ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/07 ojú ìwé 4-7
  • Bí Ìwà Rere Ṣe Ṣàdédé Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Jó Rẹ̀yìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Ìwà Rere Ṣe Ṣàdédé Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Jó Rẹ̀yìn
  • Jí!—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwà Rere Di Àtẹ̀mẹ́rẹ̀
  • Ìwà Tuntun
  • Ibo Ló Kù Téèyàn Lè Wá Ìrànlọ́wọ́ Gbà?
  • Ìdí Tí Ìwà Ọmọlúwàbí Fi Ṣe Pàtàkì
    Jí!—2019
  • Ìlànà Ìwà Híhù Ò Dúró Sójú Kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Àwọn Ìlànà Rere Ń jó Àjórẹ̀yìn
    Jí!—2003
  • Àwọn Ìwà Rere Tó Ń Mú Káyé Ẹni Dára
    Jí!—2014
Àwọn Míì
Jí!—2007
g 4/07 ojú ìwé 4-7

Bí Ìwà Rere Ṣe Ṣàdédé Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Jó Rẹ̀yìn

ÌGBÀ wo lo mọ̀ tí ìwà rere bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn? Ṣé níṣe tó o dáyé yìí náà ni àbí látìgbà táwọn ìbátan tàbí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tó jù ẹ́ lọ ti wà láyé? Àwọn kan sọ pé látìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní, tó jà lọ́dún 1914, ni ìwàkiwà tí ò láfiwé yìí ti rá pálá wọnú ayé. Ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ nípa ìtàn, Robert Wohl, sọ nínú ìwé rẹ̀, The Generation of 1914 pé: “Kì í kúrò lọ́kàn àwọn tógun náà tojú wọn jà pé lóṣù August, ọdún 1914 layé kan parí tí òmíràn sì bẹ̀rẹ̀.”

Òpìtàn Norman Cantor sọ pé: “Ibi yòówù kéèyàn yíjú sí, ìwà rere tó ti jó rẹ̀yìn tẹ́lẹ̀ ti wá wógbá báyìí. Báwọn olóṣèlú àtàwọn ọ̀gágun bá lè ṣe àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó wà lábẹ́ wọn níṣe ẹran orí ìso bẹ́ẹ̀, ìlànà ẹ̀sìn tàbí ìlànà ìwà rere wo ló wá lè ká àwọn èèyàn lọ́wọ́ kò táwọn náà ò fi ní máa fara wọn ya bíi ti ẹranko ẹhànnà tó ń gbé nínú igbó? . . . Ó ṣe tán, ìpakúpa tó wáyé nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní [lọ́dún 1914 sí ọdún 1918] kúkú ti sọ ẹ̀mí èèyàn di yẹpẹrẹ.”

Nínú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìwé tí òpìtàn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, H. G. Wells kọ, èyí tó pè ní The Outline of History, ó sọ pé lẹ́yìn tí aráyé gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, tó kọ́ni pé ara ẹranko la ti jáde wá, ni “ìwà jágbajàgba túbọ̀ wá rọ́wọ́ mú gan-an.” Kí ló fà á tó fi rí bẹ́ẹ̀? Àwọn kan sọ pé lérò tàwọn, ẹranko làwa èèyàn, ó kàn jẹ́ pé a ju àwọn ẹranko tó wà nínú igbó lọ ni. Òpìtàn Wells tóun fúnra ẹ̀ gbà gbọ́ pé ara ẹranko la ti jáde wá sọ nínú ìwé rẹ̀ lọ́dún 1920 pé: “Ibi tí wọ́n bọ́rọ̀ dé ni pé ẹranko tó fẹ́ràn láti máa gbé pa pọ̀ bí ajá táwọn ará Íńdíà fi ń dẹ̀gbẹ́ làwa èèyàn . . . , nítorí náà, ó dà bí ẹni pé kò sí aburú níbẹ̀ báwọn ajá ńlá láwùjọ ẹ̀dá bá ń bú mọ́ ará yòókù tí wọ́n sì ń tẹ̀ wọ́n lórí ba.”

