Ṣé Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ta Ko Àkọsílẹ̀ Inú Jẹ́nẹ́sísì?
Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló máa ń sọ pé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ta ko àlàyé tí Bíbélì ṣe nípa ìṣẹ̀dá. Àmọ́, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti Bíbélì kọ́ ló ta kora, èrò àwọn táwọn èèyàn ń pè ní Agbẹ́sìnkarí gan-an ló ta ko ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Èrò òdì táwọn kan lára àwọn èèyàn yìí ń gbé gẹ̀gẹ̀ ni pé, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, ọjọ́ mẹ́fà, tí gígùn ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ wákàtí mẹ́rìnlélógún ni Ọlọ́run fi ṣẹ̀dá ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú ẹ̀, ní nǹkan bí ẹgbàárùn-ún [10,000] ọdún sẹ́yìn.
Àmọ́ ṣáá o, kò sí nínú Bíbélì bí wọ́n ṣe sọ ọ́ yẹn. Bó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí ni, a jẹ́ pé ńṣe lọ̀pọ̀ àwárí táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti ṣe láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn á wulẹ̀ máa já àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì nírọ́. Béèyàn bá fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, á rí i pé ohun tó sọ ò ta ko àwọn àwárí tí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀. Ìdí nìyẹn táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò fi gbà pẹ̀lú àwọn Agbẹ́sìnkarí àti ọ̀pọ̀ àwọn tó lérò òdì nípa gígùn àkókò ìṣẹ̀dá. Wàyí o, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an?
Ìgbà Wo Ni “Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀”?
Àgbà gbólóhùn tó sì rọrùn láti yéni yìí ló bẹ̀rẹ̀ ìwé Jẹ́nẹ́sísì, ó kà pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Àwọn onímọ̀ Bíbélì gbà pé ńṣe ni ẹsẹ yìí ń ṣàpèjúwe iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tó yàtọ̀ sí èyí tó wáyé láwọn ọjọ́ tí Ọlọ́run fi dá ayé àtàwọn ohun tó wà nínú ẹ̀, èyí tí àlàyé nípa ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti ẹsẹ kẹta síwájú. Ìtumọ̀ pàtàkì sì ni gbólóhùn náà ní. Gẹ́gẹ́ bí gbólóhùn tó bẹ̀rẹ̀ Bíbélì yìí ṣe kà, ayé òun ọ̀run, tó fi mọ́ ilẹ̀ Ayé tá à ń gbé yìí, ti wà láti àìmọye ọdún kó tó di pé àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀dá bẹ̀rẹ̀.
Àwọn onímọ̀ nípa ilẹ̀ ayé àtàwọn ohun tó wà nínú ilẹ̀ fojú bù ú pé á ti tó nǹkan bí àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ẹgbàajì [4,000,000,000] ọdún tí ayé ti wà, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà sì ṣírò rẹ̀ pé ó ṣeé ṣe kí ayé ti wà láti àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [15,000,000,000] ọdún. Ṣé àwọn àwárí yìí, àti òye yòówù tí wọn ì báà ní lọ́jọ́ iwájú, ta ko Jẹ́nẹ́sísì 1:1? Rárá o. Bíbélì ò sọ pé iye ọdún pàtó báyìí ní “ọ̀run àti ilẹ̀ ayé” ti wà. Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ò ta ko ẹsẹ Bíbélì yẹn.
Báwo Làwọn Ọjọ́ Ìṣẹ̀dá Ṣe Gùn Tó?
Gígùn àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀dá wá ń kọ́ o? Ṣé wákàtí mẹ́rìnlélógún ni gígùn ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn? Àwọn kan sọ pé nítorí pé Mósè tó kọ ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé ọjọ́ tó tẹ̀ lé àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀dá mẹ́fà náà jẹ́ àpẹẹrẹ Sábáàtì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, a jẹ́ pé ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún làwọn ọjọ́ ìṣẹ̀dá gbọ́dọ̀ jẹ́. (Ẹ́kísódù 20:11) Ṣó wá lè jẹ́ pé ohun tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì ń sọ túmọ̀ sí nìyẹn?
Rárá o, ohun tó ń sọ kọ́ nìyẹn. Ohun tó wà ńbẹ̀ ni pé ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “ọjọ́” tún lè túmọ̀ sí onírúurú àkókò tó gùn jura lọ, kì í wulẹ̀ ṣe àkókò oníwákàtí mẹ́rìnlélógún nìkan. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Mósè ń ṣe àkópọ̀ àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀dá mẹ́fà náà bí ẹni pé ọjọ́ kan ṣoṣo ni wọ́n. (Jẹ́nẹ́sísì 2:4) Dájúdájú, kò sí béèyàn ṣe lè fi Ìwé Mímọ́ tì í lẹ́yìn pé gígùn ọjọ́ ìṣẹ̀dá kọ̀ọ̀kan jẹ́ wákàtí mẹ́rìnlélógún.
Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, báwo lọjọ́ ìṣẹ̀dá kọ̀ọ̀kan ṣe gùn tó? Ọ̀rọ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì orí 1 àti 2 fi hàn pé àkókò ìṣẹ̀dá gùn gan-an ni.
Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ Làwọn Nǹkan Tí Ọlọ́run Dá Bẹ̀rẹ̀ sí Í Wáyé
Èdè Hébérù ni Mósè fi kọ Bíbélì, ó sì kọ ọ́ ní ìkọ ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé ńbí. Kókó méjì yìí àti ohun tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ayé òun ọ̀run ti wà kó tó di pé àkókò tàbí “àwọn ọjọ́” ìṣẹ̀dá bẹ̀rẹ̀ á ràn wá lọ́wọ́ láti fòpin sí ọ̀pọ̀ àríyànjiyàn tó wà nídìí ìtàn ìṣẹ̀dá. Lọ́nà wo?
Bá a bá wo àkọsílẹ̀ ìwé Jẹ́nẹ́sísì láwòfín, a óò rí i pé àwọn ohun tó bẹ̀rẹ̀ ní “ọjọ́” kan máa ń nasẹ̀ dé ọjọ́ míì tàbí ọjọ́ méjì mẹ́ta tó tẹ̀ lé e. Bí àpẹẹrẹ, kí “ọjọ́” ìṣẹ̀dá àkọ́kọ́ tó bẹ̀rẹ̀, ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ oòrùn tí Ọlọ́run ti dá ṣáájú ọjọ́ náà ò lè tàn dé orí ilẹ̀ ayé, bóyá nítorí pé àwọsánmà tó nípọn ti bò ó lójú. (Jóòbù 38:9) Ní “ọjọ́” kìíní, ohun tó bo oòrùn lójú yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í ká kúrò, èyí tó mú kí ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ ríbi mọ́lẹ̀ yòò lójú sánmà.a
Ó dájú pé ní “ọjọ́” kejì, ojú sánmà ṣì ń mọ́lẹ̀ nìṣó, èyí tó mú kí àlàfo wà láàárín àwọsánmà tó nípọn lókè àti agbami òkun nísàlẹ̀. Ní “ọjọ́” kẹrin, ojú sánmà ti mọ́lẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ débi pé oòrùn àti òṣùpá fara hàn “ní òfuurufú ọ̀run.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:14-16) Tàbí ká kúkú sọ pé, ó wá ṣeé ṣe fún ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé tó ń wo oòrùn àti òṣùpá láti bẹ̀rẹ̀ sí í rí wọn kedere. Àmọ́, ẹ̀ẹ̀kan náà kọ́ ni gbogbo ẹ̀ ṣẹlẹ̀ o.
Àkọsílẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì tún ròyìn pé bí àwọsánmà ṣe ń mọ́lẹ̀ nìṣó, àwọn ẹ̀dá abìyẹ́, tó fi mọ́ àwọn kòkòrò àtàwọn ẹ̀dá kéékèèké tó ń fò, bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn ní “ọjọ́” karùn-ún. Àmọ́, Bíbélì sọ pé ní “ọjọ́” kẹfà, Ọlọ́run ṣì “ń ṣẹ̀dá gbogbo ẹranko inú pápá àti gbogbo ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:19.
Ó dájú pé ọ̀nà tí Bíbélì gbà sọ̀rọ̀ mú ká lóye pé ó ṣeé ṣe káwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì pàtàkì wáyé ní “ọjọ́” tàbí àkókò ìṣẹ̀dá kọ̀ọ̀kan. Ó tún jẹ́ ká lóye pé ó ṣeé ṣe káwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ dípò kó jẹ́ lọ́gán, àní àwọn míì tiẹ̀ lè máà parí títí tí “ọjọ́” ìṣẹ̀dá mìíràn á fi bẹ̀rẹ̀.
