ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/06 ojú ìwé 6-9
  • Ibo Lọ̀rọ̀ Ayé Yìí Ń Lọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibo Lọ̀rọ̀ Ayé Yìí Ń Lọ?
  • Jí!—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwé Atọ́nisọ́nà Kan Tó Lè Tọ́ Wa Sọ́nà
  • Ibi Tọ́rọ̀ Ti Wọ́ Wá
  • Bá A Ṣe Lè Mọ Ibi Tọ́rọ̀ Ayé Dé
  • Ibi Táyé Forí Lé
  • Gẹ́gẹ́ Bí Ọ̀tá Ìkẹyìn, Ikú Di Ohun Asán
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ki Ni Ẹ̀ṣẹ̀ Ìpilẹ̀ṣẹ̀?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Jésù Ń gbani Là—Lọ́nà Wo?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Èé Ṣe Tí A Fi Ń Kú?
    Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
Àwọn Míì
Jí!—2006
g 1/06 ojú ìwé 6-9

Ibo Lọ̀rọ̀ Ayé Yìí Ń Lọ?

KÍ LÓ máa ṣẹlẹ̀ ní ọdún mẹ́wàá, ogún ọdún, tàbí ọgbọ̀n ọdún sígbà tá a wà yìí? Lákòókò táwọn apániláyà ń pitú oríṣiríṣi yìí, ńṣe lẹ̀rù ń bani nípa bọ́jọ́ iwájú ṣe máa rí. Ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ń gbòòrò sí i. Ayé to lu jára ti mú kí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè má lè dá dúró. Ṣé a wá lè tìtorí èyí sọ pé àwọn aṣáájú ayé á fìmọ̀ ṣọ̀kan kí wọ́n sì mú kí ọjọ́ iwájú ayé yìí mìrìngìndìn? Àwọn èèyàn kan sọ pé bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ń retí pé tó bá fi máa di ọdún 2015, àwọn aṣáájú ayé á ti fòpin sí ìṣẹ́ àti ebi tó ń pa aráyé, wọ́n á sì ti fòpin sí àrùn éèdì tó ń tàn kálẹ̀. Wọ́n fọkàn sí i pé iye àwọn tí kì í rí omi tó mọ́ gaara mu tí wọn ò sì ní ibi tó dáa láti máa kó ẹ̀gbin dà sí á ti di ìlàjì.—Wo àpótí náà “Kí Ni Wọ́n Rò, Kí Ló Ṣẹlẹ̀?”

Àmọ́ ṣá, ohun táráyé máa ń fojú sọ́nà fún nípa ọjọ́ iwájú sábà máa ń jẹ́ ohun tí kò ṣeé ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ní ẹ̀wádún mélòó kan sẹ́yìn, ògbógi kan sọ pé tó bá fi máa di ọdún 1984, àwọn àgbẹ̀ á ti máa fi katakata tó lè ṣíṣẹ́ lábẹ́ omi dáko sábẹ́ òkun; ẹlòmíì sọ pé tó bá fi máa di ọdún 1995, wọ́n á ti fi kọ̀ǹpútà ṣe àwọn nǹkan kan sínú àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, èyí tí kò ní jẹ́ kí wọ́n lè máa kọ lura; òmíràn sì tún sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá fi máa di ọdún 2000, àwọn èèyàn tá a máa gbé nínú òfuurufú tí wọ́n á sì máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀ á ti tó bí ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀. Ní báyìí, àfàìmọ̀ làwọn tó ti sọ irú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ò ti ní máa kábàámọ̀ pé àwọn ì bá mọ̀ káwọn ti gbẹ́nu àwọn dání. Akọ̀ròyìn kan kọ̀wé pé: “Ká ṣáà ní sùúrù ni, nígbà tó bá yá, àwọn tó dà bíi pé ọgbọ́n yí nínú po láyé yìí ò ní pẹ́ di òmùgọ̀ lójú aráyé.”

Ìwé Atọ́nisọ́nà Kan Tó Lè Tọ́ Wa Sọ́nà

Kò sí nǹkan táwọn èèyàn ò lè méfò lé lórí nípa ọjọ́ iwájú, àmọ́ nígbà míì ohun tí wọ́n ń sọ nípa ọjọ́ iwájú kàn dà bí àsọdùn ni kì í ṣe àrògún. Ibo la ti lè rí ohun tó ṣeé gbà gbọ́ nípa ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú?

