ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 12/8 ojú ìwé 4-8
  • Bá A Ṣe Lè Rẹ́ni Bá Ṣọ̀rẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Rẹ́ni Bá Ṣọ̀rẹ́
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wá Bó O Ṣe Máa Lọ́rẹ̀ẹ́
  • Jẹ́ Kí Wọ́n Mọnú Ẹ!
  • Bó O Bá Fẹ́ Lọ́rẹ̀ẹ́, Ìwọ Náà Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Ọ̀rẹ́
  • Fi Ọ̀wọ̀ Àwọn Ẹlòmíràn Wọ̀ Wọ́n
  • Má Ṣe Retí Pé Ọ̀rẹ́ Rẹ Ò Gbọ́dọ̀ Ṣàṣìṣe
  • Àwọn Ọ̀rẹ́ Tó Ń Dúró Tini Lọ́jọ́ Ìṣòro
  • Àwọn Ọ̀rẹ́ Rere Àtọ̀rẹ́ Búburú
    Jí!—2004
  • Bí o Ṣe Lè Ní Ọ̀rẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Fọgbọ́n Yan Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • N Kò Ṣe Lè Ní Ọ̀rẹ́ Pẹ́ Títí?
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 12/8 ojú ìwé 4-8

Bá A Ṣe Lè Rẹ́ni Bá Ṣọ̀rẹ́

ÌWÉ In Search of Intimacy sọ pé: “Dídáwà kì í ṣe àìsàn. Ó dáa kéèyàn mọ̀ pé òun dá wà. . . , àmì pé èèyàn ò lálábàárò kankan ló jẹ́.” Bí ebi ṣe máa ń mú ká wá oúnjẹ tó ń fára lókun jẹ, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ kí mímọ̀ pé a dá wà mú ká wá àwọn tó dáa bá ṣọ̀rẹ́.

Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Yaël, ọ̀dọ́mọbìnrin kan nílẹ̀ Faransé sọ pé “àwọn kan kì í fẹ́ bá ẹlòmíì da nǹkan pọ̀.” Ṣùgbọ́n ìdí yòówù tí ì báà mú ká máa ya ara wa sọ́tọ̀, ìyẹn ò ní yanjú ìṣòro wa o, ó sì dájú pé á wulẹ̀ mú ká túbọ̀ máa dá wà ni. Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan; gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.” (Òwe 18:1) Nítorí náà, ó yẹ ká kọ́kọ́ gbà pé ó yẹ ká lọ́rẹ̀ẹ́ ká tó wá bá a ṣe máa ní in.

Wá Bó O Ṣe Máa Lọ́rẹ̀ẹ́

Dípò kó o máa káàánú ara ẹ tàbí kó o máa jowú àwọn tó dà bí ẹni pé wọ́n lọ́rẹ̀ẹ́ tó pọ̀ jù ọ́ lọ tàbí tí nǹkan ń lọ déédéé láàárín àwọn àtọ̀rẹ́ wọn, o ò ṣe kúkú ṣe bíi ti Manuela tó wá láti orílẹ̀-èdè Ítálì? Ó sọ pé: “Èmi tiẹ̀ máa ń rò pé nítorí pé mo jẹ́ ọ̀dọ́ ni wọ́n ṣe ń dẹ́yẹ sí mi. Kí ìyẹn lè kúrò lára ìṣòro mi, mo fara balẹ̀ kíyè sí àwọn tó lọ́rẹ̀ẹ́ tó dáa. Lẹ́yìn náà ni mo wá sapá láti máa hùwà bíi tiwọn, mo sì túbọ̀ ń ṣe ohun tó máa ń gbádùn mọ́ àwọn èèyàn.”

