Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo ni Mi Ò Ṣe ní Máa Bá Wọn Dá Sí Ọ̀ràn Ìbálòpọ̀ Nílé Ìwé?
“Ilẹ̀ ọjọ́ kan ò mọ́ rí káwọn ọmọléèwé má sọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀. Àwọn ọmọbìnrin tiẹ̀ máa ń tọ àwọn bọ̀bọ́ lọ, tí wọ́n á sì bára wọn sùn nínú ọgbà iléèwé níbẹ̀.”—Eileen, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún.
“Nílé ìwé tí mò ń lọ, àwọn abẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ máa ń ṣèṣekúṣe ní gbangba wálíà lójú àwọn ọmọléèwé yòókù, wọn ò sì kà á sí ohun tó burú.”—Michael, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún.a
ṢÉ LEMỌ́LEMỌ́ làwọn ọmọ kíláàsì rẹ máa ń sọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀? Àbí àwọn kan lára wọn ń bára wọn lò pọ̀? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi ti ọmọbìnrin kan tí kò tíì tó ọmọ ogún ọdún, tó sọ pé ṣe ni wíwà níléèwé dà bí ìgbà téèyàn “bá wà níbi tí wọ́n ti ń yàwòrán eré tí wọ́n ti ń bá ara wọn lò pọ̀.” Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ààyè máa ń gba ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó wà níléèwé dáadáa láti máa sọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ tàbí láti bá ara wọn lò pọ̀ pàápàá.
O lè gbọ́ táwọn ọmọ kíláàsì rẹ ń sọ̀rọ̀ nípa “àgbésùn” nígbà tí wọ́n bá ń sọ báwọn ṣe bá àwọn ẹlòmíì lò pọ̀ tí kálukú sì lọ nílọ ẹ̀ lẹ́yìn náà. Nígbà míì, ó lè jẹ́ pé ẹni tí wọn ò mọ̀ dáadáa ni wọ́n gbé sùn. Ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé àjèjì kan tí wọ́n kàn bá pàdé lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni wọ́n á jọ fìpàdé síbi tí wọ́n á ti bára wọn sùn. Èyí ó wù kó jẹ́ nínú àpẹẹrẹ méjèèjì yìí, ọ̀ràn àwọn tó ń gbé àgbésùn kò la ìfẹ́ lọ. Danielle, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún sọ pé: “Kò kọjá pé kéèyàn méjì wulẹ̀ tẹ́ ìfẹ́ ara wọn lọ́rùn.”
Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé ọ̀rọ̀ gbígbé àgbésùn ti di ọ̀rọ̀ tó wà lẹnu àwọn ọmọléèwé lọ́pọ̀ ilé ẹ̀kọ́. Ọmọbìnrin ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún kan gbé èrò ẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn iléèwé wọn pé: “Lẹ́yìn gbogbo òpin ọ̀sẹ̀, ńṣe làwọn ọmọléèwé á máa kóra jọ káàkiri tí wọ́n á sì máa sọ̀rọ̀ nípa ẹni tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ jọ gbéra wọn sùn, tí wọ́n á sì máa ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé fáwọn ọ̀rẹ́ wọn bó ṣe wáyé.”
Bó o bá ń gbìyànjú láti tẹ̀lé àwọn ìlànà Bíbélì, tó sì jẹ́ pé àárín àwọn èèyàn tó dà bíi pé wọn kì í rí ọ̀rọ̀ míì sọ ju ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ lọ lo bára ẹ, ṣe ni wàá dà bíi kò-rẹ́ni-bá-rìn. Bó ò bá sì ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe, o lè dẹni táwọn èèyàn á máa fi ṣe yẹ̀yẹ́. Ná, ọ̀rọ̀ ò lè ṣe kó máà rí bẹ́ẹ̀, nítorí Bíbélì sọ pé báwọn èèyàn ò bá lóye irú ọ̀nà tó ò ń tọ̀, wọ́n lè fi bọ́ràn ṣe rí lára wọn hàn nípa “sísọ̀rọ̀ [rẹ] tèébútèébú.” (1 Pétérù 4:3, 4) Síbẹ̀, kò sẹ́ni tó fẹ́ kí wọ́n fòun ṣe yẹ̀yẹ́. Nítorí náà, báwo lo ò ṣe ní bá wọn dá sí ọ̀ràn ìbálòpọ̀ nílé ìwé síbẹ̀ kó o má tìtorí ẹ̀ dẹni ẹ̀sín? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó ṣe pàtàkì pé kó o lóye ìdí ẹ̀ tí ìdẹwò ìbálòpọ̀ fi lágbára gan-an.
