ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w00 11/15 ojú ìwé 24-27
  • A Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Tọkọtaya Ẹ̀dá Ènìyàn Àkọ́kọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Tọkọtaya Ẹ̀dá Ènìyàn Àkọ́kọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Akọ àti Abo Ni Ó Dá Wọn”
  • Ní “Àwòrán Ọlọ́run”
  • Éfà Ṣẹ̀
  • Ádámù Fetí sí Ohùn Aya Rẹ̀
  • Àwọn Àbájáde Ẹ̀ṣẹ̀
  • Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n fún Wa
  • Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀ Ìpilẹ̀ṣẹ̀?
    Jí!—2006
  • Báwo Ni Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Nínú Ọgbà Édẹ́nì?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Ọlọ́run Dá Ọkùnrin àti Obìnrin Àkọ́kọ́
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Gẹ́gẹ́ Bí Ọ̀tá Ìkẹyìn, Ikú Di Ohun Asán
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
w00 11/15 ojú ìwé 24-27

A Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Tọkọtaya Ẹ̀dá Ènìyàn Àkọ́kọ́

ỌLỌ́RUN ṣàyẹ̀wò pílánẹ́ẹ̀tì ilẹ̀ ayé. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní palẹ̀ rẹ̀ mọ́ kí ènìyàn lè gbé inú rẹ̀. Ó rí i pé gbogbo ohun tí òun dá ló dára. Àní lẹ́yìn tó parí iṣẹ́ náà tán, ohun tó sọ ni pé ó “dára gan-an” ni. (Jẹ́nẹ́sísì 1:12, 18, 21, 25, 31) Àmọ́ kó tó di pé Ọlọ́run dé ìparí èrò tó pé yìí, ó sọ nípa ohun kan tí “kò dára.” A mọ̀ dájú pé Ọlọ́run kò dá nǹkankan tó kù díẹ̀ káàtó. Ó kàn jẹ́ pé kò tíì parí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀ nígbà yẹn ni. Jèhófà sọ pé: “kò dára kí ọkùnrin náà máa wà nìṣó ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:18.

Ète Jèhófà ni pé kí ẹ̀dá ènìyàn gbádùn ìyè ayérayé nínú ìlera, ayọ̀, àti ọ̀pọ̀ yanturu ohun tí wọ́n nílò nínú Párádísè ilẹ̀ ayé. Ádámù ni bàbá gbogbo ìran ènìyàn. Aya rẹ̀, Éfà, wá di “ìyá gbogbo ẹni tí ń bẹ láàyè.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:20) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe layé kún báyìí fún ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù àtọmọdọ́mọ wọn, síbẹ̀ aláìpé ni gbogbo wọn pátá.

Ìtàn Ádámù àti Éfà jẹ́ èyí táa mọ̀ bí ẹní mowó. Ṣùgbọ́n àǹfààní wo ni ìtàn náà ṣe fún wa? Kí la lè rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ náà?

“Akọ àti Abo Ni Ó Dá Wọn”

Nígbà tí Ádámù ń sọ àwọn ẹranko lórúkọ, ó rí i pé wọ́n ní ẹ̀yà kejì àmọ́ òun ò ní. Nítorí náà, inú ẹ̀ dùn gan-an nígbà tó fojú ba ẹ̀dá rírẹwà náà tí Jèhófà mú jáde látinú egungun ìhà rẹ̀. Ádámù mọ̀ pé apá kan ara òun ni ẹ̀dá aláìlẹ́gbẹ́ yìí jẹ́, ló bá polongo pé: “Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, èyí ni egungun nínú àwọn egungun mi àti ẹran ara nínú ẹran ara mi. Obìnrin ni a óò máa pe èyí, nítorí pé láti ara ọkùnrin ni a ti mú èyí wá.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:18-23.

Ọkùnrin yìí nílò “olùrànlọ́wọ́ kan.” Ó sì ti wá rí ọ̀kan tó ṣe wẹ́kú fún un báyìí. Éfà jẹ́ ẹni pípé, tó ṣe rẹ́gí fún Ádámù gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀—láti bójú tó ilé ọlọ́gbà wọn àti àwọn ẹranko, láti mú ọmọ jáde, àti láti pèsè òye tí ń fúnni ní ìṣírí àti ìtìlẹ́yìn tó máa ń wá látọ̀dọ̀ alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 1:26-30.

