Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Bí Ìfẹ́ Bá Ti Wà, Kò Sóhun Tó Burú Nínú Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó?
ÌWÁDÌÍ kan fi hàn pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àwọn ọmọ aláìtójúúbọ́ mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá tó sọ pé níwọ̀n ìgbà tí ọkùnrin àti obìnrin tó ń fẹ́ra wọn bá ti nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kò sóhun tó burú nínú ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó. Irú ọ̀rọ̀ yìí là ń gbọ́ lórí tẹlifíṣọ̀n, lórí rédíò, bákan náà là ń kà á nínú ìwé ìròyìn, ọ̀rọ̀ yìí kan náà sì làwọn akọ̀ròyìn máa ń fẹ́ gbé jáde. Lóòrèkóòrè là ń rí í lórí tẹlifíṣọ̀n àti nínú fíìmù pé tí ò bá tíì sí ìbálòpọ̀ láàárín ọkùnrin àtobìnrin tó ń fẹ́ra wọn, a jẹ́ pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú.
Ó dájú pé gbogbo ẹni tó bá fẹ́ ṣe ohun tí inú Ọlọ́run á dùn sí ò ní máa tẹ̀ lé ọgbọ́n ayé nítorí wọ́n mọ̀ pé èrò alákòóso ayé, ìyẹn Èṣù, ni ayé fi ń ṣèwà hù. (1 Jòhánù 5:19) Wọ́n tún máa ń ṣọ́ra kí èrò ara tiwọn fúnra wọn má lọ máa darí wọn torí wọ́n mọ̀ pé “ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà.” (Jeremáyà 17:9) Ẹlẹ́dàá àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní ìmísí làwọn tó gbọ́n ṣáṣá máa ń jẹ́ kó tọ́ àwọn sọ́nà.—Òwe 3:5, 6; 2 Tímótì 3:16.
Ẹ̀bùn Ọlọ́run Ni Ìbálòpọ̀
Jákọ́bù 1:17 sọ pé: “Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé jẹ́ láti òkè, nítorí a máa sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá.” Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn náà ni ìbálòpọ̀ láàárín ọkùnrin atòbìnrin tó ti ṣègbéyàwó. (Rúùtù 1:9; 1 Kọ́ríńtì 7:2, 7) Ẹ̀bùn yìí ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn ẹ̀dá èèyàn láti máa bímọ ó sì tún ń mú kí tọkọtaya ṣe ara wọn lọ́kan kí wọ́n sì máa ṣìkẹ́ ara wọn. Sólómọ́nì tó jẹ́ ọba láyé ọjọ́un sọ pé: “Sì máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ. Jẹ́ kí ọmú tirẹ̀ máa pa ọ́ bí ọtí ní gbogbo ìgbà.”—Òwe 5:18, 19.
Látilẹ̀wá, òun tí Jèhófà fẹ́ fún wa ni pé ká jàǹfààní àwọn ẹ̀bùn tó fún wa ká sì máa yọ̀. Ìdí nìyẹn tó fi fún wa láwọn òfin àti ìlànà tí kò tíì sírú ẹ̀ rí nípa bó ṣe yẹ ká máa lo ìgbésí ayé wa. (Sáàmù 19:7, 8) Jèhófà ni “Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.” (Aísáyà 48:17) Ṣé Bàbá wa ọ̀run—ẹni tó jẹ́ èkìdá ìfẹ́—á dù wá ní ohunkóhun tó lè ṣe wá láǹfààní?—Sáàmù 34:10; 37:4; 84:11; 1 Jòhánù 4:8.
Ìwà Ìkà Ni Kéèyàn Máa Bá Ẹlòmíì Lò Pọ Ṣáájú Ìgbéyàwó
Bí ọkùnrin kan àtobìnrin kan bá ti wọnú ìdè ìgbéyàwó, àwọn méjèèjì ti di “ara kan” nìyẹn. Bí ọkùnrin àtobìnrin tí ò tíì ṣègbéyàwó bá ní ìbálòpọ̀, èyí tá a mọ̀ sí àgbèrè, “ara kan” làwọn náà á dì—àmọ́ ara kan tiwọn yẹn á jẹ́ aláìmọ́ lójú Ọlọ́run.a Yàtọ̀ síyẹn, àwọn méjèèjì ò nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú. Ọ̀nà wo ló gbà jẹ́ ìwà ìkà?—Máàkù 10:7-9; 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10, 16.
