Jèhófà Mọyì Ìgbọràn Rẹ
“Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀.”—ÒWE 27:11.
1. Ẹ̀mí wo ló gbayé kan lóde òní?
ŃṢE ni ẹ̀mí tinú-mi-ni-màá-ṣe àti ẹ̀mí àìgbọràn gbayé kan lóde òní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì sọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù, ó ní: “Ẹ ti rìn ní àkókò kan rí ní ìbámu pẹ̀lú ètò àwọn nǹkan ti ayé yìí, ní ìbámu pẹ̀lú olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́, ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn.” (Éfésù 2:1, 2) Ńṣe ni ká kúkú sọ pé Sátánì Èṣù tí í ṣe “olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́” ti kó ẹ̀mí àìgbọràn ran aráyé. Bó ṣe ṣe nìyẹn ní ọ̀rúndún kìíní, ó sì wá ń ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ látìgbà tí wọ́n ti lé e kúrò lọ́run wá sáyé kété ṣáájú ìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní.—Ìṣípayá 12:9.
2, 3. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà?
2 Àmọ́, àwa Kristẹni mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run yẹ lẹ́ni tá à ń ṣègbọràn sí látọkànwá, nítorí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, Ẹni tó ń gbé ẹ̀mí wa ró, Ọba Aláṣẹ tó nífẹ̀ẹ́ wa, àti Olùdáǹdè wa. (Sáàmù 148:5, 6; Ìṣe 4:24; Kólósè 1:13; Ìṣípayá 4:11) Nígbà ayé Mósè, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé Jèhófà ló fún àwọn ní ìwàláàyè òun ló sì ń gba àwọn sílẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀tá. Ìdí nìyẹn tí Mósè fi sọ fún wọn pé: “Kí ẹ sì kíyè sí àtiṣe gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún yín gan-an.” (Diutarónómì 5:32) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà yẹ lẹ́ni tí wọ́n ń ṣègbọràn sí. Àmọ́ kàkà kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, kò pẹ́ rárá tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run wọn.
3 Báwo ló ṣe ṣe pàtàkì tó pé ká máa ṣègbọràn sí Ẹlẹ́dàá ayé òun ọ̀run? Ṣẹ́ ẹ rí i, nígbà kan rí, Ọlọ́run gbẹnu wòlíì Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù Ọba pé: “Ṣíṣègbọràn sàn ju ẹbọ.” (1 Sámúẹ́lì 15:22, 23) Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?
Bí Ìgbọràn Ṣe “Sàn Ju Ẹbọ” Lọ
4. Ọ̀nà wo la fi lè fún Jèhófà ní nǹkan?
4 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá, ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo ohun tá a ní ti wá. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ nǹkan kan wà tá a lè fún un? Bẹ́ẹ̀ ni, ohun iyebíye kan wà tá a lè fún un. Kí ni nǹkan ọ̀hún? Ẹ jẹ́ ká wò ó nínú ọ̀rọ̀ ìṣítí tí Bíbélì sọ, pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.” (Òwe 27:11) Ẹsẹ Bíbélì yìí fi hàn pé ohun kan tá a lè fún Ọlọ́run ni pé ká máa ṣègbọràn sí i. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò tí kálukú wa wà báyìí ò dọ́gba tá ò sì dàgbà nínú ipò kan náà, tí kálukú wa bá jẹ́ onígbọràn, a lè fi hàn pé irọ́ gbuu ni Sátánì Èṣù ń pa nígbà tó lọ ń ba àwa èèyàn jẹ́ pé a máa ṣíwọ́ jíjẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run tá a bá rí àdánwò. Ẹ ẹ̀ rí i pé àǹfààní ńlá la ní yìí!