Ohun kan tá á ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni pé kó o máa túnra ṣe kó o sì máa ro èrò tó dá a nípa àwọn míì. Bó o bá ń jẹ oúnjẹ tó dáa, tó ò ń fúnra ẹ nísinmi dáadáa, tó o sì ń ṣeré ìdárayá níwọ̀n tára ń fẹ́, ara ẹ á dá ṣáṣá, ìrísí ẹ á sì fani mọ́ra. Bó o bá ń mọ́ tónítóní, tó o sì ń túnra ṣe dáadáa, kì í ṣe pé wàá ṣeé rí mọ́ọ̀yàn nìkan ni ṣùgbọ́n àwọn èèyàn á tún máa fọ̀wọ̀ wọ̀ ẹ́. Àmọ́ ṣá o, má ṣe di ẹni tó ń ṣàníyàn jù nípa ìrísí rẹ o. Gaëlle tó wá láti ilẹ̀ Faransé sọ pé: “Ríró dẹ́dẹ́ àti kíkàn dudu kọ́ lèèyàn fi ń wá ọ̀rẹ́ o. Ohun tó o jẹ́ ní inú lọ́hùn-ún ló ṣe pàtàkì lójú àwọn èèyàn rere.”

Ó ṣe tán, ohun tá à ń finú rò àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa máa ń hàn nínú ohun tá à ń sọ àti ojú tá a fi ń wo nǹkan. Ṣé bí nǹkan ṣe ń lọ sí máa ń fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀ tó sì máa ń mú kó o láyọ̀? Ìyẹn ni ò ní jẹ́ kó o máa rojú kókó. Ẹ̀rín tó dénú ló máa ń fa àwọn èèyàn mọ́ra jù, àti pé gẹ́gẹ́ bí Roger E. Axtell, onímọ̀ nípa ìṣarasíhùwà ẹ̀dá ṣe sọ, “bó ṣe wà kárí ayé nìyẹn àwọn èèyàn sì ti lóye ẹ̀ bẹ́ẹ̀.”a Láfikún sí ìyẹn, tún jẹ́ ẹni tó meré ṣe, àwọn èèyàn á sì nífẹ̀ẹ́ rẹ.

Má ṣe gbà gbé pé inú lọ́hùn-ún nirú ànímọ́ wọ̀nyẹn ti ń wá. Nítorí náà, ṣe ni kó o máa ronú nípa ohun tó gbámúṣé kó o má sì jẹ́ kí nǹkan tètè máa gbòdì lára ẹ. Máa ka àwọn nǹkan tó gbádùn mọ́ni àtàwọn ẹ̀kọ́ tó jíire, irú bí ọ̀rọ̀ tó ń lọ, onírúurú àṣà ìbílẹ̀ àtàwọn nǹkan ìṣẹ̀dá. Máa gbọ́ orin tó ń dáni lára yá. Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ káwọn nǹkan tó o bá wò nínú tẹlifíṣọ̀n àti sinimá àtàwọn nǹkan tó o bá kà nínú ìwé ìtàn mú kó o máa lérò tí ò tọ́. Fi sọ́kàn pé gbogbo bó o ṣe ń rí i táwọn èèyàn máa ń ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n kọ́ ló rí lójú ayé, o wulẹ̀ jẹ́ bí ẹnì kan ṣe ronú ni.

Jẹ́ Kí Wọ́n Mọnú Ẹ!

