Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Nìdí Tí Mo Fi Ń Dọ́gbẹ́ Síra Mi Lára?
“Mo fi nǹkan ya ara mi lọ́rùn ọwọ́, ibẹ̀ sì jìn débi pé ṣe ni wọ́n rán an. Ohun tí mo sọ fún dókítà ni pé, àfọ́kù gílóòbù ló gé mi níbẹ̀, òótọ́ nìyẹn ná, ó kàn jẹ́ pé mi ò jẹ́ kó mọ̀ pé ṣe ni mo mọ̀ọ́mọ̀ fi ya ara mi lọ́wọ́.”—Sasha, ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún.
“Àwọn òbí mi máa ń rí ọgbẹ́ tí mo dá síra mi lára, àfèyí tí ò bá fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, tó kàn rí bí ìgbà tí nǹkan ha èèyàn lára. . . . Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí wọ́n bá rí èyí tí wọn ò tíì rí tẹ́lẹ̀, ṣe ni mo máa ń wá irọ́ kan pa. . . . Nítorí mi ò fẹ́ kí wọ́n mọ̀.”— Ariel, ọmọ ọdún mẹ́tàlá.
“Ọmọ ọdún mọ́kànlá ni mi tí mo ti máa ń dọ́gbẹ́ síra mi lára. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo mọ ojú pàtàkì tí Ọlọ́run fi ń wo ara èèyàn, síbẹ̀ mi ò yé ṣe é.”—Jennifer, ọmọ ogún ọdún.
ÓṢEÉ ṣe kó o mọ ẹnì kan tó ń ṣe bíi Sasha, Ariel, tàbí Jennifer.a Ó lè jẹ́ pé ilé ẹ̀kọ́ kan lẹ jọ wà. Ó lè jẹ́ àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n rẹ. Ó tiẹ̀ lè jẹ́ ìwọ alára. Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan, wọ́n fojú bù ú pé ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí púpọ̀ wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ máa ń dìídì dọ́gbẹ́ síra wọn lára lónírúurú ọ̀nà bíi fífi nǹkan gé ara wọn, fífi iná jó ara wọn, pípa ara wọn lára tàbí fífi nǹkan ha awọ ara wọn.b
Ṣé pé èèyàn lè mọ̀ọ́mọ̀ dọ́gbẹ́ síra ẹ̀ lára? Bó bá jẹ́ pé láyé ìgbà kan ni, wọ́n lè ní àrà oge àṣejù tó lòde ni tàbí kí wọ́n pè é ní àmì àwọn ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ kan. Àmọ́ ṣáá, lẹ́nu ọdún mélòó kan báyìí, ọ̀rọ̀ nípa dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára, ti wá gbilẹ̀. Ẹ̀rí fi hàn pé ṣe ni iye àwọn tó ń mọ̀ọ́mọ̀ dọ́gbẹ́ síra wọn lára ṣáà ń pọ̀ sí i. Ọ̀gbẹ́ni Michael Hollander tó jẹ́ olùdarí ibi ìgbàtọ́jú kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Gbogbo ẹni tó mọ̀ nípa ìtọ́jú ara ló ń sọ pé ìṣòro ọ̀hún ò yé pọ̀ sí i.”
Kì í kúkú ṣe pé ọgbẹ́ tí wọ́n ń dá síra wọn lára náà ń pa wọ́n ṣùgbọ́n ó léwu. Bí àpẹẹrẹ, ìwọ gbọ́ ohun tí ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Beth wí. Ó ní: “Bíléèdì lèmi máa fi ń dọ́gbẹ́ síra mi lára. Ẹ̀ẹ̀mejì ni mo ti dèrò ilé ìwòsàn. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí wọ́n ní láti tọ́jú mi ní iyàrá ìtọ́jú pàjáwìrì nítorí bí ọgbẹ́ ọ̀hún ṣe pọ̀ tó.” Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn tó máa ń mọ̀ọ́mọ̀ dọ́gbẹ́ síra wọn lára, ìwà náà mọ́ Beth lára títí tó fi dàgbà. Ó ṣàlàyé pé: “Àtìgbà tí mo ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni mo ti ń ṣe é, ní báyìí ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni mí, mi ò sì tíì jáwọ́.”