Wo àpèjúwe kan. Ká ní o wà nínú ọkọ̀ bọ́ọ̀sì kan tó ò ń rìnrìn-àjò lọ sílẹ̀ àjèjì. Nítorí pé o ò mọ ibi tó ò ń lọ dáadáa, o bẹ̀rẹ̀ sí kọminú. Lo wá ń bi ara rẹ pé ‘Ibo ni mo wà yìí ná? Ṣé ojú ọ̀nà ibi tí mò ń lọ ni bọ́ọ̀sì yìí kọrí sí? Báwo ni ibi tí mo wà yìí ṣe jìnnà tó síbi tí mò ń lọ?’ Àmọ́ tó o bá wo ìwé kan tí wọ́n yàwòrán ọ̀nà náà sí tí àwòrán inú ẹ̀ sì dáa, tó o sì ń wo àwọn àmì ojú ọ̀nà látojú wíńdò, wàá mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ò ń bi ara rẹ yẹn.

Ọ̀ràn náà jọ tí ọ̀pọ̀ àwọn tí ominú ń kọ bí wọ́n ṣe ń ronú nípa ọjọ́ iwájú. Àwọn náà ń béèrè pé, ‘Ibo là ń lọ báyìí o?’ ‘Ṣé ọ̀nà tá à ń tọ̀ yìí á mú àlàáfíà wá jákèjádò ayé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìgbà wo la máa débi tá à ń lọ?’ Bíbélì dà bí ìwé atọ́nisọ́nà kan tó lè fún wa ní ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yẹn. Tá a bá fara balẹ̀ kà á dáadáa, tá a sì ń kíyè sí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé bí ẹni ń gba ojú wíńdò bọ́ọ̀sì wo ìta, a ó rí ohun púpọ̀ kọ́ nípa ibi tá a wà àti ibi tá a dorí kọ. Àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ ká mọ báwọn ìṣòro wa ṣe bẹ̀rẹ̀.

Ibi Tọ́rọ̀ Ti Wọ́ Wá

Bíbélì sọ fún wa pé pípé ni Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ó sì fi wọ́n sínú ọgbà Párádísè tó lẹ́wà jọjọ. Ṣe ló fẹ́ kí Ádámù àti Éfà máa wà láàyè títí láé, kì í wulẹ̀ ṣe fún àádọ́rin tàbí ọgọ́rin ọdún. Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” Ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn ni pé kí Ádámù, Éfà àtàwọn àtọmọdọ́mọ wọn mú Párádísè tí wọ́n ń gbé náà gbòòrò dé orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:8, 15, 22.

Ádámù àti Éfà ò tẹ̀ lé àṣẹ Ọlọ́run. Ohun tó fà á tí Párádísè ilé wọn fi bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́ nìyẹn. Yàtọ̀ síyẹn, àtìgbà náà ni ìlera àti ọpọlọ wọn ti bẹ̀rẹ̀ sí jó rẹ̀yìn. Bójúmọ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe ń mọ́ ni ọjọ́ ikú Ádámù àti Éfà ń sún mọ́. Kí ló fà á? Ìdí ni pé bí wọ́n ṣe kẹ̀yìn sí Ẹlẹ́dàá wọn, wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì rèé “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.”—Róòmù 6:23.

Ádámù àti Éfà pàpà kú, àmọ́ kí wọ́n tó kú, wọn ti bí àwọn ọmọkùnrin àtàwọn ọmọbìnrin bíi mélòó kan. Ǹjẹ́ àwọn ọmọ tí wọ́n bí yìí á lè mú ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀ ṣẹ? Wọn ò lè mú un ṣẹ torí pé wọ́n ti jogún àìpé látọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn. Kódà, gbogbo àwọn ọmọ Ádámù àti Éfà látìrandíran ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Èyí ò sì yọ ẹnikẹ́ni nínú wa sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Róòmù 3:23; 5:12.

Bá A Ṣe Lè Mọ Ibi Tọ́rọ̀ Ayé Dé

Orí ìwà ọ̀tẹ̀ tí Ádámù àti Éfà hù ni ìrìn-àjò kíkorò táráyé ti ń rìn látìgbà pípẹ́ yìí ti bẹ̀rẹ̀, orí ìrìn ọ̀hún sì laráyé wà títí dòní. Gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan lára àwọn tó kọ Bíbélì ṣe sọ, a ti “tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo.” (Róòmù 8:20) Àbí ẹ ò rí i pé bí gbogbo kìràkìtà ẹ̀dá ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn! Ẹ tiẹ̀ wo àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, àwọn ìjìmì nínú ìmọ̀ ìṣègùn, àtàwọn ògúnnágbòǹgbò nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ, lọ́kùnrin lóbìnrin tó wà láàárín àwọn ọmọ Ádámù. Pẹ̀lú gbogbo ẹ̀ náà, kò sí ọ̀kan nínú wọn tó lè mú àlàáfíà jákèjádò ayé wá, kó sì mú káráyé ní ìlera tó dáa gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí fún èèyàn.

