ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 12/8 ojú ìwé 8-12
  • Àwọn Ọ̀rẹ́ Rere Àtọ̀rẹ́ Búburú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọ̀rẹ́ Rere Àtọ̀rẹ́ Búburú
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Níwà Ọmọlúwàbí
  • Bó O Ṣe Lè Mọ Irú Àwọn Tó Yẹ Kó O Bá Ṣọ̀rẹ́
  • Àwọn Ohun Tó Yẹ Kẹ́ Ẹ Fi Jọra
  • Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Káwọn Ọ̀rẹ́ Dàgbà Jura Wọn Lọ
  • Bó O Ṣe Lè Mú Kí Ìdè Ọ̀rẹ́ Lágbára
  • O Lè Ní Àwọn Ọ̀rẹ́ Tòótọ́
  • Bá A Ṣe Lè Rẹ́ni Bá Ṣọ̀rẹ́
    Jí!—2004
  • Fọgbọ́n Yan Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ní Àwọn Ọ̀rẹ́ Tó Dáa?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Ṣó Yẹ Kí N Ní Ọ̀rẹ́ Míì?
    Jí!—2009
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 12/8 ojú ìwé 8-12

Àwọn Ọ̀rẹ́ Rere Àtọ̀rẹ́ Búburú

Ọ̀DỌ́MỌBÌNRIN kan tá a máa pe orúkọ rẹ̀ ní Sarah sọ ohun tó ń dùn ún. Kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé apààyàn ni ọkùnrin kan báyìí tó ń bá ṣọ̀rẹ́. Ó wá béèrè pé, ‘Bí ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀ lé bá lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yẹn, báwo ni màá tún ṣe wá gbẹ́kẹ̀ lé ẹlòmíì?’ Ẹni tí Sarah ń rojọ́ fún wá bi í bóyá ó mọ irú ìwà tí ọkùnrin náà ń hù kí wọ́n tó dọ̀rẹ́. Ó fèsì pé: “Mọ̀wà tó ń hù báwo?” Ọ̀rọ̀ rè é o, Sarah ò tiẹ̀ mọ “ìwà” ẹ̀. Ìwọ náà ńkọ́? Ǹjẹ́ ò mọ irú ìwà táwọn ọ̀rẹ́ rẹ ń hù?

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sarah ti jẹ́ ká rí i pé ó yẹ kéèyàn mọ̀wà ọ̀rẹ́ ẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ikú lo fi ń ṣeré yẹn. Bí òwe kan nínú Bíbélì ṣe ṣàlàyé rẹ̀ rèé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Síbẹ̀, bíi ti Sarah, kìkì àwọn tí ‘ìná wọn bá jọ wọ̀’ lọ̀pọ̀ èèyàn máa ń yàn lọ́rẹ̀ẹ́. Gbogbo wa náà la máa ń fẹ́ láti wà pẹ̀lú ẹni tó bá ń dá wa lára yá. Ṣùgbọ́n bó bá jẹ́ ìyẹn nìkan ṣoṣo la wò tá a fi yan ọ̀rẹ́, láìronú dáadáa nípa irú ẹni téèyàn jẹ́ nínú, ó lè yọrí sí ìjákulẹ̀ ńláǹlà o. Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá ẹnì kan ní ìwà rere?

Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Níwà Ọmọlúwàbí

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àwa náà gbọ́dọ̀ níwà tó dáa tí wọ́n mọ̀ mọ̀ wá. Ó yẹ ká mọ ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, ká mọ ohun tó dáa àti ohun tó burú, ká sì máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run nígbà gbogbo. Òwe Bíbélì mìíràn sọ pé: “Irin ni a fi ń pọ́n irin. Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ṣe máa ń pọ́n ojú òmíràn.” (Òwe 27:17) Nígbà téèyàn méjì tí wọ́n níwà ọmọlúwàbí tí wọn ò sì gbàgbàkugbà bá ń bára wọn ṣọ̀rẹ́, wọ́n á lè ran ara wọn lọ́wọ́ láti má ṣe ba ọmọlúwàbí wọn jẹ́, okùn ọ̀rẹ́ wọn á wá yi sí i.