5. Báwo ni àìgbọràn ṣe máa ń rí lára Ẹlẹ́dàá? Ṣàpèjúwe.
5 Àwọn ohun tá à ń ṣe máa ń nípa lórí Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ṣàìgbọràn sí i, ó máa ń dùn ún pé à ń hu irú ìwà àìlọ́gbọ́n bẹ́ẹ̀. (Sáàmù 78:40, 41) Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe rẹ̀ báyìí ná: Ká sọ pé ẹnì kan tó ní àrùn àtọ̀gbẹ kì í jẹ oúnjẹ aṣaralóore tí dókítà tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ní kó máa jẹ, tó wá lọ ń jẹ oúnjẹ tó máa dá kún àìlera rẹ̀, báwo ló ṣe máa rí lára dókítà náà? Ó dá wa lójú pé bínú dókítà yẹn ò ṣe ní dùn náà ló ṣe jẹ́ pé inú Jèhófà kì í dùn táwọn èèyàn bá ṣàìgbọràn sí i, torí ó mọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ táwọn èèyàn ò bá tẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀ tó ní kí wọ́n máa pa mọ́ kí wọ́n lè ní ìyè.
6. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ onígbọràn sí Ọlọ́run?
6 Kí ló máa ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ láti jẹ́ ẹni tó ń ṣègbọràn? Ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ ni pé kí kálukú wa bẹ Ọlọ́run bí Sólómọ́nì Ọba ṣe bẹ́ ẹ̀, pé kó fún wa ní “ọkàn-àyà ìgbọràn.” Ìdí tí Sólómọ́nì fi ní kí Ọlọ́run fún òun ní ọkàn ìgbọràn ni pé kó lè “fi òye mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú” kó bàa lè mọ bí yóò ṣe máa ṣèdájọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bíi tiẹ̀. (1 Àwọn Ọba 3:9) Àfi ká ní “ọkàn-àyà ìgbọràn” ká tó lè mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú nínú ayé tó kún fún ẹ̀mí àìgbọràn yìí. Ká lè ní “ọkàn-àyà ìgbọràn,” Ọlọ́run fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì, àwọn ìpàdé ìjọ àtàwọn alàgbà. Ǹjẹ́ à ń lo àwọn ohun tí Ọlọ́run pèsè yìí dáadáa?
7. Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé ìgbọràn sàn ju ẹbọ lọ?
7 Lórí ọ̀rọ̀ tá à ń sọ yìí, ẹ jẹ́ ká rántí pé Jèhófà jẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ láyé àtijọ́ mọ̀ pé ìgbọràn sàn ju ẹbọ tí wọ́n ń fi ẹran rú lọ. (Òwe 21:3, 27; Hóséà 6:6; Mátíù 12:7) Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló sọ pé kí wọ́n máa fẹran rúbọ sóun? Ó dáa, kí ló mú kí ẹni tó rúbọ sí Ọlọ́run rú ẹbọ náà? Ṣé kó bàa lè ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni, àbí ṣe ló sáà kàn ń tẹ̀ lé àṣà tó ti wà nílẹ̀? Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ló wu ẹnì kan tó jẹ́ olùjọsìn Ọlọ́run láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, yóò rí i dájú pé òun ń pa gbogbo àṣẹ Ọlọ́run mọ́. Téèyàn bá fi ẹran rúbọ sí Ọlọ́run, kò da nǹkan kan fún Ọlọ́run, àmọ́ nǹkan iyebíye kan tá a lè fún un ni pé ká máa ṣègbọràn sí i.
Àpẹẹrẹ Kan Tó Jẹ́ Ìkìlọ̀ fún Wa
8. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi kọ Sọ́ọ̀lù lọ́ba?
