Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Jẹ́ ‘Onígbọràn Látọkànwá’
1. Kí ni Jèhófà ń fẹ́ kí àwọn olùjọsìn rẹ̀ ṣe?
1 Ìgbọràn ṣe pàtàkì ká tó lè sin Jèhófà lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà. (Diu. 12:28; 1 Pét. 1:14-16) Láìpẹ́, Ọlọ́run á mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sórí “àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere.” (2 Tẹs. 1:8) Báwo la ṣe lè ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti di “onígbọràn láti inú ọkàn-àyà” sí ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?—Róòmù 6:17.
2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n bàa lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára?
2 Nípa Jíjẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ àti Ìfẹ́ Wọn Máa Pọ̀ Sí I: Ìwé Mímọ́ sábà máa ń mẹ́nu kan ìgbọràn níbi tó bá ti ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa “àṣẹ Ọlọ́run àìnípẹ̀kun láti gbé ìgbọràn ga síwájú sí i nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.” (Róòmù 16:26) Hébérù orí kọkànlá tiẹ̀ mẹ́nu kan ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ nítorí pé wọ́n ń ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu. (Héb. 11:7, 8, 17) Lọ́wọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, Bíbélì sábà máa ń so àìgbọràn mọ́ àìní ìgbàgbọ́. (Jòh. 3:36; Héb. 3:18, 19) A gbọ́dọ̀ kọ́ bá a ó ṣe máa lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa ká bàa lè ran àwọn míì lọ́wọ́ láti ní irú ìgbàgbọ́ tó máa ń mú kéèyàn ṣègbọràn.— 2 Tím. 2:15; Ják. 2:14, 17.
3. (a) Báwo ni ìgbọràn ṣe tan mọ́ ìfẹ́? (b) Báwo la ṣe lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
3 Ìgbọràn tún tan mọ́ ìfẹ́ fún Ọlọ́run. (Diu. 5:10; 11:1, 22; 30:16) Ìwé 1 Jòhánù 5:3, sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” Báwo la ṣe lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? Bó o bá ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, wá ọ̀nà tó o lè gbà mú kí wọ́n mọrírì àwọn ànímọ́ Jèhófà. Máa sọ bí ìdí ọpẹ́ rẹ ṣe pọ̀ tó lọ́dọ̀ Ọlọ́run fún wọn. Ran ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti máa ronú nípa bó ṣe lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Lékè ohun gbogbo, ìfẹ́ fún Jèhófà á mú kí àwọn èèyàn àtàwa fúnra wa máa ṣe ìgbọràn sí I látọkàn wá.—Mát. 22:37.
4. (a) Kí nìdí tí àpẹẹrẹ tá à ń fi lélẹ̀ fi ṣe pàtàkì? (b) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká bàa lè ní “ọkàn-àyà ìgbọràn”?
4 Nípasẹ̀ Àpẹẹrẹ Wa: Àpẹẹrẹ tá à ń fi lélẹ̀ tún jẹ́ ọ̀nà pàtàkì míì tá a lè gbà fún àwọn ẹlòmíràn ní ìṣírí láti ṣègbọràn sí ìhìn rere. Àmọ́, a ní láti máa sapá nígbà gbogbo ká bàa lè ní “ọkàn-àyà ìgbọràn.” (1 Ọba 3:9; Òwe 4:23) Àwọn nǹkan wo gan-an ló wé mọ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀? Máa foúnjẹ tẹ̀mí bọ́ ọkàn rẹ nípa ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti lílọ sí ìpàdé déédéé. (Sm. 1:1, 2; Héb. 10:24, 25) Àwọn tí ìjọsìn tòótọ́ ti mú kí ọkàn wọn ṣọ̀kan ni kó o máa bá kẹ́gbẹ́. (Òwe 13:20) Máa lọ sóde ẹ̀rí déédéé, kó o sì máa ní in lọ́kàn pé ńṣe lo fẹ́ láti ran àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù rẹ lọ́wọ́. Gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà kó bàa lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní ọkàn tó dára. (Sm. 86:11) Máa sá fáwọn nǹkan tó lè ba ọkàn rẹ jẹ́, bí eré ìnàjú oníwà pálapàla tàbí oníwà ipá. Máa lépa àwọn nǹkan tí yóò mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run tí yóò sì mú kó o túbọ̀ ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀.—Ják. 4:7, 8.
5. Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń bùkún àwọn tó jẹ́ onígbọràn?
5 Jèhófà mú un dá àwọn èèyàn rẹ̀ ìgbàanì lójú pé òun á mú ìbùkún wá sórí wọn bí wọ́n bá fetí sí ohùn òun. (Diu. 28:1, 2) Bákan náà lónìí, Jèhófà ń rọ̀jò ìbùkún sórí “àwọn tí ń ṣègbọràn sí i gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso.” (Ìṣe 5:32) Nítorí náà, lọ́nà tá a gbà ń kọ́ni àti nípasẹ̀ àpẹẹrẹ tá à ń fi lélẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti máa ṣègbọràn látọkànwá.