Pacôme, tó wá láti ilẹ̀ Faransé, sọ pé, “Ní tèmi o, ẹni tó bá ń tẹ́tí sí mi, tó ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ sí mi, tó sì tún máa ń bá mi wí nígbà tí mo bá ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó lèmi kà sí ọ̀rẹ́ tòótọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni, yálà wọ́n jẹ́ àgbà tàbí èwe, àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa jù fún wa láti bá rìn làwọn tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun tó tọ́ tí wọ́n sì ń tọ́ wa sọ́nà nígbà tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ohun tí kò bọ́gbọ́n mu. Bíbélì sọ pé: “Otitọ li ọgbẹ ọrẹ́.” (Òwe 27:6, Bibeli Mimọ) Kí ìwà wa bàa lè sunwọ̀n sí i ká sì lágbára sí i nípa tẹ̀mí, àwọn mìíràn tí wọ́n fẹ́ràn Ọlọ́run àtàwọn ìlànà rẹ̀ ló yẹ ká máa bá rìn. Céline, tó wá láti ilẹ̀ Faransé, níran ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sì sọ pé: “Nígbà tí mi ò rí ẹlòmíì nílé ìwé tí ìwà àti ìgbàgbọ́ tèmi àti tiẹ̀ jọra, ni mo tó mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn lọ́rẹ̀ẹ́ nínú ìjọ Kristẹni. Wọ́n ti ràn mí lọ́wọ́ gidigidi láti máa hùwà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.”

Bó O Ṣe Lè Mọ Irú Àwọn Tó Yẹ Kó O Bá Ṣọ̀rẹ́

Bó bá wù ẹ̀ pé kó o yan ẹnì kan tẹ́ ẹ jọ bá ara yín pàdé lọ́rẹ̀ẹ́, o lè bi ara ẹ léèrè pé, ‘Àwọn wo lọ̀rẹ́ ẹ̀?’ Àwọn tí ẹnì kan bá ń bá ṣe wọléwọ̀de máa ń sọ púpọ̀ nípa irú ẹni tí onítọ̀hún jẹ́. Bákan náà, ojú wo làwọn àgbààgbà àtàwọn táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún láwùjọ fi ń wo irú ẹni bẹ́ẹ̀? Láfikún sí i, ó bọ́gbọ́n mu ká kíyè sí ọwọ́ táwọn tá a fẹ́ bá dọ́rẹ̀ẹ́ fi mú wa, àti ọwọ́ tí wọ́n fi ń mú àwọn ẹlòmíì, àgàgà àwọn tí wọn ò ní lè rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn. Bí ẹnì kan kì í bá sábà hùwà àìlábòsí àti ìwà títọ́, tí ò ní sùúrù tí kì í gba ti ẹnikẹ́ni rò, kí ló fi hàn pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ kọ́ ni yóò máa hù sí ọ nígbà gbogbo?

Kéèyàn tó lè mọ ìwà ẹnì kan dáadáa, ó máa ń gba pé kéèyàn ní sùúrù, kó já fáfá kó sì yọ̀ǹda àkókò láti kíyè sí bí ẹnì náà ṣe ń ṣe sáwọn ẹlòmíì. Bíbélì sọ pé: “Ìmọ̀ràn ní ọkàn-àyà ènìyàn dà bí omi jíjìn, ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ ni yoo fà á jáde.” (Òwe 20:5) Ó yẹ ká máa bá ẹni tá a bá fẹ́ yàn lọ́rẹ̀ẹ́ sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan bí àbùdá wọn, ìdí tí wọ́n fi máa ń ṣe àwọn nǹkan, tó fi mọ́ ohun tí wọ́n kà sí ìwà ọmọlúwàbí. Irú èèyàn wo ni wọ́n jẹ́? Ṣé onínúure ni wọ́n àbí ẹni tí kì í yá mọ́ọ̀yàn? Ṣé ẹni tí kì í tètè sọ̀rètí nù àti ọlọ́yàyà ni wọ́n àbí ẹni tó máa ń tètè sọ̀rètí nù tí kì í sì í gba nǹkan gbọ́? Ṣé aláìmọtara ara ẹni ni wọ́n àbí ẹni tí kì í dá sí tẹlòmíì? Ṣé wọ́n ṣeé gbára lé àbí aláìdúróṣinṣin ni wọ́n? Bí ẹnì kan bá máa ń sọ àléébù àwọn ẹlòmíì fún ọ, báwo ni ò ṣe ní máa sọ àléébù tìẹ náà fáwọn èèyàn nígbà tó ò bá sí níbẹ̀? Jésù sọ pé: “Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.” (Mátíù 12:34) Nítorí náà, ó yẹ ká máa kíyè sí ohun táwọn èèyàn bá ń sọ.