Olúkúlùkù wa ló mọ ibi tóun ti ń jìyà ìwà ọ̀tẹ̀ tí Ádámù àti Éfà hù. Àbí, ta ló lè sọ pé ohun kan tó dun òun wọra ò tíì ṣẹlẹ̀ sóun rí, ìyẹn bí ìrẹ́jẹ, ìbẹ̀rù àwọn ọ̀daràn, àìsàn tó le koko, tàbí ìbànújẹ́ tó máa ń tẹ̀ lé ikú èèyàn ẹni? Ṣe ló dà bíi pé tí nǹkan bá ń lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀ fẹ́nì kan, kì í pẹ́ tí òkò ìbànújẹ́ á fi ba onítọ̀hún. Kódà níbi tọ́rọ̀ dé dúró yìí, ṣe ni ìgbésí ayé wa rí bí Jóòbù, ẹni àtijọ́ náà, ṣe ṣàlàyé rẹ̀ nígbà tó sọ nípa èèyàn pé: “Ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ṣìbáṣìbo.”—Jóòbù 14:1.

Tá a bá wo ibi tá a ti ń bọ̀ àti inú ipò tó ń bani nínú jẹ́ tá a bá ara wa báyìí, ó lè dà bíi pé ọjọ́ iwájú ò ní dáa. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run ò ní jẹ́ kí irú ipò yìí máa bá a lọ títí láé. Ohun tó ní lọ́kàn fún ẹ̀dá èèyàn níbẹ̀rẹ̀ á ṣẹ dandan. (Aísáyà 55:10, 11) Kí ló lè mú kó dá wa lójú pé èyí ò ní pẹ́ ṣẹlẹ̀?

Sànmánì lílekoko kan tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí. (2 Tímótì 3:1) Ọjọ́ ìkẹyìn àgbáálá ayé yìí tàbí àwọn ohun alààyè tó wà nínú ẹ̀ kọ́ ni èyí ń tọ́ka sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń sọ nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan,” èyí tó já sí pé gbogbo nǹkan tó ń bà wá nínú jẹ́ ló máa dópin. (Mátíù 24:3) Bíbélì sọ àwọn nǹkan táá máa ṣẹlẹ̀ àti irú ohun táwọn èèyàn á yà lákòókò òpin yìí. Kíyè sí díẹ̀ lára ìwọ̀nyí nínú àpótí tó wà lójú ìwé 8, kó o wá bojú wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yíká ayé nínú ìrìn-àjò ìgbé ayé àwọn ọmọ ẹ̀dá. Bíbélì tó jẹ́ ìwé amọ̀nà nínú ìrìn àjò ìgbé ayé àwa ẹ̀dá ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ibi tá a wà báyìí, pé a tí sún mọ́ òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Àmọ́, kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?

Ibi Táyé Forí Lé

Kété lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà hùwà ọ̀tẹ̀ yẹn, Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ láti gbé Ìjọba kan “tí a kì yóò run láé” kalẹ̀. (Dáníẹ́lì 2:44) A ti kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn láti máa gbàdúrà fún Ìjọba yẹn nínú àdúrà tí wọ́n ń pè ní Àdúrà Olúwa, Ìjọba náà á sì mú ìbùkún tí kò ṣeé fẹnu sọ wá fáwa èèyàn.—Mátíù 6:9, 10.

Ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe ohun kan tó wà lọ́kàn ẹni. Ìjọba gidi ni, èyí táá máa ṣàkóso látọ̀run tí ìṣàkóso rẹ̀ á sì múlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Kàn tiẹ̀ ronú lórí ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òun á tipasẹ̀ Ìjọba náà ṣe fáwa èèyàn. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run á kọ́kọ́ “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 11:18) Kí láá wá ṣe fáwọn tó fi hàn pé tiẹ̀ làwọn ń ṣe? Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà lákọọ́lẹ̀ sọ pé yóò “nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìṣípayá 21:4) Ẹ̀dá èèyàn wo ló tó ṣe irú ohun tó jọ bẹ́ẹ̀? Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè mú irú nǹkan tó ní lọ́kàn láti ṣe fáwa èèyàn láti ìbẹ̀rẹ̀ ṣẹ.

