GBÓLÓHÙN KAN LÁTINÚ BÍBÉLÌ
Jésù “Kọ́ Ìgbọràn”
Gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń ṣègbọràn sí Jèhófà. (Jòh. 8:29) Kí wá nìdí tí Bíbélì fi sọ pé: “Ó kọ́ ìgbọràn látinú ìyà tó jẹ”?—Héb. 5:8
Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i yàtọ̀ sáwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i lọ́run. Bí àpẹẹrẹ, aláìpé làwọn òbí ẹ̀ àmọ́ wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Lúùkù 2:51) Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn oníwà ìbàjẹ́ fójú ẹ̀ rí màbo, àwọn alákòóso oníwà ìkà sì fìyà jẹ ẹ́. (Mát. 26:59; Máàkù 15:15) Yàtọ̀ síyẹn, ó kú ikú oró. Bíbélì sọ pé “ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ojú ikú.”—Fílí. 2:8.
Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù yìí fi hàn pé ọ̀nà tó gbà kọ́ ìgbọràn nígbà tó wà láyé yàtọ̀ sí bó ṣe kọ́ ìgbọràn nígbà tó wà lọ́run. Ìyẹn mú kó di Ọba àti Àlùfáà Àgbà pípé, ẹni tó lè bá wa kẹ́dùn. (Héb. 4:15; 5:9) Jésù wá túbọ̀ ṣeyebíye lójú Jèhófà lẹ́yìn tó ti kọ́ ìgbọràn látinú ìyà tó jẹ. Àwa náà lè túbọ̀ ṣeyebíye lójú Jèhófà ká sì ṣiṣẹ́ tó gbé fún wa dáadáa, tá a bá ń ṣègbọràn nígbà gbogbo bá a tiẹ̀ níṣòro.—Jém. 1:4.