ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/06 ojú ìwé 16-18
  • Ṣó Yẹ Kí Emi Àtàwọn Tá A Jọ Wà Níléèwé Jẹ́ Kòríkòsùn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣó Yẹ Kí Emi Àtàwọn Tá A Jọ Wà Níléèwé Jẹ́ Kòríkòsùn?
  • Jí!—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Yẹ Kó O Lọ́rẹ̀ẹ́
  • Àwa Kristẹni Kì Í Ṣe Anìkàndájẹ̀
  • Àwọn Ọ̀rẹ́ Tí Ò “Dọ́gba”
  • Bó O Ṣe Lè Yan Ọ̀rẹ́ Rere
  • Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Yíyan Ọ̀rẹ́ Níléèwé?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Fọgbọ́n Yan Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Àwọn Ọ̀rẹ́ Rere Àtọ̀rẹ́ Búburú
    Jí!—2004
  • Bá A Ṣe Lè Máa Ṣe Ọ̀rẹ́ Nínú Ayé Aláìnífẹ̀ẹ́ Yìí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Jí!—2006
g 4/06 ojú ìwé 16-18

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Ṣó Yẹ Kí Emi Àtàwọn Tá A Jọ Wà Níléèwé Jẹ́ Kòríkòsùn?

“Àwọn ọmọ tá a jọ wà nílé ìwé máa ń sọ̀rọ̀ nípa gbogbo bí wọ́n ṣe gbádùn ara wọn lópin ọ̀sẹ̀. Ó máa ń ká mi lára pé n kì í sí láàárín wọn.”—Michelle.a

“Nígbà míì tí n bá rí i táwọn ọ̀dọ́ kan kóra jọ, ara mi á bù máṣọ, màá sì sọ pé, ‘Àwọn wọ̀nyí mà ń gbádùn ara wọn o. Ó máa ń wù mí pé kí n wà láàárín wọn.’”— Joe.

“Kò ṣòro fún mi láti yan ọ̀rẹ́ níléèwé. Ó rọrùn bàjẹ́. Ìyẹn gan-an ló sì jẹ́ kí n níṣòro.”—Maria.

ÀÁRÍN àwọn ọmọ kíláàsì rẹ lo ti máa ń lo wákàtí tó pọ̀ jù lóòjọ́. Ọ̀pọ̀ lára ìṣòro, ìjákulẹ̀ àti àṣeyọrí táwọn tá a mẹ́nu bà yìí ń dojú kọ ló ń bá ìwọ náà fínra. Láwọn ọ̀nà kan, o lè máa rò pé ohun tẹ́ ẹ jọ máa ń ṣe pọ̀ ju èyí tíwọ àtàwọn òbí, àwọn àbúrò àtẹ̀gbọ́n tàbí àwọn Kristẹni bíi tìẹ jọ máa ń ṣe lọ. Bóyá ìdí nìyẹn tó o ṣe fẹ́ máa bá wọn ṣe wọléwọ̀de. Ṣé a wá lè sọ pé ìyẹn burú? Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ léwu? Bó bá dọ̀ràn yíyan ọ̀rẹ́ níléèwé, ṣó yẹ kéèyàn sọ wọ́n di kòríkòsùn? Irú àwọn wo ló yẹ kó o yàn lọ́rẹ̀ẹ́?

Ó Yẹ Kó O Lọ́rẹ̀ẹ́

Gbogbo wa la nílò ọ̀rẹ́, ìyẹn àwọn tá a lè jọ jẹ̀gbádùn bí nǹkan bá ṣẹnuure àtàwọn tó lè dúró tì wá bí nǹkan bá ṣọwọ́ òdì. Jésù náà lọ́rẹ̀ẹ́, ó sì gbádùn kí wọ́n jọ máa ṣe nǹkan pọ̀. (Jòhánù 15:15) Lọ́jọ́ tí wọ́n pa Jésù lórí òpó igi oró, ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, ìyẹn Jòhánù, “ọmọ ẹ̀yìn tó nífẹ̀ẹ́,” dúró tì í. (Jòhánù 19:25-27; 21:20) Ìwọ náà nílò ọ̀rẹ́ tó dà bíi Jòhánù, ìyẹn àwọn èèyàn tó máa dúró tì ọ́ nígbà dídùn àti nígbà kíkan. Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”—Òwe 17:17.

Ó ṣeé ṣe kó o máa rò pé èèyàn bíi Jòhánù lọ̀rẹ́ tó o ní níléèwé, ìyẹn ọmọ kíláàsì ẹ kan tẹ́ ẹ jọ mọwọ́ ara yín dáadáa. Ó lè jẹ́ pé àwọn nǹkan kan wà tẹ́ ẹ jọ nífẹ̀ẹ́ sí tẹ́ ẹ sì máa ń gbádùn fífọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀. Àmọ́ ẹni náà lè máà jẹ́ onígbàgbọ́ bíi tìẹ; síbẹ̀, o lè máa wò ó bí ẹni tí ò yẹ ká kà mọ́ ara “ẹgbẹ́ búburú.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Òótọ́ ni pé àwọn ọ̀dọ́ kan wà tó jẹ́ pé yàtọ̀ sí pé wọn ò kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bíi tìẹ, wọ́n níwà ọmọlúwàbí. (Róòmù 2:14, 15) Ṣùgbọ́n ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé àwọn ló yẹ kó jẹ́ kòríkòsùn ẹ?

