ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/07 ojú ìwé 11-13
  • Kí Ló Dé Tí Wọ́n Ń Fi Mí Wé Àwọn Ẹlòmíì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Dé Tí Wọ́n Ń Fi Mí Wé Àwọn Ẹlòmíì?
  • Jí!—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Nìdí Tó Fi Máa Ń Dun Èèyàn Bí Wọ́n Bá Fi Í Wé Ẹlòmíì?
  • Ibi Tí Àfiwé Dáa Sí
  • Bá A Ṣe Lè Máa Fara Da Àfiwé Tí Ò Dáa
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kó O Máa Fi Ara Ẹ Wé Àwọn Ẹlòmíì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Jẹ́ Kí Ìtẹ̀síwájú Rẹ Máa Múnú Rẹ Dùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Èrò Tí Kò Tọ́?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • “Kì Í Bá Wọn Sọ̀rọ̀ Láìsí Àpèjúwe”
    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
Àwọn Míì
Jí!—2007
g 4/07 ojú ìwé 11-13

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Kí Ló Dé Tí Wọ́n Ń Fi Mí Wé Àwọn Ẹlòmíì?

“Ńṣe ni orí mi máa ń kanrin báwọn òbí tàbí olùkọ́ mi bá ń fi mí wé àwọn ẹlòmíì.”—Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Mia.a

“Bí wọ́n bá fi mí wé ẹlòmíì, ó máa ń jẹ́ kó dà bíi pé mi ò mọ nǹkan ṣe tó torí pé ó ti lè máa wù mí kí n dà bí ẹni tí wọ́n ń fi mí wé yẹn.”—Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ April.

NÍLÉ ìwé, olùkọ́ yín gbá ẹ lọ́rọ̀ torí pé o ò mọ ìṣirò tó ọmọ tẹ́ ẹ jọ wà ní kíláàsì. Nílé, òbí ẹ gbá ẹ lọ́rọ̀ torí pé o ò mọ ará tún ṣe bí i ti àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n ẹ obìnrin. Ẹnì kan tiẹ̀ sọ pé: “Arẹ̀wà ni màmá ẹ nígbà tó wà ní kékeré bíi tìẹ!” Ọ̀rọ̀ àbùkù gbáà lèyí nítorí pé ó máa mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì bóyá òburẹ́wà ni wọ́n ń pè ẹ́. Á wá dà bíi kíwọ náà lọgun lé wọn lórí pé: “Ṣẹ́ ẹ̀ mọ̀ péèyàn lèmi fúnra mi ni?” “Kí ló dé tó jẹ́ gbogbo ìgbà ṣáá lẹ̀ ń fi mí wé ẹlòmíì?”

Kí ló fà á tó fi máa ń dun èèyàn gan-an bí wọ́n bá fi í wé ẹlòmíì? Ṣó ní oore èyíkéyìí tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń ṣe fúnni? Kí lo lè ṣe báwọn èèyàn bá ń fi ẹ́ wé àwọn ẹlòmíì?

Kí Nìdí Tó Fi Máa Ń Dun Èèyàn Bí Wọ́n Bá Fi Í Wé Ẹlòmíì?

Ọ̀kan lára ìdí tí àfiwé fi máa ń dun èèyàn nígbà míì ni pé ó máa ń ta èèyàn lára. Ìyẹn ni pé ó lè jẹ́ àfiwé táwọn èèyàn ń ṣe yẹn gan-an lohun tíwọ fúnra ẹ ti ń rò nípa ara ẹ. Bí àpẹẹrẹ, Becky sọ pé: “Màá wo àwọn ọmọ táwọn míì máa ń gba tiwọn nílé ìwé màá sì ronú pé, ‘ká ní mo lè dà bíi tiwọn ni, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ì bá máa gba tèmi náà.’”

Kí ló máa ń mú kéèyàn ronú pé òun ò dáa tó àwọn míì ná? Ó dára, ìwọ ronú nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ara ẹ, èrò ẹ àti òye tó o ní. Ara ẹ kàn lè bẹ̀rẹ̀ sí í yí padà. Ó lè má rọrùn mọ́ fún ìwọ àtàwọn òbí ẹ láti jọ máa bára yín gbé. Ó sì ṣeé ṣe kí ojú tó o fi ń wo àwọn tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ ti yí padà gan-an. Nítorí náà, ó lè máa ṣe ẹ́ ní kàyéfì pé, ‘Ṣé béèyàn ṣe ń dàgbà ni mò ń dàgbà yìí?’