Dájúdájú, gẹ́gẹ́ bí òpìtàn Cantor ṣe sọ, ogun àgbáyé kìíní ti dabarú ojú táwọn èèyàn fi ń wo ìwà búburú àti ìwà rere. Ó ṣàlàyé pé: “Ogun náà fi hàn pé ní gbogbo ọ̀nà làwọn àgbà tá a bá láyé fi jẹ̀bi, wọ́n jẹ̀bi nínú ọ̀ràn ìṣèlú, ọ̀nà ìgbàwọṣọ, wọ́n sì jẹ̀bi nínú ojú tí wọ́n fi ń wo ìbálòpọ̀.” Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì sì rèé, ńṣe ni wọ́n kó òkùtà bá ẹ̀kọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni. Gbígbà tí wọ́n sì gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tó sọ pé ara ẹranko la ti wá àti gbígbè tí wọ́n gbè sẹ́yìn àwọn tó ń bára wọn jagun, dá kún jíjó tí ìwà rere jó rẹ̀yìn. Frank Crozier tó jẹ́ Ọ̀gágun oníràwọ̀ kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kọ̀wé pé: “Kò tíì sí ẹni tó mọ èèyàn tì sẹ́nu ogun tó àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Wọ́n wà níkàáwọ́ wa, a sì rí wọn lò tẹ́rùn.”

Ìwà Rere Di Àtẹ̀mẹ́rẹ̀

Ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, tí kìràkìtà ìgbà ogun ti kọjá tí àríyá sì ń ṣàn, ìwà ọmọlúwàbí àti ìwà rere táwọn èèyàn ti ń hù tẹ́lẹ̀ di àtẹ̀mẹ́rẹ̀, oníkálùkù sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó bá ṣáà ti tọ́ lójú ara ẹ̀. Òpìtàn Frederick Lewis Allen ṣàlàyé pé: “Ọdún kẹwàá lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní la lè pè ní Ẹ̀wádún Ìwà Jágbajàgba. . . . Ìwà rere ti bógun lọ, bẹ́ẹ̀ ìwà rere yìí ló ń jẹ́ káyé dùn ún gbé kó sì nítumọ̀, kò wá rọrùn mọ́ láti rí nǹkan míì fi rọ́pò ẹ̀.”

Láàárín ọdún 1930 sí 1939, nígbà tí ètò ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ lágbàáyé, ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ ọ́n lọ́ràn nítorí pé wọ́n wọ gbèsè. Nígbà tí ọdún 1939 sì ń parí lọ, aráyé tún kàgbákò ogun bíburú jáì míì, ìyẹn Ogun Àgbáyé Kejì. Kíá àwọn orílẹ̀-èdè ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ohun ìjà ogun runlé rùnnà. Ìyẹn mú káwọn èèyàn ríṣẹ́ ṣe kí wọ́n sì bọ́ lọ́wọ́ wàhálà ètò ọrọ̀ ajé tó dẹ́nu kọlẹ̀, àmọ́ ṣe ni wọ́n bára wọn nínú ìjìyà àti ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tí kò ṣeé fẹnu sọ. Nígbà tí ogun náà parí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìlú ló ti bógun lọ; àwọn ìlú méjì kan tiẹ̀ wà lórílẹ̀-èdè Japan tó jẹ́ pé àgbá runlé rùnnà kọ̀ọ̀kan tí wọ́n jù sáwọn ìlú méjèèjì náà ló pa wọ́n run yán-ányán-án! Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló kú sáwọn àgọ́ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ti ń ṣẹ́ àwọn èèyàn níṣẹ̀ẹ́. Àpapọ̀ àwọn èèyàn tí ìjà náà gbẹ̀mí wọn tó àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà àádọ́ta lọ́kùnrin, lóbìnrin àtàwọn ọmọdé.

