Ojú Ìwòye Bíbélì
Béèyàn Bá Ti Ń Ṣe Ohun Tó Dáa Lójú Ara Ẹ̀ Ṣó Ti Tán Náà Nìyẹn?
Ọ̀DỌ́MỌBÌNRIN kan tó ń jẹ́ Allison sọ pé: “Mi ò fi ohunkóhun jẹ ara mi níyà, mo sì máa ń gbìyànjú láti hùwà ọmọlúwàbí sí gbogbo èèyàn.” Bíi ti Allison lèrò àwọn kan rí. Wọ́n gbà pé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kéèyàn máa gbé ìgbé ayé ẹ̀ nìyẹn.
Ó sì dá àwọn míì lójú pé báwọn bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, kò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run, báwọn èèyàn bá ṣáà ti mọ ìwà rere mọ́ àwọn. Wọ́n gbà pé ó máa ń yá Ọlọ́run lára láti dárí jini ju kó dáni lẹ́bi lọ.
Bó bá jẹ́ báyìí lọ̀rọ̀ rí, a jẹ́ pé ohun tó dáa lójú ẹnì kan lè máà dáa lójú ẹlòmíì nìyẹn o. Àmọ́, kí ni Bíbélì sọ? Kí la lè ṣe báa bá fẹ́ rójú rere Ọlọ́run? Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ ẹni tó dáa lójú Ọlọ́run?
A Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Kí Ẹlẹ́dàá Máa Tọ́ Wa Sọ́nà
Nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá wa, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti máa fún wa nítọ̀ọ́ni lórí irú ìwà tó yẹ ká máa hù. (Ìṣípayá 4:11) Nínú Bíbélì, Ọlọ́run fún wa láwọn òfin àti ìlànà tá a ó fi máa mọ irú ìwà tó yẹ ká máa hù àti bó ṣe yẹ ká máa sin òun. Ọlọ́run sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Ẹ ṣègbọràn sí ohùn mi, kí ẹ sì ṣe àwọn nǹkan ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín; dájúdájú, ẹ ó sì di ènìyàn mi, èmi alára yóò sì di Ọlọ́run yín.”—Jeremáyà 11:4.
Nítorí náà béèyàn bá fẹ́ dáa lójú Ọlọ́run àfi kó mọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ń fẹ́, kó sì máa fi wọ́n sílò nígbèésí ayé rẹ̀. Ká sọ pé o fẹ́ láti di ọ̀rẹ́ ẹnì kan. Ó dájú pé wàá fẹ́ láti mọ ìwà tóní tọ̀hún fẹ́ kó o máa hù sóhun, wàá sì mọ ìwà rẹ̀ fún un. Bíbélì fi hàn pé bíi ti Ábúráhámù baba ńlá, a lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà, ìyẹn ni pé ká di ẹni tí Ọlọ́run máa ṣojúure sí. (Jákọ́bù 2:23) Àmọ́, níwọ̀n bí ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ti pọ̀ fíìfíì ju ohun táwa èèyàn lè lérò lọ, a ò gbọ́dọ̀ retí pé kí Ọlọ́run yí àwọn ohun tó fẹ́ padà kó lè bá ohun tó wù wá mu.—Aísáyà 55:8, 9.
Bí Ìgbọràn Ṣe Ṣe Pàtàkì Tó
Ṣóòótọ́ ni pé a ò ní rí ojúure Ọlọ́run bá a bá ń ṣàìgbọràn sáwọn àṣẹ tó dà bíi pé kò tó nǹkan? Àwọn kan lè máa ronú pé kò ṣe pàtàkì pé kéèyàn máa ṣègbọràn sáwọn àṣẹ tó dà bíi pé kò tó nǹkan. Àmọ́, kò sí òfin èyíkéyìí tí Ọlọ́run ṣe tá a lè sọ pé kò ṣe pàtàkì. Kíyè sí i pé nínú Bíbélì, 1 Jòhánù 5:3 ò fìyàtọ̀ sáàárín àwọn òfin Ọlọ́run nígbà tó sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti pa gbogbo òfin Ọlọ́run mọ́, à ń fi hàn pé ìfẹ́ tó dénú la ní fún un.—Mátíù 22:37.
Jèhófà mọ̀ pé aláìpé ni wá, pé kò sì sí bá a ṣe lè rìn kórí má mì. Nítorí náà, tá a bá tọrọ ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, tá a sì sa gbogbo ipá wa láti má ṣe dẹ́ṣẹ̀ náà mọ́, ó máa dárí jì wá. (Sáàmù 103:12-14; Ìṣe 3:19) Àmọ́, ṣó yẹ ká mọ̀ọ́mọ̀ rú àwọn kan lára òfin Ọlọ́run ká wá rò pé dáadáa tá a bá ṣe nínú àwọn ọ̀ràn míì á bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀? Àpẹẹrẹ kan nínú Bíbélì fi hàn pé kò ní tìtorí ìyẹn dárí jì wá.
Èyí tó bá wu Sọ́ọ̀lù Ọba Ísírẹ́lì lára àwọn òfin Ọlọ́run ló máa ń ṣègbọràn sí. Nígbà tí Ọlọ́run ní kó lọ bá àwọn ará Ámálékì jagun, ó pàṣẹ fún un pé kó “fi ikú pa” gbogbo ohun ọ̀sìn wọn, láìṣẹ́ ọ̀kan kù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sọ́ọ̀lù ṣègbọràn sáwọn àṣẹ míì tí Ọlọ́run pa, ó pàpà ṣàìgbọràn, ó sì dá “èyí tí ó dára jù lọ nínú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran” sí. Kí ló fà á tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Àwọn ẹran náà wọ òun àtàwọn èèyàn yòókù lójú ni.—1 Sámúẹ́lì 15:2-9.
