Ẹ̀ẹ̀mejì Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Ni Wọ́n Rán Mi Lọ Sẹ́wọ̀n Ọdún Mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n Láti Lọ Sìnrú
GẸ́GẸ́ BÍ EFREM PLATON ṢE SỌ Ọ́
Nígbà tí ọdún 1951 ń parí lọ, wọ́n dájọ́ fún mi lẹ́ẹ̀kejì pé kí n lọ sìnrú fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lẹ́wọ̀n. Lọ́tẹ̀ yìí, àgọ́ Soviet burúkú kan báyìí tó wà nílùú Vorkuta lápá àríwá ayé ni wọ́n rán mi lọ. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé ohun tó gbé mi débẹ̀ àti bó ṣe jẹ́ pé díẹ̀ ló kù kí n kú ikú gbígbóná.
ỌJỌ́ kẹrìndínlógún oṣù keje ọdún 1920 ni wọ́n bí mi ní ìlú Bessarabia, lágbègbè kan tá a mọ̀ sí orílẹ̀-èdè Moldova báyìí. A ò ní gá, a ò ni go nínú ìdílé tí wọ́n bí mi sí. Ó kù díẹ̀ kí wọ́n bí mi ni bàbá mi kú, ọmọ ọdún mẹ́rin sì ni mí nígbà tí màmá mi náà kú. Ìyẹn ló sọ àwa mẹ́fẹ̀ẹ̀fà táwọn òbí wa bí di ọmọ òrukàn. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀gbọ́n mi, àwọn ló dà bí òbí fáwa àbúrò wọn.
Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, mo nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn gan-an ni, mo sì máa ń bá wọn lọ́wọ́ sáwọn ohun tó ń lọ ní Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì tá à ń lọ. Àmọ́ nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí róhun tí mo rò pé kò yẹ ká máa rí ní Ṣọ́ọ̀ṣì, pàápàá báwọn àlùfáà ṣe ń ṣètìlẹ́yìn fáwọn ohun tí wọ́n ń ṣe nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, èyí tó bẹ̀rẹ̀ lóṣù kẹsàn-án ọdún 1939.
Kété lẹ́yìn ọdún 1940, ìjà ńlá bẹ́ sílẹ̀ láàárín orílẹ̀-èdè Romania àti orílẹ̀-èdè Soviet Union, ìlú Bessarabia sì há sí wọn láàárín. Ọ̀gágun Ion Antonescu, tó ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè Romania nígbà yẹn, ṣẹ́gun ìlú Bessarabia. Àwọn aláṣẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́ fáwọn ọkùnrin tọ́jọ́ orí wọn bẹ̀rẹ̀ láti ogún ọdún, kí wọ́n lè fi múra wọn sílẹ̀ fún iṣẹ́ ológun. Mo wà lára àwọn tí wọ́n fipá mú pé kó wá gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn. Abúlé Boroşeni ni wọ́n ti lọ dá wa lẹ́kọ̀ọ́, ibẹ̀ ò sì jìnnà sí abúlé témi àti aya mi Olga ń gbé.
Bí Mo Ṣe Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Lákòókò ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà, lọ́sàn-án ọjọ́ kan nígbà tá a wà lákòókò ìsinmi oúnjẹ, mo kíyè sáwọn ọkùnrin mélòó kan tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ kan tó ká wọn lára; kò sì pẹ́ tí mo fi mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n. Ìjíròrò ráńpẹ́ tó wáyé láàárín èmi àti wọn yọrí sí ìjíròrò púpọ̀ sí i. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, ayọ̀ mi kún àkúnwọ́sílẹ̀ nígbà tí mo rí i pé ọwọ́ mi ti tẹ òtítọ́ látinú Bíbélì, mo sì ṣàlàyé òtítọ́ yìí fún aya mi Olga àtàwọn òbí ẹ̀.
Ìjíròrò tó wọ̀ mí lọ́kàn jù lọ́jọ́ náà ni èyí tó jẹ mọ́ àìdásí tọ̀tún tòsì lórí ọ̀ràn ogun. Àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn pinnu nígbà yẹn pé àwọn ní láti yan èyí táwọn á ṣe lórí ọ̀ràn yìí. Wọ́n pinnu pé àwọn á gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà ṣùgbọ́n àwọn ò ní bá wọn jẹ́jẹ̀ẹ́ ìfọkànsìn, èyí tó pọn dandan kí wọ́n tó lè kó wọn wọṣẹ́ ológun.