Láwọn àkókò tí àìrójú dà pọ̀ mọ́ àìráyè nígbà Ogun Àgbáyé Kejì yìí, dípò káwọn èèyàn máa hùwà rere tó ti wà látayébáyé nìṣó, ńṣe ni olúkúlùkù ń ṣe ohun tó wù ú. Ìwé Love, Sex and War—Changing Values, 1939-45, sọ pé: “Ó dà bíi pé ńṣe ni ìwà ìṣekúṣe ń dúró kí ogun parí, kí logun parí sí báyìí, ṣe làwọn ológun gbé ìwà ta-ní-máa-mú-mi tó ti mọ́ wọn lára lójú ogun wọlé tọ àwọn aráàlú wá. . . . Bí ayọ̀ kì í ṣeé wà pẹ́ títí lójú ogun, tí pàá kìràkìtà kì í sì í dín kú, ti mú káwọn èèyàn pa ìwà rere tì, wọ́n sì ń gbáyé nígbèé pé kò ní pẹ́ tí nǹkan á fi dá páú bó ṣe máa ń rí lójú ogún.”

Ẹ̀rù ikú tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí àwọn èèyàn ń mú kí wọ́n máa wẹ́ni tí wọ́n á fọ̀rọ̀ lọ̀, kódà bó tiẹ̀ ṣe fúngbà díẹ̀. Ìyàwó ilé kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wí àwíjàre nípa ìwà ìṣekúṣe tó légbá kan lákòókò àràmàǹdà yìí, ó sọ pé: “Kì í ṣe pó wù wá láti máa ṣèṣekúṣe, ogun tó ń lọ lọ́wọ́ ló fà á.” Ọmọ ogun ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan sọ pé: “Ojú oníṣekúṣe ni gbogbo èèyàn fi ń wò wá, àmọ́ ọmọdé ni wá, a sì lè kú kílẹ̀ ọ̀la tóó mọ́.”

Àwọn nǹkan ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ táwọn tó la ogun náà já fojú rí, kó ìdààmú tó pọ̀ bá wọn. Títí dòní olónìí àwọn kan lára wọn, títí kan àwọn tó jẹ́ ọmọdé nígbà náà lọ́hùn-ún, máa ń díjì, tó sì máa ń ṣe wọ́n bíi pé ogun náà tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í jà. Ọ̀pọ̀ ò gbà pé Ọlọ́run wà mọ́, wọ́n sì ṣe ó dìgbóṣe sí ìwà rere. Torí pé wọn ò ṣe tán àtigbọ́ràn sí ìjọba yòówù kó gbé ìlànà kalẹ̀ nípa ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́, ńṣe lọ̀rọ̀ ọ̀hún dọ̀rọ̀ bó-ṣe-dáa ò sí mọ́, bó-ṣe-gbà ló kù.

Ìwà Tuntun

Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn èèyàn gbé àbájáde ìwádìí tí wọ́n ṣe nípa ìhà tí ẹ̀dá kọ sí ìbálòpọ̀ jáde. Irú ìwádìí kan bẹ́ẹ̀ tó wáyé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1940 ni ìwádìí olójú ìwé ẹgbẹ̀rin [800], èyí tí wọ́n pè ní Kinsey Report. Nítorí ìwádìí yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ fàlàlà nípa ìbálòpọ̀, tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ń yọ́ ọ sọ tẹ́lẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àbùmọ́ wà nínú iye èèyàn tí ìròyìn náà sọ pé ó ń lọ́wọ́ sí bíbẹ́yà kan náà lòpọ̀ àtàwọn ìṣekúṣe bíburú jáì mìíràn, ìwádìí náà fi hàn pé lẹ́yìn ogun ni ìwà rere bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn.