Àwọn Ohun Tó Yẹ Kẹ́ Ẹ Fi Jọra

Àwọn kan rò pé ìwà ẹni táwọn bá máa bá ṣọ̀rẹ́ gbọ́dọ̀ jọ tàwọn ní gbogbo ọ̀nà. Ọmọdékùnrin kan tiẹ̀ fọwọ́ sọ̀yà pé òun ò jẹ́ bá ẹni tí kì í jẹ irú oúnjẹ tóun fẹ́ràn ṣọ̀rẹ́. Lóòótọ́ ni pé ó yẹ kí ìwà ọ̀rẹ́ méjì jọra kí wọ́n tó lè lóye ara wọn, ohun tó sì ṣe pàtàkì jù ni pé kí ìwà wọn àti ojú tí wọ́n fi ń wo nǹkan tẹ̀mí jọra dé ìwọ̀n àyè kan. Ṣùgbọ́n kò pọn dandan kí wọ́n rí bákan náà ní gbogbo ọ̀nà kí wọ́n sì jọ dàgbà bákan náà. Kódà, ìrírí wọn tó yàtọ̀ síra lè mú kí ọ̀rẹ́ wọn túbọ̀ jinlẹ̀ sí i kó sì ṣe àwọn méjèèjì láǹfààní.

Àpẹẹrẹ méjì tó ṣì wúlò títí dòní nípa àwọn tó bára wọn ṣọ̀rẹ́ nínú Bíbélì ni ti Jónátánì àti Dáfídì pẹ̀lú Rúùtù àti Náómì. Ohun tó mú kí ọ̀rẹ́ wọn wọ̀ ni pé wọ́n jẹ́ olùfọkànsin Ọlọ́run wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sáwọn ìlànà rẹ̀.a A lè kíyè sí i nínú ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ náà pé wọn ò fi ti ọjọ́ orí àti ìyàtọ̀ tó wà nínú ipò kálukú ṣe. Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ kọ́ wa ni ohun mìíràn nípa bíbára ẹni ṣọ̀rẹ́. Ìyẹn ni pé, àtàgbà àtọmọdé ló lóore tí wọ́n lè ṣe fúnra wọn bí wọ́n bá jọ ń ṣọ̀rẹ́.

Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Káwọn Ọ̀rẹ́ Dàgbà Jura Wọn Lọ

Àǹfààní púpọ̀ ló wà nínú kéèyàn lọ́rẹ̀ẹ́ tó dàgbà juni lọ tàbí kéèyàn lọ́rẹ̀ẹ́ tó kéré síni. Díẹ̀ rèé lára ohun táwọn ọ̀dọ́ sọ nípa ìrírí tí wọ́n ti ní.

