ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 7/15 ojú ìwé 25-27
  • O Ha Ní “Ọkàn-Àyà Ìgbọràn” Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • O Ha Ní “Ọkàn-Àyà Ìgbọràn” Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọ́n Ní Ọkàn-Àyà Ìgbọràn
  • Ààbọ̀ Ìgbọràn Kò Tó
  • Báwo Ni Ìgbọràn Rẹ Ti Jinlẹ̀ Tó?
  • Ọkàn-Àyà Ìgbọràn Ń Mú Ìbùkún Wá
  • Jèhófà Mọyì Ìgbọràn Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Jẹ́ ‘Onígbọràn Látọkànwá’
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Kọ́ Igbọran Nipa Titẹwọgba Ibawi
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Jésù “Kọ́ Ìgbọràn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 7/15 ojú ìwé 25-27

O Ha Ní “Ọkàn-Àyà Ìgbọràn” Bí?

NÍGBÀ tí Sólómọ́nì di ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì, ó nímọ̀lára àìtóótun. Nítorí náà, ó béèrè ọgbọ́n àti ìmọ̀ lọ́wọ́ Ọlọ́run. (2 Kíróníkà 1:10) Sólómọ́nì tún gbàdúrà pé: “Kí o sì fún ìránṣẹ́ rẹ ní ọkàn-àyà ìgbọràn láti máa fi ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ.” (1 Àwọn Ọba 3:9) Bí Sólómọ́nì bá ní “ọkàn-àyà ìgbọràn,” yóò pa àwọn òfin àti ìlànà àtọ̀runwá mọ́, yóò sì gbádùn ìbùkún Jèhófà.

Ọkàn-àyà ìgbọràn kì í ṣe ẹrù ìnira bí kò ṣe orísun ayọ̀. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòhánù 5:3) Dájúdájú, ó yẹ kí a ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Ó ṣe tán, Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá. Tirẹ̀ ni ilẹ̀ ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, kódà gbogbo fàdákà àti wúrà. Nítorí náà, ní ti gidi, a kò lè fún Ọlọ́run ní nǹkan kan nípa ti ara, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń gbà wá láyè láti máa lo owó wa láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ òun. (1 Kíróníkà 29:14) Jèhófà ń retí pé kí a nífẹ̀ẹ́ òun, kí a sì máa fi ìrẹ̀lẹ̀ bá òun rìn, kí a máa ṣe ìfẹ́ òun.—Míkà 6:8.

Nígbà tí a bi Jésù Kristi léèrè nípa àṣẹ títóbi jù lọ nínú Òfin, ó sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ. Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní.” (Mátíù 22:36-38) Ọ̀nà kan láti gbà fi ìfẹ́ yẹn hàn ni láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Nítorí náà, ṣe ni ó yẹ kí ó jẹ́ àdúrà olúkúlùkù wa pé kí Jèhófà fún wa ní ọkàn-àyà ìgbọràn.

Wọ́n Ní Ọkàn-Àyà Ìgbọràn

Bíbélì kún fún àpẹẹrẹ àwọn tó ní ọkàn-àyà ìgbọràn. Fún àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fún Nóà pé kí ó kan ọkọ̀ áàkì ràgàjì fún pípa ìwàláàyè mọ́. Èyí jẹ́ iṣẹ́ taakun-taakun tó gba 40 tàbí 50 ọdún. Kódà pẹ̀lú gbogbo irinṣẹ́ alágbára tòde òní àti àwọn ohun èlò mìíràn tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó nísinsìnyí, yóò jẹ́ iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ tó pabanbarì láti kan irú ọkọ̀ ràgàjì yẹn tí yóò lè léfòó. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Nóà ní láti kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn tó dájú pé wọ́n ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́ tí wọ́n sì ń pẹ̀gàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó ṣègbọràn títí dórí bín-ín-tín. Bíbélì sọ pé: “Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:9, 22; 2 Pétérù 2:5) Nóà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nípasẹ̀ ìgbọràn tí kò yingin fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ẹ wo irú àpẹẹrẹ rere tí èyí jẹ́ fún gbogbo wa!