Mọ Irú Ẹni Tó O Jẹ́
Nígbà ìbàlágà, ara rẹ á máa tètè yí padà, wàá máa dàgbà sí i, onírúurú èrò á sì máa sọ sí ọ lọ́kàn. Àkókò yìí láá máa wù ẹ́ gan-an kó o ní ìbálòpọ̀. Má mikàn, iṣẹ́ tó yẹ kí ara ṣe ló ń ṣe yẹn. Nítorí náà, bí ọkàn rẹ bá ń fà sí obìnrin tàbí ọkùnrin mìíràn nílé ìwé jù, má ṣe rò pé ẹni burúkú pátápátá ni ẹ́ tàbí pé o kò lè wà láìṣe ìṣekúṣe. O lè jẹ́ oníwà mímọ́ bó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀!
Yàtọ̀ sáwọn èrò tó máa ń sọ kúlúkúlú lọ́kàn ẹni nígbà ìbàlágà, ohun mìíràn kan tún wà tó yẹ kó o ṣọ́ra fún. Nítorí pé gbogbo èèyàn jẹ́ aláìpé, ohun tó burú ló máa ń wù wá láti ṣe. Kódà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, ó kọ̀wé pé: “Mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi.” Pọ́ọ̀lù sọ pé àìpé òun ń mú kí òun rí ara òun bí “abòṣì.” (Róòmù 7:23, 24) Ṣùgbọ́n, ó borí àìpé rẹ̀, ìwọ náà sì lè borí ẹ̀!
Lóye Bọ́ràn Àwọn Ọmọ Kíláàsì Rẹ Ṣe Jẹ́
Bá a ṣe ṣàlàyé tẹ́lẹ̀, àwọn ọmọ kíláàsì rẹ lè máa sọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ ní gbogbo ìgbà tàbí kí wọ́n máa fi iye àwọn tí wọ́n ti jọ bá ara wọn sùn yangàn. O gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí wọ́n má bàa kó ìwà tí ò dáa ràn ẹ́. (1 Kọ́ríńtì 15:33) Àmọ́ ìyẹn ò wá ní kó o mú àwọn ọmọ kíláàsì ẹ lọ́tàá o. Kí nìdí tó ò fi gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀?
Bó ṣe ń ṣe ẹ́ náà ló ń ṣe àwọn ọmọ kíláàsì rẹ. Ó máa ń wu àwọn náà pé kí wọ́n ṣe ohun tó burú. Ṣùgbọ́n ibi tí wọ́n ti yàtọ̀ sí ìwọ ni pé, àwọn kan lára wọn lè jẹ́ “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” Tàbí kí wọ́n wá látinú ilé tí kò ti sí “ìfẹ́ni àdánidá.” (2 Tímótì 3:1-4) A lè rí lára àwọn ọmọ kíláàsì rẹ tí ò rí òbí rere fún wọn ní ìbáwí onífẹ̀ẹ́ tí wọn ò sì rí ẹni kọ́ wọn níwà ọmọlúwàbí.—Éfésù 6:4.
Láìjẹ́ pé àwọn ọmọ kíláàsì rẹ ń rí ọgbọ́n tó ju ọgbọ́n lọ, irú èyí tí ìwọ ń rí látinú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kò sí bí wọ́n ṣe fẹ́ mọ ìpalára tó wà nínú kéèyàn máa ṣe ohun tọ́kàn ẹ̀ bá ṣáà ti fẹ́. (Róòmù 1:26, 27) Ńṣe ló dà bí ìgbà táwọn òbí wọn gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó le ńlẹ̀ fún wọn, tí wọ́n sì ní kí wọ́n lọ máa wà á ní títì márosẹ̀ tí ọkọ̀ pọ̀ sí, láìtíì kọ́ wọn ní ọkọ̀ wíwà. Ọkọ̀ tí wọ́n ń wà náà lè máa dùn yìn-ìn mọ́ wọn fúngbà díẹ̀, àmọ́ jàǹbá ló máa gbẹ̀yìn ẹ̀. Nítorí náà, kí lo lè ṣe báwọn ọmọ kíláàsì rẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ níbi tó o wà tàbí tí wọ́n bá ń wá ọ̀nà láti fagbára mú kó o ṣèṣekúṣe bíi tiwọn?
