ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 90
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Èrò Tí Kò Tọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Èrò Tí Kò Tọ́?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Irú ojú wo lo fi ń wo ara rẹ?
  • Kí nìdìí tó fi ṣe pàtàkì?
  • Ohun tó o lè ṣe
  • Ka púpọ̀ sí i nípa ẹ̀
  • Kí Nìdí Táwọn Ẹgbẹ́ Mi Ò Fi Gba Tèmi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Ayé Bá Sú Mi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Táwọn Òbí Mi Bá Sọ Pé Kí N Má Lo Ìkànnì Àjọlò?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Kí Ni Kí N Ṣe Bí Mi Ò Bá Ṣe Dáadáa Tó?
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 90
Obìnrin kan ń ro èrò tí kò tọ́ torí pé òjò tó ṣú bolẹ̀ pa á

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Èrò Tí Kò Tọ́?

  • Irú ojú wo lo fi ń wo ara rẹ?

  • Kí nìdìí tó fi ṣe pàtàkì?

  • Ohun tó o lè ṣe

  • Ka púpọ̀ sí i nípa ẹ̀

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Irú ojú wo lo fi ń wo ara rẹ?

  • Eni tó lérò tó dáa

    “Mo ń sapá kí n lè láyọ̀ kí n má sì máa tètè bínú. Ó wù mí kí n máa rẹ́rìn-ín músẹ́, kínú mi sì máa dùn lójoojúmọ́.”—Valerie.

  • Ẹni tó lérò tí ò dáa

    “Ohun tó kọ́kọ́ máa ń wá sí mi lọ́kàn nígbà tí nǹkan tó dáa bá ṣẹlẹ̀ ni pé, kò lè jóòótọ́ àbí pé bóyá èèṣì ni.”—Rebecca.

  • Ẹni tó fara mọ́ bí nǹkan bá ṣe rí gan-an

    “Tí mo bá lérò tó dáa nípa nǹkan, tí kò sì rí bí mo ṣe fẹ́, ó máa ń dùn mí gan-an. Tí mo bá sì lérò tí kò dáa, àmọ́ tọ́rọ̀ ò rí bí mo ṣe rò, kò sígbà tí màá láyọ̀. Torí náà, bí mo ṣe jẹ́ ẹni tó máa ń fara mọ́ bí nǹkan bá ṣe rí gan-an máa ń jẹ́ kí n lè lóye bọ́rọ̀ bá ṣe rí gẹ́lẹ́.”—Anna.

Kí nìdìí tó fi ṣe pàtàkì?

Bíbélì sọ pé “ẹni tí inú rẹ̀ ń dùn máa ń jẹ àsè nígbà gbogbo.” (Òwe 15:15) Ó ṣe kedere pé ẹni tó bá ní èrò tó tọ́ nípa ìgbésí ayé máa ń láyọ̀ ju ẹni tó ń lérò tí kò dáa. Yàtọ̀ síyẹn, ẹni tó bá ń ronú lọ́nà tó tọ́ tètè máa ń lọ́rẹ̀ẹ́. Àmọ́, kò sẹ́ni tó máa fẹ́ ṣọ̀rẹ́ ẹni tínú ẹ̀ máa ń bà jẹ́, tó sì máa ń ro èrò tí kò tọ́ nígbà gbogbo .

Síbẹ̀, tó o bá tiẹ̀ máa ń lérò tó dáa, ìyẹn ò ní kó o má láwọn ìṣòro kan nígbèésí ayé. Bí àpẹẹrẹ:

  • Kò sígbà tó ò ní máa gbọ́ ìròyìn nípa ogun, ìpániláyà tàbí ìwà ọ̀daràn.

  • Ìṣòro ìdílé lè máa bá ẹ fínra.

  • Ìwọ náà máa ń ṣàṣìṣe, o sì láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó yẹ kó o borí.

  • Ọ̀rẹ́ ẹ lè sọ ohun kan tàbí kó ṣe ohun kan tó dùn ẹ́.

Dípò tí wàá fi gbọ́kàn kúrò lórí ìṣòro yìí tàbí tí wàá jẹ́ kó gbà ẹ́ lọ́kàn, ńṣe ni kó o ní èrò tó tọ́ nípa ẹ̀. Tó o bá ń ní èrò tó dáa, kò ní jẹ́ kó o máa ronú lọ́nà tí kò yẹ, wàá lè máa fojú tó tọ́ wo ìṣòro ìgbésí ayé, kò sì ní sú ẹ.