8 Ìtàn Sọ́ọ̀lù Ọba nínú Bíbélì fi hàn pé ìgbọràn ṣe pàtàkì gan-an ni. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, onírẹ̀lẹ̀ ni ó sì jẹ́ ẹnì kan tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, àní ó ‘kéré lójú ara rẹ̀.’ Àmọ́ nígbà tó yá, ẹ̀mí ìgbéraga àti ìrònú òdì ló fi ń ṣe gbogbo nǹkan. (1 Sámúẹ́lì 10:21, 22; 15:17) Nígbà kan tí Sọ́ọ̀lù fẹ́ lọ bá àwọn Filísínì jagun, Sámúẹ́lì sọ fún un pé kó dúró de òun kóun lè wá rúbọ sí Jèhófà kóun sì sọ àwọn nǹkan míì tó máa ṣe fún un. Àmọ́ Sámúẹ́lì ò dé lákòókò tí Sọ́ọ̀lù retí, àwọn èèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í túká kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Ni Sọ́ọ̀lù bá fúnra rẹ̀ “rú ẹbọ sísun náà.” Ìyẹn sì bí Jèhófà nínú. Nígbà tí Sámúẹ́lì sì wá dé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ńṣe ni Sọ́ọ̀lù Ọba ń wí àwíjàre fún ìwà àìgbọràn rẹ̀, ó ní nígbà tí Sámúẹ́lì ń pẹ́ jù lòun ‘ṣe é ní ọ̀ranyàn fún ara òun’ láti rú ẹbọ sísun náà láti fi tu Jèhófà lójú. Sọ́ọ̀lù rò pé rírú ẹbọ yẹn sàn ju ṣíṣègbọràn sí àṣẹ tí Jèhófà pa pé kó dúró de Sámúẹ́lì kó wá rú ẹbọ náà. Sámúẹ́lì sọ fún un pé: “Ìwọ ti hùwà òmùgọ̀. Ìwọ kò pa àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́.” Nítorí pé Sọ́ọ̀lù kò ṣègbọràn sí Jèhófà, ó pàdánù ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.—1 Sámúẹ́lì 10:8; 13:5-13.
9. Kí ló fi hàn pé ó ti mọ́ Sọ́ọ̀lù lára láti máa ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run?
9 Ǹjẹ́ Sọ́ọ̀lù Ọba kọ́gbọ́n látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nítorí ìwà àìgbọràn rẹ̀ yìí? Rárá o, kò kọ́gbọ́n! Nígbà tó tún ṣe, Jèhófà pàṣẹ fún un pé kó pa gbogbo àwọn Ámálékì run. Ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn yẹn ti gbéjà ko orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láìnídìí. Jèhófà sọ pé kí Sọ́ọ̀lù má ṣe dá àwọn ẹran ọ̀sìn wọn pàápàá sí. Sọ́ọ̀lù lọ síbẹ̀ bí Jèhófà ṣe sọ, ó “ṣá Ámálékì balẹ̀ láti Háfílà títí dé Ṣúrì.” Nígbà tí Sámúẹ́lì wá pàdé Sọ́ọ̀lù, inú Sọ́ọ̀lù dùn gan-an pé Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, ó sì sọ pé: “Alábùkún ni ọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. Mo ti pa ọ̀rọ̀ Jèhófà mọ́.” Àmọ́ Sọ́ọ̀lù àtàwọn èèyàn rẹ̀ ò ṣègbọràn sí àṣẹ tó ṣe kedere tí Jèhófà pa fún wọn, torí wọ́n kò pa Ágágì Ọba àti “èyí tí ó dára jù lọ nínú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran àti àwọn tí ó sanra àti . . . àwọn àgbò àti . . . gbogbo ohun tí ó dára.” Sọ́ọ̀lù Ọba tún wá àwíjàre fún ìwà àìgbọràn yìí, ó ní: “Àwọn ènìyàn náà ní ìyọ́nú sí èyí tí ó dára jù lọ nínú agbo ẹran àti nínú ọ̀wọ́ ẹran, fún ète rírúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ.”—1 Sámúẹ́lì 15:1-15.
10. Kí ni Sọ́ọ̀lù ò mọ̀?
10 Sámúẹ́lì wá sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Jèhófà ha ní inú dídùn sí àwọn ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ bí pé kí a ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà? Wò ó! Ṣíṣègbọràn sàn ju ẹbọ, fífetísílẹ̀ sàn ju ọ̀rá àwọn àgbò.” (1 Sámúẹ́lì 15:22) Níwọ̀n bí Jèhófà ti pàṣẹ pé kí wọ́n pa àwọn ẹranko wọ̀nyẹn run, kò ní tẹ́wọ́ gbà á tí wọ́n bá fi rúbọ sí i.