Bóyá ò ń ronú pé ọ̀nà kan ṣoṣo tó o lè gbà mọ̀ ni pé kó o máa fira ẹ wé àwọn ọ̀dọ́ míì tó jẹ́ pé bó ṣe ń ṣe ẹ́ ló ṣe ń ṣe àwọn náà. Ibi tí ọ̀rọ̀ náà sì wá léwu sí gan-an nìyẹn! Bó bá dà bíi pé ọ̀rọ̀ náà ò fi bẹ́ẹ̀ mu àwọn tíwọ ń fara wé lómi, ó di pé kó o máa ronú pé o ò dáa tó wọn. Torí náà báwọn kan tó dàgbà bá wá jàjà bi ẹ́ pé, ‘Kí ló dé tí o ò máa ṣe bíi ti lágbájá?’ ó di pé kó o parí èrò pé bí ìṣòro ẹ ṣe rí gan-an ni wọ́n sọ, pé ó ní láti jẹ́ pé lóòótọ́ ní nǹkan ń ṣe ẹ́!

Ẹnì kan tó ń jẹ́ April náà tún ṣàlàyé ìdí míì tí irú àfiwé bẹ́ẹ̀ fi lè bani nínú jẹ́, ó sọ pé, “báwọn èèyàn bá fi ẹ́ wé ẹlòmíì, pàápàá ẹnì kan tẹ́ ẹ jọ sún mọ́ra, ìyẹn lè mú kó o máa jowú onítọ̀hún kó o sì máa bínú sí i.” Mia mọ bó ṣe máa ń rí lára bí wọ́n bá fèèyàn wé ẹni téèyàn jọ sún mọ́ra. Ó dà bíi pé lemọ́lemọ́ làwọn òbí àtàwọn olùkọ́ Mia máa ń fi í wé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin. Ó wá sọ pé: “Wọ́n sọ gbogbo nǹkan tó ṣe láṣeyọrí nígbà tó wà ní ọjọ́ orí kan náà bíi tèmi fún mi.” Ibo lọ̀rọ̀ yẹn bọ́ sí lára ẹ̀? “Ó mú kó ṣe mí bíi pé ńṣe lèmi àtẹ̀gbọ́n mi obìnrin ń bára wa díje. Inú ẹ̀ tiẹ̀ máa ń bí mi nígbà míì.”

Nǹkan rere kankan kì í tìdí ká máa fini wé ẹlòmíì wá. Ìwọ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn tó sún mọ́ Jésù tímọ́tímọ́ jù lọ. Lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé, “awuyewuye gbígbónájanjan kan” wáyé láàárín àwọn àpọ́sítélì. Kí ló fa awuyewuye náà? Wọ́n ń fara wéra ni, wọ́n sì tún ń jiyàn pé “èwo nínú wọn ni ó dà bí ẹni tí ó tóbi jù lọ.” (Lúùkù 22:24) Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, àwọn àfiwé kan wà tó jẹ́ pé ibi tí wọ́n máa ń bọ́ sí lára èèyàn kì í dáa rárá. Àmọ́, ṣé gbogbo àfiwé ni ò dáa?

Ibi Tí Àfiwé Dáa Sí

Ìwọ wo àpẹẹrẹ ti Dáníẹ́lì àtàwọn Hébérù mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, bá a ti rí i kà nínú Bíbélì. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yìí ò fẹ́ láti jẹ àwọn oúnjẹ adùnyùngbà tí Ọba Bábílónì gbé fún wọn torí pé òfin Ọlọ́run ka irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ léèwọ̀. (Léfítíkù 11:4-8) Kí ẹni tí wọ́n yàn ṣe olùtọ́jú wọn lè gbà láti ràn wọ́n lọ́wọ́, Dáníẹ́lì kúkú ní kó ṣe ìdánwò kan fáwọn. Ó dábàá pé lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá táwọn bá ti ń jẹ oúnjẹ tí Òfin Ọlọ́run yọ̀ọ̀da pé káwọn máa jẹ, kó fi àwọn wé àwọn ọ̀dọ́ yòókù tó wà láàfin ọba. Kí ni àbájáde fífi tí wọ́n fi wọ́n wéra?

Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ní òpin ọjọ́ mẹ́wàá, ojú [àwọn Hébérù náà] sì fara hàn lọ́nà tí ó túbọ̀ dára sí i, tí wọ́n sì sanra sí i ní ẹran ara ju gbogbo àwọn ọmọ tí ń jẹ àwọn oúnjẹ adùnyùngbà ọba.” (Dáníẹ́lì 1:6-16) Má ṣe gbàgbé pé kì í ṣe nítorí pé Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní agbára tó táyọ lọ̀rọ̀ wọn fi yọrí sí rere o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó mú kó ṣeé ṣe ni pé àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Hébérù náà yàn láti ṣègbọràn sí òfin tí Ọlọ́run fún àwọn èèyàn rẹ̀.