Àkókò kan tiẹ̀ wà táwọn èèyàn ń sapá láti máa ṣe ohun tó bójú mu tó sì ṣeé gbọ́ sétí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n rí sí i pé àwọn ò gbàgbàkugbà láyè lórí rédíò, nínú sinimá àti lórí tẹlifíṣọ̀n. Àmọ́, fúngbà díẹ̀ nìyẹn ṣá o. Ọ̀gbẹ́ni William Bennett, akọ̀wé ètò ẹ̀kọ́ tẹ́lẹ̀rí lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ṣàlàyé pé: “Láàárín ọdún 1960 sí ọdún 1969, lọ́gán lorílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn látinú ọ̀làjú lọ sínú ohun tá a lè pè ní ojú àlàsódì.” Bọ́rọ̀ sì ṣe rí lọ́pọ̀ ilẹ̀ náà nìyẹn. Kí ló fà á ná tí ìwà rere fi jó rẹ̀yìn láàárín ọdún 1960 sí ọdún 1969?

Láàárín àkókò yìí làwọn obìnrin bẹ̀rẹ̀ sí í jà fẹ́tọ̀ọ́ òmìnira, ìyípadà bá àṣà ìbálòpọ̀, àwọn èèyàn sì ń dá a láṣà pé ìwà tuntun ti gbòde. Ìgbà yìí kan náà ni wọ́n ṣe àwọn oògùn máàlóyún. Léyìí tó sì ti wá di pé àwọn èèyàn lè bára wọn lò pọ̀ kó má sì doyún yìí, bí ìbálòpọ̀ ní fàlàlà ṣe dohun tó wọ́pọ̀ nìyẹn, táwọn èèyàn sì ń gbéra wọn sùn láìná wọn ní nǹkan kan.

Lákòókò yìí kan náà, àwọn iléeṣẹ́ ìtẹ̀wé, ilé iṣẹ́ sinimá, àtàwọn iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n náà dẹwọ́ ìlànà ìwà rere tí wọ́n ń tẹ̀ lé. Nígbà tó ṣe, Ọ̀gbẹ́ni Zbigniew Brzezinski, tó jẹ́ olórí aláàbò fún National Security Council lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀rí, sọ èrò rẹ̀ lórí ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀ lé bí wọ́n bá fẹ́ gbé ohunkóhun jáde lórí tẹlifíṣọ̀n, ó ní: “Wọ́n máa ń gbé bíbọlá fúnra ẹni lárugẹ, wọ́n máa ń gbé ìwà ipá àti ìwà ìpáǹle sáfẹ́fẹ́ bíi pé kò sóun tó burú nínú ẹ̀, wọ́n sì máa ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ.”

Láàárín ọdún 1970 sí ọdún 1979 sì rèé, ẹ̀rọ fídíò ti wọ́pọ̀ gan-an. Àwọn èèyàn lè wà nínú yàrá wọn kí wọ́n sì máa wo àwòrán àwọn tó wà níhòòhò níbi tí wọ́n ti ń bára wọn ṣèṣekúṣe, irú èyí tí wọn ò jẹ́ lọ wò nílé sinimá. Lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí pàápàá, láwọn orílẹ̀-èdè jákèjádò àgbáyé, ẹnikẹ́ni tó bá ní kọ̀ǹpútà lè lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì kó sì lọ wo àwòrán ìṣekúṣe tó burú kọjá sísọ.

Àbájáde irú ìwà wọ̀nyí sì máa ń múni láyà pami. Wọ́dà kan sọ láìpẹ́ yìí ní ọgbà ẹ̀wọ̀n kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pé: “Ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, bí wọ́n bá kó àwọn ọmọdé wá sọ́gbà ẹ̀wọ̀n, mo máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ṣíṣe ohun tó dáa àti bí wọ́n ṣe lè yẹra fún ṣíṣe ohun tí kò dáa. Àmọ́, ohun tí mò ń sọ kì í tiẹ̀ yé àwọn ọmọdé tí wọ́n ń kó wá báyìí.”

Ibo Ló Kù Téèyàn Lè Wá Ìrànlọ́wọ́ Gbà?

