Bí Ọmọ Ẹní Bá Kú
◼ Bí ìgbà tí iná bá jóni lára lọ̀ràn ikú ọmọ ṣe máa ń rí lára àwọn tẹbí tọ̀rẹ́, pàápàá àwọn òbí. Ìyá kan tí iná jó ọmọdékùnrin rẹ̀ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún lọ́nà tó burú jáì nínú ìjàǹbá mọ́tò tó le gan-an, kédàárò pé: “Ọlọ́run ò gbà pé káwa òbí gba ikú àwọn ọmọ wa kú, bẹ́ẹ̀ ni kò sì gbà pé ká kú pẹ̀lú wọn.”
Síbẹ̀, àlàyé tó ṣe lẹ́yìn náà fi hàn pé kò sọ̀rètí nù. Ó sọ pé: “Ọlọ́run ò fi bọ́rọ̀ ikú ṣe jẹ́ pa mọ́ fún wa, ìyẹn ni ò sì jẹ́ kí èmi àti ọkọ mi fara ya tàbí ká ṣe ohun tí kò bọ́gbọ́n mu.” Ó fọwọ́ sọ̀yà pé, “Ọlọ́run wa kọ́ ló pa wá lọ́mọ, Ó sì ti ṣèlérí pé òun á jí àwọn òkú dìde sínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Ní tiwa o, ńṣe là ń fojú inú wò ó pé ọmọ wa wà láàyè, ara ẹ̀ le, ó láyọ̀, ó sì ń gbé láàárín tẹbí tọ̀rẹ́.”
Síbẹ̀, àwọn tí wọ́n tiẹ̀ nírètí tó dájú nínú ìlérí Ọlọ́run nípa àjíǹde ṣi nílò ìtùnú, ìyá yìí sì kún fún ọpẹ́ pé òun rí ìtùnú yìí gbà lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ òun. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára èrò tó bá Ìwé Mímọ́ mu àti inú rere tí wọ́n fi hàn sí wa wà nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú. A rọ gbogbo àwọn tó sún mọ́ wa pé kí wọ́n kà á kí wọ́n lè túbọ̀ mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa àti ohun tó ń dùn wá lọ́kàn.”
Bí ìwọ tàbí ẹnì kan tó o mọ̀ bá fẹ́ láti gbọ́rọ̀ ìtùnú nípa kíka ìwé pẹlẹbẹ Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, o lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.