Gbogbo ohun tí tọkọtaya náà lè nífẹ̀ẹ́ sí ni Jèhófà pèsè fún wọn. Nípa mímú Éfà tọ ọkọ rẹ̀ wá, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ fàṣẹ sí wíwà pa pọ̀ wọn, Ọlọ́run dá ètò ìgbéyàwó àti ti ìdílé sílẹ̀, nípa èyí tí àwùjọ yóò fi lè wà létòlétò. Àkọsílẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì sọ pé: ‘Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.’ Nígbà tí Jèhófà súre fún tọkọtaya àkọ́kọ́, tó sọ fún wọn pé kí wọ́n máa so èso, ó ṣe kedere pé ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí ni pé gbogbo ọmọ la gbọ́dọ̀ bí sínú ìdílé kan tó bìkítà, tó sì ní bàbá kan àti ìyá kan láti bójú tó o.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:24.

Ní “Àwòrán Ọlọ́run”

Ádámù jẹ́ ọmọkùnrin Ọlọ́run tí a dá ní pípé, ní ‘àwòrán àti ìrí’ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n níwọ̀n ìgbà tí “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí,” ìjọra yẹn kò lè jẹ́ èyí tó ṣeé fojú rí. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26; Jòhánù 4:24) Ìrí yẹn ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ànímọ́ tó mú kí ènìyàn ga ju ẹranko lọ. Bó ti rí nìyẹn, àtìbẹ̀rẹ̀ ni a ti gbin àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, ọgbọ́n, agbára, àti ìdájọ́ òdodo sínú ènìyàn. A fi òmìnira láti ṣe ohun tí ó wù ú àti làákàyè fún nǹkan tẹ̀mí jíǹkí rẹ̀. Àbùdá tó ní fún ìwà rere, tàbí ẹ̀rí-ọkàn tó ní, ràn-án lọ́wọ́ láti lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó dára àti èyí tó burú. Ènìyàn ní làákàyè, èyí tó ń mú un láti ronú nípa ìdí tí ẹ̀dá ènìyàn fi wà, ó tún ń mú kó lè kó ìmọ̀ púpọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jọ, kó sì ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ẹni yẹn. Níwọ̀n bó ti ní àwọn nǹkan yìí, Ádámù ní gbogbo ohun tó nílò láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùdarí àwọn iṣẹ́ tí Ọlọ́run ṣe sáyé.

Éfà Ṣẹ̀

Kò sí àní-àní pé kíákíá ni Ádámù ti sọ fún Éfà nípa èèwọ̀ kan tí Ọlọ́run kà fún wọn, pé: Wọ́n lè jẹ nínú gbogbo igi ọgbà tó jẹ́ ilé wọn náà àyàfi ìkan—ìyẹn ni igi ìmọ̀ rere àti búburú. Wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀. Bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, lọ́jọ́ yẹn gan-an ni wọ́n máa kú.—Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17.

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni ọ̀ràn kan dìde lórí èso tí a kà léèwọ̀ náà. Ejò kan tí ẹni ẹ̀mí tí kò ṣeé fojú rí kan gba ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ lọ bá Éfà. Bí ẹni pé kò mọ nǹkankan, ejò náà béèrè pé: “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ní tòótọ́, pé Ọlọ́run sọ pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?” Ni Éfà bá dá a lóhùn pé àwọn lè jẹ nínú gbogbo èso igi ọgbà náà àyàfi ọ̀kan làwọn ò gbọ́dọ̀ jẹ. Ṣùgbọ́n ńṣe lejò náà tako Ọlọ́run, ó sọ fún obìnrin náà pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú. Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” Obìnrin náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ojú mìíràn wo igi táa kà léèwọ̀ náà. “Igi náà dára fún oúnjẹ àti pé ohun kan tí ojú ń yánhànhàn fún ni.” Éfà di ẹni tí a tàn jẹ pátápátá, ló bá rú òfin Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; 1 Tímótì 2:14.