Obìnrin kan ń ro èrò tó tọ́ nígbà tí òjò náà dá

Kò sí bí ìṣòro ìgbésí àyé ṣe nira tó, fọkàn balẹ, ó máa tó dópin

Ohun tó o lè ṣe

  • Gbà pé o lè ṣàṣìṣe.

    Bíbélì sọ pé: “Kò sí olódodo kan láyé tí ń ṣe rere, tí kò lẹ́ṣẹ̀.” (Oníwàásù 7:20, Bibeli Ìròhìn Ayọ̀) Torí pé o máa ń ṣàṣìṣe kò túmọ̀ sí pé o ò wúlò, ńṣe nìyẹn ń jẹ́ kó o mọ̀ pé o ò kì í ṣẹni pípé.

    Bó o ṣe lè ní èrò tó tọ́: Sapá kó o lè ṣàtúnṣe àwọn ibi tó o kù sí, àmọ́ má gbàgbé pé o ò kì í ṣẹni pípé. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Caleb sọ pé “Mo máa ń sapá kí n lè gbọ́kàn kúrò lórí àwọn àṣìṣe mi kí n má bàa rẹ̀wẹ̀sì, dípò ìyẹn ṣe ni mo máa ń kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn kí n lè ṣàtúnṣe.”

  • Má ṣe fara wé ẹlòmíì.

    Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí á di agbéraga, kí a má ṣe máa bá ara wa díje, kí a má sì máa jowú ara wa.” (Gálátíà 5:26) Tó o bá ń wo àwọn fọ́tò ibi àpèjẹ tí wọn ò pè ẹ́ sí lórí ìkànnì àjọlò, ńṣe lá máa dùn ẹ́ tínú á sì máa bí ẹ gan-an. Inú tiẹ̀ lè bí ẹ débi pé wàá gbà pé àwọn ọ̀rẹ́ ẹ ò nífẹ̀ẹ́ ẹ.

    Bó o ṣe lè ní èrò tó tọ́: Fi sọkàn pé gbogbo àpèjẹ kọ́ ni wọ́n á máa pè ẹ́ sí. Yàtọ̀ síyẹn, kì í ṣe gbogbo ohun tẹ́nì kan jẹ́ la máa ń rí nínú àwọn fọ́tò tí wọ́n máa ń gbé sórí ìkànnì àjọlò. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Alexis sọ pé “Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó dáa nígbésí ayé nìkan làwọn èèyàn sábà máa ń gbé sórí ìkànnì àjọlò, wọn ò kì í gbé àwọn ìṣẹlẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ lárinrin síbẹ̀.”

  • Jẹ́ kí àlàáfíà jọba nínú ìdílé rẹ.

    Bíbélì sọ pé: “Tó bá ṣeé ṣe, nígbà tó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ló wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlááfíà.” (Róòmù 12:18) Kò sí bó o ṣe lè yí ìwà ẹlòmíì pa dà pátápátá, àmọ́ o lè yíwà tìẹ pa dà. O lè pinnu pé wà á jẹ́ ẹlẹ́mìí àlááfíà.

    Bó o ṣe lè ní èrò tó tọ́: Má ṣe dá kún ìṣoro tó wà nínú ìdílé rẹ, àmọ́ jẹ́ kí àlááfíà jọba nínú ìdílé rẹ bó ṣe yẹ kó rí láàárín ìwọ àtọ̀rẹ́ ẹ. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Melinda sọ pé “Aláìpé ni gbogbo wa, kò sígbà tá ò ní máa ṣẹ ara wa, àmọ́ ọwọ́ wa ló wà bóyá a máa jẹ́ ẹlẹ́mìí àlááfíà tàbí a ò ní jẹ́ bẹ́ẹ̀.”

  • Jẹ́ ẹni tó moore.

    Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa dúpẹ́.” (Kólósè 3:15) Tó o bá lẹ́mìí ìmoore, wàá lè pọkan pọ̀ sórí àwọn ohun rere tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ẹ dípò tí wàá fi máa ronú nípa àwọn ohun tó ò nífẹ̀ẹ́ sí.