Mo sọ fún ìyàwó mi àtàwọn òbí ẹ̀ pé èmi náà ti pinnu pé mi ò ní jẹ́jẹ̀ẹ́ yẹn, wọ́n sì fọwọ́ sí ìpinnu tí mo ṣe. Nígbà tí àkókò tó tí wọ́n fẹ́ fà wá wọṣẹ́ ológun, ìyẹn ní January 24, 1943, wọ́n ní ká wá máa jẹ́jẹ̀ẹ́ ìfọkànsìn wa. Àwa mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ bọ́ síwájú àlùfáà tó ń darí ètò ìjẹ́jẹ̀ẹ́ náà. Dípò tá à bá fi jẹ́jẹ̀ẹ́, ṣe la sọ pé a ò lè dá sí ogun torí pé a ò fẹ́ gbè síbì kan lórí ọ̀ràn ogun.
Wọ́n fi ọlọ́pàá mú wa, wọ́n sì kó wa lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá ní abúlé Boroşeni. Níbẹ̀, wọ́n lù wá ní ìlù ìkà débi pé ìyàwó mi ò dá mi mọ̀ mọ́. Lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n kó wa lọ sí ilé ẹjọ́ àwọn ológun ní ìlú Chişinău (tó ń jẹ́ Kishinev tẹ́lẹ̀), èyí tí í ṣe olú ìlú orílẹ̀-èdè náà.
Ibi tá a fẹsẹ̀ rìn tó ogóje kìlómítà ó sì gbà wá ní ìrìn ọjọ́ mọ́kànlélógún nítorí òtútù tó mú hóíhóí. Wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ de àwa mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ pọ̀, wọ́n sì ní káwọn sójà tó dira ogun máa kó wa lọ láìjẹ́ ká fi oúnjẹ tàbí omi kan ẹnu. Gbogbo àgọ́ ọlọ́pàá tá à ń dé ni wọ́n ti ń nà wá, àgọ́ ọlọ́pàá mẹ́tàlá la sì kàn lójú ọ̀nà! À bá má yè é tí kì í bá ṣe pé àwọn èèyàn tó ń gbé láwọn àgọ́ ọlọ́pàá tá à ń sùn sí lálaalẹ́ máa ń fún wa lóúnjẹ àti omi nígbà tá a bá débẹ̀. Bí wọ́n ṣe ṣe wá lóore yẹn jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run ń tọ́jú wa.
Ọlọ́run Fún Mi Lókun Láti Borí Ìrẹ̀wẹ̀sì
Nígbà táwa mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ wà látìmọ́lé ní ìlú Chişinău tá à ń dúró de ìgbẹ́jọ́ wa, wọ́n tún fojú wa rí màbo. Kí wọ́n bàa lè mú kí ìgbàgbọ́ wa jó rẹ̀yìn, àwọn alákòóso sọ fún wa pé àwọn Ẹlẹ́rìí kan ní abúlé Zăicani tó wà lápá àríwá orílẹ̀-èdè Moldova ti sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn, àwọn aláṣẹ sì ti dá wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè padà sílé. Nígbà tó yá la wá gbọ́ pé ṣe ni wọ́n ní kí wọ́n lọ dúró nílé títí dìgbà tí ilé ẹjọ́ máa gbọ́ ẹjọ́ wọn. Bákan náà, ọlọ́pàá kan wá sọ ohun tó kà nínú àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn pé ilé ẹjọ́ àwọn ológun lórílẹ̀-èdè Ukraine ti dájọ́ ikú fún ọgọ́rin Ẹlẹ́rìí.
Àwọn kan nínú àwa mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ bẹ̀rẹ̀ sí rẹ̀wẹ̀sì, wọ́n ń ronú pé àwọn ò ní ráwọn ọmọ àwọn mọ́. Àwọn tó kó wa ṣèlérí fún wa pé tá a bá fi lè sẹ́ ìgbàgbọ́ wa, àwọn á dá wa sílẹ̀. Wọ́n ní ká lọ lo ọ̀sẹ̀ kan nílé lọ́dọ̀ àwọn ìdílé wa ká lè ríbi ronú nípa ọjọ́ iwájú wa. Lẹ́yìn ìyẹn, àwa mẹ́ta péré ló kù lórí ìpinnu wa láti dúró láìdá sọ́rọ̀ ogun náà.