Ìdí kan ni pé, báwọn méjì bá ń bára wọn lò pọ̀ láìtíì tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn ìgbéyàwó, àgbèrè ni wọ́n ń bára wọn ṣe. Àti pàápàá, yàtọ̀ sí pé èèyàn á kan àbùkù, ó tún lè mú kéèyàn kó àrùn, kéèyàn lóyún tí ò fẹ́, ó sì lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá èèyàn. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ẹ̀ṣẹ̀ sí ìlànà òdodo Ọlọ́run ni. Nítorí náà, ẹni tó ń ṣe àgbèrè ò ro rere sí ẹni tó ń bá ṣe é, ì báà jẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tàbí lọ́jọ́ iwájú.
Bí Kristẹni ọkùnrin àtobìnrin bá ṣe àgbèrè, ṣe ni wọ́n ja ara wọn lólè ẹ̀tọ́ tí kálukú wọn ní. (1 Tẹsalóníkà 4:3-6) Bí àpẹẹrẹ, ṣe làwọn tó bá pera wọn ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n tún ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe aya tàbí ọkọ wọn ń kó èérí bá ìjọ Kristẹni. (Hébérù 12:15, 16) Bákan náà, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tún máa ń mú kẹ́ni tí wọ́n bá ṣe àgbèrè ọ̀hún di ẹlẹ́gbin níwájú Ọlọ́run, bí ẹni náà bá tún wá lọ jẹ́ àpọ́n, ẹni tó bá a ṣàgbèrè ti gba ẹ̀tọ́ tó ní láti ṣègbéyàwó gẹ́gẹ́ bí aláìléèérí kúrò lọ́wọ́ ẹ. Irú àwọn Kristẹni bẹ́ẹ̀ ti kó àbàwọ́n bá orúkọ ìdílé ara wọn, bákan náà wọ́n ti kó àbùkù bá ìdílé ẹni tí wọ́n bá ṣe àgbèrè. Lékè gbogbo ẹ̀, wọn ò ka Ọlọ́run sí, ẹni tí wọ́n ṣẹ̀ sí nípa ríré tí wọ́n ré òfin àti ìlànà òdodo rẹ̀ kọjá. (Sáàmù 78:40, 41) Jèhófà alára ò ní ‘ṣàìfi ìyà’ jẹ́ gbogbo ẹni tí kò bá ronú pìwà dà kúrò nínú híhùwà burúkú yẹn. (1 Tẹsalóníkà 4:6) A lè wá rí ìdí ẹ̀ tí Bíbélì fi sọ fún wa pé ká “sá fún àgbèrè”?—1 Kọ́ríńtì 6:18.
Ṣó o ní àfẹ́sọ́nà tó o sì ń gbèrò àtiṣe ìgbéyàwó? Nígbà náà, o ò kúkú ṣe lo àkókò tẹ́ ẹ fi ń fẹ́ra sọ́nà yìí láti ṣe àwọn ohun tó máa jẹ́ kẹ́ ẹ lè fọkàn tán ara yín kẹ́ ẹ sì lè máa bọ̀wọ̀ fún ara yín? Gbé àwọn kókó wọ̀nyí yẹ̀ wò ná: Báwo lobìnrin kan ṣe lè fọkàn tán ọkùnrin tó hàn nínú àwọn ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan pé kì í lè kó ara ẹ̀ níjàánu? Bákan náà, ṣó máa rọrùn fún ọkùnrin kan láti máa ṣìkẹ́ kó sì máa fi ọlá fún obìnrin kan tí kò ka òfin Ọlọ́run sí pàtàkì torí ìfẹ́ òdì tó kó sí i lórí tàbí torí kó lè tẹ́ ọkùnrin náà lọ́run?
