ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/06 ojú ìwé 28-29
  • ‘Màá Pàdé Ẹ Nídìí Kànga’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Màá Pàdé Ẹ Nídìí Kànga’
  • Jí!—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ojú Tí Wọ́n Fi Ń Wo Omi Látìgbà Láéláé
  • Ìdààmú Tí Àyíká Ń Kó Bá Wọn
  • Mo Borí Ìṣòro Tíì Bá Dí Mi Lọ́wọ́ Láti Sin Ọlọ́run
    Jí!—2005
  • Ṣé Omi Ń tán Lọ Láyé Ni?
    Jí!—2001
  • Ẹ̀ẹ̀mejì Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Ni Wọ́n Rán Mi Lọ Sẹ́wọ̀n Ọdún Mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n Láti Lọ Sìnrú
    Jí!—2006
  • Omi Tó Ń Tú Yàà Sókè Láti Fúnni Ní Ìyè Àìnípẹ̀kun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Jí!—2006
g 1/06 ojú ìwé 28-29

‘Màá Pàdé Ẹ Nídìí Kànga’

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ MOLDOVA

ÌYÀWÓ ọ̀ṣìngín kan tí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ yé ń wo bí wọ́n ṣe fa omi jáde látinú kànga tí wọ́n sì dà á sójú ọ̀nà. Ó bu ẹ̀rín sẹ́nu bí ọkọ ẹ̀ ṣe gbé e kọjá lórí ilẹ̀ tútù. Tẹbí tọ̀rẹ́ ló péjọ láti wòran kí wọ́n sì bá tọkọtaya alárédè yìí yọ̀ níbi ayẹyẹ àṣà ìbílẹ̀ yẹn, èyí tó ti wà látayébáyé. Àṣà ìbílẹ̀ táwọn ará Moldova máa ń tẹ̀lé níbi ìgbéyàwó mú kó ṣe kedere pé kì í ṣe torí àtipọnmi nìkan ni wọ́n ṣe ń gbẹ́ kànga.

Ìlà oòrùn gúúsù Yúróòpù ni orílẹ̀-èdè Moldova wà. Ó bá orílẹ̀-èdè Ukraine pààlà níhà àríwá, níhà ìlà oòrùn àti níhà gúúsù, ó sì bá orílẹ̀-èdè Romania pààlà níhà ìwọ̀ oòrùn. Apá tó jẹ́ ìyàngbẹ ilẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34,000] kìlómítà níbùú lóòró.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ̀rìndínlógún ó dín ọgọ́rùn-ún [3,100] odò ló wà ní Moldova, ọ̀dá kì í jẹ́ káwọn odò náà lè ní omi tó máa tó èèyàn mílíọ̀nù mẹ́rin ó lé ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [4,300,000] tó ń gbébẹ̀ láti lò. Kí wọ́n bàa lè máa rí omi tó pọ̀ tó lò láfikún sí èyí tí wọ́n lọ ń pọn lódò, ìdá márùn-ún omi náà ni wọ́n ń fà látinú kànga. Ó tó ọ̀kẹ́ márùn-ún sí ọ̀kẹ́ mẹ́wàá kànga tó wà káàkiri gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ odò Prut láwọn àgbègbè tó jẹ́ ti orílẹ̀-èdè Moldova!

Ibi tó sún mọ́ tòsí àwọn ojú pópó àtàwọn ẹ̀bá ọ̀nà tó wà lórílẹ̀-èdè Moldova, táwọn arìnrìn-àjò tó ti rẹ̀ ti lè pòùngbẹ ni wọ́n gbẹ́ àwọn kànga tí wọ́n fi òrùlé tó jojú ní gbèsè náà bò. Ní ọ̀pọ̀ abúlé lórílẹ̀-èdè náà, àwọn ọ̀rẹ́ máa ń dápàdé sídìí kànga láti fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ náà.

Ojú Tí Wọ́n Fi Ń Wo Omi Látìgbà Láéláé

Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni wọ́n gbà ń fi hàn pé ojú pàtàkì làwọn fi ń wo omi kànga lórílẹ̀-èdè Moldova. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n kì í jẹ́ kí ilé ìgbọ̀nsẹ̀ wọn sún mọ́ ibi tí wọ́n gbẹ́ kànga sí, òfin sì wà pé kí ẹnikẹ́ni má ṣe da omi tó bá ṣẹ́ kù padà sínú kànga nítorí kí omi inú kànga wọn má bàa di eléèérí. Bí omi tí wọ́n fà jáde bá pọ̀ ju èyí tí wọ́n nílò lọ, dídà ni wọ́n máa da èyí tó bá ṣẹ́ kù nù tàbí kí wọ́n dà á sínú korobá tó bá wà nídìí kànga náà. Síwájú sí i, ìwà ìbàjẹ́ ni wọ́n kà á sí fún ẹni tó bá tutọ́ tàbí ha kẹ̀lẹ̀bẹ̀ sí ẹ̀bá kànga. Kódà, èèwọ̀ ni kéèyàn jiyàn nítòsí kànga!