Máa Ṣègbọràn Nínú Ohun Gbogbo
11, 12. (a) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ipá tá à ń sà láti máa ṣe ohun tó fẹ́ bá a ṣe ń sìn ín? (b) Báwo lẹnì kan ṣe lè tan ara rẹ̀ jẹ nípa sísọ pé òun ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, nígba tó sì jẹ́ pé aláìgbọràn ni?
11 Kò sí àní-àní pé inú Jèhófà á máa dùn gan-an ni bó ṣe ń rí i táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń dúró ṣinṣin láìfi inúnibíni pè, tí wọ́n ń polongo Ìjọba Ọlọ́run láìka ti pé àwọn èèyàn ò fẹ́ gbọ́ sí, tí wọ́n sì ń pa iṣẹ́ ajé tì láti lè lọ sípàdé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn náà ń wá bí awọ ṣe máa kájú ìlù. Ẹ ò rí i pé bá a ṣe ń ṣègbọràn nínú àwọn ohun tó jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn wa yìí á máa mú ọkàn rẹ̀ yọ̀! Jèhófà ò fojú kékeré wo ipá tá à ń sà bá a ṣe ń jọ́sìn rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ tá a ní sí i ló ń mú wa ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn èèyàn lè má ka iṣẹ́ àṣekára tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run sí, àmọ́ Ọlọ́run ò ní ṣàì ka àwọn ohun tá à ń fi gbogbo ọkàn wa ṣe fún un sí, kò sì ní gbàgbé wọn.—Mátíù 6:4.
12 Àmọ́ ká tó lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí i nínú ohun gbogbo. A ò gbọ́dọ̀ tan ara wa jẹ nípa rírò pé a lè máa tẹ àwọn kan lára òfin Ọlọ́run lójú níwọ̀n ìgbà tá a bá sáà ti ń ṣe ohun tó fẹ́ láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè máa tan ara rẹ̀ jẹ, kó máa rò pé tóun bá sáà ti ń ṣe àwọn nǹkan kan nínú ìjọsìn Ọlọ́run, Ọlọ́run kò ní bínú sóun tóun bá ṣèṣekúṣe tàbí tóun bá dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ míì tó burú jáì. Ẹ ò rí i pé àṣìṣe ńlá gbáà lẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ṣe!—Gálátíà 6:7, 8.
13. Nígbà tá a bá wà láwa nìkan, báwo làwọn nǹkan kan ṣe lè dán ìgbọràn wa sí Jèhófà wò?
13 Nítorí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ mò ń ṣègbọràn sí Jèhófà nínú àwọn ohun tí mò ń ṣe lójoojúmọ́, àní nínú àwọn ọ̀ràn tó dà bíi pé kò hàn sáwọn ẹlòmíì?’ Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú, ẹni tí ó bá sì jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú.” (Lúùkù 16:10) Àní ‘nínú ilé wa’ pàápàá, nígbà táwọn ẹlòmíì ò bá rí wa, ǹjẹ́ à máa ń ‘rìn káàkiri nínú ìwà títọ́ ọkàn wa’? (Sáàmù 101:2) Bẹ́ẹ̀ ni, àní nígbà tá a bá wà nínú ilé wa pàápàá, àwọn nǹkan kan lè dán ìwà títọ́ wa wò. Láwọn orílẹ̀-èdè tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ní kọ̀ǹpútà nílé, kò ṣòro láti rí àwọn àwòrán tí kò bójú mu. Àmọ́, ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, kò sẹ́ni tó lè rí irú àwọn àwòrán bẹ́ẹ̀ tí kò bá lọ síbi táwọn èèyàn ti máa ń wo eré oníṣekúṣe. Ǹjẹ́ a máa ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀”? Ǹjẹ́ a máa yẹra pátápátá fún wíwo àwọn ohun tó máa ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe? (Mátíù 5:28; Jóòbù 31:1, 9, 10; Sáàmù 119:37; Òwe 6:24, 25; Éfésù 5:3-5) Àwọn eré orí tẹlifíṣọ̀n tó máa ń fi ìwà ipá hàn ńkọ́? Ọkàn Ọlọ́run wa “kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” Ǹjẹ́ bí ìwà ipá ṣe rí lójú rẹ̀ yìí ló rí lójú àwa náà? (Sáàmù 11:5) Kéèyàn máa mutí àmujù níkọ̀kọ̀ ńkọ́? Yàtọ̀ sí pé Bíbélì sọ pé ọtí àmupara ò dáa, ó tún sọ pé káwa Kristẹni má fi ara wa fún “ọ̀pọ̀ wáìnì.”—Títù 2:3; Lúùkù 21:34, 35; 1 Tímótì 3:3.