    Bó o ṣe lè ní èrò tó tọ́: Mọ ìṣòro tó o ní, àmọ́ máa ronú lórí àwọn ohun rere tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ẹ. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Rebecca sọ pé “Mo ni ìwé kan tí mo máa ń kọ àwọn ohun rere tó ṣẹlẹ̀ sí mi lọ́joojúmọ́ sí, kí n lè máa rántí pé bí mo tiẹ̀ níṣòro, àwọn ohun rere wà tó yẹ kí n máa ronú nípa ẹ̀.”

  • Irú ọ̀rẹ́ wo lo ní?

    Bíbélì sọ pé: “Ẹgbẹ́ búburú ń ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríntì 15:33) Tó bá jẹ́ pé ẹni tó máa ń ṣàríwísí, tó máa ń bú èèyàn tàbí tó máa ń bínú lo yàn lọ́rẹ̀ẹ́, kò sígbà tó ò ní máa hùwà bíi tiwọn.

    Bó o ṣe lè ní èrò tó tọ́: Nígbà táwọn ọ̀rẹ́ ẹ bá níṣòro tó le koko, ó lè mú kí wọ́n banú jẹ́, wọ́n sì lè ní ẹ̀dùn ọkàn fúngbà díẹ̀. Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nírú àkókò bẹ́ẹ̀, àmọ́, má ṣe jẹ́ kí ìṣòro wọn bò ẹ́ mọ́lẹ̀. Ọ̀dọ́bìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Michelle sọ pé “Kò yẹ kọ́ jẹ́ àwọn tó máa ń ronú lọ́nà tí kò tọ́ làá máa bá kẹ́gbẹ́.”

Ka púpọ̀ sí i nípa ẹ̀

Bíbélì sọ pé “àkókò tí nǹkan le gan-an, tó sì nira” là ń gbé. (2 Tímótì 3:1) Kò rọrùn kéèyàn lérò tó dáa nínú àyé tó kún fún ìṣòro tá à ń gbé yìí. Ka orí kọkànlá nínú ìwé Bíbélì Kọ́ Wa tí àkórí rẹ̀ sọ pé “Kí Nìdí Tí Ìyà Fi Pọ̀ Láyé?” lórí ìkànnì jw.org.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Emma

“Nígbà míì térò tí kò tọ́ bá ń wá sí mi lọ́kàn, ṣe ni mo máa ń kọ ohun tó dáa àti ohun tí kò dáa nípa nǹkan ọ̀hún. Ìyẹn máa ń jẹ́ kí n lè fojú tó tọ́ wo ọ̀ràn náà, mi ò sì ní jẹ́ kó fa ẹ̀dùn ọkàn fún mi. Bí ohun kan bá tiẹ̀ dà bí èyí tí kò ní dáa, ó ṣì máa níbi tó dáa sí.”—Emma.

Jesse

“Tí èrò tí kò tọ́ bá ti ń wá sí mi lọ́kàn, ṣe ni mo máa ń wá ẹni tí mo lè ràn lọ́wọ́ tàbí ohun tí mo lè ṣe fáwọn ẹlòmíì. Jésù sọ pé àyọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni, bí mo ṣe ń ran àwọn míì lọ́wọ́ kì í jẹ́ kí ń máa ro èrò tí kò tọ́.”—Jesse.

Àtúnyẹ̀wò: Báwo ni mo ṣe lè yẹra fún èrò tí kò tọ́?

Gbà pé o lè ṣàṣìṣe. Sapá kó o lè ṣàtúnṣe síbi tó o kù sí, àmọ́ má gbàgbé pé o ò kì í ṣe ẹni pípé.

Má ṣe fara wé ẹlòmíì. Má ṣe jẹ́ kó dùn ẹ́ tí wọn ò bá pè ẹ́ síbi àpèjẹ kan.

Jẹ́ kí àlàáfíà jọba nínú ìdílé rẹ. Dípò tí wàá fi dá kún ìṣòro tó wà nínú ìdílé rẹ, ṣe ni kó o máa wá àlááfíà.

Jẹ́ ẹni tó moore. Mọ ìṣòro tó o ní, àmọ́ máa ronú lórí àwọn ohun rere tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ẹ.

Irú ọ̀rẹ́ wo lo ní? Wá àwọn ọ̀rẹ́ tí kì í jẹ́ kí ìṣòro mú wọ́n rẹ̀wẹ̀sì tàbí tó ń jẹ́ kí wọ́n banújẹ ju bó ṣe yẹ lọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́