Ǹjẹ́ ìwọ fúnra ẹ tàbí ẹnì tó o mọ̀ máa ń dọ́gbẹ́ síra ẹ̀ lára? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, má bọkàn jẹ́. Ojútùú wà. Nínú ìtẹ̀jáde Jí! tó ń bọ̀, a óò jíròrò bá a ṣe lè ran àwọn tó ń dọ́gbẹ́ síra wọn lára lọ́wọ́.c Àmọ́ ní báyìí, ó máa dáa ká jíròrò nípa irú àwọn tí nǹkan yẹn máa ń ṣe àtohun tó ń mú kó máa ṣe wọ́n.
Onírúurú Nǹkan Ló Ń Sún Wọn Sí I
Kò rọrùn láti sọ pé irú kan náà ni gbogbo àwọn tó ń dọ́gbẹ́ síra wọn lára. Àwọn kan wá látinú ìdílé tó níṣòro; àwọn míì wá látinú ìdílé tí wọ́n ti láyọ̀. Olódo làwọn kan lára wọn, nígbà tí ọ̀pọ̀ lára wọn sì mọ̀wé. Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í fi bẹ́ẹ̀ sí àmì pé àwọn tó ń dọ́gbẹ́ síra wọn lára yìí níṣòro, torí ìṣòro kì í fìgbà gbogbo hàn lójú ẹni tó bá ní i. Bíbélì sọ pé: “Nínú ẹ̀rín pàápàá, ọkàn-àyà lè wà nínú ìrora.”—Òwe 14:13.
Bákan náà, ọgbẹ́ tí wọ́n máa ń dá síra wọn lára máa ń pọ̀ jura lọ. Ìwádìí kan jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀ẹ̀kan péré làwọn kan lára wọn máa ń dọ́gbẹ́ síra wọn lára jálẹ̀ ọdún nígbà táwọn míì sì ń dọ́gbẹ́ síra wọn lára lẹ́ẹ̀mejì lóòjọ́. A tiẹ̀ kíyè sí i pé àwọn ọkùnrin tó ń dọ́gbẹ́ síra wọn lára pọ̀ ju iye táwọn èèyàn rò lọ. Síbẹ̀, àárín àwọn obìnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà ni ìṣòro ọ̀hún pọ̀ sí jù.
Kódà pẹ̀lú onírúurú àwọn nǹkan tó ń sún wọn sí i yìí, ìṣesí àwọn kan lára wọn jọra. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan lórí àwọn ọ̀dọ́ sọ pé: “Àwọn aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà tí wọ́n ń dọ́gbẹ́ síra wọn lára kì í sábà lè dá nǹkan ṣe, kì í rọrùn fún irú wọn láti sọ ohun tó ń dùn wọ́n lọ́kàn fún ẹnikẹ́ni, ó máa ń ṣe wọ́n bíi pé àwọn nìkan làwọn dá wà tàbí pé kò sẹ́ni tó dá sí àwọn, ẹ̀rù máa ń bà wọ́n, wọn kì í sì í níyì lójú ara wọn.”
Ó ṣeé ṣe káwọn kan sọ pé ọ̀dọ́ èyíkéyìí tó ń bẹ̀rù àtidàgbà, tó sì ń sá fún ewu tó wà níbẹ̀ ni àlàyé tá a ṣe yìí bá mu. Àmọ́ lójú ẹni tó ń dọ́gbẹ́ síra ẹ̀ lára, ìṣòro ọ̀hún kì í ṣe kékeré. Àìlèsọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún ẹnì kan tó fọkàn tán lè mú kí àwọn wàhálà ilé ẹ̀kọ́, tibi iṣẹ́, tàbí gbọ́nmi-sí-omi-ò-to abẹ́ ọ̀ọ̀dẹ̀ dà bí èyí tó ń ga á lára. Lójú rẹ̀, gbogbo ìrètí ti pin kò sì sí ẹni tó lè fọ̀ràn lọ̀. Ó wá rí ìṣòro ọ̀hún bí èyí tí ò ṣeé fara dà. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó ronú kan nǹkan kan, ìyẹn ni pé tóun bá dọ́gbẹ́ síra òun lára àwọn ẹ̀dùn ọkàn yẹn á wábi gbà ná, àti pé òun á ṣì lè máa bá ìgbésí ayé òun lọ, kódà kó tiẹ̀ jẹ́ fúngbà díẹ̀.