Zuleica, tó ń gbé ní Ítálì níran ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Nígbà tí mo wà ní kékeré, mo máa ń tijú, ó sì ṣòro fún mi láti lọ́rẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé béèyàn bá fẹ́ lọ́rẹ̀ẹ́, ó gbọ́dọ̀ túra ká, kó máa báwọn ẹlòmíì sọ̀rọ̀ kó sì di ojúlùmọ̀ wọn.” Bó ṣe rí nìyẹn o, bá a bá fẹ́ lọ́rẹ̀ẹ́ gidi, a gbọ́dọ̀ máa sọ tinú wa jáde, káwọn èèyàn bàa lè mọ irú ẹni tá a jẹ́ gan-an. Ó rọrùn fẹ́ni tó báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ tó sì ń bá wọn fèrò wérò lọ́nà bẹ́ẹ̀ láti lọ́rẹ̀ẹ́ ju ẹni tó ń ró dẹ́dẹ́ tó ń kàn dudu, tàbí ẹni tó ń fi nǹkan ṣe fọ́rífọ́rí. Ọ̀mọ̀wé Alan Loy McGinnis, tó jẹ́ olùgbaninímọ̀ràn sọ pé: “Kò sẹ́ni tí ò lè lọ́rẹ̀ẹ́ tímọ́tímọ́ tí okùn ọ̀rẹ́ wọn á yi, ì báà jẹ́ àwọn tí kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀, alágbaja èèyàn, ọ̀dọ́, àgbà, èèyàn tútù, olóye, ẹni tí ò mọ ara mú, tàbí ẹni tó moge ṣe; ṣùgbọ́n ànímọ́ kan ṣoṣo tí gbogbo wọn sábà máa ń ní ni pé wọ́n máa ń sọ ohun tó bá wà nínú wọn jáde. Wọn ò ṣónú, nítorí náà kò ṣòro fáwọn èèyàn láti mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn.”

Èyí ò wá túmọ̀ sí pé kó o máa tò bòròbòrò tí wàá fi sọ àṣírí ẹ fẹ́ni tẹ́ ò jọ mọwọ́ ara yín o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni pé kó o mọ ohun tí wàá sọ fáwọn ẹlòmíì lára ohun tó wà lọ́kàn ẹ àti bí nǹkan ṣe rí lára ẹ gan-an, kó o sì máa sọ ọ́ díẹ̀díẹ̀. Michela, tó wá láti Ítálì sọ pé: “Ìṣòro tí mo kọ́kọ́ ní ni pé n kì í sọ bí nǹkan bá ṣe rí lára mi. Mo ní láti ṣe àwọn ìyípadà, kí n lè túbọ̀ máa sọ tinú mi jáde, káwọn ọ̀rẹ́ mi bàa lè mọ ohun tó wà lọ́kàn mi kí ọwọ́ wa sì wọ ọwọ́.”

Kódà, bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó máa ń yá mọ́ni ni ọ́, ó ṣì máa gba àkókò àti jíjùmọ̀ ṣe nǹkan pọ̀ kí ọ̀rẹ́ méjì tó lè mọwọ́ ara wọn. Kí ọ̀rọ̀ tó dà bẹ́ẹ̀, rí i pé o ò ṣàníyàn jù nípa ohun táwọn míì lè máa rò nípa rẹ. Elisa tó wà ní orílẹ̀-èdè Ítálì rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Ìṣòro mi ni pé nígbàkigbà tí mo bá ní nǹkan lọ́kàn, ẹ̀rù máa ń bà mí pé mo lè má sọ ọ́ dáadáa. Nígbà tó yá ni mo wá ronú pé, ‘Bó bá jẹ́ pé ọ̀rẹ́ mi làwọn èèyàn yìí lóòótọ́, ohun tó ń ṣe mí á yé wọn.’ Nítorí náà, bí mo bá ṣi nǹkan kan sọ, màá wulẹ̀ fi ara mi rẹ́rìn-ín ni, àwọn yòókù náà á sì gbé ẹ̀rín.”

Nítorí náà, fọkàn ẹ balẹ̀! Máa ṣe bí Ọlọ́run ṣe dá ẹ. Dídíbọ́n ò lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ o. Ẹnì kan tó ń gba ìdílé nímọ̀ràn, F. Alexander Magoun, sọ pé: “Kò sí béèyàn ṣe lè fani mọ́ra ju pé kó máa ṣe bí Ọlọ́run ṣe dá a.” Àwọn èèyàn tó ní ojúlówó ayọ̀ kì í díbọ́n, wọn kì í sì í gbìyànjú láti ṣe fọ́ńté lójú àwọn ẹlòmíì. Bá a bá ń fòótọ́ ṣe nǹkan, ó dájú pé a óò rẹ́ni tó dáa bá ṣọ̀rẹ́. Bákan náà, kò yẹ ká retí pé káwọn míì yí ohun tí wọ́n jẹ́ padà. Àwọn èèyàn aláyọ̀ máa ń gba àwọn ẹlòmíràn bí wọ́n ṣe rí ni, wọn kì í sì í bínú lé nǹkan tí ò tó nǹkan lórí. Kì í ṣe wọ́n bíi pé kí wọ́n tún àwọn ọ̀rẹ́ wọn dá kí wọ́n bàa lè máa ṣe bí wọ́n ṣe rò pé ó tọ́ lójú àwọn. Sapá kí ìwọ náà lè jẹ́ irú èèyàn aláyọ̀ bẹ́ẹ̀, tí kì í rí kìkì àṣìṣe táwọn míì ń ṣe.

