmọ Láti Lo Ẹ̀rí Ọkàn

O tún gbọ́dọ̀ mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ka ẹ̀rí ọkàn Kristẹni kọ̀ọ̀kan sí pàtàkì gidi. (Róòmù, orí 14) Àpéjọpọ̀ Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọ, tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Gíga Jù Lọ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbà mú lò ní 1989, lóye ẹ̀tọ́ tí ọmọ kan ní fún “òmìnira láti ronú, láti lo ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ àti láti ṣe ìsìn tí ó wù ú” pẹ̀lú ẹ̀tọ́ “láti sọ èrò ọkàn rẹ̀ jáde fàlàlà, kí a sì gba èrò ọkàn yẹn yẹ̀ wò dáradára nínú ọ̀ràn tàbí ìgbésẹ̀ èyíkéyìí tí ó kan ọmọ náà.”

Kò sí ọmọ méjì tí wọ́n bára mu délẹ̀délẹ̀. Nítorí náà, o lè fi pẹ̀lú ọgbọ́n retí àwọn ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ nínú ìpinnu tí àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí tàbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn bá ṣe nígbà tí ó bá kan àwọn ìgbòkègbodò àti iṣẹ́ àyànfúnni kan ní ilé ẹ̀kọ́. A ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ìwọ pẹ̀lú fọwọ́ sí ìlànà òmìnira ẹ̀rí ọkàn.

a Ní ti àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, Steven Carr Reuben, Ph.D., sọ nínú ìwé rẹ̀, Raising Jewish Children in a Contemporary World, pé: “Ó máa ń tojú sú àwọn ọmọ nígbà tí àwọn òbí wọ́n bá ń gbé ìgbésí ayé alábòsí, rúdurùdu, oníkọ̀kọ̀, tí wọ́n sì ń yẹra láti sọ̀rọ̀ nípa ìsìn. Nígbà tí àwọn òbí bá jẹ́ olóòótọ́, aláìlábòsí, tí wọ́n sì ṣe kedere nípa ìgbàgbọ́, ìlànà, àti àwòṣe ayẹyẹ wọn, àwọn ọmọ máa ń dàgbà pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀ àti ìtóótun ara ẹni nínú àyíká ìsìn tí ó ṣe pàtàkì gidi fún ìdàgbàsókè iyì ara ẹni wọn látòkè délẹ̀ àti mímọ ipò wọn nínú ayé.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́