A Mú un Dúró La Ọ̀pọ̀ Àdánwò Lílekoko Já
GẸ́GẸ́ BÍ ÉVA JOSEFSSON ṢE SỌ Ọ́
Àwùjọ kéréje lára wa ti péjọ sí àgbègbè Ujpest ti Budapest, Hungary, fún ìpàdé ráńpẹ́ kan kí a tó jáde lọ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Ọdún 1939 ni, kété kí Ogun Àgbáyé Kejì tó bẹ̀rẹ̀, a sì ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Hungary. A sábà máa ń fàṣẹ ọba mú àwọn tí wọ́n bá lọ́wọ́ nínú fífi Bíbélì kọ́ni ní gbangba nígbà náà.
NÍWỌ̀N bí ó ti jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí n óò nípìn-ín nínú ìgbòkègbodò yìí, àyà mi bẹ̀rẹ̀ sí já, mo sì nímọ̀lára pé n kò tóótun. Arákùnrin Kristẹni kan tí ó dàgbà jù mí yíjú sí mi, ó sì wí pé: “Éva, o kò ní láti bẹ̀rù. Sísin Jèhófà ni ọlá títóbi jù lọ tí ènìyàn lè ní.” Àwọn ọ̀rọ̀ agbatẹnirò àti afúnnilókun wọ̀nyẹn ṣèrànwọ́ láti mú mi dúró la ọ̀pọ̀ àdánwò ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ já.
Ipò Àtilẹ̀wá Gẹ́gẹ́ Bí Júù
Èmi ni ẹgbọ́n pátápátá nínú ìdílé Júù ọlọ́mọ márùn-ún. Ẹ̀sìn àwọn Júù kò tẹ́ Màmá lọ́rùn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí yẹ àwọn ìsìn mìíràn wò. Bí ó ṣe bá Erzsébet Slézinger, obìnrin Júù mìíràn tí òun pẹ̀lú ń wá òtítọ́ Bíbélì kiri, pàdé nìyẹn. Erzsébet mú Màmá mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyọrísí rẹ̀ sì ni pé, èmi pẹ̀lú wá di ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ jíjinlẹ̀ nínú àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ púpọ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣàjọpín ohun tí mo ti kọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.
Nígbà tí mo di ọmọ ọdún 18 ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1941, mo fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi hàn fún Jèhófà Ọlọ́run nípa ṣíṣe ìrìbọmi nínú Odò Danube. Àkókò yìí náà ni Màmá ṣe ìrìbọmi, ṣùgbọ́n Bàbá kò gba ẹ̀sìn Kristẹni tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ rí. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn ìrìbọmi mi, mo wéwèé láti di aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn ni, láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Mo nílò kẹ̀kẹ́ ológeere, nítorí náà mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ẹ̀ka ìpokẹ́míkà ti ilé iṣẹ́ ahunṣọ ńlá kan.
Ìbẹ̀rẹ̀ Àwọn Àdánwò
Ìjọba Nazi ti gbàkóso Hungary, ilé iṣẹ́ tí mo sì ti ń ṣiṣẹ́ ti bọ́ sábẹ́ ìṣàkóso àwọn ará Germany. Lọ́jọ́ kan, a ké sí gbogbo òṣìṣẹ́ pátá láti wá síwájú àwọn ọ̀gá, kí wọ́n sì búra pé gbágbágbá ni àwọn wà lẹ́yìn ìjọba Nazi. Wọn sọ fún wa pé àbájáde kíkùnà láti ṣe bẹ́ẹ̀ kò ní dára rárá. Nígbà ayẹyẹ tí a fi ní kí a kókìkí Hitler, mo dúró tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ṣùgbọ́n n ko ṣe ohun tí wọ́n ní ká ṣe. Wọ́n pè mí sínú ọ́fíìsì ní ọjọ́ náà gan-an, wọ́n fún mi ní owó oṣù mi, wọ́n sì lé mi kúrò níbi iṣẹ́. Níwọ̀n bí iṣẹ́ kò ti rọrùn láti rí, mo bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ìwéwèé mi láti di aṣáájú ọ̀nà. Ṣùgbọ́n, ní ọjọ́ kejì, mo rí iṣẹ́ tuntun kan, wọ́n sì ṣe tán láti san owó tí ó pọ̀ ju ti ilé iṣẹ́ ìṣáájú lọ.
