Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
January-March 2006
Kí ni Ká Máa Retí Lọ́jọ́ Iwájú?
Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti ronú wò rí nípa bí ayé yìí ṣe máa rí ní ọdún mẹ́wàá, ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ sígbà tá a wà yìí? Bíbélì fún wa ní ẹ̀rí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tá a fi lè gbà gbọ́ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dùn bí oyin.
5 Ṣé Ọjọ́ Iwájú á Dára Jù Báyìí Lọ?
14 Àjàkálẹ̀ Àrùn Tó Tíì Burú Jù Lọ Látọjọ́ Táláyé Ti Dáyé
17 Àrùn Gágá Ibi Tó Yé Wa Dé Báyìí
20 Àjàkálẹ̀ Àrùn Ibi Tó Máa Já Sí
30 Ibi Róbótó Tó Jẹ́ Kàyéfì ní Áfíríkà
Kí Nìdí Tí Mo Fi Ń Dọ́gbẹ́ Síra Mi Lára? 10
Àwọn kan wà tí wọ́n máa ń ṣe ara wọn léṣe nípa fífi nǹkan tó mú ya ara wọn, kà nípa wọn àti ohun tó ń sún wọn ṣe é.
Ẹ̀ẹ̀mejì Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Ni Wọ́n Rán Mi Lọ Sẹ́wọ̀n Ọdún Mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n Láti Lọ Sìnrú 24
Kà nípa ìgbàgbọ́ ẹnì kan tó jìyà torí pé ó kọ̀ láti bá wọn jagun lórílẹ̀-èdè Soviet Union nígbà Ogun Àgbáyé Kejì tí wọ́n sì tìtorí ẹ̀ ní kó ṣiṣẹ́ bí ẹní máa kú lọ́gbà ẹ̀wọ̀n tó ti ń sìnrú.