Ní Irú Tiwọn
Ṣé bí àwọn ewéko àti ẹranko ṣe ń wáyé ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ yìí túmọ̀ sí pé dípò kí Ọlọ́run dá wọn, ńṣe ló mú kí wọ́n hú yọ báwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n ṣe ń kọ́ni? Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Àkọsílẹ̀ náà sọ lọ́nà tó ṣe kedere pé Ọlọ́run ló dá “irú” àwọn ewéko àti ẹranko tó kọ́kọ́ wà. (Jẹ́nẹ́sísì 1:11, 12, 20-25) Ṣé Ọlọ́run ṣe é tó fi jẹ́ pé “irú” àwọn ewéko àti ẹranko tó kọ́kọ́ dá yìí á lágbára láti lè mú ara wọn bá bí àyíká bá ṣe rí mu? Ibo ni “irú” ewéko tàbí ẹranko kan á bá a dé tá a ò fi ní lè kà á kún ewéko tàbí ẹranko yẹn mọ́? Bíbélì ò sọ fún wa. Àmọ́, ó sọ nípa ẹ̀dá alààyè kọ̀ọ̀kan èyí tó ń “gbá yìn-ìn ní irú tiwọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:21) Ìtumọ̀ gbólóhùn yìí ni pé ó níbi tí ìyípadà tó lè wáyé nínú “irú” ewéko tàbí ẹranko kan mọ. Àwọn àkọsílẹ̀ tó dá lórí àkẹ̀kù ewéko àti ti ẹranko, tó fi mọ́ ìwádìí tí wọ́n ṣe lóde òní, fara mọ́ èrò náà pé díẹ̀ ni ìyípadà tó tíì wáyé lára irú àwọn ewéko àti ẹranko tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá látijọ́ táláyé ti dáyé.
Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ohun táwọn Agbẹ́sìnkarí ń sọ, ìwé Jẹ́nẹ́sísì ò kọ́ni pé láàárín àkókò kúkúrú tí kò tíì fi bẹ́ẹ̀ pẹ́ yìí ni Ọlọ́run dá àgbáyé, tó fi mọ́ ilẹ̀ ayé àti gbogbo ohun alààyè tó wà nínú ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀nà tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì gbà ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe dá àgbáyé àti báwọn nǹkan alààyè ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í wáyé ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ohun táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣàwárí ẹ̀ lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.
Nítorí pé ọ̀pọ̀ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ gba èrò èèyàn gbọ́, wọ́n kọ̀ láti fara mọ́ Bíbélì tó kọ́ni pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo. Àmọ́, ó ṣe wẹ́kú pé nínú ìwé Bíbélì àtijọ́ nì, Jẹ́nẹ́sísì, Mósè kọ̀wé pé àgbáyé ní ibi tó ti bẹ̀rẹ̀ àti pé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ni Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn nǹkan, ìyẹn sì gba àkókò. Báwo wá lọwọ́ Mósè ṣe tẹ irú ìsọfúnni tó bá ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ mu bẹ́ẹ̀ ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ lé lẹ́gbàá [3,500] ọdún sẹ́yìn? Àlàyé tó mọ́gbọ́n dání kan ṣoṣo la lè fi dáhùn ìbéèrè yìí. Ìyẹn ni pé, Ẹni tó lágbára àti ọgbọ́n láti dá àwọn ọ̀run àti ayé ló ti ní láti fún Mósè ní irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ káwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tó ṣàwárí pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn. Èyí túbọ̀ mú ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé Bíbélì jẹ́ ìwé tí “Ọlọ́run mí sí.”—2 Tímótì 3:16.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nígbà tí Mósè ń ṣàpèjúwe ohun tó ṣẹlẹ̀ ní “ọjọ́” àkọ́kọ́, ọ̀rọ̀ Hébérù tó lò fún ìmọ́lẹ̀ ni ʼohr, ìyẹn èdè tí wọ́n sábà máa ń lò fún ìmọ́lẹ̀; àmọ́ nígbà tó ń ṣàpèjúwe “ọjọ́” kẹrin, ọ̀rọ̀ tó lò ni ma·ʼohr ʹ, tó túmọ̀ sí orísun ìmọ́lẹ̀.
ǸJẸ́ Ó TI ṢE Ọ́ BÍI KÓ O BÉÈRÈ PÉ?
◼ Báwo ló ṣe pẹ́ tó tí Ọlọ́run ti da ayé òun ọ̀run?—Jẹ́nẹ́sísì 1:1.
◼ Ṣé ọjọ́ mẹ́fà, tí gígùn ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ wákàtí mẹ́rìnlélógún ni Ọlọ́run fi dá ayé? —Jẹ́nẹ́sísì 2:4.
◼ Báwo làwọn àkọsílẹ̀ Mósè nípa bí ilẹ̀ ayé ṣe bẹ̀rẹ̀ ṣe lè bá ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ mu?—2 Tímótì 3:16.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]
Ìwé Jẹ́nẹ́sísì ò kọ́ni pé láàárín àkókò kúkúrú tí kò tíì fi bẹ́ẹ̀ pẹ́ yìí ni Ọlọ́run dá àgbáyé
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 30]
“Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” —Jẹ́nẹ́sísì 1:1
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]
Àgbáyé: Àwòrán tí IAC/RGO/David Malin Images yà
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 30]
Fọ́tò NASA