Nísinsìnyí mo lè mú ìfẹ́-ọkàn mi láti ṣe aṣáájú ọ̀nà ṣẹ. Mo ní ọ̀pọ̀ aṣáájú ọ̀nà tí a jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀, ẹni tí a sì jọ ṣiṣẹ́ pọ̀ kẹ́yìn ni Juliska Asztalos. Bíbélì wa nìkan ni a ń lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a kò sì ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kankan láti fi lọni. Nígbà tí a bá bá àwọn tí ó fi ìfẹ́ hàn pàdé, a máa ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, tí a óò sì yá wọn ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́.
Léraléra, èmi àti Juliska ní láti yí àgbègbè ìpínlẹ̀ tí a ti ń ṣiṣẹ́ padà. Èyí jẹ́ nítorí pé gbàrà tí àlùfáà kan bá ti gbọ́ pé a ń bẹ ‘àwọn àgùntàn òun’ wò ni yóò ti kéde ní ṣọ́ọ̀ṣì pé bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá wá bẹ̀ wọ́n wò, kí wọ́n wá sọ fún òun tàbí kí wọ́n fi tó àwọn ọlọ́pàá létí. Nígbà tí àwọn tí ó fẹ́ràn wa bá ta wá lólobó, a óò gbéra lọ sí àgbègbè ìpínlẹ̀ mìíràn.
Lọ́jọ́ kan, èmi àti Juliska kàn sí ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí ó fi ìfẹ́ hàn. A ṣètò fún ìpadàbẹ̀wò, kí a lè yá a ní nǹkan kan tí yóò máa kà. Ṣùgbọ́n nígbà tí a óò fi padà dé, àwọn ọlọ́pàá ti débẹ̀, wọ́n fàṣẹ ọba mú wa, wọ́n sì mú wa lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá ní Dunavecse. Àṣé wọ́n lo ọmọkùnrin náà láti lè rí wa mú ni. Nígbà tí a dé àgọ́ ọlọ́pàá, a bá àlùfáà kan níbẹ̀, a sì mọ̀ pé òun pẹ̀lú mọ̀ nípa rẹ̀.
Àdánwò Mi Tí Ó Burú Jù Lọ
Ní àgọ́ ọlọ́pàá náà, a fá orí mi mọ́lẹ̀ kodoro, mo sì ní láti dúró ní ìhòòhò goloto níwájú àwọn ọlọ́pàá bíi méjìlá. Wọ́n fẹ́ lù mí lẹ́nu gbọ́rọ̀, wọ́n fẹ́ mọ ẹni tí ó jẹ́ olórí wa ní Hungary. Mo ṣàlàyé pé a kò ní olórí kankan àyàfi Jésù Kristi. Wọ́n fi kóńdó lù mí bí ẹní máa kú, síbẹ̀síbẹ̀ n kò da àwọn Kristẹni arákùnrin mi.
Lẹ́yìn náà, wọ́n di ẹsẹ̀ mi méjèèjì papọ̀, wọ́n ká ọwọ́ mi méjèèjì sókè, wọ́n sì dì wọ́n papọ̀. Lẹ́yìn náà, lọ́kọ̀ọ̀kan, wọ́n fipá bá mi lòpọ̀, àyàfi ẹnì kan ṣoṣo nínú àwọn ọlọ́pàá náà ni kò ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n dì mí pinpin débi pé àpá rẹ̀ ṣì wà ní ọrùn ọwọ́ mi títí di ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà. Wọ́n hùwà ìkà sí mi tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ débi pé wọ́n fi mí sí àjàalẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ méjì títí di ìgbà tí àwọn ọgbẹ́ tí ó jìn jù lọ san díẹ̀.