Bó O Bá Fẹ́ Lọ́rẹ̀ẹ́, Ìwọ Náà Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Ọ̀rẹ́

Ohun kan tún wá wà o, ìyẹn gan-an ló sì ṣe pàtàkì jù. Ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn, Jésù fi hàn pé ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan ni kì í jẹ́ kí àjọṣe ẹ̀dá bà jẹ́. Ẹ̀kọ́ tó fi kọ́ni ni pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.” (Lúùkù 6:31) Bẹ́ẹ̀ ni o, ọ̀nà kan ṣoṣo téèyàn lè gbà ní ọ̀rẹ́ gidi ni pé kóun náà jẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan àti ọ̀làwọ́. Ká kúkú sọ pé, bó o bá fẹ́ lọ́rẹ̀ẹ́, ìwọ náà gbọ́dọ̀ ṣe bí ọ̀rẹ́. Ohun tó máa ń jẹ́ kí okùn ọ̀rẹ́ yi ni pé kéèyàn máa wá nǹkan ṣe fáwọn ẹlòmíì dípò kéèyàn kàn máa gba tọwọ́ wọn. Bí ohun tá a fẹ́ bá yàtọ̀ sí tọ̀rẹ́ wa, tó sì jẹ́ pé ìyẹn ló máa rọrùn fún wa jù lọ, ó ṣì yẹ ká fi tọ̀rẹ́ wa ṣáájú.

Manuela, tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹ̀ tán sọ pé: “Bí Jésù ṣe sọ gan-an ló rí, nínú fífúnni layọ̀ tòótọ́ wà. Ẹni tó rí nǹkan gbà á láyọ̀, ṣùgbọ́n ẹni tó fún èèyàn ní nǹkan ló máa láyọ̀ jù. Bá a bá béèrè bí nǹkan ṣe ń lọ sí lọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ wa, ara fífúnni náà ni. Bá a bá tún gbìyànjú láti lóye àwọn ìṣòro tí wọ́n ń bá yí tá a sì ń ṣe gbogbo nǹkan tó bá wà ní ìkáwọ́ wa láìṣẹ̀ṣẹ̀ retí pé kí wọ́n bi wá, à ń fún wọn ní nǹkan náà ni.” Nítorí náà, ìwọ ni kó o kọ́kọ́ fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, tó fi mọ́ àwọn ọ̀rẹ́ tó o ti ní tẹ́lẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe yín jẹ́. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ohun tí ò tó nǹkan tàbí lílé nǹkan tí ò ní láárí ba ọ̀rẹ́ yín jẹ́. Àwọn ọ̀rẹ́ ẹni máa ń fẹ́ kéèyàn lo àkókò pẹ̀lú àwọn, kéèyàn sì fetí sí àwọn. Ruben, tó wá láti Ítálì kọ̀wé pé: “Ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó lè lọ́rẹ̀ẹ́ tó máa tọ́jọ́. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó máa ń pẹ́ díẹ̀ kéèyàn tó lè di ẹni tó ń fetí sílẹ̀ láti gbọ́ ti ẹlòmíì. Gbogbo wa la lè túbọ̀ kọ́ béèyàn ṣe ń fara balẹ̀ gbọ́rọ̀ ká sì túbọ̀ máa tẹ́tí sí ohun tí wọ́n bá ń sọ láì já lù wọ́n.”

