Ṣé Ọjọ́ Iwájú á Dára Jù Báyìí Lọ?
Kókó táwọn èèyàn kì í fẹ́ jánu lórí ẹ̀ lọ̀rọ̀ ọjọ́ iwájú jẹ́. Àbí, nínú wa, ta ni ò fẹ́ mọ ohun tóun á ṣe lóṣù tó ń bọ̀, lọ́dún tó ń bọ̀, tàbí lọ́dún mẹ́wàá sígbà tá a wà yìí? Tá a bá wá wo òréré, báwo layé á ṣe rí ní bí ọdún mẹ́wàá, ogún ọdún tàbí bí ọgbọ̀n ọdún sígbà tá a wà yìí?
ṢÓ O gbà pé ọjọ́ iwájú ń bọ̀ wá dára? Ẹgbàágbèje èèyàn ló gbà bẹ́ẹ̀, a sì lè pín àwọn wọ̀nyí sí ìsọ̀rí méjì. Àwọn tàkọ́kọ́ làwọn tó sọ pé àwọn rí ìdí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ láti gbà pé nǹkan ṣì máa dára, àwọn kejì sì làwọn tó ṣáà gba kámú pé ọ̀la máa dára torí, lérò tiwọn, èèyàn ò gbọ́dọ̀ máa ronú pé nǹkan ò ní dáa.
Àmọ́, àwọn kan wà tí wọn ò gbà rárá pé ọjọ́ iwájú lè dáa. Lára wọn làwọn wòlíì asàsọtẹ́lẹ̀ ìparun tó ṣáà máa ń wù pé kí wọ́n máa kéde pé ṣe ni Àgbáálá ayé yìí máa pa run. Lójú tiwọn, tá a bá máa rẹ́ni tó máa bọ́ nínú ìparun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, kò lè tó nǹkan.
Kí ni ìwọ rò pó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? Ṣó o gbà pé ègbé àti ìparun ló ń bọ̀ ni àbí àlàáfíà àti ààbò? Tó o bá ń retí àlàáfíà àti ààbò, kí ló fún ọ nírú ìrètí yẹn—ṣó o kàn rò pó yẹ kó rí bẹ́ẹ̀ ni àbí ẹ̀rí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ wà?
Àwọn tó ń tẹ ìwé ìròyìn Jí! ò dà bí àwọn tó ń sàsọtẹ́lẹ̀ ìparun, wọn ò gbà pé gbogbo àgbáyé máa pa rẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ wà nínú Bíbélì pé ọjọ́ iwájú ṣì ń bọ̀ wá dùn bí oyin.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]
Fọ́tò tí U.S. Department of Energy yà