Àkókò Ìtura
Lẹ́yìn náà, a mú mi lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Nagykanizsa, níbi tí ọ̀pọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà. Láìka ìfisẹ́wọ̀n wa sí, ọdún méjì tí ó kún fún ayọ̀ ní ìfiwéra ni ó tẹ̀ lé e. A ṣe gbogbo ìpàdé wa ní bòókẹ́lẹ́, a sì wà gẹ́gẹ́ bí ìjọ. A tún ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà. Inú ọgbà ẹ̀wọ̀n yìí ni mo ti bá Olga Slézinger pàdé, arábìnrin Erzsébet Slézinger nípa ti ara, obìnrin tí ó fi òtítọ́ Bíbélì han èmi àti màmá mi.
Nígbà tí yóò fi di ọdún 1944, ìjọba Nazi ní Hungary ti pinnu láti rẹ́yìn àwọn Júù tí ń gbé Hungary, àní bí wọn ti ṣe ń pa wọ́n díẹ̀díẹ̀ ní àwọn àgbègbè mìíràn tí wọ́n ń gbé. Lọ́jọ́ kan, wọ́n wá mú èmi àti Olga. A kó wa sẹ́yìn ọkọ̀ ojú irin tí a fi ń kó màlúù, lẹ́yìn ìrìn àjò tí kò rọrùn dé Czechoslovakia, a dé ibi tí a ń lọ ní gúúsù Poland—àgọ́ ikú ní Auschwitz.
Lílà Á Já ní Auschwitz
Ọkàn mi balẹ̀ nígbà tí èmi pẹ̀lú Olga wà papọ̀. Ó mọ bí a ti í dẹ́rìn-ín pani àní nínú ipò tí ń dáni lágara pàápàá. Nígbà tí a gúnlẹ̀ sí Auschwitz, a fara hàn níwájú Dókítà Mengele, olórúkọ burúkú náà, ẹni tí iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ láti ya àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀dé tí kò lè ṣiṣẹ́ kúrò lára àwọn abarapá. Wọ́n á kó gbogbo àwọn tí kò lè ṣiṣẹ́ lọ sínú ilé gáàsì. Nígbà tí ó kàn wá, Mengele bi Olga pé, “Ọmọ ọdún mélòó ni ọ́?”
Pẹ̀lú ìgboyà, àti ẹ̀rín músẹ́ lójú rẹ̀, ó fèsì pé, “ọmọ 20 ọdún ni mí.” Ní tòótọ́, ọjọ́ orí Olga tó ìlọ́po méjì ìyẹn. Ṣùgbọ́n Mengele rẹ́rìn-ín, ó sì ní kí ó bọ́ sí apá ọ̀tún, bí ó ṣe bọ́ lọ́wọ́ ikú nìyẹn.
Gbogbo ẹlẹ́wọ̀n tí ó wà ní Auschwitz ni ó ní àmì níwájú aṣọ ẹlẹ́wọ̀n wọn—àwọn Júù ní Ìràwọ̀ Dáfídì, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ní àmì onígun mẹ́ta elésè àlùkò. Nígbà tí wọ́n fẹ́ rán Ìràwọ̀ Dáfídì mọ́ aṣọ wa, a ṣàlàyé pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, àmì onígun mẹ́ta elésè àlùkò sì ni à ń fẹ́. Èyí kì í ṣe nítorí pé jíjẹ́ tí a jẹ́ Júù ń tì wá lójú, àmọ́ nítorí pé, nísinsìnyí, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá. Wọ́n gbìyànjú láti fipá mú wa tẹ́wọ́ gba àmì àwọn Júù nípa títa wá nípàá àti lílù wá. Ṣùgbọ́n a dúró gbọn-in títí tí wọ́n fi gbà wá gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, mo pàdé àbúrò mi Elvira, ẹni tí mo fi ọdún mẹ́ta jù lọ. Wọ́n ti kó gbogbo ìdílé wa ẹlẹ́ni méje lọ sí Auschwitz. Èmi àti Elvira nìkan ni wọ́n gbà pé ó lè ṣiṣẹ́. Bàbá, Màmá, àti àwọn àbúrò wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti kú sínú ilé gáàsì. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, Elvira kò tí ì di Ẹlẹ́rìí, a kò sì jọ gbé ibì kan náà nínú àgọ́ náà. Ó là á já, ó lọ sí United States, ó di Ẹlẹ́rìí ní Pittsburgh, Pennsylvania, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó kú níbẹ̀ ní ọdún 1973.