Má Ṣe Bá Wọn Sọ̀rọ̀ Ìṣekúṣe
Bí àwọn ọmọ kíláàsì rẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ìṣekúṣe, ó lè ṣe ẹ́ bíi pé kó o máa tẹ́tí sí ohun tí wọ́n ń sọ tàbí kó o tiẹ̀ dá sí i kó o má bàa dá yàtọ̀ láàárín gbogbo wọn. Ìwọ wo èrò tí ìyẹn á mú kí wọ́n ní sí ẹ. Ṣé bó o bá dá sí ọ̀rọ̀ wọn, ìyẹn ò ní jẹ́ kí wọ́n máa wò ẹ́ bí ọkàn lára wọn tàbí pé ohun táwọn ń sọ wù ẹ́ pé o kàn ń díbọ́n ni?
Kí lo gbọ́dọ̀ ṣe bó bá wá di pé ìjíròrò kan tó o dá sí dédé yí padà sí ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe? Ṣé wàá kàn dìde fùú ni tí wàá sì kúrò níbẹ̀? Ohun tó yẹ kó o ṣe gan-an nìyẹn! Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:3) Nítorí náà, bó o bá kúrò níbi tí ìjíròrò náà ti ń wáyé, ìyẹn kì í ṣe pé o hùwà àrífín, o wulẹ̀ ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mú ni.
Dájúdájú, kò yẹ kí ara tì ẹ́ láti kúrò níbi táwọn èèyàn bá ti ń sọ̀rọ̀ ìṣekúṣe. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé irú àwọn ọ̀rọ̀ míì wà táwọn èèyàn á máa sọ tó jẹ́ pé ojú ò ní tì ẹ́ láti kúrò níbi tí wọ́n ti ń sọ ọ́, pàápàá bí ohun tí wọ́n ń sọ ò bá wù ẹ́ tàbí tó ò bá fẹ́ dá sí irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé àwọn kan kóra jọ lára àwọn ọmọ kíláàsì rẹ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jíròrò báwọn á ṣe lọ digun jalè. Ṣé wàá dúró tì wọ́n kó o bàa lè tẹ́tí sí ète tí wọ́n ń pa? Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn lè rò pé ara wọn ni ẹ́. Nítorí náà, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kó o bá ẹsẹ̀ rẹ sọ̀rọ̀. Ohun tó o gbọ́dọ̀ ṣe gan-an nìyẹn bó bá di pé ìjíròrò kan dédé yí padà sí ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe. Ọ̀pọ̀ ìgbà lo lè wá bí wàá ṣe bẹ́sẹ̀ rẹ sọ̀rọ̀ láìṣe bí olódodo àṣelékè tó ò sì ní tọrọ àbùkù.
Òótọ́ ni pé ó lè máà jẹ́ gbogbo ìgbà ni wàá lè máa yọra ẹ kúrò nínú ipò tí kò bára dé. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ní kẹ́ ẹ jọ máa jókòó ní kíláàsì lè gbìyànjú láti fà ẹ́ wọnú ìjíròrò lórí ìbálòpọ̀. Bọ́rọ̀ bá dà bẹ́ẹ̀, o lè sọ fún wọn láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, láìsì bú wọn, pé kí wọ́n yé pín ọkàn rẹ níyà. Bí ìyẹn ò bá ràn wọ́n, o kúkú lè ṣe bíi ti Brenda, ẹni tó sọ pé: “Mo dọ́gbọ́n sọ fún olùkọ́ wa pé kó gbé mi kúrò láàárín wọn.”