Fi Ọ̀wọ̀ Àwọn Ẹlòmíràn Wọ̀ Wọ́n

Ohun pàtàkì mìíràn tó tún máa ń jẹ́ kí ọ̀rẹ́ tọ́jọ́, kó sì máa fúnni láyọ̀ ni bíbọ̀wọ̀ fúnra ẹni. Èyí tó ń béèrè pé kéèyàn máa fàyè gba èrò àwọn ẹlòmíràn. Bí àpẹẹrẹ, wàá fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ ẹ fi ọgbọ́n àti òye bá ọ lò bí èrò wọn tàbí ohun tí wọ́n fẹ́ bá yàtọ̀ sí tìẹ, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ṣé kò wá yẹ kí ìwọ náà máa fi òye àti ọgbọ́n bá àwọn náà lò?—Róòmù 12:10.

Ọ̀nà míì tá a lè gbà bọ̀wọ̀ fáwọn ẹlòmíì ni pé ká má máa nífẹ̀ẹ́ wọn ní àníjù débi tá á fi dà bíi pé wọ́n wà nínú àhámọ́. Ọ̀rẹ́ tòótọ́ kì í jowú kì í sì fẹ́ kí nǹkan jẹ́ tòun nìkan. (1 Kọ́ríńtì 13:4) Giancarlo, tó wá láti Ítálì sọ pé: “Ó dà bíi pé mo máa ń jowú. N kì í fẹ́ rí ẹlòmíì pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi. Nítorí náà, bí wọ́n bá jàjà sọ̀rọ̀ àṣírí fáwọn ẹlòmíì, ó máa ń dùn mí màá sì yàn wọ́n lódì fún àkókò díẹ̀. Mo wá gbà pé gbogbo wa ló yẹ ká wá ọ̀rẹ́ kún ọ̀rẹ́ àti pé mo ní láti yọ̀ọ̀da káwọn náà lọ́rẹ̀ẹ́ míì.”

Má ṣe gbàgbé pé àwọn àkókò kan á wà táwọn ọ̀rẹ́ á fi fẹ́ láti gbọ́ tara wọn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan àtàwọn lọ́kọláya, máa ń nílò àkókò tí wọ́n á fi gbọ́ tara wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sóhun tó ní kó o má báwọn ẹlòmíì ṣọ̀rẹ́, ó gbèrò kò sì yẹ kó o ti àṣejù bọ̀ ọ́, kí ọ̀ràn ẹ má bàa sú wọn. Ọ̀rọ̀ ìṣọ́ra tí Bíbélì sọ ni pé: “Jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ṣọ̀wọ́n ní ilé ọmọnìkejì rẹ, kí ọ̀ràn rẹ má bàa sú u.”—Òwe 25:17.