Lílà Á Já ní Àwọn Àgọ́ Mìíràn
Ní ìgbà òtútù ọdún 1944 sí 1945, àwọn ará Germany pinnu láti kó àwọn tí ó wà ní Auschwitz kúrò níbẹ̀, níwọ̀n bí àwọn ará Rọ́ṣíà ti ń sún mọ́ tòsí. Nítorí náà, a kó wa lọ sí Bergen-Belsen, ní apá àríwá Germany. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí a débẹ̀, a rán èmi àti Olga lọ sí Braunschweig. Níhìn-ín ni a ti fẹ́ kí a palẹ̀ pàǹtírí mọ́ lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogún Onígbèjà ti fi bọ́ǹbù ba ibẹ̀ jẹ́. Èmi àti Olga jíròrò ọ̀ràn náà. Níwọ̀n bí kò ti dá wa lójú bóyá ṣíṣe iṣẹ́ yìí yóò lòdì sí àìdásí tọ̀tún tòsì wa, àwa méjèèjì pinnu láti má ṣe lọ́wọ́ nínú rẹ̀.
Ìpinnu wa dá họ́wùhọ́wù sílẹ̀. Wọ́n fi kòbókò nà wá, wọ́n sì mú wa lọ síwájú àwọn tí ń yìnbọn pani. Wọ́n fún wa ní ìṣẹ́jú kan ṣoṣo láti ronú lórí ọ̀ràn náà, wọ́n sì sọ fún wa pé bí a kò bá yí èrò wa padà, wọn óò yìnbọn pa wá. A fèsì pé a kò nílò àkókò kankan láti ronú nípa rẹ̀ nítorí pé a ti ṣe ìpinnu yẹn lọ́kàn wa. Ṣùgbọ́n, níwọ̀n bí ọ̀gá ibùdó náà kò ti sí níbẹ̀, tí ó sì jẹ́ pé òun nìkan ni ó lẹ́tọ̀ọ́ láti pàṣẹ kí a pa ẹnì kan, wọ́n ní láti sún pípa wá síwájú.
Láàárín àkókò kan náà, a fipá mú wa láti dúró sí àgbàlá àgọ́ náà láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀. Àwọn sójà méjì tí wọ́n gbé ìbọn lọ́wọ́ ni wọ́n ń ṣọ́ wa, wọ́n sì ń pààrọ̀ wọn ní wákàtí méjì méjì. Wọn kò fún wa lóúnjẹ, òtútù sì fẹ́rẹ̀ẹ́ pa wá kú, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ oṣù February. Ọ̀sẹ̀ kan ìfìyàjẹni yìí kọjá, ṣùgbọ́n ọ̀gágun náà kò dé. Nítorí náà a kó wa sẹ́yìn ọkọ̀ ẹrù, sí ìyàlẹ́nu wa, a tún padà bá ara wa ní Bergen-Belsen.
Nígbà yẹn, ipò èmi àti Olga ti burú gan-an. Gbogbo irun mi ti re jẹ pátápátá, ara mi sì gbóná kọjá ààlà. Agbára káká ni mo fi lè ṣiṣẹ́ díẹ̀. Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ olómi ṣooro àti ègé búrẹ́dì díẹ̀ tí wọ́n ń fún wa lójoojúmọ́ kò tó. Ṣùgbọ́n ó pọndandan pé kí a ṣiṣẹ́ nítorí pé pípa ni wọ́n ń pa àwọn tí kò lè ṣiṣẹ́. Àwọn arábìnrin tí wọ́n jẹ́ ará Germany tí a jọ ṣiṣẹ́ ní ilé ìdáná ràn mí lọ́wọ́ láti sinmi díẹ̀. Nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ń ṣèbẹ̀wò bá ti ń bọ̀, àwọn arábìnrin náà yóò ta mí lólobó, kí n bàa lè dìde dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ tábìlì ìṣiṣẹ́, bí ẹni pé mo ń ṣiṣẹ́ kára.