Ọ̀rọ̀ kànga ò ṣe kànga yìí máa ń jẹ́ káwọn ará Moldova mú ara wọn bíi tẹ̀gbọ́n tàbúrò ni. Gbogbo àwọn tó wà ládùúgbò ló máa ń dáwọ́ jọ gbẹ́ kànga tuntun, lójú wọn kò yàtọ̀ sígbà tí wọ́n ń kọ́lé tuntun. Ó tiẹ̀ máa ń jáde nínú ọ̀rọ̀ kan tó wọ́pọ̀ lẹ́nu àwọn ará ibẹ̀, wọ́n á ni, Ẹni tó wáyé tí ò kọ́lé, tí ò ní ọmọkùnrin, tí ò gbẹ́ kànga, tí ò sì gbin igi, kò ráyé wá. Bí wọ́n bá ti wá gbẹ́ kànga ọ̀hún tán, wọ́n á fi ilé pọntí fọ̀nà rokà fún gbogbo ará àdúgbò tó wá bá wọn gbẹ́ ẹ.

Ìdààmú Tí Àyíká Ń Kó Bá Wọn

Èyí tó pọ̀ lára àwọn kànga tí wọ́n ń gbẹ́ lórílẹ̀-èdè Moldova máa ń jìn tó mítà márùn-ún sí mítà méjìlá, ìyẹn [ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ogójì ẹsẹ̀ bàtà] kí wọ́n tó já omi. Wọ́n máa ń kan omi tó mọ́ jùyẹn lọ ní nǹkan bí àádọ́jọ sí àádọ́talérúgba mítà. Láìka àwọn ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà mú kí omi wọn wà ní mímọ́ sí, ọ̀pọ̀ omi inú ilẹ̀ lórílẹ̀-èdè Moldova ló ti di eléèérí látàrí dídà táwọn ilé iṣẹ́ ń da kẹ́míkà tí wọ́n ò bá nílò mọ́ síbi tó bá wù wọ́n àti lílò táwọn àgbẹ̀ ń lò kẹ́míkà nílòkulò. Ìwé kan nípa ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè Moldova tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tẹ̀ jáde lọ́dún 1996, Republic of Moldova Human Development Report, kíyè sí i pé èròjà ajílẹ̀ kan tó ń jẹ́ nitrate àti kòkòrò bakitéríà kan tó ń fa àìsàn ti sọ “mẹ́ta nínú gbogbo kànga márùn-úntó wà lórílẹ̀-èdè Moldova di eléèérí.” Ó kàn jẹ́ pé láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, omi inú kànga ti dára sí i látàrí bí iye àwọn ilé iṣẹ́ tó wà níbẹ̀ ti ṣe dín kù tí ìwọ̀n kẹ́míkà àti epo rọ̀bì tó rọra ń lọ sínú ìsun omi abẹ́lẹ̀ pẹ̀lú sì dín kù.

Bó o bá lọ kí wọn lórílẹ̀-èdè Moldova, kò dìgbà tó o bá da omi sójú ọ̀nà kó o tó lè rí ẹni bá ọ tàkúrọ̀sọ. Kódà ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ náà lè ta sí ọ létí nígbà tó o bá ń fi omi tútù tí wọ́n bù sínú ife pòùngbẹ. Gbogbo ohun tó o fẹ́ ò ju pé kí ará Moldova kan tó jẹ́ ọ̀làwọ́ sọ pé òun máa pàdé ẹ nídìí kànga.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28, 29]

IṢẸ́ ỌWỌ́ TÁWỌN ARÁ MOLDOVA MỌ̀ Ọ́N ṢE

Láti ìgbà tí Oleg ti kúrò nílé ìwé, irin fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ ló máa ń gé láti fi ṣe òrùlé tó jojú ní gbèsè sórí kànga. Oleg ṣàlàyé ara rẹ̀ pé: “Mo gbà pé inú ẹ̀jẹ̀ wa ni iṣẹ́ ká fi irin gígé ṣe ọnà wà. Ọ̀dọ̀ ọ̀kan lára àwọn Júù tó ń gbé ládùúgbò àwọn Júù, lẹ́yìn odi abúlé kan tó ń jẹ́ Lipcani, ni bàbá bàbá mi ti kọ́ iṣẹ́ náà ní nǹkan tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí. Lẹ́yìn ìpakúpa ìgbà Ogun Àgbáyé Kejì, kò sí Júù kankan lára àwọn oníṣòwò díẹ̀ tó ṣẹ́ kù. Bí bàbá mi ṣe kọ́ iṣẹ́ yẹn nìyẹn, tó sì wá fi lé mi lọ́wọ́.”

Irin iṣẹ́ mélòó kan àti bátànì tí Oleg ti gé sílẹ̀ ló máa fi ń yọ àwọn igun tín-tìn-tín tó máa ń jẹ́ kí òrùlé náà jojú ní gbèsè; bó ṣe bá a lọ́wọ́ bàbá ẹ̀ àti ojú ọnà tó ní tún máa ń ràn án lọ́wọ́. Ojú pàtàkì làwọn ará ibẹ̀ fi máa ń wo iṣẹ́ tó ń ṣe yìí. Oleg fúnra ẹ̀ sọ pé: “Àwọn oníbàárà mi kì í fẹ́ san iye táwọn tó ń ṣe irú iṣẹ́ tí mò ń ṣe bá ní kí wọ́n san ṣùgbọ́n bí mo bá bá wọn ṣe òrùlé kànga, ó máa ń jojú ní gbèsè débi pé kì í ni wọ́n lára láti san iye tí mo bá dá lé wọn.”

[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 28, 29]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

UKRAINE

MOLDOVA

ROMANIA

Òkun Dúdú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́