Manuela tó wá láti Ítálì sọ pé: “Mo bá tọkọtaya kan tí wọ́n dàgbà jù mí lọ ṣọ̀rẹ́ nígbà kan báyìí. Mi ò fọ̀rọ̀ ara mi pa mọ́ fún wọn, ohun tó sì wá mú mi láyọ̀ ni pé àwọn náà máa ń sọ tinú wọn fún mi. Wọn ò fojú kéré mi nítorí pé mo jẹ́ ọmọdé. Ìyẹn sì mú kí n túbọ̀ fara mọ́ wọn pẹ́kípẹ́kí. Bí mo bá níṣòro, wọ́n máa ń ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni. Mo rí i pé nígbà tí mo bá sọ ìṣòro mi fáwọn tá a jọ jẹ́gbẹ́, nígbà míì ìmọ̀ràn táwọn ọ̀rẹ́ mi ń fún mi máa ń fi hàn pé wọn ò ro àròjinlẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rẹ́ mi àgbà ní ìrírí, wọ́n lóye, wọ́n sì mọ béèyàn ṣe ń ṣe nǹkan ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, èyí táwa ọ̀dọ́ ò tíì lè ṣe. Àwọn ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti ṣe àwọn ìpinnu tó sàn jù.”

Zuleica tó wá láti Ítálì sọ pé: “Àwa ọ̀dọ́ nìkan kọ́ la máa ń kóra jọ síbi àpèjẹ, a tún máa ń ké sí àwọn tó jù wá lọ síbẹ̀. Ní tèmi o, mo ti rí i pé nígbà táwọn àgbà àtàwọn ọmọdé bá jọ wà níbi àpèjẹ, inú gbogbo wa máa ń dùn ara wa sì máa ń yá gágá tí irú àpèjẹ bẹ́ẹ̀ bá parí. A máa ń gbádùn ara wa nítorí pé ojú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la fi ń wo nǹkan.”

Ẹ̀yin àgbà, ẹ̀yin náà lè fìfẹ́ hàn sáwọn ọmọdé. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú ọ̀rọ̀ táwọn ọ̀dọ́ sọ sílẹ̀ yìí, ọ̀pọ̀ lára wọn ló mọrírì ìrírí rẹpẹtẹ tẹ́ ẹ ní tí wọ́n sì ń gbádùn àtimáa wà pẹ̀lú yín. Amelia, opó kan tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin ọdún sọ pé: “Èmi ni mo kọ́kọ́ máa ń tọ àwọn ọmọdé lọ. Okun àti agbára wọn máa ń mórí mi yá gágá!” Bí tàgbà tèwe bá ń fúnra wọn níṣìírí bẹ́ẹ̀, rere tá á máa tìdí ẹ̀ wá á pọ̀ gan-an ni. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti bàlágà tí wọ́n sì máa ń láyọ̀ sọ pé àwọn ọ̀rẹ́ táwọn ní nígbà èwe, tí wọ́n dàgbà díẹ̀ ju àwọn lọ, tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere, tí wọ́n sì fáwọn nímọ̀ràn rere ló mú káwọn kẹ́sẹ járí.

Bó O Ṣe Lè Mú Kí Ìdè Ọ̀rẹ́ Lágbára

Kò dìgbà tó o bá wá ẹni tuntun bá ṣọ̀rẹ́, kó o tó lè lọ́rẹ̀ẹ́ àtàtà. Bó o bá ti láwọn ọ̀rẹ́ àtàtà, o ò ṣe kúkú wá nǹkan tó o lè ṣe sí i kẹ́ ẹ lè máa bá ọ̀rẹ́ yín nìṣó? Ìṣúra iyebíye gbáà làwọn ọ̀rẹ́ tọ́jọ́ ti pẹ́ tí wọ́n ti ń bára wọn bọ̀ jẹ́, ojú tó sì yẹ ká máa fi wò wọ́n náà nìyẹn. Má ṣe fojú kékeré wo jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin.