Má Ṣe Retí Pé Ọ̀rẹ́ Rẹ Ò Gbọ́dọ̀ Ṣàṣìṣe

Àmọ́ ṣá o, nígbà táwọn èèyàn bá ti mọ ara wọn tán, dandan ni kí wọ́n tún mọ̀ nípa àléébù ara wọn àti ibi tí wọ́n dáa sí. Síbẹ̀, ìyẹn ò ní ká máà báwọn ẹlòmíì ṣọ̀rẹ́. Pacôme, tó wá láti ilẹ̀ Faransé sọ pé: “Ohun táwọn ẹlòmíì ń retí látọ̀dọ̀ àwọn tó bá fẹ́ bá wọn ṣọ̀rẹ́ ti máa ń pọ̀ jù. Ànímọ́ tó dáa nìkan ni wọ́n fẹ́ kí wọ́n ní, ṣùgbọ́n ìyẹn ò lè ṣeé ṣe.” Kò sẹ́ni kan nínú wa tó lè ṣe nǹkan lọ́nà pípé, a ò sì lẹ́tọ̀ọ́ láti retí pé káwọn míì ṣe bẹ́ẹ̀. Ńṣe la máa fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ wa mọ̀wà wa fún wa kí ọ̀rẹ́ wa bàa lè jọ̀rẹ́. Ṣé ò wá yẹ káwa náà máa fara da àṣìṣe àwọn ọ̀rẹ́ wa, ká má retí pé wọ́n á ṣe àìdáa ká má sì máa fẹ àṣìṣe wọn lójú? Òǹkọ̀wé Dennis Prager rán wa létí pé: “Àfàwọn ẹran ọ̀sìn nìkan lọ̀rẹ́ tí ò lè ṣẹ̀ẹ̀yàn, ìyẹn ni ọ̀rẹ́ tí ò jẹ́ rojọ́, tá á máa fẹ́ni nígbà gbogbo, tínú ẹ̀ kì í bà jẹ́, tí kì í yani lẹ́sẹ̀ kan, tí ò sì jẹ́ jáni kulẹ̀ láé.” Bá ò bá fẹ́ ní kìkì àwọn èèyàn tó dà bí ẹran ọ̀sìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́, ó yẹ ká gba ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pétérù fúnni pé ká jẹ́ kí ‘ìfẹ́ bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.’—1 Pétérù 4:8.

Wọ́n máa ń sọ pé ìgbà ìpọ́njú là á mọ̀rẹ́. Àmọ́ ṣá o, òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé kò tọ́ ká rò pé gbogbo ohun tá à ń fẹ́ pátá làwọn ọ̀rẹ́ wa á ṣe fún wa, tàbí pé wọ́n á bá wa yanjú gbogbo ìṣòro wa. Ìmọtara-ẹni-nìkan ló lè mú ká ní irú èrò bẹ́ẹ̀.

Àwọn Ọ̀rẹ́ Tó Ń Dúró Tini Lọ́jọ́ Ìṣòro

Gbàrà tí ẹnì kan bá ti dọ̀rẹ́ wa, kò yẹ ká kóyán ẹ̀ kéré. Bí ọ̀rẹ́ àtọ̀rẹ́ kì í bá ríra déédéé tí ọ̀nà wọn sì jìn síra, wọn a máa ronú nípa ara wọn, wọn a sì máa gbàdúrà fúnra wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni wọ́n máa ń ríra, ọ̀rọ̀ wọn tètè máa ń wọ̀. Bí ìṣòro tàbí àìní èyíkéyìí bá wà, ìgbà yẹn gan-an ló ṣe pàtàkì jù lọ pé ká rántí àwọn ọ̀rẹ́ wa. A ó gbọ́dọ̀ sá bí àwọn ọ̀rẹ́ wa bá wà nínú ìṣòro. Ó lè jẹ́ pé ìgbà yẹn gan-an ni wọ́n á nílò ìrànlọ́wọ́ wa jù lọ. “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Bí èdè àìyedè bá sì wáyé láàárín àwọn ojúlówó ọ̀rẹ́, kì í pẹ́ tí wọ́n á fi yanjú ẹ̀ tí wọ́n á sì dárí ji ara wọn. Irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ kì í pa ara wọn tì nítorí pé ọ̀rọ̀ ṣe bí ọ̀rọ̀ lásán.

Bí o kì í bá ṣe ẹni tó mọ tara ẹ̀ nìkan, tó o sì ń fọkàn kan bá àwọn ẹlòmíì lò, ó dájú pé wàá rẹ́ni bá ṣọ̀rẹ́. Ṣùgbọ́n irú ọ̀rẹ́ tó o bá ní náà tún ṣe pàtàkì. Báwo lo ṣe lè rí àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa? Máa bá wa ká lọ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tún wo àpilẹ̀kọ náà, “Ẹ̀rín Músẹ́—Á Ṣe Ẹ́ Láǹfààní!” nínú ìtẹ̀jáde Jí! July 8, 2000.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]

Ṣé Ọkùnrin àti Obìnrin Lè Jẹ́ “Ọ̀rẹ́ Lásán”?

