Èé Ṣe Tí A Fi Ń Kú?
“Kẹ́kẹ́ pa ní orí gbogbo àwọn òké wàyí, orí àwọn igi dákẹ́ wẹ́lo; àwọn ẹyẹ sùn fọnfọn lórí igi: dúró ná; láìpẹ́ bí o ṣe máa sinmi jẹ́ẹ́ nìyẹn.”—JOHANN WOLFGANG VON GOETHE, ÒǸKỌ̀WÉ ÀRÒKỌ, ỌMỌ ILẸ̀ GERMANY.
1, 2. (a) Ìfẹ́-ọkàn wo ni a dá mọ́ ènìyàn? (b) Irú ìgbésí ayé wo ni ẹ̀dá ènìyàn méjì àkọ́kọ́ gbádùn?
ỌLỌ́RUN dá ènìyàn tòun ti ìyánhànhàn láti wà láàyè títí láé. Ní ti gidi, Bíbélì sọ pé ó fi “òye ti wíwà títí láéláé sínú ọkàn-àyà wọn.” (Oníwàásù 3:11, Beck) Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ṣe ju fífún ènìyàn ní ìfẹ́-ọkàn láti wà láàyè títí láé lọ. Ó tún fún wọn ní àǹfààní láti lè ṣe bẹ́ẹ̀.
2 A dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, ní pípé, láìsí àbùkù èrò inú tàbí ti ara rárá. (Diutarónómì 32:4) Rò ó wò ná—ìrora àti ẹ̀dùn àìdabọ̀ kò sí, kò sí ìpayà tàbí àníyàn kankan! Síwájú sí i, Ọlọ́run fi wọ́n sínú Párádísè, ibùgbé ẹlẹ́wà kan. Ọlọ́run pète pé kí ènìyàn máa gbé títí láé àti pé ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ kí ọmọ rẹ̀ pípé kún inú ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:31; 2:15) Kí ló wá dé tí a fi ń kú?
Àìgbọràn Fa Ikú
3. Orí kí ni ìyè ayérayé fún Ádámù àti Éfà sinmi lé?
3 Ọlọ́run pàṣẹ fún Ádámù pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Nítorí náà, ìyè ayérayé Ádámù àti Éfà sinmi lórí ipò kan; ó sinmi lórí ìgbọràn wọn sí Ọlọ́run.
4. Nígbà tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, èé ṣe tí wọ́n fi pàdánù ìrètí wíwàláàyè títí láé nínú Párádísè?
4 Àmọ́, ó dunni pé Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí òfin Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n di ẹlẹ́ṣẹ̀, nítorí pé “ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ìwà àìlófin.” (1 Jòhánù 3:4) Nítorí náà, Ádámù àti Éfà kò lè retí wíwà láàyè títí láé mọ́. Èé ṣe? Nítorí pé “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” (Róòmù 6:23) Nípa báyìí, nígbà tí Ọlọ́run ń ṣèdájọ́ Ádámù àti Éfà, ó wí pé: “Ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.” Bí a ṣe lé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ kúrò nínú ilé wọn Párádísè nìyẹn. Lọ́jọ́ tí Ádámù àti Éfà ti dẹ́ṣẹ̀ ni kíkú wọn ti bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́.—Jẹ́nẹ́sísì 3:19, 23, 24.
“Ikú . . . Tàn Dé Ọ̀dọ̀ Gbogbo Ènìyàn”
5. Báwo ni ikú ṣe tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ìran ènìyàn?
5 Ẹ̀ṣẹ̀ wá lẹ̀ típẹ́típẹ́ mọ́ inú apilẹ̀ àbùdá Ádámù àti Éfà wàyí. Látàrí ìyẹn, wọn kò lè bí ọmọ pípé mọ́, gan-an bí ohun tí a fi ń mọ nǹkan, tí ó lábùkù, kò ti lè mú ohun pípé jáde. (Jóòbù 14:4) Ní tòótọ́, gbogbo ìgbà tí a bá bímọ ni ẹ̀rí ń hàn pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ti pàdánù ìlera pípé àti ìyè ayérayé tiwọn àti ti àtọmọdọ́mọ wọn. Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Róòmù 5:12; fi wé Sáàmù 51:5.
6. Èé ṣe tí a fi ń kú?
6 Lónìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò mọ ohun tó ń fà á gan-an tí ènìyàn fi ń kú. Àmọ́, Bíbélì ṣàlàyé pé a ń kú tìtorí pé a bí wa ní ẹlẹ́ṣẹ̀, ipò kan tí a jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́. Ṣùgbọ́n kí ní ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tí a bá kú?