Tún ronú nípa baba wa Ábúráhámù. Ọlọ́run sọ fún un pé kí ó ṣí láti Úrì ìlú ọlọ́lá ti àwọn ará Kálídíà lọ sí ilẹ̀ tí kò mọ̀. Ábúráhámù ṣègbọràn láìmikàn. (Hébérù 11:8) Ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ ni òun àti ìdílé rẹ̀ fi gbé inú àgọ́. Lẹ́yìn tó ti fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣàtìpó ní ilẹ̀ náà, Jèhófà fi ọmọ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ísákì bù kún òun àti Sárà, aya rẹ̀ onígbọràn. Ẹ wo irú ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Ábúráhámù ẹni 100 ọdún yóò ti ní sí ọmọkùnrin ọjọ́ ogbó rẹ̀! Ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé kí ó fi Ísákì rú ẹbọ sísun. (Jẹ́nẹ́sísì 22:1, 2) Kìkì ríronú nípa ṣíṣe èyí ní láti dun Ábúráhámù gan-an. Síbẹ̀síbẹ̀, ó tẹ̀ síwájú láti ṣègbọràn nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì ní ìgbàgbọ́ pé ọmọ ìlérí yóò tipasẹ̀ Ísákì wá, bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé ṣe ni Ọlọ́run yóò jí i dìde láti inú òkú. (Hébérù 11:17-19) Ṣùgbọ́n, nígbà tí Ábúráhámù fẹ́ pa ọmọ rẹ̀, Jèhófà dá a dúró, ó sì sọ pé: “Nísinsìnyí ni mo mọ̀ pé olùbẹ̀rù Ọlọ́run ni ìwọ ní ti pé ìwọ kò fawọ́ ọmọkùnrin rẹ, ọ̀kan ṣoṣo tí o ní, sẹ́yìn fún mi.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:12) Nítorí ìgbọràn rẹ̀, Ábúráhámù olùbẹ̀rù Ọlọ́run ni a wá mọ̀ sí “ọ̀rẹ́ Jèhófà.”—Jákọ́bù 2:23.

Jésù Kristi ni àpẹẹrẹ títayọ jù lọ tí a ní nínú ọ̀ràn ìgbọràn ṣíṣe. Kí ó tó wá sí ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn, ó ní inú dídùn nínú ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn onígbọràn sí Baba rẹ̀ ọ̀run. (Òwe 8:22-31) Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, Jésù ṣègbọràn sí Jèhófà nínú ohun gbogbo, ìgbà gbogbo ni inú rẹ̀ máa ń dùn láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Sáàmù 40:8; Hébérù 10:9) Nípa báyìí, Jésù sọ tòótọ́-tòótọ́ pé: “Èmi kò ṣe nǹkan kan ní àdáṣe ti ara mi; ṣùgbọ́n gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti kọ́ mi ni mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí. Ẹni tí ó rán mi sì wà pẹ̀lú mi; kò pa mí tì ní èmi nìkan, nítorí pé nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wù ú.” (Jòhánù 8:28, 29) Níkẹyìn, láti dá ipò ọba aláṣẹ Jèhófà láre àti láti ra aráyé onígbọràn padà, tinútinú ni Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀, ó kú ikú olóró tí ń tẹ́ni lógo jù lọ. Ní ti gidi, “nígbà tí ó rí ara rẹ̀ ní àwọ̀ ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró.” (Fílípì 2:8) Ẹ wo àpẹẹrẹ rere tó fi lélẹ̀ ní fífi ọkàn-àyà ìgbọràn hàn!

