Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
NÍBO LÓ TI ṢẸLẸ̀?
1. Níbi ìwọ́jọpọ̀ omi wo ni ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú àwòrán yìí ti wáyé?
Fa ìlà yípo ìdáhùn rẹ nínú àwòrán-ilẹ̀.
Òkun Ńlá
Òkun Gálílì
Odò Jọ́dánì
Òkun Iyọ̀
◆ Ǹjẹ́ o mọ orúkọ èèyàn méjì tí ò sí nínú ọkọ̀ ojú omi yìí?
․․․․․
․․․․․
◆ Kí ló fà á tó jẹ́ pé ẹnì kan ṣoṣo ló ń rì?
․․․․․
ÌGBÀ WO LÈYÍ ṢẸLẸ̀?
Fa ìlà láti ibi àwòrán lọ sí ibi déètì tó bá a mu.
1077 Ṣ.S.K. (Ṣáájú Sànmánì Kristẹni) 947 Ṣ.S.K. 647 Ṣ.S.K. 537 Ṣ.S.K. 539 Ṣ.S.K.
2. Dáníẹ́lì 5:5
TA NI MÍ?
5. Mo fi ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù ṣá ẹgbẹ̀ta àwọn Filísínì balẹ̀.
TA NI MÍ?
6. Mo jẹ oyin, èyí sì lòdì sí ohun tí bàbá mi mú káwọn èèyàn torí ẹ̀ búra.
NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, kó o sì kọ (àwọn) ẹsẹ Bíbélì tó yẹ sínú àlàfo.
Ojú ìwé 7 Kí nìdí téèyàn fi ń kú? (Róòmù 6:․․․)
Ojú ìwé 9 Báwo ni Bíbélì ṣe sọ pé ọjọ́ iwájú máa rí? (Ìṣípayá 21:․․․)
Ojú ìwé 12 Kí ló lè mú kéèyàn máa hùwà lọ́nà tí kò mọ́gbọ́n dání? (Oníwàásù 7:․․․)
Ojú ìwé 23 Ibo ló yẹ ká máa wá ìtọ́sọ́nà lọ, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀? (2 Tímótì 3:․․․)
Eré Àwòrán Wíwá Fáwọn Ọmọdé
Ṣó o lè wá ibi táwọn àwòrán yìí wà nínú ìtẹ̀jáde yìí? Fi ọ̀rọ̀ ara rẹ ṣàlàyé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú àwòrán kọ̀ọ̀kan.
ÌDÁHÙN SÁWỌN ÌBÉÈRÈ OJÚ ÌWÉ 31
1. Òkun Gálílì.—Jòhánù 6:1, 16.
◆ Jésù àti Pétérù.—Mátíù 14:26-31.
◆ Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì; Jésù kò ṣiyèméjì.—Mátíù 14:31.
2. 539 Ṣ.S.K. 3. 647 Ṣ.S.K.
4. 1077 Ṣ.S.K.
5. Ṣámúgárì.—Àwọn Onídàájọ́ 3:31.
6. Jónátánì.—1 Sámúẹ́lì 14:27.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]
Top circle: U.S. Fish & Wildlife Service, Washington, D.C./Duane C. Anderson