Kí nìdí tẹ́ni tó ń dọ́gbẹ́ síra ẹ̀ lára ṣe yàn láti máa ṣe ara ẹ̀ léṣe bẹ́ẹ̀ torí kí ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ lè wábi gbà? Ẹ jẹ́ ká wò ó lọ́nà yìí, ro ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tó o bá ń dúró dé dókítà kan tó fẹ́ fún ọ ní abẹ́rẹ́. Nígbà tí dókítà bá fẹ́ ki abẹ́rẹ́ bọ̀ ọ́ lára, ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí pé o máa ń já ara ẹ ní èékánná tàbí pé o máa ń fi èékánná di ara rẹ mú torí kó o má bàa mọ ìgbà tí abẹ́rẹ́ máa wọlé? Ohun táwọn tó ń dọ́gbẹ́ síra wọn lára ń ṣe jọ ìyẹn, ó kàn jẹ́ pé tiwọn máa ń le jù bẹ́ẹ̀ lọ ni. Ẹni tó ń dọ́gbẹ́ síra ẹ̀ lára gbà pé ìyẹn ló máa jẹ́ kóun lè gbọ́kàn kúrò nínú ẹ̀dùn ọkàn tó ń dààmú òun. Ẹ̀dùn ọkàn náà máa ń ga débi pé ó sàn kéèyàn máa jẹ̀rora ojú ọgbẹ́. Bóyá ìyẹn ló jẹ́ kẹ́nì kan tó ń dọ́gbẹ́ síra ẹ̀ lára sọ pé dídọ́gbẹ́ síra òun lára ni oògùn sí ẹ̀rù tó máa ń ba òun.
“Ohun Tó Lè Bá Èèyàn Kojú Ẹ̀dùn Ọkàn”
Lójú àwọn tí ò tíì gbọ́ nípa dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára tẹ́lẹ̀, wọ́n lè máa wò ó bí ìgbà téèyàn fẹ́ fọwọ́ ara ẹ̀ para ẹ̀. Ṣùgbọ́n kì í sábà rí bẹ́ẹ̀. Olùdarí àgbà fún ilé iṣẹ́ kan tó ń tẹ ìwé ìròyìn tó wà fáwọn èwe, Sabrina Solin Weill, sọ pé: “Ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé ṣe làwọn èèyàn yẹn kàn ń wá bí ìrora wọn á ṣe wábi gbà kì í ṣe bí wọ́n á ṣe gbẹ̀mí ara wọn.” Ìdí nìyẹn tí ìwé kan ṣe ṣàpèjúwe dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára bí “ohun ‘agbẹ́mìíró’ dípò ohun tó ń gbẹ̀mí ẹni.” Ó tún pe àṣà yẹn ní “ohun téèyàn fi í kojú ẹ̀dùn ọkàn.” Irú ẹ̀dùn ọkàn wo?
Ìwádìí ti fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń dọ́gbẹ́ síra wọn lára ló ti fojú winá àwọn ìṣòro kan rí, bíi lílo ọmọdé nílòkulò tàbí àìsí ìtọ́jú tó péye fún ọmọdé. Gbọ́nmi-si-omi-ò-tó nínú ìdílé ló fa tàwọn kan tàbí kó jẹ́ pé mímu tí òbí wọn ń mutí ní àmupara. Àwọn míì sì wà tó jẹ́ pé àìsàn ọpọlọ ló sún wọn sí i.
Àwọn ìṣòro míì wà tó tún lè fà á. Bí àpẹẹrẹ, kéèyàn máà fẹ́ kù síbì kankan ló sún Sara sí i. Lẹ́yìn tó ṣe ọ̀pọ̀ àṣìṣe ńlá táwọn alàgbà nínú ìjọ Kristẹni sì ń ràn án lọ́wọ́, ṣe ni ìbànújẹ́ dorí ẹ̀ kodò torí pé ó máa ṣe nǹkan tí ò dáa. Ó ní: “Mo rí i pé mo gbọ́dọ̀ bá ara mi wí. Lójú tèmi, dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára ò jẹ́ bàbàrà ju pé mo fi ń bá ara mi wí lọ. Lára ‘ìbáwí tí mo sì máa ń fún ara mi’ ni fífa irun orí mi tu, dídọ́gbẹ́ síra mi ní ọwọ́ àti ní apá, lílu ara mi àti dídá egbò tó pọ̀ síra mi lára lọ́nà tó le gan-an. Mo tún máa ń fi àwọn ìyà kan jẹ ara mi, irú bíi kí n ki ọwọ́ sínú omi gbígbóná, kí n jókòó síta gbangba nínú otútù tó mú gan-an láìwọ aṣọ tó lè gba otútù, tàbí kí n má fi ẹnu kan oúnjẹ èyíkéyìí látàárọ̀ ṣúlẹ̀.”
