ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 11/8 ojú ìwé 26-27
  • Fífi Ìbáwí Ọlọ́run Tọ́ Àwọn Ọmọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífi Ìbáwí Ọlọ́run Tọ́ Àwọn Ọmọ
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Ìbáwí Túmọ̀ sí Gan-an
  • Ẹ Máa Fọ̀ràn Ro Ara Yín Wò
  • Ó yẹ Kó O Wáyè Láti Máa Gbọ́ Tàwọn Ọmọ Rẹ
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ẹ Máa Wáyè Gbọ́ Tàwọn Ọmọ
    Jí!—2005
  • Mímọrírì Ìdí Tá A Fi Ń Báni Wí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ẹ̀yin Òbí—ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Tìfẹ́tìfẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 11/8 ojú ìwé 26-27

Ojú Ìwòye Bíbélì

Fífi Ìbáwí Ọlọ́run Tọ́ Àwọn Ọmọ

“Bó O Ṣe Lè Ṣòfin Táwọn Ọmọ Ẹ Ò Ní Máa Rú”

“Ìlànà Ìwà Híhù Márùn-ún Tó Yẹ Kó O Kọ́ Ọmọ Ẹ Nígbà Tó Bá Pé Ọmọ Ọdún Márùn-ún”

“Ìdánúṣe Márùn-ún Tó Yẹ Kí Gbogbo Ọmọ Ní”

“Àmì Márùn-ún Tó Ń Fi Hàn Pé O Ti Gbọ̀jẹ̀gẹ́ Jù”

“Àṣírí Bó O Ṣe Lè Bọ́mọ Wí Níṣẹ̀ẹ́jú Kan Péré”

BÓ BÁ jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ ló rọrùn láti bọ́mọ wí ni, àwọn èèyàn ò ní sú já àwọn àpilẹ̀kọ tí ìwé ìròyìn ń gbé jáde bí irú àwọn tá a tó sókè yìí. Wọ́n ì bá sì ti kógbá àìmọye ìwé táwọn èèyàn ń kọ lórí ọmọ títọ́ sílé. Àmọ́ ṣá, kò tíì sígbà kan rí tí iṣẹ́ ọmọ títọ́ rọrùn o. Kódà, láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ni Bíbélì ti sọ pé “arìndìn ọmọ jẹ́ ìbìnújẹ́ fún baba rẹ̀ àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i.”—Òwe 17:25.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìmọ̀ràn ń wá lọ́tùn-ún lósì lórí ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́, ọ̀pọ̀ òbí ò mọ bí wọ́n ṣe lè bá àwọn ọmọ wọn wí. Ọ̀nà wo ni Bíbélì lè gbà ran irú àwọn bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́?

Ohun Tí Ìbáwí Túmọ̀ sí Gan-an

Bíbélì ṣàlàyé kedere lórí ipa tó yẹ káwọn òbí kó bó bá dọ̀ràn bíbá ọmọ wí. Bí àpẹẹrẹ, Éfésù 6:4 sọ pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” Ìwé Mímọ́ yìí dìídì sọ pé bàbá ni kó jẹ́ aṣáájú nínú ọ̀ràn àbójútó àwọn ọmọ. Ìyá náà ò sì gbọ́dọ̀ dá ọkọ rẹ̀ dá a.

Lórí ọ̀rọ̀ yìí, ìwé atúmọ̀ èdè kan tó ń jẹ́ The Interpreter’s Dictionary of the Bible, sọ pé: “Bí Bíbélì ṣe sọ̀rọ̀ nípa ìbáwí sábà máa ń tan mọ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́, ìtọ́ni àti ìmọ̀, ó tún ń jẹ mọ́ ìtọ́nisọ́nà, kíkọ́ni láti ṣàtúnṣe àti ìfìyàjẹni. Ibi tí ìjíròrò bá sì ti dá lórí ọmọ títọ́ la ti máa ń lò ó.” Nítorí náà, ìbáwí ò wulẹ̀ mọ sórí pé à ń fọ̀rọ̀ ẹnu báni wí; ó tún ní í ṣe pẹ̀lú gbogbo ìdálẹ́kọ̀ọ́ táwọn ọmọ nílò kí wọ́n lè di ọmọ tó yàn, tó yanjú. Ṣùgbọ́n kí làwọn òbí lè ṣe tí wọn ò fi ní máa mú àwọn ọmọ bínú?

Ẹ Máa Fọ̀ràn Ro Ara Yín Wò

Kí ló máa ń bí ọmọdé nínú? Ronú nípa àpẹẹrẹ yìí ná. Ẹnì kan wà tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́. Inú máa ń tètè bí i, kò sì ní sùúrù kọ́bọ̀. Kò sí ohun tó o ṣe tó tẹ́ ẹ lọ́rùn rí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun tó o sọ tàbí ohun tó o ṣe tí ò ní rí àléébù tó wà níbẹ̀. Iṣẹ́ ẹ kì í tẹ́ ẹ lọ́rùn, kò sì kà ọ́ kún nǹkan kan. Ṣé ìyẹn ò ní bí ọ nínú, kó sì bà ọ́ lọ́kàn jẹ́?