Ṣé Éfà kò ríbi yẹ ẹ̀ṣẹ̀ yẹn sí ni? Kò sóhun tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀! Ìwọ fira ẹ sípò rẹ̀ ná. Ńṣe ni nǹkan tí ejò náà sọ yí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run àti Ádámù ti sọ fún-un tẹ́lẹ̀ padà. Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ, ká ní àjèjì kan fi ẹ̀sùn àìṣòdodo kan ẹnì kàn tóo fẹ́ràn tóo sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹ̀? Kò yẹ kí Éfà hùwà bó ṣe hùwà yẹn rárá, ńṣe ló yẹ kó pa ejò yẹn tì, kó jájú mọ́ ọn, kó má tiẹ̀ tẹ́tí sí ohun tó fẹ́ sọ rárá. Ó ṣe tán, tá ni ejò tó fi máa wá gbé ìbéèrè dìde sí òdodo Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ tí ọkọ rẹ̀ sọ? Ká ní Éfà bọ̀wọ̀ fún ìlànà ipò orí ni, ó yẹ kó kọ́kọ́ béèrè ìmọ̀ràn kó tó di pé ó ṣe ìpinnu èyíkéyìí. Nǹkan tó yẹ kí àwa náà ṣe nìyẹn o, bí ẹnì kan bá gbé ìsọfúnni kan wá bá wa tó tako àwọn ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún wa. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ Adẹniwò yẹn ni Éfà gbà gbọ́, ó wù ú láti di onídàájọ́ ara rẹ̀ kó máa dá pinnu ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́. Bó ṣe ń ronú nípa ọ̀rọ̀ yẹn, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń wù ú. Àṣìṣe ńlá gbáà mà ló ṣe o nípa gbígba èròkérò láàyè, dípò kó yáa mú un kúrò lọ́kàn kíá tàbí kó jíròrò ọ̀ràn ọ̀hún pẹ̀lú olórí ìdílé rẹ̀!—1 Kọ́ríńtì 11:3; Jákọ́bù 1:14, 15.

Ádámù Fetí sí Ohùn Aya Rẹ̀

Láìpẹ́, Éfà mú kí Ádámù dara pọ̀ mọ́ òun nínú ẹ̀ṣẹ̀. Báwo la ṣe fẹ́ ṣàlàyé ọwọ́ dẹngbẹrẹ tí Ádámù fi mú ọ̀rọ̀ yìí? (Jẹ́nẹ́sísì 3:6, 17) Ádámù dojú kọ ìpinnu nípa ti ta ló yẹ kí òun ṣe. Ṣé yóò ṣègbọràn sí Ẹlẹ́dàá rẹ̀ tó fún un ní ohun gbogbo, títí kan olólùfẹ́ rẹ̀, Éfà? Ṣé Ádámù á wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run lórí ohun tó yẹ kó ṣe lórí ọ̀ràn yìí? Àbí ṣe ni ọkùnrin náà máa kúkú dara pọ̀ mọ́ aya rẹ̀? Ádámù mọ̀ pé ẹ̀tàn pátápátá ló wà nídìí ohun tí obìnrin náà ń retí àtirí nípa jíjẹ èso tí a kà léèwọ̀ náà. A mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “A kò tan Ádámù jẹ, ṣùgbọ́n obìnrin náà ni a tàn jẹ pátápátá, ó sì wá wà nínú ìrélànàkọjá.” (1 Tímótì 2:14) Nítorí náà, Ádámù mọ̀ọ́mọ̀ yàn láti ṣàìka Jèhófà sí ni. Dájúdájú, ìbẹ̀rù Ádámù pé kóun máà wá dẹni táa yà kúrò lọ́dọ̀ ìyàwó òun ju ìgbàgbọ́ rẹ̀ pé Ọlọ́run lè ṣe nǹkankan láti yanjú ìṣòro náà lọ.

Ohun tí Ádámù ṣe yẹn mú ẹ̀mí lọ́wọ́. Kò tún yàtọ̀ sí pé ńṣe ló pa gbogbo ọmọ tí Jèhófà fi tàánútàánú fún un láǹfààní láti jẹ́ bàbá fún, nígbà tó kúkú jẹ́ pé inú ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ sí ikú ni a bí gbogbo wọn sí. (Róòmù 5:12) Ohun tó ń tìdí àìgbọràn nítorí ìmọtara-ẹni-nìkan jáde kì í màá ṣe kékeré o!