Báwo lo ṣe lè gbádùn àwọn ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú wá? Jòhánù 17:3 sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fáwọn èèyàn ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ kárí ayé, ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ló ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti gba ìmọ̀ náà. Nǹkan bí igba ó lé ọgbọ̀n ilẹ̀ ni wọ́n ti ń wàásù, wọ́n sì ti tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn ní oríṣi èdè tó lé ní irínwó. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, kàn sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ tàbí kó o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

“Ẹ wá, nísinsìnyí, ẹ̀yin tí ẹ ń sọ pé: ‘Lónìí tàbí lọ́la a ó rin ìrìn àjò lọ sí ìlú ńlá yìí, a ó sì lo ọdún kan níbẹ̀, a ó sì kó wọnú iṣẹ́ òwò, a ó sì jèrè,’ nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ kò mọ ohun tí ìwàláàyè yín yóò jẹ́ lọ́la.”—Jákọ́bù 4:13, 14

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

Bíbélì fi hàn wá pé láti ọ̀dọ̀ ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ la ti wá. Bó ṣe fi ibi tá a ti ṣẹ̀ wá hàn wá nìyẹn. Ó tún jẹ́ ká mọ ibi táyé ń lọ. Àmọ́ ká tó lè lóye ohun tí Bíbélì ń sọ fún wa ó yẹ ká fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ohun tó wà nínú ẹ̀, bá a ṣe máa fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìwé tó ń ṣàlàyé ojú ọ̀nà

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]

Ohun tá a lè pè ní “ẹ̀ṣẹ̀” ni ìwà kan tí kò bójú mu téèyàn hù tàbí èrò ohun kan tó ń wá séèyàn lọ́kàn láti mú kó hùwà ìbàjẹ́. Inú ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n bí wa sí, ó sì ń nípa lórí àwọn nǹkan tá à ń ṣe. “Kò sí olódodo kankan ní ilẹ̀ ayé tí ń ṣe rere tí kì í dẹ́ṣẹ̀.”—Oníwàásù 7:20

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

Tó o bá fi ẹ̀rọ tó ń ṣẹ̀dà ìwé ṣe ẹ̀dà ìwé kan tó ní ohun dúdú kan lójú, ohun dúdú yẹn á hàn lójú gbogbo ẹ̀dà ìwé yẹn tó o bá ṣe. Gẹ́gẹ́ bí àtọmọdọ́mọ Ádámù, tá a lè fi wé ẹ̀dà ìwé tá a ṣe, a ti ní àbàwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ lára. Ìyẹn ni àmì tó wà lára Ádàmù tá a lè fi wé bébà tá a ṣẹ̀dà rẹ̀

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

Bíbélì sọ pé: “Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Èyí ló jẹ́ ká mọ ìdí tí gbogbo ohun táráyé ń ṣe láti mú àlàáfíà wá sáyé fi ń já sí pàbó. Ẹlẹ́dàá ò dá èèyàn láti “darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀” láìfi ti Ọlọ́run ṣe

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

Onísáàmù náà sọ fún Ọlọ́run pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.” (Sáàmù 119:105) Gẹ́gẹ́ bíi fìtílà, Bíbélì ràn wá lọ́wọ́ láti máa gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó tọ́ nígbà tá a bá fẹ́ ṣèpinnu. Gẹ́gẹ́ bí ‘ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà wa,’ ó ń tànmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà tó wà níwájú wa, èyí sì ń jẹ́ ká lè fòye mọ ohun tó ń dúró de ìràn èèyàn lọ́jọ́ iwájú

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

KÍ NI WỌ́N RÒ, KÍ LÓ ṢẸLẸ̀?

Ní oṣù September ọdún 2000, àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè gbé àwọn àfojúsùn kan kalẹ̀ tí wọ́n rò pé ọwọ́ àwọn á tẹ̀ tó bá fi máa di ọdún 2015. Lára wọn ni ìwọ̀nyí:

◼ Wọ́n fẹ́ kí iye àwọn tí kì í rí gbà ju dọ́là kan owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà lójúmọ́ àtàwọn tébi ń hàn léèmọ̀ dín kù sí ìlàjì.