Lọ́jọ́ kan, Olga kò ní okun tí ó tó láti lọ sí ibi iṣẹ́ rẹ̀, lẹ́yìn náà a kò rí i mọ́. Mo pàdánù ọ̀rẹ́ àti alájọṣepọ̀ onígboyà kan, ẹni tí ó ti ràn mí lọ́wọ́ gidigidi ní àwọn oṣù tí ó ṣòro wọ̀nyẹn nínú àgọ́. Gẹ́gẹ́ bí ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi Olúwa wa, ó ti gbọ́dọ̀ rí ẹ̀bùn rẹ̀ ti ọ̀run gbà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.—Ìṣípayá 14:13.
Ìtúsílẹ̀ àti Ìgbésí Ayé Lẹ́yìn Náà
Nígbà tí ogun parí ní May 1945, tí ìdáǹdè sì dé, ó rẹ̀ mí débi pé n kò lè fò fún ayọ̀ pé a ti fọ́ àjàgà àwọn aninilára yángá nígbẹ̀yìngbẹ́yín; bẹ́ẹ̀ sì ni n kò lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ń kó àwọn tí a dá sílẹ̀ lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó fẹ́ láti gbà wọ́n wọlé. Oṣù mẹ́ta ni mo fi wà ní ilé ìwòsàn láti lè rí okun gbà padà. Lẹ́yìn náà, a gbé mi lọ sí Sweden, tí ó wá di ilé mi tuntun. Lójú ẹsẹ̀, mo kàn sí àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin mi, kò sì pẹ́ púpọ̀ tí mo fi tẹ́wọ́ gba ìṣúra ṣíṣeyebíye ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá.
Ní ọdún 1949, èmi àti Lennart Josefsson, tí ó ti sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣègbéyàwó. A ti fi òun pẹ̀lú sẹ́wọ̀n rí nígbà Ogun Àgbáyé Kejì nítorí dídi ìgbàgbọ́ rẹ̀ mú. A bẹ̀rẹ̀ sí gbé papọ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà ní September 1, 1949, a sì rán wa lọ sìn ní ìlú Borås. Ní àwọn ọdún tí a kọ́kọ́ lò níbẹ̀, a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́wàá déédéé níbẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn. Inú wa dùn láti rí ìjọ Borås tí ó di mẹ́ta láàárín ọdún mẹ́sàn-án, nísinsìnyí wọ́n ti di márùn-ún.
Kò ṣeé ṣe fún mi láti ṣe aṣáájú ọ̀nà fún ìgbà pípẹ́ nítorí pé ní ọdún 1950 a di òbí ọmọbìnrin kan, ọdún méjì lẹ́yìn náà, a bí ọmọkùnrin kan. Nípa báyìí, mo ní àǹfààní amóríyá ti kíkọ́ àwọn ọmọ wa ní òtítọ́ ṣíṣeyebíye náà tí arákùnrin olùfẹ́ ní Hungary kọ́ mi nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún 16 péré, pé: “Sísin Jèhófà ni ọlá títóbi jù lọ tí ènìyàn lè ní.”
Ní bíbojú wẹ̀yìn wo ìgbésí ayé mi, mo rí i pé mo ti nírìírí òtítọ́ ohun tí ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù kọ̀wé rẹ̀ nígbà tí ó ń rán wa létí ìfaradà Jóòbù pé: “Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú.” (Jákọ́bù 5:11) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àdánwò lílekoko dé bá mi, a ti fi ọmọ méjì, àti alábàáṣègbéyàwó wọn, àti ọmọ ọmọ wọn mẹ́fà, bù kún mi—gbogbo wọn jẹ́ olùjọsìn Jèhófà. Ìyẹn nìkan kọ́, mo tún ní ọ̀pọ̀ ọmọ àti ọmọ ọmọ nípa tẹ̀mí, àwọn kan lára wọn ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àti míṣọ́nnárì nísinsìnyí. Nísinsìnyí, ìrètí mi ńlá ni láti pàdé àwọn olólùfẹ́ mi tí wọ́n ti sùn nínú ikú, kí n sì gbá wọn mọ́ra nígbà tí wọ́n bá jí dìde láti inú isà òkú ìrántí.—Jòhánù 5:28, 29.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní Sweden lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Èmi àti ọkọ mi