Ààbọ̀ Ìgbọràn Kò Tó

Kì í ṣe gbogbo àwọn tó sọ pé àwọn jẹ́ onígbọràn sí Ọlọ́run ló ń ṣègbọràn ní tòótọ́. Gbé ọ̀ràn Sọ́ọ̀lù Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì yẹ̀ wò. Ọlọ́run sọ fún un pé kí ó pa àwọn ará Ámálékì tí í ṣe olubi run. (1 Sámúẹ́lì 15:1-3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sọ́ọ̀lù pa odindi orílẹ̀ èdè yẹn run, ó dá ọba wọn sí, ó sì tọ́jú lára àgùntàn àti màlúù wọn pa mọ́. Sámúẹ́lì béèrè pé: “Èé ṣe tí o kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà?” Nígbà tí Sọ́ọ̀lù máa fèsì, ó ní: “Ṣùgbọ́n mo ti ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà . . . Àwọn ènìyàn [Ísírẹ́lì] bẹ̀rẹ̀ sí mú àgùntàn àti màlúù nínú àwọn ohun ìfiṣèjẹ náà, èyí tí ó jẹ́ ààyò jù lọ nínú wọn . . . , láti fi rúbọ sí Jèhófà.” Sámúẹ́lì wá tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ṣíṣègbọràn jálẹ̀jálẹ̀, ó ní: “Jèhófà ha ní inú dídùn sí àwọn ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ bí pé kí a ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà? Wò ó! Ṣíṣègbọràn sàn ju ẹbọ, fífetísílẹ̀ sàn ju ọ̀rá àwọn àgbò; nítorí pé ìṣọ̀tẹ̀ jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ ìwoṣẹ́, fífi ìkùgbù ti ara ẹni síwájú sì jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú lílo agbára abàmì àti ère tẹ́ráfímù. Níwọ̀n bí o ti kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, òun kọ̀ ọ́ ní ọba.” (1 Sámúẹ́lì 15:17-23) Ẹ wo ohun ribiribi tí Sọ́ọ̀lù pàdánù nítorí àìní ọkàn-àyà ìgbọràn!

Kódà Sólómọ́nì Ọba, tó gbàdúrà fún ọkàn-àyà ìgbọràn, kò ṣègbọràn sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀. Ní ìlòdìsí ìlànà Ọlọ́run, ó fi àwọn obìnrin ilẹ̀ òkèèrè ṣe aya, àwọn wọ̀nyí sì mú kí ó ṣẹ Ọlọ́run. (Nehemáyà 13:23, 26) Sólómọ́nì pàdánù ojú rere Ọlọ́run nítorí pé ó ṣíwọ́ níní ọkàn-àyà ìgbọràn. Ẹ wo ìkìlọ̀ ńlá tí èyí jẹ́ fún wa!

Èyí kò túmọ̀ sí pé Jèhófà ń béèrè ìjẹ́pípé lọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí í ṣe ẹ̀dá ènìyàn. Ó “rántí pé ekuru ni wá.” (Sáàmù 103:14) Gbogbo wa ló ń ṣe àṣìṣe, ṣùgbọ́n Ọlọ́run lè rí i pé bóyá lóòótọ́ ni a ní ìfẹ́ ọkàn láti ṣe ohun tó wu òun. (2 Kíróníkà 16:9) Bí a bá ṣàṣìṣe nítorí àìpé ènìyàn, ṣùgbọ́n tí a ronú pìwà dà, a lè béèrè fún ìdáríjì lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Kristi, pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà “yóò dárí jì lọ́nà títóbi.” (Aísáyà 55:7; 1 Jòhánù 2:1, 2) A lè nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn Kristẹni alàgbà tí wọ́n jẹ́ onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú kí a bàa lè padà bọ̀ sípò nípa tẹ̀mí, kí a sì ní ìgbàgbọ́ tó pegedé àti ọkàn-àyà ìgbọràn.—Títù 2:2; Jákọ́bù 5:13-15.

Báwo Ni Ìgbọràn Rẹ Ti Jinlẹ̀ Tó?

Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa ló ní ọkàn-àyà ìgbọràn. A lè ronú pé, Èmi kò ha ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà bí? N kò ha ń dúró gbọn-in nígbà tí àwọn ọ̀ràn pàtàkì bí àìdásí tọ̀tún tòsì bá dìde? N kò ha sì ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé bí, gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti rọ̀ wá láti máa ṣe? (Mátíù 24:14; 28:19, 20; Jòhánù 17:16; Hébérù 10:24, 25) Lóòótọ́, àwọn ènìyàn Jèhófà lápapọ̀ ń ṣègbọràn látọkànwá nínú àwọn ọ̀ràn pàtàkì bẹ́ẹ̀.

Ṣùgbọ́n nípa ìwà wa ojoojúmọ́ ńkọ́, bóyá nínú àwọn ọ̀ràn tí a kò fojú pàtàkì wò? Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú, ẹni tí ó bá sì jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú.” (Lúùkù 16:10) Nítorí náà, yóò dára kí olúkúlùkù wa bi ara rẹ̀ léèrè pé, Mo ha ní ọkàn-àyà ìgbọràn nígbà tó bá kan àwọn nǹkan kéékèèké tàbí àwọn ọ̀ràn tí àwọn ẹlòmíràn kò mọ̀ nípa rẹ̀?