Lójú Sara, dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára jẹ́ ọ̀nà tó lè fi bó ṣe kórìíra ipò tó wà yẹn tó hàn. Ó sọ pé: “Àwọn ìgbà kan wà tí mo mọ̀ pé Jèhófà ti dárí àwọn àṣìṣe kan jì mí, ṣùgbọ́n mi ò fẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀. Mo fẹ́ kí n jìyà yẹn torí mo kórìíra ara mi gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo mọ̀ pé Jèhófà ò ní ibì ìdálóró kankan bíi hẹ́ẹ̀lì táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń sọ, mo fẹ́ ko ṣe irú ibẹ̀ yẹn kan fún èmi nìkan.”
“Àkókò Tó Nira Láti Bá Lò”
Àwọn kan lè máa ṣe kàyéfì pé kí ló dé tó jẹ́ pé lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni àṣà yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sójú táyé. Síbẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ pé “àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” la wà yìí. (2 Tímótì 3:1) Ìdí nìyẹn tí ò fi yà wọ́n lẹ́nu láti rí àwọn èèyàn, kódà àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń hùwà tó ṣòro ṣàlàyé.
Bíbélì tiẹ̀ sọ pé “ìnilára pàápàá lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bí ayírí.” (Oníwàásù 7:7) Ìṣòro tó ń bá ìgbà ìbàlágà rìn tó ohun tó lè mú kéèyàn máa hùwà tó léwu bíi dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ àdánwò ìgbésí ayé tó ń dojú kọ àwọn kan lára àwọn tó ń bàlágà. Ọ̀dọ́ kan tó rí ara rẹ̀ bí ẹni tí wọ́n ti pa tì tó sì gbà pé òun ò lẹ́ni tóun lè fọ̀rọ̀ lọ̀ lè gbà pé dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára láá mú kóun bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀dùn ọkàn. Ṣùgbọ́n, ká tiẹ̀ ní dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára máa mú ìtura wá, fúngbà díẹ̀ ni. Bó pẹ́ bóyá, ìṣòro náà ṣì ń padà bọ̀, bí ọ̀rọ̀ dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára sì ṣe rí náà nìyẹn.
A lè sọ pé ó wu àwọn tó ń dọ́gbẹ́ síra wọn lára kí wọ́n jáwọ́, ó kàn jẹ́ pé kì í rọrùn ni. Báwo làwọn kan ṣe ṣe é tí wọ́n fi jáwọ́ nínú dídọ́gbẹ́ síra wọn lára? A óò jíròrò èyí nínú àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” tó ní àkọlé náà, “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣíwọ́ Dídọ́gbẹ́ Síra Mi Lára?” nínú ìwé ìròyìn Jí! ti April–June 2006, tó ń bọ̀ lọ́nà.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà nínú àpilẹ̀kọ́ yìí.
b Dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára yàtọ̀ sí dídá ara lu tàbí fífín ara. Lọ́pọ̀ ìgbà ló sábà máa ń jẹ́ àṣà tó lòde kì í ṣe àṣà fífi abẹ la ara láìnídìí. Wo Jí! August 8, 2000, ojú ìwé 22 sí 23.
c Léfítíkù 19:28 sọ pé: “Ẹ kò sì gbọ́dọ̀ kọ ara yín lábẹ nítorí ọkàn tí ó ti di olóògbé.” Àṣà àwọn kèfèrí yìí, tí wọ́n fi máa ń bọ àwọn ọlọ́run wọn tí wọn gbà gbọ́ pé ó máa ń bójú tó àwọn òkú, yàtọ̀ pátápátá sí àṣà dídọ́gbẹ́ síra ẹni lára tá à ń jíròrò yìí o.
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
◼ Kí ló mú káwọn ọ̀dọ́ kan máa dọ́gbẹ́ síra wọn lára?
◼ Lẹ́yìn tó o bá ti ka àpilẹ̀kọ yìí, ǹjẹ́ o lè ronú àwọn ọ̀nà míì tó dáa tó o lè gbà kojú ẹ̀dùn ọkàn tó o ni?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]
“Nínú ẹ̀rín pàápàá, ọkàn-àyà lè wà nínú ìrora.”—Òwe 14:13
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]
“Ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé, ṣe làwọn èèyàn yìí kàn ń wá bí ìrora wọn á ṣe wábi gbà kì í ṣe bí wọ́n á ṣe gbẹ̀mí ara wọn”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]
“Àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” la wà yìí.—2 Tímótì 3:1