Àwa Kristẹni Kì Í Ṣe Anìkàndájẹ̀

Kì í ṣe pé àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í dá sí àwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ bíi tiwọn o. Ó ṣe tán, bí wọ́n bá máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn, ìyẹn sísọ “àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn,” wọ́n ní láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn látinú gbogbo ẹ̀yà, gbogbo ẹ̀sìn àti gbogbo àṣà. (Mátíù 28:19) Àwọn Kristẹni kì í ta kété sáwọn tí wọ́n jọ wà níbi iṣẹ́ kan náà tàbí àwọn tí wọ́n jọ wà níléèwé, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kì í sá fáwọn aládùúgbò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe làwọn Kristẹni nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú.

Àwòkọ́ṣe tó dáa gan-an ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ lórí ọ̀ràn yìí. Ó mọ bó ṣe yẹ kéèyàn máa bá “onírúurú èèyàn” sọ̀rọ̀ kódà bí ìgbàgbọ́ wọn ò tiẹ̀ pa pọ̀. Ó kàn jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù kì í bá wọn ṣe wọlé wọ̀de ni. Ó sọ ohun tó ní lọ́kàn, ó ní: “Mo ń ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí n lè di alájọpín nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.”—1 Kọ́ríńtì 9:22, 23.

Ìwọ náà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù. Nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ. Mọ bí wàá ṣe máa fèrò wérò dáadáa pẹ̀lú wọn. Àwọn kan lára àwọn ọmọléèwé bíi tiẹ̀ lè máa wá bí àwọn náà ṣe máa mọ àwọn ìrètí tó o ní nínú Bíbélì. Ìwọ wo ọ̀ràn arábìnrin ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Janet. Wọ́n ní kóun àtàwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ kọ ọ̀rọ̀ lórí ohun díẹ̀ tí wọ́n mọ̀ nípa ara wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, lẹ́yìn náà, kálukú á wá ka ohun tí wọ́n kọ nípa ẹ̀. Ọ̀kan lára ohun tẹ́nì kan kọ nípa Janet kà pé: “Ó dà bíi pé gbogbo ìgbà ní inú ẹ̀ máa ń dùn. Dákun sọ àṣírí ohun tó máa ń múnú ẹ dùn fún wa!”

Gẹ́gẹ́ bí ìrírí tá a gbọ́ yìí, àwọn ọmọ kíláàsì ẹ kan lè fẹ́ mọ̀ nípa ohun tó o gbà gbọ́. Ẹ̀ hẹ́ẹ̀n, ó máa dáa tó bá jẹ́ pé irú wọn lo ní lọ́rẹ̀ẹ́. Ó dájú pé èyí á jẹ́ kó o láǹfààní láti ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ fún wọn. Jẹ́ káwọn ọmọ kíláàsì ẹ náà sọ òye wọn nípa kókó tẹ́ ẹ̀ ń jíròrò, kó o sì fara balẹ̀ gbọ́ wọn. Ìrírí tó o bá ní nípasẹ̀ ìfèròwérò pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ á wúlò gan-an fún ọ nígbà tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ tírú ẹ̀ bá tún wá ṣẹlẹ̀. Níléèwé tàbí níbi iṣẹ́, ìwà bí ọ̀rẹ́ á mú kó o “lè ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́ nínú ohun gbogbo.”—Títù 2:10.

Àwọn Ọ̀rẹ́ Tí Ò “Dọ́gba”

Bó ṣe wù kó rí, ọ̀tọ̀ ni pé kéèyàn máa ṣe dáadáa sí ọmọ kíláàsì ẹ̀, ọ̀tọ̀ ni pé kéèyàn jẹ́ kòríkòsùn rẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.” (2 Kọ́ríńtì 6:14) Tó o bá máa jẹ́ kóríkòsùn fẹ́nì kan, o gbọ́dọ̀ fẹ́ ohun tẹ́ni náà fẹ́, ohun kan náà ló sì gbọ́dọ̀ máa jẹ ẹ̀yin méjèèjì lógún. Ìyẹn ò sì lè ṣeé ṣe pẹ̀lú ẹni tí kì í fi ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò bíi tìẹ. Bó o bá wá lọ ń bá ọmọ kíláàsì rẹ tí kì í ṣe onígbàgbọ́ bíi tìẹ ṣe wọléwọ̀de, ó ṣeé ṣe kó sún ẹ dẹni tó lọ́wọ́ nínú àwọn ìwà burúkú tàbí kó ba àwọn ìwà rere tó o ní jẹ́.

Kí Maria tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè yẹn tó mọ̀, nǹkan ti bà jẹ́ jìnnà. Torí pé ó jẹ́ ọlọ́yàyà, àwọn èèyàn máa ń bá a ṣọ̀rẹ́, àmọ́ kì í mọ ibi tó yẹ kí irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ mọ. Ó ní: “Mo fẹ́ràn báwọn ọmọkùnrin àtọmọbìnrin ṣe máa ń gba tèmi. Mi ò mọ̀ títí tí mo fi kànjàngbọ̀n.”

