ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/06 ojú ìwé 30
  • Ibi Róbótó Tó Jẹ́ Kàyéfì ní Áfíríkà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibi Róbótó Tó Jẹ́ Kàyéfì ní Áfíríkà
  • Jí!—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Ẹ Dúró Nínú Ọ̀rọ̀ Mi’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Iṣẹ́ Àrà Tí Ẹyẹ Malle Ń Ṣe Lórí Ìtẹ́ Rẹ̀
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
  • Máa Lo Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tó Gbéṣẹ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ—Ìdí Tí A Fi Nílò Rẹ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Jí!—2006
g 1/06 ojú ìwé 30

Ibi Róbótó Tó Jẹ́ Kàyéfì ní Áfíríkà

Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn gúúsù Áfíríkà ni Aṣálẹ̀ Namib wà. Ilẹ̀ salalu kan tó jẹ́ ẹgbàá mẹ́wàá kìlómítà [2,000] ní gígùn wà lápá ibi tí aṣálẹ̀ náà parí sí níhà ìwọ̀ oòrùn. Lórí ilẹ̀ náà, àwọn ibì róbótó róbótó kan wà tó dápàá. Àwọn ojú ibi tó dápàá náà fẹ̀ tó mítà méjì sí mítà mẹ́wàá, ìyẹn ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà sí ọgbọ̀n ẹsẹ̀ bàtà kò sì sí koríko kankan tó hù sójú ibẹ̀. Àfi eteetí ibi róbótó wọ̀nyẹn tí koríko gíga hù sí yíká. Lójú àwọn arìnrìn-àjò kan, àfi bí ìgbà tí ìgbóná bá sú séèyàn lára tàbí kí òjò tí ọwọ́ ẹ̀ le wọ́n sórí yanrìn ni ibi róbótó yẹn rí lórí ilẹ̀. Ìgbàgbọ́ wọn ládùúgbò yẹn ni pé àwọn nǹkan abàmì wà lójú ibi róbótó wọ̀nyẹn. Àwọn ẹ̀yà kan tiẹ̀ gbà gbọ́ pé ojú oórì ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ògbójú ọdẹ tí wọ́n ń pè ní Bushmen, tí wọ́n kú nínú ìjà tó wáyé láàárín àwọn ògbójú ọdẹ yìí àtàwọn òyìnbó amúnisìn lọ́pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, làwọn ibi róbótó náà.

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì pẹ̀lú ti sapá láti ṣàlàyé bọ́rọ̀ àwọn ibi róbótó yẹn ṣe jẹ́. Lọ́dún 1978, àwọn olùṣèwádìí fi irin kan gún àárín àwọn kan lára ibi róbótó yẹn gẹ́gẹ́ bí àmì nítorí èrò wọn pé bí ọjọ́ bá ṣe ń gorí ọjọ́, ibi róbótó yẹn á ṣípò padà. Lọ́dún méjìlélógún lẹ́yìn yẹn, ojú ibi róbótó yẹn ò má ṣípò padà o. Àìmọye nǹkan làwọn èèyàn ti sọ pé ó fa àwọn ibi róbótó yẹn. Ìwé ìròyìn kan nílùú London, The Daily Telegraph, sọ pé lára àwọn nǹkan ọ̀hún ni “ikán, májèlé tó wà lára àwọn koríko ibẹ̀ tó ní èròjà olóró, àkóràn látinú àwọn ohun àmúṣọrọ̀ inú ilẹ̀ tó léwu fún ìwàláàyè, kódà wọ́n mẹ́nu ba eruku tí pẹ́pẹ́yẹ ń kù.” Obìnrin kan tó jẹ́ ògbógi nínú ìmọ̀ ewéko ní Yunifásítì Pretoria ní orílẹ̀-èdè South Africa, Ọ̀jọ̀gbọ́n Gretel van Rooyen, ṣe ìwádìí kan láti lè ṣàwárí bọ́rọ̀ ibi róbótó wọ̀nyẹn ṣe jẹ́. Ohun tó sọ ni pé: “Ọ̀kọ̀ọ̀kan la ṣàyẹ̀wò àwọn ohun táwọn èèyàn sọ pé ó fà á, ọ̀kọ̀ọ̀kan náà sì ni gbogbo wọn kùnà.”

Ohun kan tó dà bí àṣeyọrí ni pé, àwọn olùwádìí rí i pé ṣe ni ohun tí wọn gbìn sórí ilẹ̀ tí wọ́n bù látinú ibi róbótó yẹn gbẹ dànù. Ṣùgbọ́n ó hù dáadáa lórí ilẹ̀ tí wọ́n bù láàárín koríko tó hù yíká ibi róbótó yẹn, èyí tó jẹ́ kó ṣe kedere pé ìyàtọ̀ wà nínú ilẹ̀ tó wà níbi méjèèjì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo bí wọ́n ṣe ṣèwádìí nípa ilẹ̀ yẹn ò tíì fún wọn ní àbájáde gidi kan, síbẹ̀ Ọ̀jọ̀gbọ́n Van Rooyen nírètí pé táwọn bá lo irin iṣẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní spectrometer, àwọn á mọ púpọ̀ sí i. Ọ̀jọ̀gbọ́n Van Rooyen ò tíì mọ̀ bóyá àwọn èròjà olóró lè wà nínú ilẹ̀ tó wà níbi róbótó yẹn. Ìyẹn ló ṣe sọ nínú ìwé ìròyìn New Scientist pé: “Àmọ́ tá a bá wà rí i dájú pé wọ́n wà níbẹ̀, ohun tá a tún ní láti mọ̀ ni bí wọ́n ṣe débẹ̀.” Àmọ́ lọ́wọ́ tá a wà yìí, àwọn ibi róbótó yẹn ṣì jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ àwọn ibi tó fani mọ́ra àmọ́ tó jẹ́ kàyéfì.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 30]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Austin Stevens

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́