Ṣé àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọn ò jọ fẹ́ra lè máa ṣọ̀rẹ́ lásán? Ìyẹn sinmi lórí ohun tá a bá lóye ọ̀rọ̀ náà, “ọ̀rẹ́” sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Màríà àti Màtá ò lọ́kọ, ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni Jésù jẹ́ sí wọn. (Jòhánù 11:1, 5) Ọ̀rẹ́ Pọ́ọ̀lù ni Pírísílà àti ọkọ rẹ̀, Ákúílà. (Ìṣe 18:2, 3) Ó dá wa lójú pé àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin wọ̀nyí ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ síra wọn. Síbẹ̀ náà, a ò jẹ́ ronú pé Jésù tàbí Pọ́ọ̀lù á jẹ́ kí irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ mú wọn nífẹ̀ẹ́ ìkọ̀kọ̀ sáwọn tí wọ́n ń bá ṣọ̀rẹ́.

Yàtọ̀ sí bí nǹkan ṣe rí látijọ́, tọkùnrin tobìnrin ló jùmọ̀ ń ṣe àwọn nǹkan pa pọ̀ lóde òní, ìyẹn sì ti mú kó di dandan pé kí tọkùnrin tobìnrin máa jọ ṣe wọléwọ̀de kí wọ́n sì máa bára wọn ṣọ̀rẹ́. Àwọn tọkọtaya náà máa ń gbádùn àjọṣe gbígbámúṣé pẹ̀lú àwọn tọkọtaya mìíràn àtàwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó.

Ìwé ìròyìn Psychology Today ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé: “Ńṣe ló túbọ̀ ń ṣòro sí i láti mọ̀ bóyá ìfẹ́ tẹ́nì kan ní jẹ́ ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀, ìfẹ́ ìbálòpọ̀ tàbí ìfẹ́ ọ̀rẹ́ lásán. . . . Òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé láìròtẹ́lẹ̀, ìfẹ́ ìbálòpọ̀ lè wọ àárín tọkùnrin tobìnrin tí wọ́n jọ ń bára wọn ṣọ̀rẹ́. Wíwulẹ̀ dì mọ́ọ̀yàn gbàgì lásán lè mú kó bẹ̀rẹ̀ sí i ronú pé ọkàn onítọ̀hún ń fà sí òun.”

Ní ti àwọn tọkọtaya, àìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ àti mímọ ohun tó tọ́ sí wọn ṣe pàtàkì. Òǹkọ̀wé Dennis Prager sọ nínú ìwé rẹ̀, Happiness Is a Serious Problem, pé: “Gbogbo wọléwọ̀de téèyàn bá ń ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì ló lè wu ìgbéyàwó léwu. Nípa ìbálòpọ̀ nìkan kọ́ lèèyàn fi ń ní àjọṣe tímọ́tímọ́ nínú ìgbéyàwó, ọkọ tàbí aya rẹ sì lẹ́tọ̀ọ́ láti retí pé bó o bá máa lọ́rẹ̀ẹ́ kòríkòsùn lóbìnrin tàbí lọ́kùnrin, òun nìkan ṣoṣo ni.” Jésù sọ pé dídarí ọkàn ẹni síbi tó tọ́ ló ń sọni di oníwà mímọ́. (Mátíù 5:28) Nítorí náà, kò burú láti jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn ẹlòmíì, ṣùgbọ́n máa ṣọ́ ohun tó wà lọ́kàn rẹ kó o si máa yẹra fún gbogbo nǹkan tó bá lè mú kó o máa ronú lọ́nà tí kò tọ́, tàbí kó o máa ní ìmọ̀lára tí kò tọ́, kó o sì fẹ́ láti hùwà tí kò tọ́ sí ẹni tó jẹ́ ẹ̀yà kejì.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Bó o bá ń ro ohun tó dáa lọ́kàn tó o sì ń túnra ṣe, àwọn èèyàn ò ní jìnnà sí ẹ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Àwọn ọ̀rẹ́ kì í fọ̀rọ̀ pa mọ́ fúnra wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́