Bíi ti Maria, ó lè má rọrùn fún ọ láti mọ̀ pé ọ̀rẹ́ tíwọ àtẹni tí ò gba ohun tó o gbà gbọ́ ń ṣe ti di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn. Síbẹ̀ náà, o ṣì lè gba ara ẹ lọ́wọ́ àbámọ̀ yẹn nípa pípinnu ẹni tó máa jẹ́ ojúlùmọ̀ rẹ àtẹni tí wàá yàn bí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn. Báwo lo ṣe lè ṣèyẹn?

Bó O Ṣe Lè Yan Ọ̀rẹ́ Rere

Bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, Jésù láwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Jésù ṣe bẹ́ẹ̀ nípa gbígbé ìgbé ayé tí ò lábòsí àti nípa sísọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́. Àwọn tó bá fara mọ́ ẹ̀kọ́ Jésù àtọ̀nà tó gbà gbé ìgbésí ayé ẹ̀ máa ń sún mọ́ ọn. (Jòhánù 15:14) Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn táwọn ọkùnrin mẹ́rin kan gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, “wọ́n . . . pa ohun gbogbo tì, wọ́n sì tẹ̀ lé e.” Àwọn ọkùnrin ọ̀hún, ìyẹn Pétérù, Áńdérù, Jákọ́bù àti Jòhánù di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jésù.—Lúùkù 5:1-11; Mátíù 4:18-22.

Ọ̀rọ̀ tí Jésù máa ń sọ àtàwọn ohun tó máa ń ṣe mú kó ṣe kedere pé kò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn ohun tó gbà gbọ́ àti pé kì í fi bá ẹnikẹ́ni ṣeré. Àwọn tí kò fẹ́ ohun tó fẹ́ máa ń fi í sílẹ̀ ni, ojú kì í sì í ro òun alára láti fi wọ́n sílẹ̀.—Jòhánù 6:60-66.

Bí àpẹẹrẹ, òótọ́ inú tí ọ̀dọ́kùnrin kan ní wú Jésù lórí. Bíbélì ròyìn pé: “Jésù wò ó, ó sì ní ìfẹ́ fún un.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà wá mọ ohun tí òun gbọ́dọ̀ ṣe láti lè jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù, “ó lọ kúrò.” Ó dà bíi pé ọmọlúwàbí lọ́kùnrin yẹn, àní Jésù “ní ìfẹ́ fún un.” Ṣùgbọ́n, Jésù fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ òun ṣe ju jíjẹ́ ọmọlúwàbí lọ. (Máàkù 10:17-22; Mátíù 19:16-22) Ṣé ìwọ náà á lè ṣe bíi ti Jésù?

Ìwọ àtẹni tẹ́ ẹ jọ wà níléèwé lè mọwọ́ ara yín dáadáa. Ṣùgbọ́n, o lè bi ara ẹ pé: ‘Ṣé ẹni yìí á lè ṣe ohun tí Jésù pa láṣẹ? Ṣé ẹni yìí fẹ́ kọ́ nípa Jèhófà, ìyẹn ẹni tí Jésù fún wa nítọ̀ọ́ni pé ká máa jọ́sìn?’ (Mátíù 4:10) Bó o ṣe ń fèrò wérò pẹ̀lú àwọn ọmọ kíláàsì rẹ tó o sì ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí á fara hàn kedere.

Ó dáa kó o máa ṣe dáadáa sáwọn ọmọ kíláàsì rẹ gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe ṣe sí onírúurú èèyàn. Ṣùgbọ́n, Jésù rí i dájú pé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lòun mú lọ́rẹ̀ẹ́. Ìwọ náà lè ṣe bí Jésù ṣe ṣe. ‘Tọ́jú ìwà rẹ kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀’ nílé ìwé kó o sì máa fọgbọ́n sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíràn. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, rí i dájú pé ẹni tó dáa jù lo yàn lọ́rẹ̀ẹ́.—1 Pétérù 2:12.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Ewu wo ló lè tìdí lílo àkókò ọwọ́dilẹ̀ pẹ̀lú ọmọ kíláàsì tí kì í ṣe Kristẹni bíi tẹni wá? Ṣé irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ mọ́gbọ́n dání?

◼ Lẹ́yìn tó o ti ka àpilẹ̀kọ yìí, ṣé kò ṣe ọ́ bíi pé ìwọ àtọmọ kíláàsì ẹ kan ti di kòríkòsùn? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló yẹ kó o ṣe?

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

HOW CAN I MAKE REAL FRIENDS?

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe fídíò yìí, ó sì dá lórí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó jóòótọ́ látẹnu àwọn ọ̀dọ́ tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Ítálì, ilẹ̀ Faransé àti Sípéènì. Ó wà ní oríṣi èdè mẹ́rìndínlógójì.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àwọn ọmọ kíláàsì ẹ kan lè fẹ́ mọ̀ nípa ohun tó o gbà gbọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́