Ṣóòótọ́ Ni Wọ́n Pẹ́ Tó Bẹ́ẹ̀ Láyé?
A rí i kà nínú Bíbélì pé gbogbo ọdún tí Ádámù lò láyé jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé ọgbọ̀n [930], ti Sẹ́ẹ̀tì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé méjìlá [912], ti Mètúsélà sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún ó dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n [969]! (Jẹ́nẹ́sísì 5:5, 8, 27) Ṣé gígùn ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọdún yẹn tó ohun tá à ń kà sí ọdún kan lónìí ṣá, àbí wọ́n kéré sí i, bóyá ọ̀kan náà tiẹ̀ ni wọ́n jẹ́ pẹ̀lú àwọn oṣù ọlọ́gbọ̀n-ọjọ́ tá à ń lò lónìí báwọn kan ṣe ń sọ?
Ẹ̀rí tó wà nínú Bíbélì fi hàn pé gígùn ọdún tí wọ́n lò láyé ò yàtọ̀ sí tòde òní. Àpẹẹrẹ kan rèé: Ká sọ pé oṣù ọlọ́gbọ̀n-ọjọ́ tá à ń lò lónìí lọdún tí Ọlọ́run sọ pé wọ́n lò túmọ̀ sí ni, a jẹ́ pé Kénánù ì bá ti bímọ nígbà tó ṣì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà, Máhálálélì àti Énọ́kù ì bá sì ti bímọ nígbà tí wọ́n lé díẹ̀ lọ́mọ ọdún márùn-ún.—Jẹ́nẹ́sísì 5:12, 15, 21.
Àti pé, àwọn tó gbáyé nígbà tá à ń sọ yìí mọ̀ pé ìyàtọ̀ wà láàárín ọjọ́, oṣù àti ọdún. (Jẹ́nẹ́sísì 1:14-16; 8:13) Kódà, àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tí Nóà kọ sílẹ̀ ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti pinnu bí oṣù kọ̀ọ̀kan ṣe gùn tó. Bá a bá fi Jẹ́nẹ́sísì 7:11, 24 wéra pẹ̀lú Jẹ́nẹ́sísì 8:3, 4, a óò rí i pé oṣù márùn-ún ló wà láàárín ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì sí ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù keje. Àròpọ̀ oṣù márààrún sì jẹ́ àádọ́jọ ọjọ́ [150]. Ó dájú nígbà náà pé nínú àkọsílẹ̀ Nóà, ọgbọ̀n ọjọ́ ló wà nínú oṣù kan, méjìlá irú oṣù bẹ́ẹ̀ ló sì para pọ̀ di ọdún kan.—Jẹ́nẹ́sísì 8:5-13.a
Àmọ́ kí ló jẹ́ káwọn èèyàn lè gbé tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900] ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ láyé? Bíbélì sọ fún wa pé Ọlọ́run dá èèyàn kó lè máa wà láàyè títí láé ni. Ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ló fa àìpé, ìyẹn ló sì fà á táráyé fi ń kú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17; 3:17-19; Róòmù 5:12) Ọlọ́run dá Ádámù ní pípé, àwọn tó gbé láyé ṣáájú Ìkún-omi sì sún mọ́ ìgbà tiẹ̀ ju àwa tá à ń gbé láyé lóde òní lọ, ìyẹn sì ni olórí ohun tó fà á tí wọ́n fi pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ kí wọ́n tó kú. Bí àpẹẹrẹ, ìran méje péré ló wà láàárín Ádámù àti Mètúsélà.—Lúùkù 3:37, 38.
Láìpẹ́ láìjìnnà, Jèhófà Ọlọ́run á fòpin sí ohun yòówù kí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ti fà fún gbogbo àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi. Bíbélì ti sọ̀rọ̀ tán, ó ní: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 6:23) Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbà kan ń bọ̀ tí gbogbo ẹgbẹ̀rún ọdún ó dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n [969] ti Mètúsélà lò láyé á dà bí ìgbà téèyàn kàn pajú pẹ́!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo gbédègbẹ́yọ̀ Insight on the Scriptures, Apá Kejì, ojú ìwé 1214, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
[Graph tó wà ní ojú ìwé 24]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
1000
Mètúsélà
Ádámù
Sẹ́ẹ̀tì
900
800
700
600
500
400
300
200
100
Ibi tọ́jọ́ orí já wálẹ̀ dé