Ní ogúnjọ́ oṣù kejì ọdún 1943, wọ́n tún gbé mi lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ní abúlé Boroşeni, níbi tí wọ́n ti kọ́kọ́ lu pásapàsa sí mi lára tẹ́lẹ̀. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé àwọn méjì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí bíi tèmi tí wọn ò tíì juwọ́ sílẹ̀. Ṣe ni ìdùnnú ṣubú lu ayọ̀ fún wa nígbà tá a fojú kanra! Nígbà tó yá wọ́n fi kẹ̀kẹ́ tí ẹṣin ń fà kó wa lọ sílùú Bălţi. Nígbà ìrìn-àjò yẹn, mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣàìsàn, àìsàn yẹn sì wá ṣiṣẹ́ rere torí pé ọkọ̀ bọ́ọ̀sì ni wọ́n fi gbé wa rin ìyókù nínú ìrìn-àjò náà dé ìlú Chişinău.
Nígbà tá a gúnlẹ̀, ẹ̀ṣọ́ kan dá wa mọ̀, ó rántí pé àwa mẹ́ta yẹn la dúró lórí ìpinnu wa. Lílù ni wọ́n tún fi kí wa káàbọ̀. Lóṣù kan lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n dájọ́ pé ká lọ sẹ́wọ̀n láti lọ sìnrú fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lórílẹ̀-èdè Romania.
Mo Ṣèrìbọmi Nínú Ihò Tí Bọ́ǹbù Gbẹ́
Nígbà tó ṣáà yá, wọ́n rán wa lọ sí ìlú Cugir lórílẹ̀-èdè Romania, níbi tá a ti ń gé gẹdú nínú igbó. Wọ́n ní tá a bá ṣe àwọn nǹkan kan débi táwọn fẹ́, wọ́n máa fún wa ní oúnjẹ díẹ̀ sí i. Àwa mẹ́wàá tá a jẹ́ Ẹlẹ́rìí tá a jọ wà níbẹ̀ kì í fiṣẹ́ falẹ̀, torí náà, a rí oúnjẹ jẹ ju ti ẹ̀wọ̀n tí wọ́n kó wa sí tẹ́lẹ̀ lọ.
Lọ́dún 1944, àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ sí yin bọ́ǹbù sí àgbègbè tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n tá a ti ń sìnrú. Lọ́jọ́ kan, bọ́ǹbù tí wọ́n yìn gbẹ́ ihò gìrìwò sẹ́gbẹ̀ẹ́ odò kékeré kan. Omi bẹ̀rẹ̀ sí rọ́ sínú ihò yìí, ká sì tó ṣẹ́jú pẹ́, ó ti di adágún odò ńlá. Lóṣù September ọdún 1944, inú adágún odò yìí ni mo ti ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run ní ohun tó ju ọdún kan àbọ̀ ṣáájú ìgbà yẹn.
Mo Dòmìnira Lẹ́yìn-Ọ̀-Rẹyìn!
Ọ̀sẹ̀ mélòó kan sígbà yẹn ni ilé iṣẹ́ ológun orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà dá ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwa Ẹlẹ́rìí tá a wà káàkiri àgbègbè yẹn sílẹ̀, a sì láǹfààní láti padà sílé. Ìyẹn ni ìgbà àkọ́kọ́ tí mo fojú mi kan Vasile, ọmọkùnrin tí ìyàwó mi bí fún mi lọ́dún 1943 nígbà tí mo wà lágọ̀ọ́ ìsìnrú.
Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì fi máa parí nílẹ̀ Yúróòpù lóṣù May ọdún 1945, ìlú Bessarabia ti bọ́ sábẹ́ àkóso orílẹ̀-èdè Soviet Union ó sì ti di Orílẹ̀-èdè Olómìnira Àjùmọ̀ni Moldavia Lábẹ́ Àkóso Soviet, ìyẹn Moldavian Soviet Socialist Republic. Ojú ẹsẹ̀ kọ́ làwọn aláṣẹ ìjọba lòdì sí iṣẹ́ táwa Kristẹni ń ṣe. Àmọ́, wọ́n kíyè sí i pé a kì í dìbò, ọ̀ràn ńlá ni ìjọba sì ka ìyẹn sí lórílẹ̀-èdè náà.