14. Àwọn ọ̀nà wo la ti lè fi hàn pé à ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run nínú ọ̀ràn tó jẹ mọ́ owó?
14 Ìhà mìíràn tó ti yẹ ká kíyè sára ni bá a ṣe ń ṣe nínú àwọn ọràn tó jẹ mọ́ owó. Bí àpẹẹrẹ, ṣé a máa lọ́wọ́ nínú àwọn òwò tó ń sọni dolówó òjijì tí ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí kéèyàn lu jìbìtì? Ǹjẹ́ a máa ń fẹ́ ṣe àwọn ohun tí kò bófin mu ká má bàa san owó orí? Àbí ńṣe la máa ń sa gbogbo ipá wa láti ṣègbọràn sí àṣẹ Bíbélì tó sọ pé ká “fi ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn fún wọn, ẹni tí ó béèrè fún owó orí, [ká] fún un ní owó orí”?—Róòmù 13:7.
Ìfẹ́ Ló Yẹ Kó Múni Ṣègbọràn
15. Kí nìdí tó o fi ń pa àṣẹ Jèhófà mọ́?
15 Ṣíṣègbọràn sí ìlànà Ọlọ́run máa ń ṣàǹfààni tó pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá yẹra fún lílo tábà, tí a kì í ṣèṣekúṣe, tá a sì ń ta kété sí ẹ̀jẹ̀ nítorí pé ó jẹ́ nǹkan ọ̀wọ̀, a ò ní kó àwọn àrùn kan. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń pa ọ̀rọ̀ Bíbélì mọ́ nínú àwọn ohun mìíràn nígbèésí ayé wa, ó lè ṣe wá láǹfààní nínú ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ owó, nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, tàbí nínú ilé wa. (Aísáyà 48:17) Irú àwọn àǹfààní bẹ́ẹ̀ ń fi hàn pé àwọn òfin Ọlọ́run bọ́gbọ́n mu. Àmọ́ ṣá o, olórí ìdí tá a fi ń ṣègbọràn sí Jèhófà ni pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kì í ṣe tìtorí àwọn ohun tá a máa rí gbà lọ́wọ́ rẹ̀ la ṣe ń sìn ín. (Jóòbù 1:9-11; 2:4, 5) Ó ṣe tán, Ọlọ́run fún wa lómìnira láti máa ṣègbọràn sí ẹnikẹ́ni tó bá wù wá. Àwa yàn láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà nítorí pé a fẹ́ láti múnú rẹ̀ dùn àti pé ó wù wá láti máa ṣe ohun tó tọ́.—Róòmù 6:16, 17; 1 Jòhánù 5:3.
16, 17. (a) Báwo ni ìfẹ́ àtọkànwá ṣe sún Jésu láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run? (b) Báwo la ṣe lè ṣe bíi ti Jésù?