Àwọn Àbájáde Ẹ̀ṣẹ̀

Ìtìjú ni ohun àkọ́kọ́ tó máa ń jẹ́ àbájáde ẹ̀ṣẹ̀. Dípò tí àwọn tọkọtaya náà ì bá fi tayọ̀tayọ̀ sáré lọ bá Jèhófà láti bá a sọ̀rọ̀, ṣe ni wọ́n lọ fara pamọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:8) Wọ́n ti ba àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Nígbà tí ìbéèrè dìde lórí ohun tí wọ́n ṣe, wọn ò tiẹ̀ ṣe ìṣe pé ó dùn wọ́n, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn méjèèjì ló mọ̀ pé àwọn ti rú òfin Ọlọ́run. Nípa jíjẹ èso tí a kà léèwọ̀ náà, wọ́n kẹ̀yìn wọn sí Ọlọ́run, tí í ṣe olóore wọn.

Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, Ọlọ́run jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìrora ńlá ní yóò máa bá bíbímọ rìn. Éfà yóò máa ṣàfẹ́rí ọkọ rẹ̀, ọkọ rẹ̀ yóò sì máa jẹ gàba lé e lórí. Bí gbogbo ìgbìyànjú obìnrin náà láti gba òmìnira ṣe já sí òdìkejì fún un nìyẹn. Pẹ̀lú ìrora ni Ádámù ní tiẹ̀ á fi máa jẹ ohun tó bá tinú ilẹ̀ wá. Dípò tí ì bá fi máa jẹun ní Édẹ́nì láìsí pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣe wàhálà, ó ní láti làkàkà kó tó lè rí ohun tí yóò fi máa wà láàyè, títí tí yóò fi padà sínú erùpẹ̀ níbi táa ti mú un jáde wá.—Jẹ́nẹ́sísì 3:16-19.

Bí Ádámù àti Éfà ṣe dẹni táa lé jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì níkẹyìn nìyẹn. Jèhófà wá sọ pé: “Kíyè sí i, ọkùnrin náà ti dà bí ọ̀kan lára wa ní mímọ rere àti búburú, wàyí o, kí ó má bàa na ọwọ́ rẹ̀ jáde, kí ó sì tún mú èso ní ti tòótọ́, láti ara igi ìyè, kí ó sì jẹ kí ó sì wà láàyè fún àkókò tí ó lọ kánrin . . . ” Gordon Wenham, tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ sọ pé: “Òfurugbádá ni ìparí gbólóhùn yẹn fi wá sí. Jẹ́ kí n lé e jáde kúrò nínú ọgbà náà, ni ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìparí èrò Ọlọ́run níhìn-ín.” Bí ó ti sábà máa ń rí, òǹkọ̀wé Bíbélì kan máa ń ri í pé òun sọ ohun tó jẹ́ èrò Ọlọ́run parí. Ṣùgbọ́n níhìn-ín, Wenham tẹ̀ síwájú láti sọ pé, “fífi tí a kò fi ìparí ọ̀rọ̀ náà síbẹ̀ fi bí Ọlọ́run ṣe gbégbèésẹ̀ ní kíákíá hàn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má tíì parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a fi lé wọn jáde nínú ọgbà náà.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:22, 23) Pẹ̀lú ìyẹn, ó dà bí ẹni pé gbogbo ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ láàárín Jèhófà àti tọkọtaya àkọ́kọ́ dópin.

Ádámù àti Éfà kò kú nípa tara láàárín ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún yẹn. Ṣùgbọ́n wọ́n kú nípa tẹ̀mí. Kò sí àtúnṣe sí àjèjì tí wọ́n wá sọ ara wọn dà sí Orísun ìwàláàyè wọn, ara wọn bẹ̀rẹ̀ sí daṣẹ́ sílẹ̀ títí tí wọ́n fi kú. Fojú inú wo bí ìbànújẹ́ wọn ṣe tó nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ mọ ohun tó ń jẹ́ ikú—ìyẹn nígbà tí Kéènì, àkọ́bí wọn, lu Ébẹ́lì ọmọkùnrin wọn kejì pa!—Jẹ́nẹ́sísì 4:1-16.