Lékè gbogbo ẹ̀, máa rántí pé nípa ṣíṣe nǹkan fáwọn ẹlòmíì, lílo àkókò rẹ àtàwọn ohun ìní rẹ fún wọn, lo fi lè rí ayọ̀ tòótọ́ àti ọ̀rẹ́ tòótọ́. Èrè tó wà níbẹ̀ pọ̀ ju ìsapá àtàwọn ohun tó ń náni lọ. Àmọ́ ṣá o, bó bá jẹ́ pé tara ẹ nìkan lò ń rò nígbà tó ò ń yan ọ̀rẹ́, o ò lè rẹ́ni bá ṣọ̀rẹ́. Nítorí náà, nígbà tó o bá ń wá ẹni tó o máa bá ṣọ̀rẹ́, má fi wọ́n mọ sáàárín àwọn tó o gba tiwọn nìkan tàbí àwọn tó o lè rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn. Máa ṣọ̀rẹ́ àwọn táwọn míì ti gbójú fò dá tàbí tó ṣòro fún láti lọ́rẹ̀ẹ́. Gaëlle, tó wá láti ilẹ̀ Faransé sọ pé: “Nígbà tá a bá ń wá àwọn èèyàn tá a jọ máa ṣe nǹkan pa pọ̀, tá a sì mọ̀ pé àwọn ọ̀dọ́ kan ń dá wà, a máa ń pe àwọn náà kúnra. A ó sọ pé: ‘Ṣé o ò jáde ni? Kúkú bá wa ká lọ. Jẹ́ á túbọ̀ mọ́ra wa dáadáa sí i.’”—Lúùkù 14:12-14.

Bó bá sì ṣẹlẹ̀ pé àwọn èèyàn tó dáa ní kó o wá báwọn ṣọ̀rẹ́, má ṣe yára sọ pé o ò ṣe o. Elisa, tó wà ní Ítálì sọ pé: “Bóyá nítorí pé àwọn kan ti dẹ́yẹ sí ẹ nígbà kan rí, ó ṣeé ṣe kí inú ṣì máa bí ẹ. O lè bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé, ‘Ṣé ọ̀rẹ́ ni mo fẹ́ jẹ ni.’ Ìyẹn lè mú kó o kóra ẹ nílẹ̀, kó o máà fẹ́ bá ẹnikẹ́ni da nǹkan pọ̀, kó o sì máa ronú nípa ara ẹ nìkan. Dípò kó o máa wá ọ̀rẹ́, ó di pé kó o máa kanrí mọ́nú.” Dípò tí wàá fi jẹ́ kí àníyàn lásánlàsàn tàbí ìmọtara ẹni nìkan sọ ọ́ dẹni tí ò fẹ́ lọ́rẹ̀ẹ́ mọ́, wá ọ̀rẹ́ síbòmíì. Ńṣe ló yẹ ká kún fọ́pẹ́ gidigidi báwọn èèyàn bá kà wá kún débi pé wọ́n fẹ́ di ọ̀rẹ́ wa.

O Lè Ní Àwọn Ọ̀rẹ́ Tòótọ́

Bó o bá fẹ́ lọ́rẹ̀ẹ́ tòótọ́, má ṣe jókòó sídìí ti pé o fẹ́ irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀, tàbí pé kí irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ wá bá ọ lọ́jọ́ kan tàbí kíka àwọn àpilẹ̀kọ bí irú èyí nìkan. Ńṣe ni kíkọ́ béèyàn ṣeé lọ́rẹ̀ẹ́ dà bíi kíkọ́ béèyàn ṣe ń gun kẹ̀kẹ́. Ìwé kíkà nìkan ò lè kọ́ wa ní gbogbo ohun tó yẹ ká mọ̀. A gbọ́dọ̀ jáde lọ dánra wò, kódà bá a bá tiẹ̀ máa ṣubú nígbà mélòó kan. Bíbélì fi hàn pé àjọṣe àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n bá fẹ́ràn Ọlọ́run ò ní bà jẹ́ láé. Kí Ọlọ́run tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti lọ́rẹ̀ẹ́ àwa náà gbọ́dọ̀ sapá láti jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn ẹlòmíì. Ṣé o ti múra tán láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́? Má ṣe jẹ́ kó rẹ̀ ọ́! Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn ọ́ lọ́wọ́, máa finú kan yan àwọn ẹlòmíì lọ́rẹ̀ẹ́, kí ìwọ náà sì jẹ́ adùn-únbárìn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a O lè kà nípa wọn nínú Bíbélì, nínú ìwé Rúùtù, Sámúẹ́lì Kìíní àti Sámúẹ́lì Kejì.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Ọ̀rọ̀ Rè É O Ẹ̀yin Òbí