Ṣó o lè ríbi tọ́rọ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùrin Hébérù yìí gbà bá tìẹ mu? Bó o bá ń hùwà tó bá Bíbélì mu, wàá dá yátọ́ gedegbe láàárín àwọn ọ̀dọ́ mìíràn. Ó lè rú àwọn èèyàn kan tí wọ́n bá kíyè sí bó o ṣe yàtọ̀ yìí lójú kí wọ́n ‘sì máa bá a lọ ní sísọ̀rọ̀ ẹ tèébútèébú.’ (1 Pétérù 4:3, 4) Àmọ́, àwọn míì á rí àbájáde rere ìwà àtàtà tó o bá ń hù, ìyẹn sì lè sún wọn láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. (1 Pétérù 2:12) Nínú irú àwọn ọ̀ràn bí èyí, kò burú bí wọ́n bá fi èèyàn wé ẹlòmíì.

Ká fini wéra tún lè wúlò lọ́nà míì. Bí àpẹẹrẹ, o lè ronú pé ò ń ṣe ipa tó pọ̀ tó lára iṣẹ́ ilé táwọn òbí ẹ yàn fún ẹ, bó bá ṣẹlẹ̀ pé o fi èyí tó o ṣe wé èyí táwọn àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n ẹ lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin ń ṣe. Àmọ́, àwọn òbí ẹ lè máà rí i bẹ́ẹ̀. Kí wọ́n bàa lè tún ojú tó o fi ń wo ọ̀ràn náà ṣe, wọ́n lè lo àpẹẹrẹ kan nínú Bíbélì kí wọ́n sì ní kó o fi ìwà àti ìṣe ẹ wé tẹni tí Bíbélì sọ̀rọ̀ ẹ̀ yẹn.

Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè rán ẹ létí pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń pè é ní Olúwa àti Olùkọ́, ó fínnú fíndọ̀ wẹ ẹsẹ̀ wọn. (Jòhánù 13:12-15) Lẹ́yìn náà, wọ́n wá lè sọ pé kó o fìwà jọ Jésù nípa jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti òṣìṣẹ́ kára. Kódà, Bíbélì gba gbogbo àwa Kristẹni, tàgbà tèwe, níyànjú pé ká má ṣe dẹ́kun láti máa fi ara wa wé Kristi ká sì máa gbìyànjú láti “tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21) Irú àfiwé yìí máa ń mú ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì máa ń jẹ́ ká hùwà táá túbọ̀ máa mú inú Jèhófà dùn.

Bá A Ṣe Lè Máa Fara Da Àfiwé Tí Ò Dáa

Òótọ́ ni pé inú lè máa bí ẹ kí ọkàn ẹ sì máa bà jẹ́ bí wọ́n bá ń fi ẹ́ wé àwọn àbúrò ẹ̀, àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ tàbí ẹnì kan tẹ́ ẹ jọ jẹ́gbẹ́, tírú àfiwé bẹ́ẹ̀ ò sì bá ẹ lára mu. Báwo lo ṣe lè fara dà á? Sólómọ́nì, ọlọgbọ́n Ọba sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú.” (Òwe 19:11) Báwo ni ìjìnlẹ̀ òye ṣe lè ṣèrànlọ́wọ́? Bóyá o ò tiẹ̀ rò pé ìjìnlẹ̀ òye lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o má sì mọ̀ pé torí ire ara tìẹ lẹni tó ń ṣe irú àfiwé bẹ́ẹ̀, yálà òbí tàbí olùkọ́, ṣe ń ṣe é. Cathy sọ pé: “Bí ẹnì kan bá fi mí wé ẹlòmíì, mó máa ń bi ara mi pé, ‘Ọ̀nà wo lonítọ̀hún ń gbà láti ràn mí lọ́wọ́?’” Cathy rí i pé bóun bá wò ó pé torí ire ara òun ni, òun kì í sábà torí ẹ bọkàn jẹ́ tàbí kínú bí òun.

Àmọ́, kí lo lè ṣe bó bá ṣe ẹ́ bíi pé wọn ò lè ṣe kí wọ́n má fi ẹ́ wé ẹlòmíì? Bí àpẹẹrẹ, ó lè dà bíi pé ìgbà gbogbo ṣáá ni màmá tàbí bàbá rẹ máa ń fi ẹ́ wé ọ̀kan lára àwọn àbúrò ẹ tàbí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ. O ò ṣe kúkú tọ irú òbí bẹ́ẹ̀ lọ kó o sì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé fún un kó lè mọ bí irú àfiwé bẹ́ẹ̀ ṣe máa ń rí lára ẹ. Òbí ẹ lè má mọ̀ pé àfiwé náà máa ń ta ẹ́ lára.

