ORÍ 8
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ní Àwọn Ọ̀rẹ́ Tó Dáa?
“Bínú bá ń bí mi, ó máa ń wù mí kí n rẹ́ni sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára mi fún. Bínú mi ò bá dùn, ó máa ń wù mí kí n rẹ́ni tù mí nínú. Bínú mi bá ń dùn, mo máa ń fẹ́ kí n rẹ́ni bá mi yọ̀. Ní tèmi, ọ̀rẹ́ ṣe kókó.”—Brittany.
ÀWỌN kan sọ pé ọmọdé ń fẹ́ alábàáṣeré, àmọ́ àgbàlagbà nílò ọ̀rẹ́. Kí ni ìyàtọ̀ tó wà nínú méjèèjì?
Alábàáṣeré jẹ́ ẹni tẹ́ ẹ kàn jọ máa ń ṣeré pọ̀.
Ọ̀rẹ́ rẹ ni ẹni tó jẹ́ pé ẹ tún jọ máa ń nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ohun kan náà.
Bíbélì sì tún sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Ṣé o wá rí i pé irú ọ̀rẹ́ tí ibí yìí ń sọ ti kọjá alábàáṣeré kan lásán tí ọmọdé máa ń ní nígbà kékeré?
Òótọ́ ọ̀rọ̀: Bó o ṣe ń dàgbà sí i, o nílò àwọn ọ̀rẹ́ tó
1. Ní ìwà tó dáa
2. Máa ń ṣe àwọn ohun tó bá ìlànà rere mu
3. Máa ní ipa rere lórí rẹ
Ìbéèrè: Báwo lo ṣe lè rí àwọn ọ̀rẹ́ tí ìwà wọn bá àwọn ohun tá a sọ yìí mu? Jẹ́ ká gbé àwọn nǹkan yìí yẹ̀ wò ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.
Àkọ́kọ́ Nínú Ohun Tá A Fi Ń Mọ Ọ̀rẹ́ Tó Dáa: Ìwà Tó Dáa
Ohun tó yẹ kó o mọ̀. Kì í ṣe gbogbo ẹni tó pe ara rẹ̀ ni ọ̀rẹ́ èèyàn ló ń hùwà tí wọ́n fi lè jẹ́ ọ̀rẹ́ tó dáa. Bíbélì pàápàá sọ pé: “Àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wà tí wọ́n nítẹ̀sí láti fọ́ ara wọn sí wẹ́wẹ́ lẹ́nì kìíní-kejì.” (Òwe 18:24) Ọ̀rọ̀ yìí lè dà bí àsọdùn. Àmọ́ ro èyí wò ná: Ǹjẹ́ ẹnì kan ti pe ara rẹ̀ ní ọ̀rẹ́ rẹ rí, tó sì wá rẹ́ ẹ jẹ? Àbí ẹnì kan wà tó pe ara rẹ̀ ní ọ̀rẹ́ rẹ, tó wá ń bà ẹ́ lórúkọ jẹ́? Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú kó o má fọkàn tán ọ̀rẹ́ yẹn mọ́.a Bó bá dọ̀rọ̀ ká lọ́rẹ̀ẹ́, máa fi sọ́kàn pé, iye ọ̀rẹ́ tó o ní kọ́ ló ṣe pàtàkì, bí kò ṣe pé kí èyí tó o bá ní jẹ́ ojúlówó ọ̀rẹ́!
Ohun tó o lè ṣe. Àwọn tó ní ìwà dáadáa, tó ṣeé fara wé, ni kó o yàn lọ́rẹ̀ẹ́.
“Gbogbo èèyàn ló máa ń sọ ohun tó dáa nípa Fiona ọ̀rẹ́ mi. Mo fẹ́ káwọn èèyàn máa sọ ohun tó dáa nípa èmi náà. Ó wù mí kí wọ́n mọ èmi náà sí èèyàn rere. Ìwà ẹ̀ dáa gan-an ni.”—Yvette, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17].
Gbìyànjú èyí wò.
1. Ka Gálátíà 5:22, 23.
2. Wá bi ara rẹ pé, ‘Ṣé àwọn ọ̀rẹ́ mi ń hùwà tó bá “èso ti ẹ̀mí” mu?’
3. Kọ orúkọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ sórí ìlà tó wà nísàlẹ̀ yìí. Wá kọ ìwà ẹnì kọ̀ọ̀kan síwájú orúkọ rẹ̀.
Orúkọ
․․․․․
Ìwà
․․․․․
Àkíyèsí: Bó bá jẹ́ pé ìwà tí kò dáa lò ń rántí nípa wọn, á dáa kó o wá àwọn ọ̀rẹ́ míì!