Nígbà tí wòlíì Sámúẹ́lì bi Sọ́ọ̀lù pé kí ló fà á tó fi ṣàìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run, Sọ́ọ̀lù yarí, ó sì sọ pé iṣẹ́ tí Jèhófà rán òun gan-an lòún jẹ́. Ó mẹ́nu ba ohun rere tóun àtàwọn èèyàn náà ti ṣe, tó fi dórí àwọn ẹbọ tí wọ́n rú sí Ọlọ́run. Sámúẹ́lì wá bi í pé: “Jèhófà ha ní inú dídùn sí àwọn ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ bí pé kí a ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà? Wò ó! Ṣíṣègbọràn sàn ju ẹbọ, fífetísílẹ̀ sàn ju ọ̀rá àwọn àgbò.” (1 Sámúẹ́lì 15:17-22) Nítorí náà, a ò lè fi ẹbọ rírú ṣe bojúbojú, ìyẹn ni pé ká máa ṣe àwọn nǹkan míì tó dára ká wá rò pé Ọlọ́run á tìtorí ẹ̀ dárí jì wá tá a bá ṣàìgbọràn sí òfin rẹ̀.
Àwọn Ìlànà Ọlọ́run Jẹ́ Ká Mọ̀ Pé Ó Nífẹ̀ẹ́ Wa
Nítorí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, kò fẹ́ ká máa ṣe kámi-kàmì-kámi nípa bá a ṣe lè máa ṣe ohun tó wù ú. Nínú Bíbélì, Ọlọ́run fún wa ní ìlànà tó ṣe kedere lórí ìwà tó yẹ ká máa hù, ìyẹn ló fi sọ pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.” (Aísáyà 30:21) Èrò táwọn èèyàn ní nípa ìwà tó yẹ ká máa hù ta kora, bá a bá sì ní ká máa yẹ èrò tí ò ṣọ̀kan wọ̀nyí wò, kò dájú pé a máa rí èyí tó ṣeé tẹ̀ lé, a sì máa dààmú gidigidi. Àmọ́, a lè yẹra fún ìdààmú bẹ́ẹ̀ bá a bá ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run. Ó sì dájú pé oore ńlá ni títẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run máa ṣe wá, níwọ̀n bó ti ‘ń kọ́ wa ká lè ṣe ara wa láǹfààní.’—Aísáyà 48:17, 18.
Ewu wo ló tiẹ̀ wà nínú ká máa dá pinnu òun tá a rò pó dáa? Kò sẹ́ni tí kì í fẹ́ hùwà ìmọtara-ẹni-nìkan nínú gbogbo wa. Ọkàn tiwa fúnra wa lè tàn wá jẹ. (Jeremáyà 17:9) Nítorí náà, bá ò bá kíyè sára, kò ní pẹ́ tí a ó fi máa fojú kéré àwọn ìlànà Ọlọ́run tá a rò pó ṣòro fún wa tàbí pé ó ń ká wa lọ́wọ́ kò.
Bí àpẹẹrẹ, àwọn tí ò tíì ṣègbéyàwó lè yàn láti bára wọn lò pọ̀, kí wọ́n sì máa rò pé kò sóhun tó kan ẹlòmíì níbẹ̀, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ó wu àwọn méjèèjì bẹ́ẹ̀ làwọn ṣe ṣe é. Bó bá yá, wọ́n lè wá rí i pé ohun táwọn ṣe ò bá ìlànà tó wà nínú Bíbélì mu, àmọ́ wọ́n lè wá sọ pé bí ohun táwọn ṣe ò bá “ṣáà ti pa ẹnikẹ́ni lára,” kò dájú pé Ọlọ́run á bínú sí i. Torí pé ohun tó wù wọ́n láti ṣe ni, wọ́n lè máà rí bó ṣe burú tó, wọ́n sì lè máà ronú lórí ibi tí ìwà tí wọ́n hù máa já sí. Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ọ̀nà kan wà tí ó dúró ṣánṣán lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ikú ni òpin rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.”—Òwe 14:12.
Àpẹẹrẹ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa ẹ̀dá àti pé kò fẹ́ kí ìyà jẹ wá wà nínú gbogbo òfin Rẹ̀. Látìgbà táwọn èèyàn sì ti ń rú òfin Ọlọ́run tó lòdì sí ṣíṣe ìṣekúṣe àti híhu àwọn ìwà míì tí ò dáa, ìyẹn ò sọ pé kí ayọ̀ wọn pọ̀ sí i, kò sì mú káyé wọn dára sí i. Ó tiẹ̀ ti mú káyé ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́jú pọ̀ gidigidi. Àmọ́, bá a bá ń ṣègbọràn sáwọn òfin Ọlọ́run, kò ní máa jẹ́ kí ìsapá wa láti gbé ìgbé ayé rere já sásán, á sì tún máa kó àwa àtàwọn míì yọ nínú ewu.—Sáàmù 19:7-11.
Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lo fẹ́ jẹ́ ẹni rere lójú Ọlọ́run, ṣe ni kó o yáa máa sa gbogbo ipá ẹ láti máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Ìwọ fúnra ẹ á sì wá rí i pé “àwọn àṣẹ [Jèhófà] kì í ṣe ẹrù ìnira.”—1 Jòhánù 5:3.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
◼ Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ẹlẹ́dàá wa?—Ìṣípayá 4:11.
◼ Ṣé gbogbo àṣẹ Ọlọ́run ló yẹ ká máa ṣègbọràn sí?—1 Jòhánù 5:3.
◼ Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu pé ká fọwọ́ ara wa yan ìwà tá a ó máa hù?—Òwe 14:12; Jeremáyà 17:9.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ṣé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìwà rere nìwọ náà fi ń wò ó?