Máa Fi Òye Hùwà
Bópẹ́ bóyá, a máa rí lára àwọn ọmọ kíláàsì rẹ táá fẹ́ mọ ohun tó fà á tí o kì í fi í bá wọn dá sí ọ̀rọ̀ rírùn tí wọ́n máa ń sọ. Bí wọ́n bá béèrè pé báwo ni tìẹ ṣe jẹ́, fi òye dá wọn lóhùn. Àwọn míì wulẹ̀ lè máa béèrè nítorí àtifi ẹ́ ṣẹlẹ́yà, kó máà jẹ́ nítorí pé wọ́n fẹ́ mọ èrò rẹ ni o. Àmọ́, bó bá dà bíi pé èrò rere lẹni tó ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ ní, má ṣe jẹ́ kójú tì ẹ́ láti sọ ohun tó o gbà gbọ́ fún un. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ti fi ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ ran àwọn ọmọ kíláàsì wọn lọ́wọ́ kí wọ́n bàa lè mọrírì àwọn àǹfààní tó wà nínú gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì.b
Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀
Kí lo gbọ́dọ̀ ṣe bí akẹ́kọ̀ọ́ bíi tìẹ bá gbójú gbóyà débi tó fi lè fẹ́ fọwọ́ pa ẹ́ lára tàbí tó fẹ́ fẹnu kò ẹ́ lẹ́nu? Bó o bá jẹ́ kó ṣe é láṣegbé, ńṣe làyà ẹ̀ á ki tá a sì máa fẹ̀gbin náà lọ̀ ẹ́ nìṣó. Bíbélì ṣàpèjúwe ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó jẹ́ kí obìnrin oníwà pálapàla kan rá òun mú tó sì jẹ́ kó fẹnu ko òun lẹ́nu. Ó jẹ́ kó kó ọ̀rọ̀ sóun lórí lọ́nà tó fi hàn pé ó ń fẹ́ kí ọ̀dọ́mọkùnrin náà bá òun ṣèṣekúṣe. Ibo lọ̀ràn náà wá já sí? “Lójijì, ó ń tọ obìnrin náà lẹ́yìn, bí akọ màlúù tí ń bọ̀ àní fún ìfikúpa.”—Òwe 7:13-23.
Àmọ́, wo bí Jósẹ́fù ṣe ṣe nígbà tírú ọ̀ràn náà dojú kọ ọ́. Lemọ́lemọ́ ni aya ọ̀gá rẹ̀ ń rọ̀ ẹ́ pé kó bá òun ṣe, àmọ́ ó kọ̀ jálẹ̀. Nígbà tí obìnrin náà sì wá gbìyànjú láti rá a mú, kò fọ̀rọ̀ falẹ̀ rárá tó fi fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ.—Jẹ́nẹ́sísì 39:7-12.
Bíi ti Jósẹ́fù, ó lè pọn dandan pé kí ìwọ náà fi hàn pé o ò gbàgbàkugbà bí ọmọ kíláàsì rẹ kan tàbí ojúlùmọ̀ rẹ míì bá gbìyànjú láti fọwọ́ pa ẹ́ lára. Eileen sọ pé: “Bí bọ̀bọ́ kan bá fẹ́ fọwọ́ pa mí lára, ṣe ni màá sọ fún un pé kò máà tún dán irú ẹ̀ wò mọ́. Bó bá kọ̀ tí ò dá mi lóhùn, ṣe ni màá pariwo lé e lórí pé kó gbé ọwọ́ ẹ̀ kúrò lára mi.” Eileen wá sọ síwájú sí i nípa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n jọ ń relé ẹ̀kọ́ pé: “Wọn ò jẹ́ bọ̀wọ̀ fún ẹ, àyàfi bó o bá mú kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún ẹ.”
Àwọn ọmọ kíláàsì rẹ á bọ̀wọ̀ fún ìwọ náà bó o bá kọ̀ láti máa tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe, bó o bá ń fi ọ̀wọ̀ ṣàlàyé ọwọ́ tó o fi mú ìwà rere fún wọn nígbàkigbà tó bá yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀, tó ò sì gbojú bọ̀rọ̀ bí wọ́n bá fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ ẹ́. Àǹfààní míì tó tún máa tìdí ẹ̀ wá ni pé inú tìẹ gan-an á dùn síra ẹ. Pàtàkì jù lọ ibẹ̀ sì wá ni pé, wàá jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lójú Jèhófà!—Òwe 27:11.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́.
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
◼ Kí lo lè sọ táwọn èèyàn á fi mọ̀ pé o ò fẹ́ láti bá wọn dá sí ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe?
◼ Kí lo máa sọ, kí lo sì máa ṣe bí ọmọ kíláàsì rẹ kan bá fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ ẹ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Bí ìjíròrò bá ń yí sí ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe, bá ẹsẹ̀ rẹ sọ̀rọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Máà gbojú bọ̀rọ̀ bí wọ́n bá fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ ẹ́