Ohun kan náà ló lè ṣẹlẹ̀ sí ọmọ kan báwọn òbí bá ń rojọ́ lé e lórí nígbà gbogbo tàbí tí wọ́n ń fi ìbínú bá a wí. Òótọ́ ni pé àwọn ọmọdé nílò ìbáwí lemọ́lemọ́, Bíbélì sì fún àwọn òbí láṣẹ pé kí wọ́n fún wọn ní irú ìbáwí bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣá o, mímú ọmọ kan bínú nípa fífi ọwọ́ líle koko, tí kò fi ìfẹ́ hàn mú un lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá a, ó sì lè ṣèpalára fún un nípa tẹ̀mí àti nípa tara pàápàá.

Ó yẹ Kó O Wáyè Láti Máa Gbọ́ Tàwọn Ọmọ Rẹ

Ó pọn dandan pé káwọn òbí wá àkókò láti máa bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀. Àṣẹ tí Ọlọrun pa fáwọn bàbá nínú Diutarónómì 6:7 ni pé: “Kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” Gbàrà tí wọ́n bá ti bí ọmọ kan lọmọ náà á ti fẹ́ káwọn òbí òun máa fún òun ní àbójútó tó péye. Fífi ohùn tútù bá àwọn ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ lè mú kó o mọ èrò wọn. Èyí á wá mú kó túbọ̀ rọrùn fún ọ láti jẹ́ kí àwọn ìlànà inú Bíbélì tó o fi ń kọ́ wọn wọ̀ wọ́n lọ́kàn kó sì sún wọn láti “bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí [wọ́n] sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (Oníwàásù 12:13) Ara ìbáwí Ọlọ́run náà ni gbogbo ẹ̀.

Bá a bá fi ọmọ títọ́ wé ilé kíkọ́, a jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn ohun èlò ìkọ́lé ni ìbáwí jẹ́. Báwọn òbí bá lò ó bó ṣe yẹ, wọ́n lè mú káwọn ọmọ ní àwọn ànímọ́ tó dáa, èyí tá á mú wọn gbára dì láti dojú kọ àwọn àdánwò ìgbésí ayé. Òwe 23:24, 25 ṣàlàyé ohun tí yóò jẹ́ àbájáde èyí nígbà tó sọ pé: “Baba olódodo yóò kún fún ìdùnnú láìsí àní-àní; ẹni tí ó bí ọlọ́gbọ́n yóò yọ̀ pẹ̀lú nínú rẹ̀. Baba rẹ àti ìyá rẹ yóò yọ̀, obìnrin tí ó bí ọ yóò sì kún fún ìdùnnú.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

“ÌLÀNÀ ÈRÒ ORÍ JÈHÓFÀ”

Éfésù 6:4 mẹ́nu kan “ìlànà èrò orí Jèhófà.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tó pilẹ̀ túmọ̀ sí “ìlànà èrò orí” làwọn Bíbélì kan túmọ̀ sí “fífi nǹkan sọ́kàn,” “ìkìlọ̀,” àti “ìgbàníyànjú.” Gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn gbọ́dọ̀ ṣe kọjá wíwulẹ̀ máa ka Bíbélì tàbí kí wọ́n máa wáyè bákan ṣáá láti ka àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn òbí gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn lóye ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run túmọ̀ sí, bí ìgbọràn ti ṣe pàtàkì tó, bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn àti bó ṣe ń dáàbò bò wọ́n.

Báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe gbogbo èyí láṣeyọrí? Judy, ìyá kan tó bí ọmọ mẹ́ta, rí i pé òun gbọ́dọ̀ ṣe kọjá rírán àwọn ọmọ òun létí àwọn ìlànà Ọlọ́run lemọ́lemọ́. “Mo wá rí i pé kì í wù wọ́n kí n máa sọ ohun kan náà lásọtúnsọ àti lọ́nà kan náà tí mo máa ń gbà sọ ọ́. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa onírúurú ọ̀nà ti mo lè gbà máa kọ́ wọn. Ọgbọ́n kan tí mo dá ni pé mo máa ń wo àwọn àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn Jí! tó jíròrò àwọn kókó náà lọ́nà tó yàtọ̀. Bí mo ṣe wá mọ ọ̀nà tí mo lè gbà máa rán àwọn ọmọ létí ohun tó yẹ kí wọ́n mọ̀ láìmú inú bí wọn nìyẹn o.”

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Angelo, tí ìdílé ẹ̀ forí rọ́ ìṣòro, sọ bó ṣe kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin láti máa ṣe àṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sọ pé: “A máa ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì papọ̀, màá wá ṣàlàyé bí àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan nínú ohun tá a kà náà ṣe bá ipò àwọn ọmọbìnrin mi mu. Mo wá kíyè sí i pé báwọn náà bá ń dá Bíbélì kà, wọ́n máa ń ronú jinlẹ̀, wọ́n sì máa ń ṣàṣàrò lórí ohun tó túmọ̀ sí fún wọn.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́