Àmọ́, kó o má ṣe gbàgbé pé ọ̀tọ̀ ni “ìgbà sísọ̀rọ̀,” ọ̀tọ̀ sì ni “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́.” (Oníwàásù 3:7) Dípò kí ìbínú ru bò ẹ́ lójú bí wọ́n bá tún fi ẹ́ wé ẹlòmíì, ì bá dáa kó o dúró títí ti inú ẹ á fi tutù pẹ̀sẹ̀, lẹ́yìn náà ni kó o wá bá òbí ẹ tàbí ẹni yòówù tó ń fi ẹ́ wé ẹlòmíì lọ́nà tí kò bá ẹ lára mu, sọ̀rọ̀. Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ ẹ á túbọ̀ wọ onítọ̀hún létí.—Òwe 16:23.

Lọ́pọ̀ ìgbà, ìwọ pàápàá lè dín bí àfiwé tí kò bá ẹ lára mu á ṣe máa dùn ẹ́ tó kù nípa mímọ ibi tó o dáa sí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kankan fojú tẹ́ńbẹ́lú èwe rẹ.” (1 Tímótì 4:12) Ọmọdé ṣì ni Tímótì nígbà tí wọ́n yàn án sípò gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe káwọn kan ti máa fi Tímótì wé àwọn ọkùnrin mìíràn tí wọ́n dàgbà jù ú lọ, tí wọ́n sì nírìírí jù ú lọ, kí èyí má sì bá Tímótì lára mu. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, kò sídìí kankan fún wọn láti máa ṣe àfiwé tí kò dáa bẹ́ẹ̀. Bí Tímótì tilẹ̀ jẹ́ ọ̀dọ́, ó ní ìrírí tó pọ̀ nígbà tó ń rìnrìn-àjò pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù. Ó sì mọ bá a ṣeé lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó múná dóko. Ó sì fi tinútinú bójú tó àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ.—1 Kọ́ríńtì 4:17; Fílípì 2:19, 20.

Nítorí náà, nígbà míì tí wọ́n bá tún fi ẹ́ wé ẹlòmíì lọ́nà tí kò bá ẹ lára mu, bí ara ẹ pé, ‘Ṣé òótọ́ lohun tí wọ́n ń sọ nípa mi?’ Bí òótọ́ díẹ̀ bá wà nínú ohun tí wọ́n sọ, gbìyànjú láti kẹ́kọ̀ọ́ látinú ẹ̀. Àmọ́, bó bá jẹ́ pé àfiwé ṣákálá kan ni, bíi kí wọ́n sọ pé, “Ìwọ ò lè ṣe bíi ti àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n ẹ ni?” Má ṣe gbà á sódì, gbìyànjú láti rí ibi tí àfiwé náà dáa sí.

Kì í ṣe nípa fífi ẹ́ wé aláìpé míì bíi tìẹ ni Jèhófà Ọlọ́run ṣe ń mọ bó o ṣe wúlò tó. (Gálátíà 6:4) Ó máa ń wò ré kọjá ìrísí òde ara, ó sì máa ń lóye irú ẹni tó o jẹ́ nínú ọkàn ẹ lọ́hùn-ún. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Kódà, kì í ṣe ohun tó o jẹ́ nìkan ni Jèhófà ń rí, ó tún ń rí ohun tó ò ń gbìyànjú láti jẹ́ pẹ̀lú. (Hébérù 4:12, 13) Ó máa ń fi àyè àṣìṣe sílẹ̀, ó sì máa ń wá apá ibi tó o dáa sí. (Sáàmù 130:3, 4) Mímọ àwọn nǹkan yìí lásán ti tó láti mú kó o fara dà á nígbà tí wọ́n bá fi ẹ́ wé àwọn ẹlòmíì.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Irú àfiwé wo ló máa ń bí ẹ nínú?

◼ Bó bá jẹ́ ìgbà gbogbo làwọn òbí ẹ máa ń fi ẹ́ wé àwọn ẹlòmíì, kí lo máa ṣe sí i?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]

“Kì í wù mí kẹ́ni tó ń bá mi wí dárúkọ ẹlòmíì kó sì wá sọ pé, ‘Ìwọ ò ṣe máa ṣe bíi ti lágbájá,’ àmọ́ màá fẹ́ kó kọ́kọ́ yìn mí fún ohun rere tí mo ṣe, lẹ́yìn náà, kó wá fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣàlàyé ibi tí mo kù díẹ̀ káàtó sí.”—Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Natalie

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

O kúkú lè fìrẹ̀lẹ̀ ṣàlàyé bí àfiwé náà ṣe máa ń rí lára ẹ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́