Lẹ́yìn tíyẹn ṣẹlẹ̀, a ò tún fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ nǹkankan mọ́ nípa tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ náà. Wọ́n bí Sẹ́ẹ̀tì, ọmọkùnrin wọn kẹta nígbà tí Ádámù dẹni àádóje ọdún. Lẹ́yìn ẹgbẹ̀rin ọdún sí àkókò yìí ni Ádámù tó kú, nígbà tó jẹ́ ẹni ọdún àádọ́rin dín lẹ́gbẹ̀rún [930], lẹ́yìn tó di bàbá fún “àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.”—Jẹ́nẹ́sísì 4:25; 5:3-5.

Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n fún Wa

Yàtọ̀ fún pé àkọsílẹ̀ nípa tọkọtaya àkọ́kọ́ jẹ́ ká mọ ohun tó fà á tí ipò tí àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn wà fi ń burú sí i lónìí, ó tún kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan. Ó jẹ́ ká mọ̀ pè ìwà arìndìn lásánlàsàn ló jẹ́ láti máa dọ́gbọ́n wá òmìnira kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní tòótọ́ máa ń lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọn kì í gbà pé ìmọ̀ tí wọ́n rò pé àwọn ní ti tó fún wọn. Jèhófà ló ń pinnu ohun tó dára àti èyí tó burú, ìgbà táa bá sì ṣe ohun tó tọ́ la tó lè sọ pé a ń ṣègbọràn sí i. Híhùwà àìtọ́ túmọ̀ sí rírú àwọn òfin rẹ̀ àti ṣíṣàìka àwọn ìlànà rẹ̀ sí.

Gbogbo ohun tí ìran ènìyàn lè nífẹ̀ẹ́ sí ni Ọlọ́run nawọ́ rẹ̀ sí wọn, kò sì dáwọ́ bó ṣe ń nawọ́ wọn sí wa dúró—ìyẹn ni, ìyè àìnípẹ̀kun, òmìnira, ìtẹ́lọ́rùn, ayọ̀, ìlera, àlàáfíà, aásìkí, àti ṣíṣàwárí àwọn nǹkan tuntun. Àmọ́, bí a óò bá gbádùn gbogbo àwọn nǹkan yìí, ó ń béèrè pé ká gbà pé Jèhófà, tí í ṣe Baba wa ọ̀run ni ẹni tí a gbára lé pátápátá.—Oníwàásù 3:10-13; Aísáyà 55:6-13.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ìtàn Ádámù àti Éfà—Ṣé Àròsọ Ládán Ni?

Ìgbàgbọ́ náà pé Párádísè kan ti wà rí, àmọ́ pé kò sí mọ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀, jẹ́ èyí tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ènìyàn ayé ọjọ́un tó ń gbé ní Bábílónì, Ásíríà, Íjíbítì, àti àwọn ibòmíràn. Ohun tí àwọn ìròyìn náà sábà máa ń ní nínú ni pé, igi ìyè kan wà tí èso rẹ̀ lè fún àwọn tó bá jẹ nínú ẹ̀ ní ìyè ayérayé. Ó túmọ̀ sí pé ìràn èèyàn ṣì ń rántí pé nǹkan ìbànújẹ́ kan ṣẹlẹ̀ ní Édẹ́nì.

Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ pé ìtàn àròsọ lásán ni àkọsílẹ̀ nípa Ádámù àti Éfà jẹ́. Síbẹ̀síbẹ̀, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló gbà pé ìran ènìyàn lápapọ̀ jẹ́ ẹyọ ìdílé kan ṣoṣo tó ní orírun kan náà. Ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ni kò lè sẹ́ òtítọ́ náà pé a tàtaré àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ baba ńlá náà sí ìran ènìyàn. Tó bá jẹ́ pé ìgbàgbọ́ wọn ni pé ó ju orísun kan lọ tí èèyàn ti wá, ìyẹn á mú kó di dandan fún wọn láti sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn baba ńlá ló dá ẹ̀ṣẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà. Ńṣe lèyí ẹ̀wẹ̀ á sì tún wá sọ ọ́ di dandan fún wọn láti sẹ́ rírà tí Kristi, tó jẹ́ “Ádámù ìkẹyìn” ra aráyé padà. Ṣùgbọ́n Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kò kóra wọn sínú irú wàhálà yẹn. Wọ́n mọ̀ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ti gidi ni àkọsílẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì jẹ́.—1 Kọ́ríńtì 15:22, 45; Jẹ́nẹ́sísì 1:27; 2:24; Mátíù 19:4, 5; Róòmù 5:12-19.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́