16 Àpẹẹrẹ pípé ni Jésù fi lélẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ pé kí ìfẹ́ àtọkànwá sún èèyàn ṣègbọràn sí Jèhófà. (Jòhánù 8:28, 29) Nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ó “kọ́ ìgbọràn láti inú àwọn ohun tí ó jìyà rẹ̀.” (Hébérù 5:8, 9) Báwo ló ṣe ṣe bẹ́ẹ̀? Bó ṣe ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó “rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró.” (Fílípì 2:7, 8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ṣègbọràn lọ́run kó tó wá sáyé, ó tún rí àwọn ohun tó dán ìgbọràn rẹ̀ wò síwájú sí i lórí ilẹ̀ ayé. Ó dá wa lójú pé Jésù kúnjú ìwọ̀n láti sìn gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà fún àwọn arákùnrin rẹ̀ àtàwọn yòókù nínú aráyé tí wọ́n nígbàgbọ́.—Hébérù 4:15; 1 Jòhánù 2:1, 2.
17 Àwa ńkọ́? A lè ṣe bíi ti Jésù, ká máa fi ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run ṣáájú nígbèésí ayé wa. (1 Pétérù 2:21) A máa láyọ̀ tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ló ń mú ká máa ṣe ohun tó pa láṣẹ, àní láwọn ìgbà tá a bá rí ìdẹwò tàbí tí ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ ń tì wá láti ṣe ohun tí kò tọ́. (Róòmù 7:18-20) Èyí kan pé ká fẹ́ láti ṣègbọràn sí ìtọ́ni tí àwọn tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọsìn tòótọ́ ń fún wa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wọ́n. (Hébérù 13:17) Bákan náà, tá a bá ń pa àṣẹ Jèhófà mọ́ nígbà tá a bá wà láwa nìkan, ìyẹn ṣeyebíye lójú rẹ̀.
18, 19. Tá a bá ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run látọkànwá, kí ló máa yọrí sí?
18 Lónìí, ṣíṣègbọràn sí Jèhófà lè gba pé ká fara da inúnibíni ká bàa lè pa ìwà títọ́ wa mọ́. (Ìṣe 5:29) Bákan náà, ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà pé ká máa wàásù ká sì máa kọ́ni gba pé ká ní ìfaradà títí dé òpin ètò àwọn nǹkan yìí. (Mátíù 24:13, 14; 28:19, 20) A ní láti ní ìfaradà ká tó lè máa bá a lọ láti pé jọ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìṣòro tó wà nínú ayé yìí ń bá àwa náà fínra. Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ mọ gbogbo ipá tá à ń sa láti máa ṣègbọràn sí i ní gbogbo ọ̀nà tá a mẹ́nu kàn yìí. Àmọ́ ká tó lè ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀, a ní láti máa bá ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀yáàjà ká sì máa yàgò fún ohun tó burú, ká wá máa nífẹ̀ẹ́ ohun rere.—Róòmù 12:9.
19 Tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà àti mímọyì tá a mọyì oore rẹ̀ ló mú ká máa sìn ín, ó máa di “olùsẹ̀san fún [àwa tá à] ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Ó pọn dandan ká máa rú àwọn ẹbọ tó yẹ, Jèhófà sì nífẹ̀ẹ́ sí i. Àmọ́ tá a bá ń ṣègbọràn sí i nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, irú ìgbọràn yẹn ló máa ń múnú rẹ̀ dùn jù lọ.—Òwe 3:1, 2.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Kí nìdí tá a fi lè sọ pé nǹkan kan wà tá a lè fún Jèhófà?
• Àṣìṣe wo ni Sọ́ọ̀lù ṣe?
• Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o gbà pé ìgbọràn sàn ju ẹbọ lọ?
• Kí ló ń mú kó o máa ṣègbọràn sí Jèhófà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Báwo ló ṣe máa rí lára dókítà tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́, tí aláìsàn tó ń tọ́jú ò bá ṣe àwọn ohun tó sọ fún un?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Kí nìdí tí Sọ́ọ̀lù Ọba fi rí ìbínú Jèhófà?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Ǹjẹ́ ò ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run nígbà tó o bá dá wà nínú ilé rẹ?