Ohun Kejì Tá A Fi Ń Mọ Ọ̀rẹ́ Tó Dáa: Ṣíṣe Ohun Tó Bá Ìlànà Rere Mu
Ohun tó yẹ kó o mọ̀. Bó o bá ń fi ìkánjú yan ọ̀rẹ́, àfàìmọ̀ lo ò ní láwọn ọ̀rẹ́kọ́rẹ̀ẹ́. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Àwọn tí ẹsẹ Bíbélì yìí pè ní “àwọn arìndìn” kì í ṣe àwọn ẹni tí kò mọ̀wé tàbí àwọn tó ya ọ̀dẹ̀ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó túmọ̀ sí àwọn tí wọ́n ya olórí kunkun tí wọ́n sì ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tí kò bójú mu. Kò yẹ kó o fi irú wọn ṣe ọ̀rẹ́!
Ohun tó o lè ṣe. Dípò tí wàá fi máa bá ẹni tó bá ṣáà ti wù ẹ́ ṣọ̀rẹ́, ṣe ni kó o ṣọ́ irú àwọn tí wàá máa yàn lọ́rẹ̀ẹ́. (Sáàmù 26:4) Kò túmọ̀ sí pé wàá kàn máa ka àwọn èèyàn kan sí ẹni tí kò dáa o. Ohun tá à ń sọ ni pé, tó o bá fẹ́ yan ọ̀rẹ́, kó o lo òye láti fi “rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tí ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.”—Málákì 3:18.
“Mo dúpẹ́ pé àwọn òbí mi ràn mí lọ́wọ́ tí mo fi láwọn ọ̀rẹ́, ìyẹn àwọn tá a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ tí wọ́n ń sin Ọlọ́run dáadáa.”—Christopher, ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13].
Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Tí mo bá wà lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi, ṣé ẹ̀rù máa ń bà mí pé wọ́n lè mú kí n ṣe ohun tí mo mọ̀ pé kò dáa?
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
Ṣé mi kì í fẹ́ fi àwọn ọ̀rẹ́ mi han àwọn òbí mi torí wọ́n lè sọ pé àwọn ò fẹ́ kí n máa bá wọn rìn?
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
Àkíyèsí: Bó o bá dáhùn bẹ́ẹ̀ ni sáwọn ìbéèrè yìí, ṣe ni kó o wá àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n níwà tó dáa, ìyẹn àwọn tó ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run dáadáa.
Ohun Kẹta Tá A Fi Ń Mọ Ọ̀rẹ́ Tó Dáa: Ó Máa Ní Ipa Rere Lórí Rẹ
Ohun tó yẹ kó o mọ̀. Bíbélì sọ pé: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Lauren sọ pé: “Nítorí pé mi ò ṣe ohun táwọn ọmọ iléèwé mi ń fẹ́ kí n máa ṣe, wọn ò gba tèmi. Nígbà tó sì di pé mi ò rẹ́ni bá rìn mọ́, mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bíi tiwọn.” Lauren wá rí i nígbà tó yá pé, tó bá ti jẹ́ pé ohun táwọn ẹlòmíì ń fẹ́ lo kàn máa ń ṣe, ṣe lo máa dà bí ọmọ ayò lọ́wọ́ wọn, àwọn lá máa tì ẹ́ síbi tí wọ́n bá fẹ́. Ìwọ náà sì mọ̀ pé ìyẹn ò pọ́n ẹ lé!
Ohun tó o lè ṣe. Táwọn kan bá fẹ́ fipá mú ẹ pé kó o máa ṣe bíi tàwọn, má ṣe bá wọn ṣọ̀rẹ́ mọ́. Tó o bá ṣe èyí, àwọn ọ̀rẹ́ tó o máa ní lè má fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ o, àmọ́ inú rẹ máa dùn pé o ṣe ohun tó tọ́, wàá sì lè ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi, ìyẹn àwọn ọ̀rẹ́ tó máa ní ipa rere lórí rẹ.—Róòmù 12:2.
“Èèyàn jẹ́jẹ́ tórí ẹ̀ pé tó sì láàánú ni Clint ọ̀rẹ́ mi àtàtà, alábàárò gidi ló jẹ́ fún mi.”—Jason, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21].
Bí ara rẹ láwọn ìbéèrè yìí:
Ṣé mò ń yí ìmúra mi, bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ tàbí bí mo ṣe ń ṣe nǹkan pa dà sí èyí tí kò dáa kí n lè tẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ mi lọ́rùn?
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
Ṣé mo máa ń lọ sáwọn ibi tí kò yẹ ọmọlúwàbí, ká ní kì í ṣe torí tàwọn ọ̀rẹ́ mi?
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
Àkíyèsí: Bó o bá dáhùn bẹ́ẹ̀ ni sáwọn ìbéèrè yìí, a jẹ́ pé o nílò ìrànlọ́wọ́ nìyẹn. Ó máa dáa kó o sọ fáwọn òbí rẹ tàbí kó o lọ bá àgbàlagbà míì pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bó o bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o lè sọ fún alàgbà kan nínú ìjọ pé ò ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ lórí bó o ṣe lè yan àwọn ọ̀rẹ́ tó máa ní ipa rere lórí rẹ.
KÀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 9, NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ
Ṣé ọ̀rẹ́ rẹ kan, tàbí ọkàn ìwọ fúnra rẹ pàápàá, máa ń tì ẹ́ láti ṣe ohun tí kò dáa? Kí lo lè ṣe?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ṣùgbọ́n kò sẹ́ni tí kì í ṣàṣìṣe o. (Róòmù 3:23) Torí náà, bí ọ̀rẹ́ rẹ bá ṣe ohun tó dùn ẹ́, àmọ́ tó fi tọkàntọkàn bẹ̀bẹ̀ pé kó o dárí ji òun, má gbàgbé pé “ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.”—1 Pétérù 4:8.
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Ọ̀rẹ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.”—Òwe 18:24.
ÌMỌ̀RÀN
Máa gbé ìgbé ayé rẹ lọ́nà tó bá ìlànà rere mu, àwọn tó fẹ́ máa hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ lè torí ìyẹn wá bá ẹ ṣọ̀rẹ́. Irú wọn ló sì ń di ọ̀rẹ́ àtàtà!
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àmọ́ tó bá dọ̀rọ̀ ẹni tó máa gbà ní ‘àlejò sínú àgọ́ rẹ̀,’ kì í ṣe gbogbo èèyàn ló kàn ń gbà láyè.—Sáàmù 15:1-5.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Ohun tí màá ṣe kí n lè ní àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa ni pé ․․․․․
Lára àwọn tó dàgbà jù mí lọ tí màá fẹ́ sún mọ́ dáadáa ni ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ dádì tàbí mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
Kí Lèrò Ẹ?
● Àwọn ìwà wo ló wù ẹ́ jù pé kí ọ̀rẹ́ rẹ ní, kí sì nìdí?
● Àwọn ìwà wo ló yẹ kó o ní kó o bàa lè jẹ́ ọ̀rẹ́ àtàtà?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 60]
“Nígbà táwọn òbí mi sọ pé kí n má ṣe bá àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi rìn mọ́, mo sọ lọ́kàn ara mi pé àwọn tí wọ́n sọ yìí nìkan ni mo rí pé mo lè máa bá rìn ní tèmi. Àmọ́, ìmọ̀ràn tó dáa làwọn òbí mi fún mi, nígbà tí mo sì wá ronú lórí ọ̀rọ̀ wọn dáadáa, mo rí i pé àwọn èèyàn tí ìwà wọn dáa tiẹ̀ pọ̀ nílẹ̀ tí mo lè bá ṣọ̀rẹ́.”—Cole
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 61]
Gbìyànjú Àwọn Àbá Yìí
Bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe lè yan ọ̀rẹ́. Ní kí wọ́n sọ irú àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ọ́ bíi tìẹ. Ǹjẹ́ wọ́n kábàámọ̀ nítorí irú àwọn tí wọ́n yàn lọ́rẹ̀ẹ́? Bí wọ́n bá kábàámọ̀, kí nìdí? Ní kí wọ́n sọ ohun tó o lè ṣe tó ò fi ní kó sínú irú ìṣòro tí wọ́n ní nígbà yẹn.
Fi àwọn ọ̀rẹ́ rẹ han àwọn òbí rẹ. Tí kò bá yá ẹ lára láti fi àwọn ọ̀rẹ́ rẹ han àwọn òbí rẹ, á dáa kó o bi ara rẹ pé, ‘Kí ló fà á?’ Ǹjẹ́ àwọn nǹkan kan wà táwọn ọ̀rẹ́ rẹ ń ṣe tó o mọ̀ pé àwọn òbí rẹ ò ní fọwọ́ sí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o túbọ̀ máa ṣọ́ irú àwọn tí wàá yàn lọ́rẹ̀ẹ́.
Máa fetí sílẹ̀ dáadáa. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ máa jẹ ẹ́ lógún.—Fílípì 2:4.
Máa dárí jini. Má retí pé káwọn ọ̀rẹ́ rẹ máa ṣe gbogbo nǹkan láìsí àṣìṣe kankan. “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.”—Jákọ́bù 3:2.
Fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lómìnira díẹ̀. Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa dá ẹ lóhùn nígbà tó o bá nílò wọn, torí náà kò yẹ kó o máa so mọ́ wọn káàkiri.—Oníwàásù 4:9, 10.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 63]
Tó bá jẹ́ ohun táwọn ẹlòmíì ń fẹ́ lo kàn máa ń ṣe torí kí wọ́n lè gba tìẹ, ṣe lo dà bí ọmọ ayò lọ́wọ́ wọn, tí wọ́n ń tì síbi tí wọ́n bá fẹ́