Onísáàmù náà fi hàn pé nínú ilé òun pàápàá, níbi tí àwọn ẹlòmíràn kò ti rí òun, òun ‘ń rìn káàkiri nínú ìwà títọ́ ọkàn-àyà òun.’ (Sáàmù 101:2) Nígbà tí o bá wà nínú ilé rẹ, o lè tan tẹlifíṣọ̀n, kí o sì máa wo eré kan. Níbẹ̀ yẹn gan-an, a lè dán ìgbọràn rẹ wò. Wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìṣekúṣe nínú eré náà. Ìwọ yóò ha máa bá a nìṣó ní wíwò ó, kí o máa wí àwíjàre pé bí gbogbo eré tí wọ́n ń ṣe lóde òní ti rí nìyẹn? Tàbí kẹ̀, ọkàn-àyà ìgbọràn rẹ yóò ha sún ọ láti ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ náà pé, ‘kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ láàárín yín’? (Éfésù 5:3-5) Ìwọ yóò ha pa tẹlifíṣọ̀n, bí ìtàn náà bá tilẹ̀ wọni lọ́kàn? Tàbí ìwọ yóò ha yí i sí ìkànnì mìíràn bí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe eré oníwà ipá? Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.”—Sáàmù 11:5.

Ọkàn-Àyà Ìgbọràn Ń Mú Ìbùkún Wá

Dájúdájú, ọ̀pọ̀ ibi ni a lè yẹ̀ wò nínú ìgbésí ayé wa, fún àǹfààní ara wa, láti rí i bí ó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni a ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run látọkànwá. Ìfẹ́ wa fún Jèhófà yẹ kí ó sún wa láti tẹ́ ẹ lọ́rùn, kí a sì máa ṣe ohun tó sọ fún wa nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọkàn-àyà ìgbọràn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìbátan rere pẹ̀lú Jèhófà. Ní tòótọ́, bí a bá ṣègbọràn lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ‘àwọn àsọjáde ẹnu wa àti àṣàrò ọkàn-àyà wa yóò dùn mọ́ Jèhófà.’—Sáàmù 19:14.

Nítorí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó ń kọ́ wa ní ìgbọràn fún ire tiwa. A ó sì ṣe ara wa láǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ bí a bá fiyè sílẹ̀ tọkàntọkàn sí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá. (Aísáyà 48:17, 18) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a máa fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ tí Baba wa ọ̀run ń pèsè nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí rẹ̀, àti ètò àjọ rẹ̀. A ń kọ́ wa dáadáa tó fi dà bí ẹni pé ṣe ni a ń gbọ́ ohùn kan láti ẹ̀yìn wa tí ń sọ pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.” (Aísáyà 30:21) Bí Jèhófà ti ń kọ́ wa nípasẹ̀ Bíbélì, àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni, àti àwọn ìpàdé ìjọ, ǹjẹ́ kí a máa fetí sílẹ̀, kí a máa fi àwọn nǹkan tí a ń kọ́ sílò, kí a sì jẹ́ “onígbọràn nínú ohun gbogbo.”—2 Kọ́ríńtì 2:9.

Ọkàn-àyà ìgbọràn yóò yọrí sí ayọ̀ ńláǹlà àti ọ̀pọ̀ ìbùkún. Yóò fún wa ní ìfọ̀kànbalẹ̀, nítorí a ó mọ̀ pé inú Jèhófà Ọlọ́run dùn sí wa gan-an àti pé a ń mú ọkàn-àyà rẹ̀ yọ̀. (Òwe 27:11) Ọkàn-àyà tí ń ṣègbọràn yóò jẹ́ ààbò fún wa nígbà tí a bá dán wa wò láti ṣe ohun tí kò tọ́. Dájúdájú, nígbà náà, ó yẹ kí a máa ṣègbọràn sí Baba wa ọ̀run, kí a sì máa gbàdúrà pé: “Fún ìránṣẹ́ rẹ ní ọkàn-àyà ìgbọràn.”

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]

Láti inú ìwé náà, Self-Pronouncing Edition of the Holy Bible, tí ó ní Bíbélì King James àti Revised nínú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́