Lọ́dún 1946 la bí ọmọkùnrin kejì tá a sọ ní Pavel, a sì bí ọmọbìnrin wa tá a sọ ní Maria lọ́dún 1947. A mà gbádùn ara wa gẹ́gẹ́ bí ìdílé o! Àmọ́, ìbànújẹ́ míì tún wọlé tọ̀ wá lọ́dún méjì lẹ́yìn ìgbà yẹn. Òjijì ni Maria ọmọ wa ṣàìsàn tó sì kú. Ọjọ́ karùn-ún oṣù keje ọdún 1949 la sin ín. Àmọ́, ìbànújẹ́ wa ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ nígbà yẹn ni.
Wọ́n Kó Wa Nígbèkùn Lọ sí Siberia
Kò ju wákàtí mélòó kan lọ lẹ́yìn tá a sin Maria, nínú òkùnkùn biribiri nídàájí ọjọ́ kejì làwọn sójà mẹ́ta wá jí wa lójú oorun. Wọ́n sọ fún wa pé àwọn ń kó wa kúrò nílùú torí pé à ń hùwà tó lòdì sí ètò ìjọba àjùmọ̀ni tí orílẹ̀-èdè Soviet. Wọ́n gbà wá láàyè láti mú oúnjẹ àti aṣọ díẹ̀ dání, torí náà lọ́jọ́ kẹfà oṣù keje ọdún 1949, wọ́n kó wa kúrò nílùú, ó di ìlú Kurgan ní ẹkùn Siberia tó jẹ́ nǹkan bí ẹgbàajì [4,000] kìlómítà lápá àríwá orílẹ̀-èdè Kazakhstan.
Ọjọ́ méjìdínlógún gbáko ni ìrìn-àjò náà gbà wá. Ńṣe ni wọ́n kó wa sínú ọkọ̀ ojú irin bí ẹní kó màlúù. Ẹ̀ẹ̀mejì péré ni wọ́n fún wa lóúnjẹ díẹ̀ lójú ọ̀nà. Ṣe la rọra ń jẹ oúnjẹ wa díẹ̀díẹ̀ kó bàa lè gbé wa parí ìrìn-àjò náà. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni gbogbo àwa tá a wà nínú ọkọ̀ ojú irin tiwa. Ọ̀pọ̀ ìjíròrò Bíbélì tá à ń ṣe ló mú ká ṣì lókun nípa tẹ̀mí. Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ lára àwọn ohun tá a ní ni Ìwé Mímọ́.
Nígbà tá a dé ìlú Kurgan, a rí i pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àgọ́ ìsìnrú là ń gbé, síbẹ̀ a ṣì ní òmìnira díẹ̀ láti lọ síbi tó bá wù wá. Ìsọ̀ alágbẹ̀dẹ kan ni mo ti ń ṣiṣẹ́ mo sì máa ń láǹfààní àtimáa bá àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ìrètí tí mo rí nínú Bíbélì. Wọ́n mú mi lọ́dún méjì lẹ́yìn náà, ìyẹn ní September 27, ọdún 1951, wọ́n sì tún gbé mi lọ sílé ẹjọ́. Àwọn méjìdínlógún ni agbẹjọ́rò ìjọba kó wá láti wá jẹ́rìí pé mo ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìparun Orílẹ̀-èdè náà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ohun tí mo ṣe ò ju pé mo lo àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 2:44 láti fi hàn pé gbogbo ìjọba ayé yìí ni Ìjọba Ọlọ́run máa rọ́pò.
Yàtọ̀ síyẹn, àwọn aláṣẹ ti yẹ ibi tá à ń gbé wò wọ́n sì ti rí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí wa ní bòókẹ́lẹ́ láti orílẹ̀-èdè Moldova. Ohun táwọn aláṣẹ sábà máa ń rí tẹ́lẹ̀ ni àwọn ẹ̀dà tá a fọwọ́ dà kọ tàbí èyí tá a ti tún tẹ̀ lábẹ́lé. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n rí èyí tí wọn ò tẹ̀ lórílẹ̀-èdè Soviet Union. Bí wọ́n tún ṣe jù mí sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún míì lágọ̀ọ́ ìsìnrú nìyẹn. Lọ́tẹ̀ yìí, ibi tí wọ́n ti ń wa èédú ni ìlú Vorkuta, ìyẹn lágọ̀ọ́ ìsìnrú tó burú kan báyìí nípẹ̀kun Òkè Ural, lápá àríwá ayé ni wọ́n rán mi lọ.