◼ Wọ́n fẹ́ rí i dájú pé gbogbo àwọn ọmọdé lọ síléèwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀.

◼ Wọ́n fẹ́ mú káwọn obìnrin láǹfààní láti kàwé débi tó bá wù wọ́n bíi tàwọn ọkùnrin.

◼ Wọ́n fẹ́ rí i pé àwọn ọmọdé tí wọn ò tíì pé ọmọ ọdún márùn-ún tó ń kú ti dín kù sí ìdámẹ́ta.

◼ Wọ́n fẹ́ dín iye àwọn aláboyún tó ń kú nítorí ọmọ bíbí kù sí nǹkan bí ọ̀kan nínú mẹ́rin.

◼ Wọ́n fẹ́ fòpin sí ìtànkálẹ̀ kòkòrò àrùn éèdì, àrùn éèdì fúnra ẹ̀, àtàwọn àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí míì, bí ibà.

◼ Wọ́n fẹ́ dín iye àwọn tí kò rí omi tó mọ́ gaara mu kù sí ìlàjì iye tí wọ́n jẹ́.

Ṣé ọwọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n gbé síwájú ara wọn yìí? Nígbà tí àgbáríjọ àwọn òṣìṣẹ́ ìlera jákèjádò ayé wo ibi tí wọ́n bọ́ràn dé lọ́dún 2004, ìgbìmọ̀ náà sọ pé ohun táráyé tíì rí gbé ṣe kò tíì tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ohun tó yẹ kí wọ́n ti gbé ṣe, ó sì fi hàn pé ó yẹ káwọn èèyàn máa ṣọ́ ẹnu wọn nípa irú ìlérí tí wọ́n á máa ṣe. Nínú ìwé tí wọ́n fi ròyìn nípa bí ayé ṣe rí, èyí tí wọ́n pè ní State of the World 2005, ọ̀rọ̀ àkọ́sọ ibẹ̀ ni pé: “Apá ibi púpọ̀ ni ipò òṣì ò ti jẹ́ ká ṣàṣeyọrí tó bó ṣe yẹ. Àwọn àrùn bí éèdì ń gbilẹ̀ sí i ni, ṣe ló sì dà bí ẹ̀tù tó lè gbiná nígbàkigbà, èyí tó lè dá ìṣòro àìlera sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Láti bí ọdún márùn-ún báyìí, ó ti tó nǹkan bí ogún mílíọ̀nù ọmọdé táwọn àrùn tó ṣeé dènà tí wọ́n ń kó nínú omi ti pa, ẹgbàágbèje mílíọ̀nù èèyàn ló sì ń ráre nínú òṣì àti ẹ̀gbin torí pé kò sí omi tó mọ́ gaara àti ọ̀nà tí wọ́n lè gbà máa kẹ́gbin dà nù.”

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

DÍẸ̀ LÁRA ÀPẸẸRẸ “ÀWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN”

Ogun tá ò rírú ẹ̀ rí.—Mátíù 24:7; Ìṣípayá 6:4.

Ìyàn.—Mátíù 24:7; Ìṣípayá 6:5, 6, 8.

Àjàkálẹ̀ àrùn.—Lúùkù 21:11; Ìṣípayá 6:8.

Ìwà àìlófin tó ń pọ̀ sí i.—Mátíù 24:12.

Rírun ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 11:18.

Àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ńláńlá.—Lúùkù 21:11.

Àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.—2 Tímótì 3:1.

Ìfẹ́ àníjù fún owó.—2 Tímótì 3:2.

Ṣíṣàìgbọràn sí òbí.—2 Tímótì 3:2.

Àìní ìfẹ́ni àdánidá.—2 Tímótì 3:3.

Níní ìfẹ́ fàájì dípò Ọlọ́run.—2 Tímótì 3:4.

Àìní ìkóra-ẹni-níjàánu.—2 Tímótì 3:3.

Àìní ìfẹ́ ohun rere.—2 Tímótì 3:3.

Káwọn èèyàn má fiyè sí ewu tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lé wọn lórí.—Mátíù 24:39.

Àwọn olùyọṣùtì ò gbà pé àmì ọjọ́ ìkẹyìn là ń rí.—2 Pétérù 3:3, 4.

Wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé.—Mátíù 24:14.

[Àwọn Credit Line]

© Àwòrán tí G.M.B. Akash/Panos Pictures yà

© Àwòrán tí Paul Lowe/Panos Pictures yà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

A mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́