Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
SỌ ẸNI TÁWỌN Ẹ̀DÁ Ẹ̀MÍ YÌÍ JẸ́
Fa ìlà láti ibi àwòrán áńgẹ́lì lọ síbi tí orúkọ irú áńgẹ́lì náà wà, kó o wá dáhùn ìbéèrè tó wà níbẹ̀.
Olú-áńgẹ́lì
Orúkọ wo la fi mọ olú-áńgẹ́lì yìí?
Kérúbù
Kí làwọn kérúbù ń ṣọ́ nínú ọgbà Édẹ́nì?
Séráfù
Kí ni Aísáyà gbọ́ táwọn séráfù ń sọ?
Áńgẹ́lì
Ó kéré tán, ó tó áńgẹ́lì mélòó tó wà?
1. ․․․․․
2. ․․․․․
3. ․․․․․
4. ․․․․․
◼ Fún Ìjíròrò: Báwo ni mímọ̀ nípa ìdílé Jèhófà lókè ọ̀run ṣe lè mú kó o túbọ̀ nígboyà?—2 Àwọn Ọba 6:15-17.
ÌGBÀ WO LÈYÍ ṢẸLẸ̀?
Fa ìlà láti ibi ìṣẹ̀lẹ̀ kọ̀ọ̀kan lọ sídìí ọdún tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.
1761 Ṣ.S.K. Nǹkan bíi 538 Ṣ.S.K. 33 Ṣ.K.
1728 Ṣ.S.K. Nǹkan bíi 455 Ṣ.S.K. 44 Ṣ.K.
5. Ìṣe 12:5-11
TA NI MÍ?
8. Mo kọtí ikún sí ìkìlọ̀ áńgẹ́lì kan àti àròyé tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mi ń ṣe.
TA NI MÍ?
9. Mo jíṣẹ́ fún Dáníẹ́lì, Sekaráyà àti ìyá Ìmánúẹ́lì.
NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, kó o sì kọ (àwọn) ẹsẹ Bíbélì tó yẹ sínú àlàfo.
Ojú ìwé 4 Báwo ni wíwo tẹlifíṣọ̀n ṣe dà bíi jíjẹ oyin? (Òwe 25:․․․)
Ojú ìwé 7 Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nípa ohun tá à ń wò lórí tẹlifíṣọ̀n? (Òwe 13:․․․)
Ojú ìwé 25 Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí èrò èèyàn tó bá ti kú? (Sáàmù 146:․․․)
ÌDÁHÙN
1. Kérúbù. “Ọ̀nà tó lọ síbi igi ìyè.” —Jẹ́nẹ́sísì 3:24.
2. Olú-áńgẹ́lì. Máíkẹ́lì.—Júúdà 9.
3. Áńgẹ́lì. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́.—Dáníẹ́lì 7:10.
4. Séráfù. “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà.”—Aísáyà 6:3, 6, 7.
5. 44 S.K.
6. 1761 Ṣ.S.K.
7. Nǹkan bíi 538 Ṣ.S.K.
8. Báláámù.
9. Gébúrẹ́lì.