Bíi tàwọn ẹ̀kọ́ míì téèyàn ń kọ́, ilé ni kíkọ́ nípa béèyàn ṣe ń ṣọ̀rẹ́ ti ń bẹ̀rẹ̀. Ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé bí ọmọ kékeré kan bá ṣe ń dàgbà, àwọn tó ń gbé e mọ́ra tí wọ́n sì ń tọ́jú ẹ̀ nínú ilé ló máa jẹ́ bí ọ̀rẹ́ fún un. Kódà bí ọmọ náà ṣe láwọn agbọ́mọjó yìí, ohun tó bá kọ́ lọ́dọ̀ àwọn ojúlamọ̀ míì ṣì máa hàn nínú ìrònú ẹ̀, bí nǹkan á ṣe máa rí lára ẹ̀, àti bá á ṣe máa hùwà. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa bí ọmọ àwọn tó bá kó lọ sí ìlú mìíràn ṣe tètè máa ń gbọ́ èdè tí wọ́n ń sọ ní ìlú náà nípa wíwulẹ̀ bá àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn ṣeré.

Gẹ́gẹ́ bí òbí, ojúṣe yín ni pé kẹ́ ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè fọgbọ́n yan ẹni tí wọ́n máa bá ṣọ̀rẹ́. Àwọn ọmọdé àtàwọn ọ̀dọ́langba ò tíì gbọ́n tó láti dá ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ láìjẹ́ pé àwọn òbí tọ́ wọn sọ́nà. Àmọ́ ṣá, ìṣòro kan wà o. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ máa ń fẹ́ fara mọ́ àwọn ọ̀dọ́ bíi tiwọn ju àwọn òbí wọn tàbí àwọn àgbàlagbà mìíràn lọ.

Àwọn ògbógi kan gbà pé ohun kan tó máa ń mú káwọn ọ̀dọ́ tọ àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn lọ dípò àwọn òbí wọn ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn òbí ló ń kọminú nípa bóyá àwọn lè kọ́ àwọn ọmọ wọn níwà tó yẹ kí wọ́n máa hù. Ó yẹ káwọn òbí bójú tó iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ wọn jẹ wọ́n lógún. (Éfésù 6:1-4) Ọ̀nà wo ni wọ́n lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Dókítà Ron Taffel, onímọ̀ nípa ọ̀ràn ìdílé bá ọ̀pọ̀ àwọn òbí tí wọn ò mọ èwo gan-an ni ṣíṣe nípa àwọn ọmọ wọn tó ti bàlágà sọ̀rọ̀. Ó kọ̀wé pé ọ̀pọ̀ lára wọn máa “ń dara dé onírúurú àbá nípa ọmọ títọ́ èyí tí wọ́n máa ń gbé sáfẹ́fẹ́” dípò káwọn fúnra wọn gẹ́gẹ́ bí òbí tọ́ àwọn ọmọ wọn. Kí ló ń mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀ ná? Ó dáhùn pé: “Wọn ò mọ àwọn ọmọ tí wọ́n bí dáadáa débi tí wọ́n á fi mọ irú ọwọ́ tí wọ́n á fi mú àwọn ọmọ náà.”

Kò yẹ kí ọ̀ràn rí bẹ́ẹ̀ yẹn ṣá o. Ó yẹ káwọn òbí mọ̀ pé àwọn ọmọ á tọ àwọn ọ̀rẹ́ wọn lọ bí wọn ò bá rí ohun tí wọ́n ń fẹ́ nínú ilé. Kí sì lohun náà? Taffel sọ pé: “Kò ju ohun táwọn ọmọdé sábà máa ń fẹ́ lọ. Ìyẹn ni ẹ̀kọ́ ilé, oríyìn, ààbò, ìlànà tó yè kooro àti mímọ ohun táwọn òbí ń retí látọ̀dọ̀ wọn dunjú, kí wọ́n sì mọ̀ pé ilé nilé àwọn. Ìṣòro tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ń dojú kọ lákòókò wa yìí ni pé àwọn àgbà kì í ṣe àwọn ohun tó jẹ́ kòṣeémánìí yìí fún wọn, nítorí náà bí àjèjì ni wọ́n máa ń rí nínú ilé tiwọn.”