A ò lè wá ìtọ́sọ́nà lórí ìwà rere gba ṣọ́ọ̀ṣì lọ. Nítorí pé kàkà káwọn oníṣọ́ọ̀ṣì máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà òdodo bí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe ṣe ní ọ̀rúndún kìíní, wọ́n ti sọ ara wọn di apá kan ayé yìí àti apá kan ìwà láabi tó wà nínú ẹ̀. Òǹkọ̀wé kan béèrè pé: “Ogun wo ló tíì jà rí tí wọn ò sọ pé ó lọ́wọ́ Ọlọ́run nínú àti pé Ọlọ́run ló ń ti tọ̀tún tòsì tó ń bára wọn jà lẹ́yìn?” Lórí ọ̀rọ̀ ti pé káwọn èèyàn máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà òdodo Ọlọ́run, lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, àlùfáà kan nílùú New York City, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: ‘Ṣọ́ọ̀ṣì ni ètò kan ṣoṣo tóun mọ lágbàáyé yìí tó rọrùn láti wọ̀ ju ọkọ̀ èrò gan-an lọ.”

Dájúdájú, bí ìwà rere ṣe ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn nínú ayé yìí ti jẹ́ ká rí bó ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó pé ká wá nǹkan ṣe sí i. Kí wá ni ṣíṣe báyìí o? Ìyípadà wo ló yẹ kó wáyé? Ta ló máa mú ìyípadà náà wá, ọ̀nà wo ló sì máa gbé e gbà?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

“Pípa tí wọ́n pa àwọn èèyàn nípakúpa nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní [lọ́dún 1914 sí ọdún 1918] ò jẹ́ kí ẹ̀mí èèyàn jọ aráyé lójú mọ́”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

OHUN TÓ DÁA YÀTỌ̀ SÍ OHUN TÓ WUNI

Ìgbà kan wà tí ò ṣòro láti mọ̀ bí nǹkan bá dáa. Bákan méjì ló sì sábà máa ń jẹ́, yálà kéèyàn jẹ́ olóòótọ́, adúróṣinṣin, oníwà mímọ́ àti ẹni iyì tàbí kó máà jẹ́ bẹ́ẹ̀. Àmọ́, bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, ohun tó wu àwọn èèyàn ló kù tí wọ́n ń ṣe o, wọ́n ò sì fẹ́ mọ̀ bóyá ó dáa tàbí kò dáa. Ṣùgbọ́n ìyẹn náà ní wàhálà tiẹ̀ nínú gẹ́gẹ́ bí òpìtàn Gertrude Himmelfarb ṣe sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní The De-Moralization of Society, ó sọ pé: “Bó bá tiẹ̀ ṣeé sọ pé ẹnì kan lè ṣe ohun tó wù ú, òótọ́ ibẹ̀ ni pé, . . . ohun tó dáa ò lórúkọ méjì.”

Ó tún wá sọ pé àwọn tó ń ṣe ohun tó wù wọ́n máa ń ṣe ohun tó bá ṣáà ti wà ní ìbámu pẹ̀lú “ohun tí wọ́n gbà gbọ́, ohun tó bá bá èrò, ìwà, bí nǹkan ṣe rí lára wọn àti ìṣesí wọn mu. Wọ́n tún máa ń ṣe ohun táwọn èèyàn bá rò pé ó tọ́ láti ṣe àti ohun tí wọ́n bá ṣáà ti fẹ́. Kódà, ìwà wọn tún máa ń fi ẹ̀dùn ọkàn wọn àtàwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wọn hàn. Lédè kan ṣá, ohunkóhun tí ẹnì kan, àwùjọ tàbí ẹgbẹ́ kan bá ṣáà ti fẹ́ nígbàkigbà àti fún ìdí èyíkéyìí ni wọ́n máa ń ṣe.” Láwùjọ má-fayé-ni-mí-lára tá à ń gbé yìí, àwọn èèyàn kì í bẹ̀rù àtiṣe ohun tó wù wọ́n, ṣe ló dà bí ìgbà téèyàn mú irú ọjà tó fẹ́ lórí àtẹ. Bó bá wá jẹ́ bọ́ràn ṣe rí nìyí, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ṣíṣe ohun tó dáa àti híhùwà rere?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]

Ó túbọ̀ ń rọrùn sí i láti gbádùn eré ìnàjú tí ń tàbùkù síni

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́