Tún rántí pé kò sẹ́ni tó kọ etí ikún sáwọn ìlànà tí Ọlọ́run fi tìfẹ́tìfẹ́ gbé kalẹ̀ tí ò ní ká ohun tó gbìn. (Gálátíà 6:7) Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 6:18; Òwe 7:5-27) Òótọ́ ni pé bí ọkùnrin àtobìnrin tó ṣàgbèrè ṣáájú ìgbéyàwó wọn bá ronú pìwà dà ní tòótọ́, tí wọ́n sapá tó tọkàn wá láti tún àárín àwọn àti Ọlọ́run ṣe tí wọ́n sì pinnu láti máa fọkàn tán ara wọn, ó ṣeé ṣe kí ìwà àìnítìjú tí wọ́n hù yẹn dohun ìgbàgbé bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́. Ó kàn jẹ́ pé kò sọ́gbọ́n téèyàn lè dá láyé tí ojú àpá fi lè jọ ojú ara. Tọkọtaya ọ̀dọ́ kan tí wọ́n ṣègbéyàwó lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣàgbèrè géka àbámọ̀ jẹ. Èyí ọkọ máa ń bi ara ẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé, ‘Ṣé kò lè jẹ́ pé àtúbọ̀tán ìṣekúṣe tá a fi pilẹ̀ ìgbéyàwó wa ló ń fa àìgbọ́ra-ẹni-yé tó ń wáyé yìí?’
Ìfẹ́ Tòótọ́ Kì Í Wá Ire Ti Ara Rẹ̀ Nìkan
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ tòótọ́ lè máa pààyàn bí ọtí, síbẹ̀ “kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu” kì í sì í “wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.” (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Ohun tó ṣàǹfààní tó sì máa fún ẹnì kejì láyọ̀ dọjọ́ alẹ́ ló máa ń ṣe. Irú ìfẹ́ yìí máa ń mú kí ọkùnrin àti obìnrin bọ̀wọ̀ fún ẹnì kìíní kejì ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n lè fi ìbálòpọ̀ sáyè tí Ọlọ́run fi sí, ìyẹn àárín ọkùnrin àti obìnrin tó ṣègbéyàwó.—Hébérù 13:4.
Ó ṣe pàtàkì kí ìfọkàn-tánra-ẹni àti ìfọ̀kànbalẹ̀ wà nínú ìgbéyàwó tó bá máa láyọ̀, pàápàá ìgbéyàwó tí ọmọ bá ti wọ̀, nítorí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé káwọn òbí tọ́ àwọn ọmọ dàgbà nínú ilé tí ìfẹ́ wà, ilé tó tòrò tí ọkàn wọn ti máa balẹ̀. (Éfésù 6:1-4) Ìgbéyàwó nìkan nibi téèyàn méjì tí jọ máa ń ṣe nǹkan pa pọ̀ láìkọminú. Torí pé nínú ọkàn àti lọ́pọ̀ ìgbà nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ síra wọn, àwọn méjèèjì máa ń jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣìkẹ́ àti láti jẹ́ alátìlẹyìn ara wọn nígbà dídùn àti kíkan títí dìgbà tíkú á fi yà wọ́n.—Róòmù 7:2, 3.
Ìbálòpọ̀ láàárín ọkọ àtaya lè túbọ̀ mú kí wọ́n sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí. Nínú ìgbéyàwó aláyọ̀, ìbálòpọ̀ tún máa ń gbádùn mọ́ tọkọtaya gan-an, ó máa ń nítumọ̀, kò sì ní kó ẹ̀gàn bá ìdè ìgbéyàwó, ẹ̀rí ọkàn àwọn tó gbéra wọn níyàwó ò ní máa dá wọn lẹ́bi, wọ́n á sì mọ̀ pé àwọn ò ṣẹ̀ sí Ẹlẹ́dàá.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “àgbèrè” ní nínú gbogbo eré ìfẹ́ tó bá jẹ mọ́ ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tá ò jọ ṣègbéyàwó, èyí tó kan lílo ẹ̀yà ara tó wà fún ìbálòpọ̀ tàbí fífẹnu pa á.—Wo Jí! August 8, 2004, ojú ìwé 14, àti Ilé Ìṣọ́, February 15, 2004, ojú ìwé 13, táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀.
ǸJẸ́ Ó TI ṢE Ọ́ RÍ BÍI KÓ O BÉÈRÈ PÉ?
◼ Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó?—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.
◼ Kí nìdí tí àgbèrè fi léwu?—1 Kọ́ríńtì 6:18.
◼ Ọ̀nà wo ni ọkùnrin kan àtobìnrin kan tí wọ́n ń gbèrò àtifẹ́ra lè gbà fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénúdénú?—1 Kọ́ríńtì 13:4, 5.