Bí Ikú Ṣe Yẹ̀ Lórí Mi ní Ìlú Vorkuta
Ọgbà ẹ̀wọ̀n ńlá kan báyìí ló wà ní ìlú Vorkuta, àwọn àgọ́ tí wọ́n ti ń fipá kó èèyàn ṣiṣẹ́ níbẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́ta. Àwa tí wọ́n ń kó ṣiṣẹ́ ní àgọ́ tiwa nìkan tó ẹgbẹ̀rún mẹ́fà. Nítorí bí ibẹ̀ ṣe máa ń tutù ju yìnyín lọ àti irú ìyà burúkú tó ń jẹ́ àwọn tó ń gbébẹ̀, tó fi mọ́ èédú tí wọ́n ń wà lábẹ́ ilẹ̀, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló sọnù síbẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ là ń rí òkú tá a ní láti bò mọ́lẹ̀. Ìlera mi wá jagọ̀ débi pé mi ò lè ṣiṣẹ́ agbára mọ́. Iṣẹ́ tí wọ́n rò pé kò fi bẹ́ẹ̀ gba agbára, bíi fífi ṣọ́bìrì kó èédú sínú ọkọ̀, ni wọ́n ní kí n máa ṣe.
Nǹkan burú ní àgọ́ Vorkuta débi pé àwọn awakùsà tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ daṣẹ́ sílẹ̀, àmọ́ ó pàpà búrẹ́kẹ́ di ọ̀tẹ̀. Àwọn awakùsà níbẹ̀ dá ẹgbẹ́ tá á máa bójú tó ọ̀rọ̀ ara wọn sílẹ̀ wọ́n sì kó nǹkan bí àádọ́jọ ìgìrìpá jọ, pé táwọn ikọ̀ ìjọba bá dé, kí wọ́n má gbà fún wọn. Wọ́n ní kémi àti bí ọgbọ̀n Ẹlẹ́rìí míì dara pọ̀ mọ́ àwọn ajàjàgbara yìí. Àmọ́ a kọ̀.
Ọ̀sẹ̀ méjì gbáko ni wọ́n fi dìtẹ̀ yìí káwọn ọmọ ogun tó dé tí wọ́n sì pa gbogbo wọn pátá. A wá gbọ́ pé àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà ti ń gbèrò àtigbé wa kọ́gi níléeṣẹ́ yẹn! A dúpẹ́ pé ète wọn ò jọ. Tẹ́ ẹ bá ro ti ọgbọ́n táwọn ìjọba Soviet ń dá láti ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́, ẹ ó rí ìdí tá a fi sọ pé Jèhófà, Ẹni ńlá ló jẹ́ ká yè é!
A Lo Òmìnira Wa Tó Pọ̀ sí I Dé Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
Nígbà tí Stalin tó ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè Soviet kú lóṣù March ọdún 1953, nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí sunwọ̀n sí i fún wa. Lọ́dún 1955, wọ́n dá mi sílẹ̀ kúrò lágọ̀ọ́ Vorkuta wọ́n sì gbà mí láàyè láti padà sọ́dọ̀ àwọn aráalé mi tí wọ́n ṣì ń gbé nínú àgọ́ tó wà nínú igbó ní abúlé Kurgan. À ń bá ìwàásù wa lọ fáwọn tó ń gbébẹ̀, a sì ń sọ ìrètí àgbàyanu tá a ní fún wọn.
Nígbà tó di ọdún 1961, a pinnu láti lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù míì. La bá kọ lẹ́tà sí alákòóso orílẹ̀-èdè náà, Nikita Khrushchev, pé kó gbà wá láàyè láti jáde torí pé kò sí ilé ìwé fáwọn ọmọ wa láti lọ, òótọ́ sì ni. Wọ́n gbà wá láàyè láti lọ sí ilú kékeré kan tó ń jẹ́ Makushino, tí àgọ́ ìsìnrú kan wà. Ó mà dùn mọ́ wa nínú o pé a ran ìdílé ńlá mẹ́rin lọ́wọ́ láti di ìránṣẹ́ Jèhófà tó ya ara wọn sí mímọ́!
Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, lọ́dún 1965, wọ́n dá mi sílẹ̀ ní àgọ́ yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò gbá wá láàyè láti padà sílùú Moldova, a lè lọ sí apá ibòmíì lórílẹ̀-èdè Soviet Union. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, a gbabẹ̀ lọ sí ìlú Qostanay (tó ń jẹ́ Kustanai tẹ́lẹ̀) lórílẹ̀-èdè Kazakhstan níbi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ní ìjọ méjì. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọwọ́ àwọn tó wà níbẹ̀ yẹn máa ń dun ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn, ẹ̀yìn ọdún mẹ́ta la kúrò níbẹ̀ lọ sí ìlú Chirchik lórílẹ̀-èdè Uzbekistan. Lákòókò yẹn, àwọn ọmọ wa Vasile àti Pavel ti fẹ́yàwó. Torí náà a múra sí ọ̀ràn báwọn ọmọ wa tó kù, ìyẹn Dumitru ọmọ ọdún mẹ́wàá àti Liuba ọmọ ọdún méje, ṣe máa túbọ̀ lóye ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yékéyéké.
A lo ọdún mẹ́wàá ní orílẹ̀-èdè Uzbekistan, a sì láǹfààní láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà láàárín àkókò yẹn. Lọ́dún 1979, a kó lọ síbi tó fi ohun tó ju ẹgbẹ̀rún kan àbọ̀ kìlómítà jìnnà síbi tá a wà, ìyẹn ìlú Krasnodar, nítòsí Òkun Dúdú lápá gúúsù orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Níbẹ̀ yẹn lèmi àti Olga ti fi ọdún méjì ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà alákòókò kíkún, a sì láǹfààní láti ran àwọn míì lọ́wọ́ láti di Ẹlẹ́rìí.
A Padà sí Orílẹ̀-Èdè Moldova
Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1989, lẹ́yìn ogójì ọdún tí wọ́n ti rán wa ní ìgbèkùn, a pinnu láti padà sílé lórílẹ̀-èdè Moldova. Bá a ṣe ń débẹ̀ báyìí la bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, èyí tá a wà lẹ́nu ẹ̀ títí di ọdún 1993. Ó ju ọgbọ̀n èèyàn lọ tá a ràn lọ́wọ́ láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń fi aápọn ṣiṣẹ́. Ayọ̀ máa ń kúnnú ọkàn mi bí mo bá ronú nípa bí Jèhófà ṣe bù kún wa gẹ́gẹ́ bí ìdílé! Àmọ́, ó dùn mí nígbà tí ìyàwó mi àtàtà kú lóṣù May ọdún 2004.
Síbẹ̀, ohun ìtùnú ló jẹ́ fún mi pé àwọn ọmọ wa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àtàwọn ọmọ-ọmọ wa mẹ́rẹ̀ẹ̀rìnlá tó fi mọ́ àwọn ọmọ-ọmọ-ọmọ wa méjìdínlógún ló ń sin Jèhófà báyìí. Lóòótọ́, ìgbésí ayé ò rọrùn fún wa, àmọ́ ó yà wá lẹ́nu gan-an ni pé Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ láti dúró bí olóòótọ́ lójú àdánwò!
Bí mo ṣe ń dàgbà sí i, ara mi tí kò gbé kánkán mọ́ àtọjọ́ ogbó ò jẹ́ kí n lè ṣe tó bẹ́ẹ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Síbẹ̀, mò ń ṣe gbogbo ohun tí agbára mi bá gbé. Ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ni pé ìṣòro yòówù kó dojú kọ wá nígbèésí ayé wa, Jèhófà á dúró tì wá á sì máa fún wa ni okun àti ìṣírí tá a nílò.a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Arákùnrin Efrem Platon kú ní July 28, ọdún 2005, nígbà tí iṣẹ́ ń lọ lọ́wọ́ lórí àtigbé àpilẹ̀kọ yìí jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ti ń sìnrú nílùú Vorkuta
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Èmi àti aya mi Olga rèé lọ́dún 2002