Báwo lo ṣe lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ lórí ọ̀ràn ti ọlọ́rẹ̀ẹ́ dé yìí? Ohun tó yẹ kó o kọ́kọ́ ṣe ni pé kó o ṣàyẹ̀wò irú ìgbésí ayé tó ò ń gbé àti irú àwọn ọ̀rẹ́ tó o ní. Ṣé ohun tíwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ ń lépa àtiṣe àti bẹ́ ẹ ṣe ń gbé ìgbésí ayé yín dára tí kì í sì í ṣe pé tara yín nìkan lẹ̀ ń fẹ́? Ṣé nǹkan tẹ̀mí ló jẹ yín lógún ni àbí nǹkan tara? Douglas, Bàbá kan tó jẹ́ alàgbà nínú ìjọ, sọ pé: “Àwọn èèyàn tètè máa ń kíyè sí ohun tá a bá ṣe ju ohun tá a bá sọ lẹ́nu lọ, ó sì dájú pé àwọn ọmọ rẹ á máa kíyè sí ìwà rẹ àti ohun tí wọ́n bá rí tí ìwọ, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, àtàwọn ọmọ ọ̀rẹ́ rẹ bá ń ṣe.”

Kódà àwọn ẹranko kan wà tí ọgbọ́n àtinúdá máa ń mú kí wọ́n forí lakú nítorí àtidáàbò bo àwọn ọmọ wọn kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹranko mìíràn tó léwu. Ògbógi kan tó mọ̀ nípa ẹranko béárì tiẹ̀ sọ pé: “Àwọn abo béárì kì í gbà lẹ́yọ bó bá di pé kí wọ́n dáàbò bo àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ ohunkóhun tí wọ́n bá rí pé ó lè ṣèpalára fún wọn.” Ṣé kò wá yẹ káwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ òbí ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú? Ruben, tó wá láti Ítálì sọ pé: “Àwọn òbí bá mi jíròrò ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Wọ́n ràn mí lọ́wọ́ láti lóye pé irú àwọn ọ̀rẹ́ kan wà tí ò yẹ kí n bá kẹ́gbẹ́. Ohun tí mo kọ́kọ́ rò ni pé: ‘Wọ́n dé nìyẹn o! Ṣé kí n máà tiẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́ rárá ni!’ Ṣùgbọ́n mo ti wá rí i pé òótọ́ ni wọ́n ń sọ, ǹ bá sì ti ṣi ọ̀rẹ́ ní bí kì í bá ṣe ti sùúrù tí wọ́n ní.”

Láfikún sí i, tún sapá láti fojú àwọn ọmọ ẹ mọ àwọn tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere tí wọ́n á sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́ bí wọ́n ṣe lè máa lépa ohun tó dára. Francis jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin kan tó kẹ́sẹ̀ járí tó sì ń láyọ̀. Ó sọ pé: “Màmá mi kíyè sí i pé àwa ọmọ òun kì í bá ẹnikẹ́ni da nǹkan pọ̀, nítorí náà, ó wá bá wa pe àwọn ọ̀rẹ́ tó jẹ́ ọkùnrin bíi tiwa wá sílé. Ọ̀rẹ́ tó ń ṣe déédéé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ni wọ́n. Bá a ṣe mọ̀ wọ́n nìyẹn, tá a sì dọ̀rẹ́ ara wa, nínú ilé wa níbẹ̀.” Bí ìwọ náà bá sapá bẹ́ẹ̀ yẹn, irú ìgbésí ayé táwọn ọmọ ẹ ń gbé lábẹ́ ọ̀ọ̀dẹ̀ rẹ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ni àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Fara balẹ̀ kíyè sí ìwà ẹni tó o fẹ́ bá ṣọ̀rẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Bí ọjọ́ orí àti ipò ìgbésí ayé bá tiẹ̀ yàtọ̀ síra síbẹ̀, igi ọ̀rẹ́ tí kì í ṣe onímọ̀ tara ẹni nìkan á rúwé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́